Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORI KẸJỌ—LUTHER NIWAJU ÌGBÌMỌ

    Ọba miran, Charles V, gun ori itẹ ni Germany, awọn aṣoju Romu si yara kankan lọ ki ku oriire, wọn rọ ọba naa lati lo agbara rẹ lati tako iṣẹ Atunṣe. Ni ọna keji, afọbajẹ ti Saxony, ẹni ti o ran Charles lọwọ jọjọ lati de ori ipo, rọ ọ ki o maṣe gbe igbesẹ kankan lati tako Luther titi ti yoo fi gbọ ti ẹnu rẹ. Bayi ni a ṣe fi ọba naa sinu ipo isoro ati idamu nla. Ko si ohun ti o le tẹ awọn atẹle popu lọrun ayafi ki ọba o ṣe idajọ iku fun Luther. Afọbajẹ naa si sọ wipe, “ko si ẹnikẹni, ati ọba pẹlu ti o ti fihan wipe awọn akọsilẹ Luther ko tọna;” nitori naa, o beere ki “a fun Luther ni iwe idaabobo, ki o baa le fi ara han niwaju igbimọ onidajọ ti wọn jẹ ọmọwe, olufọkansin, ti wọn ki i si i ṣe oju isaju.”ANN 63.1

    Gbogbo eniyan wa fiyè si ipade awọn ipinlẹ Germany ti a pe si Worms, ni kete lẹyin ti Charles gun ori itẹ ijọba naa. Awọn ọrọ oṣelu ti wọn ṣe pataki wà ti igbimọ yii yoo gbe yẹwo; fun igba akọkọ awọn ijoye Germany yoo pade ọba wọn ti o jẹ ọdọ yii ni ipade apero. Awọn ijoye ijọ ati ti ilu wá lati ibi gbogbo ni ilẹ naa. Awọn alaṣẹ ilu, awọn ẹni ti a bi ni ile ọlọrọ, awọn alagbara, ti wọn n daabo bo ohun ajogunba wọn; awọn alufa ọlọla fi ara han ninu ipo ọla ati agbara wọn; awọn ijoye ti wọn tun jẹ jagunjagun, ati awọn ti n gbe ohun ìjà wọn; ati awọn aṣoju lati ilẹ ajeji ati ilẹ jijina,— gbogbo wọn ni wọn pejọ pọ si Worms. Sibẹ ninu igbimọ nla naa, ẹni ti gbogbo awọn eniyan fi oju si lara julọ ni Alatunṣe ti Saxony.ANN 63.2

    Charles ti sọ fun afọbajẹ naa lati mu Luther dani wa si Igbimọ naa pẹlu rẹ, o si fun ni idaniloju idaabobo, ati ileri lati ṣe ijiroro laisi idiwọ, pẹlu awọn ti wọn da ara wọn loju, lori ọrọ ti o wa nilẹ yii. Ọkan Luther n poruuru lati fi ara han niwaju ọba. Ailera ti n ba ni akoko yii; sibẹ, o kọwe si afọbajẹ naa wipe: “Bi n ko ba le lọ si Worms pẹlu ilera ti o péye, a yoo gbe mi lọ sibẹ pẹlu bi mo ti ṣe jẹ alailera yii. Nitori bi ọba ba n pemi, n ko gbọdọ jiyan wipe ipe Ọlọrun funra Rẹ ni. Bi wọn ba fẹ lati wu iwa ipa si mi, eyi si ṣe e ṣe daradara, (nitori ki i ṣe fun ikilọ wọn ni wọn fi paṣẹ fun mi pe ki n wa), mo fi ọrọ naa si ọwọ Oluwa. Ẹni ti O pa awọn ọdọmọkunrin mẹta nì mọ ninu ina ileru si wa laaye sibẹ, O si n jọba. Bi ko ba ni gbami silẹ, ẹmi mi ko ṣe pataki. E saa maṣe jẹ ki iyinrere o di ohun ẹgan ni oju awọn eniyan buburu, ki ẹ si jẹ ki a ta ẹjẹ wa silẹ ki wọn ma baa bori. Ki i ṣe fun mi lati yan boya iwalaaye mi tabi iku mi yoo ran igbagbọ awọn eniyan lọwọ julọ. . . . Ẹ maa reti ohunkohun lati ọdọ mi. . . ayafi sisa kuro ninu ewu, ati ìkó-ọrọ-ẹni-jẹ. Ni sisa n ko le salọ, bẹẹ si ni n ko le ko ọrọ mi jẹ.”ANN 63.3

    Bi iroyin ti tan kalẹ ni Worms wipe Luther yoo fi ara han niwaju Igbimọ, gbogbo ilu ba ru soke. Ẹnu ya Aleander, aṣoju popu ti a gbe ọrọ naa le lọwọ, o si binu. O ri wipe ayọrisi rẹ yoo ko ijamba ba iṣẹ ijọ padi. Lati ṣe iwadi si ọran ti popu ti ṣe idajọ idalẹbi le lori yoo ko ẹgan ba aṣẹ popu. Siwaju si o bẹru wipe iṣọwọsọrọ, ati iṣọwọronu ọkunrin yii, eyi ti o lagbara, le yi ọpọlọpọ ọkan pada kuro ninu iṣẹ popu. Nitori naa, o yara kankan ba Charles sọrọ lati tako bi Luther ti ṣe fẹ fi ara han ni Worms. Ni aarin akoko yii ni a gbe aṣẹ ti o yọ Luther kuro ninu ijọ jade; eyi pẹlu bi aṣoju naa ti gbe ọrọ naa kalẹ, mu ki ọba naa o gbọ ti rẹ. O kọwe si afọbajẹ naa wipe, bi Luther ko ba ni yi ọrọ rẹ pada, ki o duro ni Wittenberg.ANN 63.4

    Aṣeyọri yii ko tẹ lọrun, Aleander ṣiṣẹ pẹlu gbogbo agbara ati arekereke ti o wa ni ikawọ rẹ lati ri wipe a da Luther lẹbi. Pẹlu iforiti ti o yẹ fun iṣẹ ti o ni itumọ, o pe akiyesi awọn ijoye, alufa agba, ati awọn ọmọ igbimọ miran si ọrọ yii, o si n fi ẹsun “iyapa, iṣọtẹ, iwa aiwabiọlọrun, ati ọrọ odi” kan Alatunṣe naa. Ṣugbọn agbara ati itara ti aṣoju naa fi ṣe iṣẹ yii fi iru ẹmi ti o n lo o han kedere. Ohun ti gbogbo eniyan n sọ ni wipe, “Ẹmi ikorira ati ẹmi igbẹsan ni o n lo o, ki i ṣe ẹmi itara ati ifọkansin rara.” Ọpọlọpọ awọn ọmọ igbimọ naa tun wa ni ife lati fi oju rere wo iṣẹ Alatunṣe naa si.ANN 63.5

    Pẹlu itara ti o gbona si, Aleander ran ọba leti ojuṣe rẹ lati mu aṣẹ popu ṣe. Ṣugbọn ni abẹ ofin Germany, a ko le ṣe eyi laiṣe wipe awọn ijoye fi ọwọ si; nigbati inilara aṣoju yii bo o mọlẹ, Charles sọ fun wipe ki o gbe ọrọ rẹ wa siwaju igbimọ. “Ọjọ nla ni o jẹ fun aṣoju popu naa. Agbajọ naa tobi: ṣugbọn idi ti wọn fi pejọ pọ tobi ju u lọ. Aleander ni agbẹnusọ fun Romu, . . . ìyá ati adari gbogbo awọn ijọ.” Yoo wi awijare fun ipo Peteru niwaju gbogbo awọn ijoye inu ẹsin Kristẹni. “O ni ẹbun ọrọ sisọ, imura rẹ si ba bi iṣẹlẹ naa ti tobi to mu. Agbara Ọlọrun dari Romu lati fi ara han ki o si sọrọ nipasẹ ẹni ti o dara julọ ninu awọn sọrọsọrọ rẹ niwaju igbimọ igbẹjọ pataki ti o da lẹbi yii.” Awọn ti wọn fi oju rere wo Alatunṣe naa n wo ipa ti ọrọ Aleander yoo ni pẹlu iyemeji. Afọbajẹ ti Saxony ko si nibẹ, ṣugbọn o paṣẹ fun awọn ijoye rẹ ti wọn wa nibẹ ki wọn kọ awọn ọrọ aṣoju naa silẹ.ANN 63.6

    Pẹlu gbogbo agbara ẹkọ ati ẹbun isọrọ, Aleander dide lati bi otitọ ṣubu. Lẹsẹlẹsẹ ni o n fi ẹsun kan Luther gẹgẹ bi ọta ijọ ati ilu, oku ati alaaye, awọn alufa ati ọmọ ijọ, awọn igbimọ ati ti awọn Kristẹni lasan. O sọ wipe, “Awọn aṣiṣe Luther pọ to bẹẹ gẹẹ” ti o le mu ki a sun “ẹgbẹrun lọna ọgọrun ẹlẹkọ odi nina.”ANN 64.1

    Ni akotan o ṣe akitiyan lati kẹgan awọn ti wọn gbagbọ ninu igbagbọ ti a tunṣe naa: “Kini awọn atẹle Luther wọnyi jamọ? Ẹgbẹ awọn olukọ alafojudi, awọn alufa oniwa ibajẹ, awọn ajẹjẹ ẹsin ti n wuwa aimọ, awọn amofin alaimọkan, ati awọn ijoye ti a ti yọ nipo, pẹlu awọn ara ilu ti wọn ti ṣi lọna kuro ninu ohun ti o tọna. Ẹgbẹ ijọ Katoliki ti ju wọn lọ tó ni iye, ipá, ati agbara! Aṣẹ ajumọṣe kan lati inu igbimọ nla yii yoo la awọn òpè lọyẹ, yoo ki awọn ọlọgbọn nilọ, yoo jẹ ki awọn oniyemeji o ṣe ipinu wọn, yoo si fun awọn alailagbara ni okun.”ANN 64.2

    Pẹlu iru awọn ohun ija yii ni a fi maa n kọlu awọn ti n waasu otitọ ni igba gbogbo. Iru iṣọwọronu kan naa ni a si n lo lati tako awọn ti wọn ba ni igboya lati waasu ọrọ Ọlọrun ni ailabawọn ni atako si awọn èké ti a ti fi idi wọn mulẹ. Awọn ti wọn ni ifẹ si ẹsin ti o gbajugbaja n sọ wipe, “Awọn wo ni wọn n waasu ikọni tuntun yii?” Wọn ko kàwé, wọn kere niye, wọn ko si ni ọrọ. Wọn sọ wipe wọn ni otitọ, ati wipe Ọlọrun ni o yan wọn. Wọn jẹ alaimọkan, a si n tan wọn jẹ. Ijọ wa ti pọ to ni iye, o si ti ni agbara to! Awọn ẹni nla ati ọmọwe ti pọ ni aarin wa tó! Agbara ti o wa ni ọdọ wa ti pọ tó!” Awọn iṣọwọronu wọnyi n ni agbara lori aye; ṣugbọn wọn ko ni itumọ ni ode oni gẹgẹ bi wọn ko ti ṣe ni itumọ ni akoko Alatunṣe naa.ANN 64.3

    Iṣẹ Atunṣe naa ko pari pẹlu Luther gẹgẹ bi ọpọlọpọ ti rò. Yoo tẹsiwaju titi di opin aye yii. Luther ni iṣẹ nla lati ṣe ni titan imọlẹ ti Ọlọrun jẹ ki o tan si sí awọn miran; sibẹ ko gba gbogbo imọlẹ ti o yẹ ki a fun araye. Lati akoko naa titi di isinsinyii, imọlẹ tuntun si n tan si inu Iwe Mimọ, awọn otitọ tuntun si n tan sita nigba gbogbo.ANN 64.4

    Ọrọ aṣoju yii ni ipa ti o pọ lori igbimọ naa. Ko si Luther nibẹ, lati ṣẹgun olugbeja popu pẹlu otitọ ọrọ Ọlọrun ti o da ṣaka, ti ko si ni abawọn. A ko ṣe akitiyan kankan lati gbeja Alatunṣe naa. O dabi ẹnipe gbogbo wọn ni ifẹ si, ki i ṣe lati da lẹbi pẹlu awọn ohun ti o fi kọni nikan, ṣugbọn bi o ba ṣe e ṣe lati fa ẹkọ odi naa tu. Romu ti jẹ anfani ti o dara julọ lati gbeja ara rẹ. Gbogbo awijare ti o le ṣe nipa ara rẹ ni o ti ṣe. Ṣugbọn ohun ti o fi ara han gẹgẹ bi iṣẹgun jẹ ami ibaku. Lati akoko yii lọ, a yoo tubọ ri kedere si iyatọ ti o wa ni aarin otitọ ati èké bi wọn ti n wọya ija ni ojutaye. Lati igba naa lọ, ọkan Romu ko le balẹ bi i ti tẹlẹ mọ.ANN 64.5

    Nigba ti ọpọ awọn ọmọ igbimọ naa ko ni lọra lati fi Luther lé igbẹsan Romu lọwọ, ọpọlọpọ wọn ni wọn ri, ti inu wọn ko si dun si iwa ibajẹ ti o wa ninu ijọ, ti wọn si n fẹ ki ìyà ti awọn ara Germany n jẹ nitori iwa ibajẹ ati ojukokoro ijọ o dinku. Aṣoju naa ti fi iṣakoso popu han ni ọna ti o dara julọ. Bayi, Ọlọrun wa mi si ọkan lara awọn ọmọ igbimọ naa lati ṣe alaye ododo nipa awọn ayọrisi iwa onroro popu. Pẹlu iduroṣinṣin ti o yẹ ipo rẹ, Duke George ti Saxony dide laarin awujọ awọn ijoye naa, o si ṣe alaye kikun nipa awọn itanjẹ ati iwa èérí ẹsin popu, ati ayọrisi buburu ti wọn ni. Ni ipari, o sọ wipe: “Ara awọn iwa ibajẹ ti wọn n kigbe tako Romu ni iwọnyi. A ti pa gbogbo itiju ti si ẹgbẹ kan, ohun kan ṣoṣo ti wọn n wa ni . . . owó, owó, owó, . . . to bẹẹ gẹẹ ti oniwaasu ti o yẹ ki o kọni ni otitọ ko sọ ohun miran ayafi èké, ki i si i ṣe wipe a n fi ara da wọn nikan, ṣugbọn a n fun wọn ni ẹbun, nitori bi irọ wọn ba ti ṣe pọ to, bẹẹ ni ẹbun wọn yoo ti pọ to. Lati inu orisun yii ni omi idọti ti n san jade. Iwa ibajẹ laisi ikora ẹni nijanu n na ọwọ rẹ si ifẹ owo. . . . O maṣe o, awọn iwa ibajẹ ti awọn alufa n wu ni o n sọ ọpọlọpọ ọkan sinu ijiya ayeraye. A nilati ṣe atunṣe gbogboogbo.”ANN 64.6

    Luther funra rẹ ko le sọ awọn ọrọ ti o tobi ju eyi lọ nipa awọn iwa ibajẹ popu; nitori pe ẹni ti o sọ ọrọ yii tun jẹ ọta pọnbele Alatunṣe naa tun jẹ ki awọn ọrọ rẹ o ni agbara si.ANN 65.1

    Bi a ba ṣi awọn eniyan inu awujọ naa loju ni, wọn i ba ri awọn angẹli Ọlọrun laarin wọn, ti wọn n tan imọlẹ lati bi okunkun irọ pada, ti wọn si n ṣi iye ati ọkan awọn eniyan silẹ lati gba otitọ. Agbara Ọlọrun otitọ ati ọgbọn ni o dari, ani, awọn ọta iṣẹ atunṣe, ti o si pese ọna silẹ fun iṣẹ nla ti a fẹ ṣe. Martin Luther ko si nibẹ; ṣugbọn a gbọ ohùn Ẹni ti O tobi ju Luther lọ ninu igbimọ naa.ANN 65.2

    Loju ẹsẹ, apero naa yan igbimọ alabẹṣekele kan lati ṣe akọsilẹ awọn inilara popu ti wọn di ẹru wuwo le awọn ara Germany lori. Ọpọlọpọ nnkan ni wọn kọ silẹ, ti wọn si fi le ọba lọwọ, pẹlu ẹbẹ wipe ki o yara kankan lati ṣe atunṣe si awọn aṣeju wọnyi. Awọn onkọwe naa sọ wipe, “Ẹ wo adanu nla si ọkan awọn Kristẹni, ẹ wo ikonilẹrùlọ, ẹ wo ilọnilọwọgba, nitori awọn ẹsun iwa ibajẹ ti wọn yi Olori ẹsin Kristẹni ka! Ojuṣe wa ni lati maṣe jẹ ki iparun ati itiju o de ba awọn eniyan wa. Nitori idi eyi, a fi tọwọtọwọ, ṣugbọn pẹlu ikanju rọ ọ lati paṣẹ atunṣe gbogboogbo, ki o si ri wipe o di ṣiṣe.”ANN 65.3

    Igbimọ naa wa fẹ ki Alatunṣe naa o fi ara han niwaju wọn. Pẹlu gbogbo ẹbẹ, ẹhonu, ati ihalẹ Aleander, ọba fi ọwọ si nikẹyin, a si pe Luther lati wa fi ara han niwaju igbimọ. A fi iwe idaabobo ti o fi da loju wipe yoo pada si ibi aabo ranṣẹ pẹlu ipe yii. Ojiṣẹ kan ti a ran lati mu wa si Worms ni o ko wọn wa si Wittenberg.ANN 65.4

    Ẹru ba awọn ọrẹ Luther, ọkan won si poruuru. Wọn mọ iru ẹtanu, ati ikorira ti wọn ni si, wọn bẹru wipe wọn le ma nani iwe idaabobo, wọn si rọ ọ ki o maṣe fi ẹmi rẹ wewu. O da wọn lohun: “Awọn atẹle popu ko fẹ ki n wa si Worms, ohun ti wọn fẹ ni idalẹbi ati iku mi. Ko si nitumọ. Ẹ maṣe gbadura fun mi, bikoṣe fun ọrọ Ọlọrun. . . . Kristi yoo fun mi ni Ẹmi Rẹ lati bori awọn iranṣẹ irọ wọnyi. Mo korira wọn ni igba aye mi; maa si bori wọn nipasẹ iku mi. Wọn n ṣiṣẹ ni Worms lati le fi ipa mumi yi ọrọ mi pada; eyi ni yoo si jẹ ìyí-ọrọ-padà mi: Mo sọ tẹlẹ wipe popu ni aṣoju Kristi; nisinsinyi, mo gbagbọ wipe oun ni ọta Oluwa wa, ati apostoli eṣu.”ANN 65.5

    Luther ko danikan rin irin ajo ti o lewu yii. Yatọ si iranṣẹ ọba, awọn mẹta ninu awọn ọrẹ rẹ ti wọn duro ṣinṣin julọ ni wọn tẹle. Melancthon si fẹ lati tẹle wọn. Ọkan rẹ ti so pọ mọ ti Luther, o si fẹ lati tẹle, bi o ba ṣe e ṣe, si ọgba ẹwọn, tabi si iku. Ṣugbọn a ko gba a laaye. Bi Luther ba ku, ireti iṣẹ Atunṣe yoo wà lori ọdọ, alabaṣiṣẹpọ rẹ yii. Alatunṣe naa sọ bi o ti n kuro ni ọdọ Melancthon wipe: “Bi n ko ba pada, ti awọn ọta mi si pa mi, tẹsiwaju lati maa kọni, ki o duro gbọin ninu otitọ. Maa ṣiṣẹ ni ipo mi. . . . Bi o ba wa laaye, iku mi ki yoo jamọ nnkankan.” Ibanujẹ bo awọn akẹkọ ati awọn ara ilu ti wọn pejọ pọ lati wo bi Luther ti n lọ. Ọpọlọpọ awọn eniyan ti iyinrere ti fi ọwọ ba lọkan, ki i pe o digboṣe pẹlu ẹkun. Alatunṣe naa si bẹrẹ irin ajo rẹ lati Wittenberg.ANN 65.6

    Ni oju ọna, o ri wipe ohun buburu ti o le ṣẹlẹ ko ibanujẹ ba awọn eniyan. Ninu awọn ilu miran, a bu ọla fun wọn. Bi wọn ti duro lati sun, alufa kan ti o jẹ ọrẹ wọn fi ibẹru rẹ han nipa fifi aworan alatunṣe ara Italy ti o jiya ijẹriku han Luther. Ni ọjọ keji, wọn gbọ wipe ati ṣe ofin wipe awọn iwe Luther ko dara ni Worms. Awọn iranṣẹ ọba n kede aṣẹ ọba, wọn n pe gbogbo eniyan lati ko awọn iṣẹ ti a ko gba laaye naa wa si ọdọ awọn alaṣẹ ilu. Iranṣẹ ọba naa bẹru boya Luther yoo ni aabo ninu igbimọ naa; o ro boya ẹru le maa ba a, o beere boya o si fẹ lati tẹsiwaju. O dahun wipe: “Bi a ba tilẹ le mi kuro ni gbogbo ilu, maa tẹsiwaju.”ANN 65.7

    Ni Erfurt, a tẹwọgba Luther pẹlu ẹyẹ. Awọn ero ti wọn fẹran rẹ rọgba yi ka, o kọja laarin ilu ti o ti fi igba kan la kọja ri pẹlu àpò onibara rẹ. O bẹ yara rẹ ninu ile awọn ajẹjẹ ẹsin naa wo, o si ronu lori awọn ijakadi ti wọn jẹ ki imọlẹ ti n tan si gbogbo Germany o tan si ọkan oun. A rọ ọ lati waasu. A ti paṣẹ fun lati maṣe ṣe eyi, ṣugbọn iranṣẹ ọba fun ni aaye, alufa onibara, ti o ti fi igba kan ri jẹ ẹni ti o n ṣe iṣẹ ti o n yẹpẹrẹ ẹni ni ile awọn ajẹjẹ ẹsin, wa gun ori pẹpẹ iwaasu.ANN 66.1

    O sọ lati ara awọn ọrọ Kristi, “Alaafia fun yin” si awọn eniyan. O sọ wipe: “Awọn elero ijinlẹ, ọmọwe, ati onkọwe ti ṣe akitiyan lati kọ awọn eniyan ni ọna lati le ri iye ainipẹkun, wọn ko ṣe aṣeyege. Emi wa n sọ fun yin: . . . Ọlọrun ji Ọkunrin kan dide kuro ninu ipo oku, Jesu Kristi Oluwa, ki O baa le pa iku run, ki O le mu ẹṣẹ kuro, ki O si ti ilẹkun ọrun apaadi. Eyi ni iṣẹ igbala. . . . Kristi ti ṣẹgun! eyi ni iroyin ayọ; a gba wa la nipa iṣẹ rẹ, ki si i ṣe nipa iṣẹ wa. . . . Jesu Kristi Oluwa wa sọ wipe, ‘Alaafia ni fun yin; ẹ kiyesi ọwọ mi;’ o tumọ si wipe, Iwọ eniyan, kiyesi i! Emi ni, ani Emi nikan, ni o ko ẹṣẹ rẹ lọ, Mo si ti ra ọ pada; nitori naa iwọ ni alaafia, ni Oluwa wi.”ANN 66.2

    O tẹsiwaju lati fihan wipe igbagbọ tootọ yoo fi ara han ninu igbesi aye mimọ. “Niwọn igba ti Ọlọrun ti gba wa la, ẹ jẹ ki awa pẹlu o ṣe iṣẹ wa ni ọna ti yoo fi jẹ itẹwọgba ni ọwọ re. Njẹ iwọ jẹ ọlọrọ bi? lo ọrọ rẹ fun awọn alaini. Njẹ iwọ jẹ alaini bi? jẹ ki iṣẹ rẹ o ṣe itẹwọgba ni ọwọ awọn ọlọrọ. Bi o ba jẹ wipe iwọ nikan ni iṣẹ rẹ wulo fun, irọ patapata ni iṣẹ ti iwọ n ro wipe o n ṣe fun Ọlọrun.”ANN 66.3

    Awọn eniyan naa fi eti silẹ, afi bi ẹnipe a fi àbo mu wọn. A bu akara iye fun ọkan ti ebi n pa. A gbe Kristi ga ju awọn popu, alufa, ọba ati awọn alaṣẹ lọ. Luther ko sọ nipa ipo ewu ti o wa. Ko fẹ ki gbogbo eniyan o maa ro nipa oun tabi ki wọn maa ṣe ikaanu fun oun. O gbagbe ara rẹ nipa riro nipa Kristi. O fi ara rẹ pamo si ẹyin Ọkunrin Kalfari, afojusun rẹ kan ṣoṣo ni lati waasu Jesu, Olurapada ẹlẹṣẹ.ANN 66.4

    Bi Alatunṣe naa ti n lọ ninu irin ajo rẹ, ibi gbogbo ni a ti n fi tiyanutiyanu wo o. Ọpọ ero ni wọn yii ka ti awọn ọrẹ rẹ si n ki i nilọ nipa erongba awọn ẹlẹsin Romu. Awọn kan sọ wipe, “Wọn yoo sun ọ nina, wọn a sọ ọ di eeru bi wọn ti ṣe si John Huss.” Luther dahun wipe: “Bi wọn tilẹ da ina lati Worms de Wittenberg, ti o si jó ga de ọrun, emi yoo la a kọja ni orukọ Oluwa; maa fi ara han niwaju wọn; maa wọ ẹnu ẹranko buburu yii lọ, maa kan an ni eyín, maa si jẹwọ Jesu Kristi Oluwa.”ANN 66.5

    Iroyin wipe Alatunṣe naa ti de si Worms fa irọkẹkẹ nla. Awọn ọre rẹ bẹru nitori aabo rẹ; awọn ọta rẹ si bẹru nitori aṣeyọri iṣẹ wọn. A ṣa ipa kikankikan lati rọ ọ ki o maṣe wọ inu ilu naa. Awọn atẹle popu ran awọn eniyan si ti wọn gba a niyanju lati lọ si ile iṣọ ijoye ti o jẹ ọrẹ rẹ kan, nibi ti a ti le pari gbogbo wahala naa ni tubi inubi. Awọn ọrẹ rẹ n gbiyanju lati ru ibẹru rẹ soke nipa ṣiṣe alaye ewu ti o le wu u. Gbogbo akitiyan wọn ni o baku. Luther, laimikan, sọ wipe: “Bi awọn ẹmi eṣu ba le pọ ni Worms bi awọn àwo ìbolé, emi yoo si wọ inu rẹ lọ.”ANN 66.6

    Nigba ti o de Worms, ọpọ ero ni wọn pejọ pọ lati ki kaabọ. Iru awọn ero bayi ko pejọ pọ lati wa ki ọba funra rẹ. Irọkẹkẹ gba ilu kan, ohùn kan si n kọ orin arò laarin awọn ero gẹgẹ bi ikilọ nipa ohun ti o n duro de Luther. Ṣugbọn “Ọlọrun yoo jẹ aabo mi” ni o sọ jade lẹnu bi o ti n sọkalẹ lati inu kẹkẹ ti a fi gbe.ANN 66.7

    Awọn atẹle popu ko gbagbọ wipe Luther yoo wa si Worms, ipaya si ba wọn nigba ti o de. Ọba yara pe awọn ijoye rẹ lati jiroro nipa ohun ti wọn yoo ṣe. Biṣọbu kan, atẹle popu tọkantọkan, sọ wipe: “A ti jiroro lori ọrọ yii pẹ ju. Jẹ ki ọba o pa ọkunrin yii ni kiakia. Ṣebi Sigismund jẹ ki a pa John Huss? A ko ni ojuṣe lati fun ẹlẹkọ odi ni iwe idaabobo, tabi ki a bọwọ fun eyi ti o ni.” Ọba dahun wipe, “Rara, a nilati mu ileri wa ṣe.” Nitori naa, a sọ wipe a nilati gbọ ti ẹnu Alatunṣe naa.ANN 66.8

    Gbogbo ilu naa ni wọn fẹ lati ri ọkunrin pataki yii. Ọpọ awọn alejo ni wọn si rọ wa si ile rẹ. Ara Luther ṣẹṣẹ n ya bọ ni lati inu aisan ti o n ṣe e; irin ajo ti o rin fun ọsẹ meji gbako si ti jẹ ki o rẹ ẹ. O nilati mura silẹ fun iṣẹlẹ pataki ti yoo ṣẹlẹ ni ọjọ keji, nitori naa o nilo isinmi ati idakẹjẹ. Ṣugbọn ifẹ awọn eniyan lati ri pọ tobẹẹ gẹẹ ti o fi jẹ wipe akoko kekere ni o ni lati fi sinmi, nigba ti awọn ijoye, jagunjagun, alufa, ati awọn ọmọ ilu pejọ pọ yii ka. Ọpọ ninu awọn ijoye ti wọn fi igboya beere ki ọba o ṣe atunṣe si awọn aṣeju inu ijọ wa ninu awọn wọnyi, ti Luther si sọ wipe “gbogbo wọn ni wọn ti ri ominira nitori iyinrere mi.” Awọn ọrẹ ati ọta ni wọn wa lati wa wo alufa onigboya naa, ṣugbọn o tẹwọ gba wọn ni aimikan, o si da wọn lohun pẹlu ifọkanbalẹ ati ọgbọn. O duro gbọin pẹlu igboya. Oju rẹ ti o tinrin ti o si ru nitori wahala ati aisan, fi aanu ati ayọ han. Ọwọ ati itara ọrọ rẹ fun ni igboya ti awọn ọta rẹ ko le dojukọ. Ẹnu ya awọn ọta ati ọrẹ lapapọ. Awọn kan gbagbọ wipe ọwọ Ọlọrun wa pẹlu rẹ; awọn miran sọ bi awọn Farisi ti sọ nipa Jesu wipe: “O ni ẹmi eṣu.”ANN 66.9

    Ni ọjọ keji, a pe Luther wa siwaju igbimọ. Iranṣẹ ọba si mu wa si gbọngan ipade; sibẹ pẹlu wahala ni o fi debẹ. Awọn oluworan ti wọn fẹ wo alufa ti o gboya lati ṣe atako si aṣẹ popu kun ibi gbogbo.ANN 67.1

    Bi o ti fẹ de iwaju awọn adajọ, jagunjagun agba kan, ẹni ti o ti ṣẹgun ọpọlọpọ ogun fi aanu sọ fun wipe: “Ajẹjẹ ẹsin alailagbara, ajẹjẹ ẹsin alailagbara, iwọ yoo ṣe ipinu ti o niyi ju eyi ti emi tabi eyikeyi ninu awọn adari ogun ti ṣe ri ninu awọn ogun wa ti wọn gbona janjan lọ. Ṣugbọn bi ọna rẹ ba jẹ ododo, ti o si da ọ loju, tẹsiwaju ni orukọ Ọlọrun, maṣe bẹru ohunkohun. Ọlọrun ko ni fi ọ silẹ.”ANN 67.2

    Lẹyin-ọrẹyin, Luther duro niwaju igbimọ. Ọba gun ori itẹ rẹ. Awọn ti wọn ṣe pataki julọ ninu ijọba naa ni wọn yi ká. Ko si ẹni ti o tii fi ara han niwaju awujọ pataki nibi ti Martin Luther ti fẹ dahun si igbagbo rẹ yii ri. “Ifarahan yii funra rẹ jẹ ami iṣẹgun lori aṣẹ popu. Popu ti da ọkunrin naa lẹbi, o wa n fi ara han niwaju igbẹjọ, ti o jẹ wipe, nipa ṣiṣe eyi, o ti gbe ara rẹ ga ju popu lọ. Popu ti yọ kuro ninu ijọ, o si ti yọ kuro ninu awujọ awọn eniyan; sibẹ ede apọnle ni a fi pe e, ti o si fi ara han niwaju igbimọ ti o ṣe pataki julọ ni agbaye. Popu ti sọ wipe ko gbọdọ sọrọ mọ titi lae, o wa fẹ sọrọ niwaju ọgọọrọ awọn eniyan ti wọn wá lati ilẹ jijina réré nibi ti wọn ti n ṣe ẹsin Kristẹni. Ayipada nla ni o ṣẹlẹ nipasẹ Luther. Romu ti n sọkalẹ kuro ni ori itẹ rẹ, ohùn ajẹjẹ ẹsin kan ni o si fa irẹsilẹ yii.”ANN 67.3

    Niwaju igbimọ alagbara ti o si lorukọ yii, ẹru ba Luther, ẹni ti a kò bi ni ile ọlọrọ, ti o si dabi ẹnipe oju ti. Diẹ lara awọn ijoye ti wọn wo bi o ti ṣe, lọ ba wọn si sọ kẹlẹkẹlẹ si leti wipe: “Maṣe bẹru awọn ti wọn le pa ara ṣugbọn ti wọn ko le pa ọkan.” Omiran sọ wipe: “Nigba ti a ba mu yin wa siwaju awọn alaṣẹ ati ọba nitori Mi, Ẹmi Baba yin yoo fun yin ni ohun ti ẹyin yoo wi.” Bayi ni awọn eniyan nla aye ṣe fi ọrọ Ọlọrun fun iranṣẹ Rẹ ni okun ninu akoko idanwo rẹ.ANN 67.4

    A gbe Luther wa si ibi ti o ti doju kọ itẹ ọba gan. Gbogbo awọn ero inu awujọ naa dakẹ jẹẹ. Iranṣẹ ọba kan wa dide, o tọka si awọn iwe Luther, o beere ki Alatunṣe naa o dahun awọn ibeere meji—boya o gba wọn gẹgẹ bi tirẹ, ati boya o fẹ lati sẹ awọn ohun ti o kọ si inu wọn. Nigba ti a ti ka akọle awọn iwe naa, Luther dahun si ibeere akọkọ wipe ohun gba awọn iwe naa gẹgẹ bi ti oun. O sọ wipe, “Ni ti ekeji, niwọn igba ti o jẹ wipe ibeere naa ni i ṣe pẹlu igbagbọ ati igbala ọkan, ti o si kan ọrọ Ọlọrun, ohun ìní ti o ṣe iyebiye, ti o tobi julọ ni ọrun ati ni aye, maa wuwa omugọ bi mo ba dahun ni aironu. Mo le ma sọ to ohun ti o yẹ ki n sọ, tabi ki n sọ ju ohun ti otitọ nilo lọ, o sile jẹ ki n ṣe si ọrọ Kristi: ‘Ẹnikẹni ti o ba sẹ Mi niwaju eniyan, òun naa ni Emi yoo sẹ niwaju Baba Mi ti n bẹ ni ọrun.‘[Matiu 10:33.] Nitori idi eyi, mo fi gbogbo irẹlẹ bẹ ọba alayeluwa, ki o fun mi ni akoko, ki n baa le fesi lai ṣẹ si ọrọ Ọlọrun.”ANN 67.5

    Luther wuwa pẹlu ọgbọn nipa bibẹ ẹbẹ yii. Iwa rẹ fi da gbogbo agbajọ naa loju wipe ki i ṣe igbonara tabi aironu ni o fi wuwa. Iru ifọkanbale ati ikora-ẹni-nijanu yii, ti a ko reti lati ọdọ ẹni ti o fi ara rẹ han gẹgẹ bi onigboya, ti ki i pa ohùn da fi kun agbara rẹ, o si ran an lọwọ lati fesi pẹlu ọgbọn, ipinu, òye, ati idara-ẹni-loju ti o ya awọn ọta rẹ lẹnu ti o si ja wọn kulẹ, ti o tun ṣe ibawi fun igberaga ati afojudi wọn.ANN 67.6

    Ni ọjọ keji, yoo fi ara han lati wa ṣe idahun ikẹyin. Fun igba diẹ, ọkan rẹ rẹwẹsi nigba ti o ronu lori awọn agbara ti wọn papọ tako otitọ. Igbagbọ rẹ mi; ibẹru ati iwariri ba, ipaya si bo o mọlẹ. Awọn ewu sọ ara wọn di pupọ niwaju rẹ; o dabi ẹnipe awọn ọta rẹ fẹ ṣẹgun, ti agbara okunkun si fẹ bori. Ikuuku bo o mọlẹ, o si dabi ẹnipe o fẹ pin niya kuro ni ọdọ Ọlọrun. O nilo idaniloju wipe Oluwa awọn ọmọ ogun yoo wa pẹlu oun. Ninu iporuuru ọkan rẹ, o dubulẹ o si kigbe awọn ẹdun ọkan rẹ sita, eyi ti ko lè yé ẹnikẹni ayafi Ọlọrun.ANN 67.7

    O bẹbẹ wipe: “Ọlọrun ayeraye alagbara, aye yii ti buru to! Kiyesi o la ẹnu rẹ lati gbemi mi, igbẹkẹle mi ninu rẹ si kéré. . . . Bi o ba jẹ wipe agbara aye yii nikan ni mo gbẹkẹle, gbogbo rẹ yoo dopin. . . . Akoko ikẹyin mi ti de, a ti ṣe idalẹbi mi. . . . Iwọ Ọlọrun ran mi lọwọ lati doju kọ gbogbo ọgbọn aye yii. Ṣe eyi, . . . Iwọ nikan ṣoṣo; . . . nitori iṣẹ yii ki i ṣe temi bikoṣe tirẹ. Emi ko ni ohunkohun lati ṣe nihin, ko si ohun ti mo le ja fun pẹlu awọn eniyan nla aye yii. . . . Ṣugbọn Iwọ ni O ni iṣẹ naa, . . . iṣẹ ododo ati iṣẹ ayeraye ni. Oluwa ran mi lọwọ! Ọlọrun olododo ti ki i yi pada, emi ko gbe igbẹkẹle mi sinu eniyan kankan. . . . Ohun gbogbo ti o jẹ ti eniyan ko daju; ohun gbogbo ti o ti ọdọ eniyan wa n baku. . . . Iwọ ti yan mi fun iṣẹ yii. . . . Duro ni ẹgbẹ mi, nitori Ayanfẹ Rẹ Jesu Kristi, Ẹni ti i ṣe aabo, asa, ati ile iṣọ agbara mi.”ANN 68.1

    Agbara Ọlọrun ọlọgbọn julọ ni o jẹ ki Luther o mọ inu ewu ti o wa, ki o ma baa gbẹkẹle agbara rẹ, ki o si yara fi aigbọn sare wọ inu ewu lọ. Sibẹ ki i ṣe ibẹru ijiya ara rẹ, tabi ibẹru ijiya, tabi iku, ti o dabi ẹni pe o de tan ni o ko ipaya ba. O ti wọ inu wahala naa, o si ri wipe oun ko kun oju oṣuwọn lati pade rẹ. Adanu le ba iṣẹ otitọ nitori ibaku rẹ. Ko ba Ọlọrun jijakadi nitori aabo ara rẹ, bikoṣe nitori iṣẹgun iyinrere. Bii Israeli, ni aṣalẹ ijakadi ni ẹba odo naa, bẹẹ ni idamu ati ibanujẹ ọkan rẹ ti ri. Bi Israeli, o si ṣẹgun pẹlu Ọlọrun. Ninu ipo ainiranlọwọ rẹ, igbagbọ rẹ di Kristi, Oludande rẹ alagbara mu. A fun ni okun pẹlu idaniloju wipe ko ni fi ara han niwaju igbimọ ni ohun nikan. Alaafia pada si ọkan rẹ, inu rẹ si dun nitori pe a fun ni anfani lati gbe ọrọ Ọlọrun ga niwaju awọn alaṣẹ orilẹ ede.ANN 68.2

    Pẹlu ọkan rẹ ti o duro si ọdọ Ọlọrun, Luther mura silẹ fun wahala ti o wa niwaju rẹ. O ronu lori bi oun yoo ti fesi, o yẹ awọn abala inu iwe rẹ wo, o si wa awọn ẹsẹ ti wọn yẹ lati inu Iwe Mimọ lati fi gbe ara rẹ lẹsẹ. O wa gbe ọwọ alaafia rẹ le ori Iwe Mimọ ti o ṣi silẹ niwaju rẹ, o si gbe ọwọ ọtun rẹ si oke ọrun, o jẹjẹ “lati jẹ olootọ si iyinrere, ati lati ṣe ijẹwọ igbagbọ rẹ laisi idiwọ, ani bi yoo ba tilẹ fi ẹjẹ rẹ ṣe edidi si ijẹri rẹ.”ANN 68.3

    Nigba ti a da pada siwaju igbimọ, oju rẹ ko fi ibẹru tabi itiju han. Ọkan rẹ balẹ, o si wa ni alaafia, sibẹ o ni igboya, o si duro pẹlu iyì, o duro gẹgẹ bi ẹlẹri Ọlọrun laarin awọn ẹni nla aye. Iranṣẹ ọba tun wa beere lọwọ rẹ boya o fẹ lati yi awọn ikọni rẹ pada. Luther dahun pẹlu ohùn jẹjẹ, laipariwo, laisi igbonara tabi irunu. Iṣesi rẹ ni ibọwọ fun, bẹẹ ni ko jọ ara rẹ loju; sibẹ o fi igboya ati ayọ ti o jọ apejọpọ naa loju han.ANN 68.4

    Luther sọ wipe, “Ọba oniwatutu julọ, ẹyin ijoye ti o gbayi, ati ẹyin oluwa oloore ọfẹ, mo fi ara han niwaju yin loni ni ibamu pẹlu aṣẹ ti ẹ fi fun mi lana, mo si rọ kabiyesi ati ẹyin eniyan pataki pẹlu oore ọfẹ Ọlọrun lati fi pẹlẹkutu tẹti si awijare si ohun ti emi gbagbọ wipe o jẹ ododo ati otitọ. Bi mo ba tasẹ agẹrẹ si ilana iwuwasi ni aafin nipa aimọkan, mo rọ yin lati fi ori ji mi; nitori pe a ko tọ mi dagba ni aafin ọba bikoṣe ni ile awọn ajẹjẹ ẹsin.”ANN 68.5

    Lẹyin eyi, o wa tẹsiwaju lati dahun ibeere ti a bí; o sọ wipe awọn iwe wọnyi ko jẹ ohun kan naa. Ninu awọn kan, o sọ nipa igbagbọ ati iṣẹ rere, ani awọn ọta rẹ sọ wipe wọn ko lewu, ṣugbọn wọn dara. Lati yi awọn nnkan wọnyi pada yoo jasi titako otitọ ti gbogbo eniyan fi ọwọ si. Awọn keji ní awọn ikọni ti wọn ṣe afihan awọn iwa ibajẹ ati aṣeju ilana popu ninu. Lati yi awọn wọnyi pada yoo tumọ si fifun iwa onroro Romu lokun ti yoo si ṣi ilẹkun silẹ si fun ọpọlọpọ awọn iwa aitọ miran. Ninu awọn isọri iwe rẹ kẹta, o tako awọn eniyan ti wọn wi awijare nipa awọn iwa ibi wọnyi. Nipa awọn wọnyi, o sọ wipe oun ti wu iwa ipa ju bi o ti yẹ lọ. Ko sọ wipe oun ko ni aṣiṣe rárá; ṣugbọn oun ko le sẹ awọn iwe wọnyi paapa, nitori ṣiṣe bẹẹ yoo ki awọn ọta otitọ laya, wọn yoo si ri anfani lati fi iya jẹ awọn eniyan Ọlọrun si.ANN 68.6

    O tẹsiwaju wipe, “Sibẹ eniyan ni mi, mi ki i ṣe Ọlọrun; maa wa wi awijare nipa ara mi gẹgẹ bi Kristi ti ṣe: Bi mo ba ti sọ ohun buburu, tabi ti mo jẹri si ohun buburu, mo rọ ọba oniwatutu julọ ati gbogbo ẹyin ijoye ọlọla ati gbogbo ẹyin eniyan pẹlu aanu Ọlọrun lati fihan lati inu awọn akọsile awọn woli ati apostoli ibi ti mo ti ṣe aṣiṣe. Ni kete ti mo ba ti ri eyi, maa kọ gbogbo aṣiṣe silẹ, n o si jẹ ẹni akọkọ ti yoo ko awọn iwe wọnyi, ti n o si da wọn sinu ina.ANN 69.1

    “Mo ni ireti wipe ohun ti mo sẹsẹ sọ tan yii fihan wipe mo ti gbe awọn ewu ti mo fi ara mi si yẹwo finifini; ṣugbọn dipo ki aya o fo mi, inu mi dun ni nitori pe, bii ti igba iṣaaju, iyinrere di okunfa wahala ati iyapa, gẹgẹ bi a ti ri loni yii. Bi ọrọ Ọlọrun ati atubọtan rẹ ti ri niyii. ‘Mo wa, ki i ṣe lati ran alaafia wa si aye, bikoṣe ida’ ni Jesu Kristi wi. Ọlọrun jẹ oniyanu, O si ni ẹru ninu imọran Rẹ; ẹ ṣọra nitori nipa rírò lati pa ina iṣọtẹ, ki ẹ ma baa ṣe inunibini si ọrọ mimọ Ọlọrun, ki ẹ ma si ṣe ko idamu wahala ti ẹ ko le bori, ni ajalu ti isinsinyi, ati iparun ayeraye si ori ara yin. . . . Mo le sọ ọpọlọpọ apẹẹrẹ lati inu ọrọ Ọlọrun. Mo le sọ nipa Farao, awọn ọba Babiloni, ati ti Israeli, ti iṣe wọn ko pakún iparun wọn to igba ti wọn ba n ṣe imọran, ti o dabi ẹnipe oun ni o dara ju lati fi idi ijọba wọn mulẹ. ‘Ọlọrun n ṣi oke ni idi, wọn ko si mọ bẹẹ.’”ANN 69.2

    Luther ti sọrọ ni ede Germany, a wa sọ wipe ki o sọ ohun kan naa ni ede Latin. Bi o tilẹ jẹ wipe o ti rẹ ẹ nitori akitiyan rẹ ni akọkọ, o gba si wọn lẹnu, o tun sọ ọrọ rẹ ni ọna ti o da ṣaka, ati pẹlu agbara bi i ti akọkọ. Agbara Ọlọrun ṣiṣe ninu ọrọ yii. Èké ati aimọkan ti fọ ọpọlọpọ awọn ijoye niye ti o fi jẹ wipe wọn ko ri oye iṣọwọronu rẹ ninu ọrọ rẹ akọkọ; ṣugbọn atunsọ rẹ ran wọn lọwọ lati ri ohun ti o n sọ daradara.ANN 69.3

    Awọn ti wọn mọọmọ di oju wọn si otitọ, ti wọn si ti pinu lati maṣe jẹ ki otitọ o yé wọn, binu si agbara ọrọ Luther. Bi o ti dakẹ ọrọ sisọ, abẹnugan inu igbimọ naa fi ibinu sọ wipe: “O koi ti i dahun ibeere ti a bi ọ. . . . O nilati dahun ni ọna ti o yeni yekeyeke. . . . Ṣe wa a yi ọrọ rẹ pada, tabi o ò ni yi pada?”ANN 69.4

    Alatunṣe naa dahun wipe: “Niwọn igba ti kabiyesi ọlọwọ julọ ati ẹyin ọlọla julọ fẹ ki n dahun ni ṣoki, ni ọna ti o yeni yekeyeke, maa fun yin ni ọkan, ohun naa si ni eyi: Emi ko lè jọwọ igbagbọ mi le popu tabi igbimọ lọwọ, nitori ti o han kedere wipe ni ọpọ igba wọn maa n ṣe aṣiṣe, wọn si maa n tako ara wọn. Ayafi bi mo ba ri oye rẹ lati inu ẹri Iwe Mimọ, tabi pẹlu ironu ti o da ṣaka, ayafi bi awọn ayọka ti mo ka ba fi yemi, ati ayafi bi wọn ba so ẹri ọkan mi pọ mọ ọrọ Ọlọrun, n ko le, bẹẹ ni n ko ni yi ọrọ mi pada, nitori o lewu fun Kristẹni lati sọrọ tako ẹri ọkan rẹ. Eyi ni ipinu mi, n ko le ṣe ohun miran mọ; ki Ọlọrun ran mi lọwọ. Amin.”ANN 69.5

    Bayi ni ọkunrin olododo yii ṣe duro lori ipilẹ ti o daju ti ọrọ Ọlọrun. Imọle ọrun tan si oju rẹ. Gbogbo wọn ni wọn ri bi o ti tobi to ati iwa mimọ rẹ, alaafia ati ayọ ọkan rẹ bi o ti n jẹri ni atako si agbara èké, ti wọn si jẹri si bi igbagbọ ti o bori aye ti jẹ alagbara tó.ANN 69.6

    Fun igba diẹ, iyalẹnu ko le jẹ ki gbogbo agbajọ naa o sọrọ. Nigba ti o kọkọ n fesi, Luther sọrọ pẹlu ohun jẹjẹ, ati pẹlu ibọwọ fun ti o fẹ jọ wipe o ti n juwọ silẹ. Awọn ẹlẹsin Romu tumọ eyi si ẹri wipe igboya rẹ ti n baku. Wọn ri ẹbẹ fun akoko gẹgẹ bi imura rẹ lati yi ohun pada. Charles funra rẹ, nigba ti o wo irisi ajẹjẹ ẹsin naa, aṣọ talaka rẹ, ati isọrọ ṣakala rẹ, o sọ pẹlu ẹgan wipe: “Ajẹjẹ ẹsin yii ko le sọ mi di ẹlẹkọ odi laelae.” Igboya ati iduroṣinṣin ti o wa fihan nisinsinyii, pẹlu agbara ironu rẹ ti o da ṣaka, ya gbogbo wọn lẹnu. Ọba naa sọ pẹlu idunnu wipe: “Ajẹjẹ ẹsin naa sọrọ pẹlu ọkan líle, ati igboya tí kò mi.” Ọpọlọpọ awọn ijoye Germany fi iwuri ati ayọ wo aṣoju orilẹ ede wọn yii.ANN 69.7

    A ṣẹgun awọn atẹle Romu; iṣẹ wọn fi ara han ni ọna ti o buru julọ. Wọn wọna lati fi idi agbara wọn mulẹ, ki i ṣe nipa lilo Iwe Mimọ, bikoṣe nipa hihalẹ, iṣọwọsọrọ Romu ti ki i baku. Abẹnugan igbimọ naa sọ wipe: “Bi o ò ba ni yi ọrọ rẹ pada, ọba ati awọn ipinlẹ inu ijọba yii yoo ro nipa ohun ti wọn yoo ṣe si ẹlẹkọ odi ti ko le yipada.”ANN 69.8

    Awọn ọrẹ Luther ti wọn fi ayọ nla tẹti si ọrọ rẹ wariri nitori ọrọ wọnyi; ṣugbọn ọmọwe naa sọ pẹlu ifọkanbalẹ wipe: “Ki Ọlọrun o jẹ oluranlọwọ mi, nitori pe n ko le yi ohunkohun pada.”ANN 70.1

    A sọ wipe ki o kuro ninu igbimọ naa, nigba ti awọn ijoye n jiroro papọ. Awọn eniyan naa mọ wipe wahala nla naa ti de. Bi Luther ti kọ jalẹ lati yipada lè yí itan ijọ pada fun ọpọlọpọ ọdun. A wa pinu lati fun ni anfani kan si lati yipada. Fun igba ikẹyin, a mu wa sinu igbimọ naa. A tun bi i leere lẹẹkan si boya yoo yi awọn ikọni rẹ pada, tabi ko ni yi wọn pada. O sọ wipe, “Emi ko ni esi miran lati fọ ju eyi ti mo ti fọ tẹlẹ lọ.” O han gbangba wipe a ko le rọ ọ lati tẹriba fun aṣẹ Romu, boya pẹlu awọn ileri, tabi ihalẹ.ANN 70.2

    Inu bi adari ijọ paadi wipe ajẹjẹ ẹsin lasan yii le ṣe bayii kẹgan agbara ti o ti n mu ki awọn ọba ati ijoye o wariri; wọn fẹ ki o ri ibinu wọn nipa fifi iya jẹ ẹ titi ti yoo fi ku. Ṣugbọn Luther, nigba ti o mọ ewu to le wu oun, ba gbogbo awọn Kristẹni sọrọ tọwọtọwọ ati pẹlu idaniloju. Ọrọ rẹ ko ni igberaga, igbonara, tabi ṣiṣe afihan ni ọna ti ko tọ. Ko ri ara rẹ tabi awọn eniyan nla ti wọn yi ka, ṣugbọn o ni imọlara wipe oun wa niwaju Ẹni ti O fi ohun gbogbo ju popu, awọn alufa agba, awọn ọba, ati awọn alaṣẹ ijọba lọ. Kristi sọrọ nipasẹ ẹri Luther pẹlu agbara ati ọlanla ti o ya awọn ọta ati ọrẹ rẹ lẹnu ni asiko naa. Ẹmi Ọlọrun wa ninu igbimọ naa, O n ba ọkan awọn ijoye ijọba naa sọrọ. Ọpọ awọn ijoye naa ni wọn fi igboya sọ wipe iṣẹ Luther tọna. Ọpọ ni wọn gbagbọ ninu otitọ naa; ṣugbọn imọlara yii ko pẹ ninu awọn kan. Awọn miran si wa ti ko fi igbagbọ wọn han ni akoko naa, ṣugbọn nigba ti wọn funra wọn yẹ Iwe Mimọ wò ni igba ti o yá, wòn fi igboya ran iṣẹ Atunṣe lọwọ.ANN 70.3

    Afọbajẹ Frederick ti n wọna bi Luther yoo ti fi ara han niwaju igbimọ, o si fi gbogbo ara tẹti silẹ si ọrọ rẹ. O fi ayọ ati iwuri wo igboya, iduroṣinṣin, ikora-ẹni-nijanu, ati ipinu ọmọwe naa lati duro ṣinṣin si ninu awijare rẹ. O fi eyi wé awọn ẹgbẹ keji, o si ri wipe agbara otitọ ti sọ ọgbọn awọn popu, ọba, ati awọn alufa agba di asan. Agbara ijọ padi ri ibaku ti a yoo mọ laarin gbogbo awọn orilẹ ede, ati ni awọn akoko ti n bọ.ANN 70.4

    Bi aṣoju naa ti ri ipa ọrọ Luther, o bẹru fun aabo agbara Romu ju ti atẹyinwa lọ, o si pinu lati lo ohun gbogbo ti o wa ni ikawọ rẹ lati bi Alatunse naa ṣubu. Pẹlu gbogbo ọgbọn isọrọ ati oṣelu eyi ti a mọ ọ mọ, o fihan ọba ọdọ naa bi o ti jẹ iwa omugọ tó ati ewu ti o wa ninu ṣiṣe ainani ibadọrẹ ati iranlọwọ agbara Romu nitori ajẹjẹ ẹsin kan lasan.ANN 70.5

    Awọn ọrọ rẹ ni ipa ti wọn. Ni ọjọ keji ti Luther fesi, Charles jẹ ki a ka iṣẹ iranṣẹ kan si igbimọ naa ti o kede ipinu rẹ lati tẹsiwaju ninu ipinu awọn ti wọn ti jẹ ṣaaju rẹ, lati ṣe iranwọ fun, ati lati daabo bo ẹsin Katoliki. Niwọn igba ti Luther ti kọ lati kọ awọn aṣiṣe rẹ silẹ, a yoo ṣe atako rẹ, ati awọn ẹkọ odi rẹ ni ọna ti o lagbara. “Ajẹjẹ ẹsin kan ṣoṣo, ti iwa omugọ rẹ ṣi lọna, ti dide lati tako igbagbọ ẹsin Kristẹni. Maa fi ijọba mi, ohun ini mi, awọn ọrẹ mi, ara mi, ẹjẹ mi, ọkan mi, ati ẹmi mi ṣofo lati le dawọ iru iwa aiwabọlọrun yii duro. Mo ṣetan lati kọ Augustine Luther silẹ, lati fi ofin de e lati maṣe da wahala silẹ bi o ti wu ki o kéré mọ laarin awọn eniyan; ma a tun tako òun ati awọn atẹle rẹ gẹgẹ bi ẹlẹkọ odi alaigbọran, nipa lile wọn kuro ninu ijọ, lile wọn kuro ninu ilu, ati pẹlu ohun gbogbo ti yoo pa wọn run. Mo pe gbogbo awọn ara ilu lati wuwa bi Kristẹni tootọ.” Ṣugbọn ọba naa sọ wipe a nilati bọwọ fun iwe idaabobo Luther, ati pe ṣaaju ki a to ṣe ohunkohun si, a nilati jẹ ki o de ile rẹ ni alaafia.ANN 70.6

    Ero meji ni o gbilẹ kan laarin awọn ọmọ igbimọ. Awọn aṣoju popu fẹ ki a ma bọwọ fun iwe idaabobo rẹ. Wọn sọ wipe, “O yẹ ki odò Rhine o gba eeru rẹ, gẹgẹ bi o ti ṣe gba ti John Huss ni ọgọrun ọdun sẹyin.” Ṣugbọn awọn ijoye Germany, bi o tilẹ jẹ wipe awọn funra wọn jẹ ọmọ ijọ paadi ati ọta Luther, wọn tako iru aika ẹjẹ si yii gẹgẹ bi abawọn ni ara ọla orilẹ ede wọn. Wọn tọka si awọn rogbodiyan ti wọn ṣẹlẹ lẹyin iku Huss, wọn si sọ wipe, wọn ko le jẹ ki iru awọn iṣẹlẹ buburu yii o tun ṣẹlẹ si Germany, tabi si ọba wọn ti o jẹ ọdọ.ANN 70.7

    Charles funra rẹ dahun si ibeere alailojuti yii wipe: “Bi a ba tilẹ le iṣotitọ ati iṣododo kuro ninu aye, o yẹ ki wọn ri ibi aabo ninu ọkan awọn ijoye.” Awọn ọta Luther tun rọ ọ lati ṣe si Alatunṣe naa gẹgẹ bi Sigismund ti ṣe si Huss—ki o fi i silẹ si ikawọ ijọ; ṣugbọn nigba ti o ranti bi Huss ti na ọwọ rẹ si ẹwọn ti a fi de e, ti o si ran ọba naa leti nipa ileri rẹ ti a kò kà sí niwaju gbogbo eniyan, Charles V sọ wipe: “Oju ko gbọdọ ti mi bii ti Sigismund.ANN 71.1

    Sibẹ Charles mọọmọ kọ otitọ ti Luther sọ silẹ. Ọba naa kọwe wipe, “Mo ti ṣe ipinu atọkanwa lati tẹle apẹẹrẹ awọn baba nla mi.” O ti pinu wipe oun ko ni yẹsẹ kuro ni oju ọna aṣa, bi o ba tilẹ jẹ lati rin ni ọna otitọ ati ododo. Nitori pe awọn baba rẹ ṣe bẹẹ, oun yoo tẹle ilana popu, pẹlu gbogbo iwa ika ati iwa ibajẹ rẹ. Bi o ṣe ṣe ipinu rẹ niyi, ti o kọ lati gba imọlẹ miran ni afikun si eyi ti awọn baba rẹ gba, tabi lati ṣe iṣẹ ti wọn kò ṣe.ANN 71.2

    Ọpọlọpọ wa loni ti wọn dirọ mọ aṣa ati ikọni awọn baba wọn. Nigba ti Ọlọrun ba ran imọlẹ miran si wọn, wọn kọ lati gba a nitori, niwọn igba ti a ko ti fifun awọn baba wọn, wọn ko nilati gba a. A ko fi wa si ipo ti awọn baba wa wà; nitori naa, ojuṣe ati iṣẹ wa ko ri bakan naa pẹlu ti wọn. Ọlọrun ko ni fi ọwọ si bi a ba n wo apẹẹrẹ awọn baba wa lati mọ ojuṣe wa dipo ki a wa ọrọ otitọ funra wa. Ojuṣe wa tobi ju ti awọn baba nla wa lọ. A yoo jiyin fun imọlẹ ti wọn gba, ti a fi le wa lọwọ gẹgẹ bi ajogunba, bẹẹ ni a yoo jiyin fun imọlẹ tuntun ti o n tan si wa lati inu ọrọ Ọlọrun nisinsinyii.ANN 71.3

    Kristi sọ fun awọn Ju alaigbagbọ wipe: “Bi n ko ba wa lati wa ba wọn sọrọ, wọn ki ba ti ni ẹṣẹ: ṣugbọn nisinsinyii, wọn di alairiwi fun ẹṣẹ wọn.” Johanu 15:22. Agbara Ọlọrun kan naa ni o ti ipa Luther sọrọ si ọba ati awọn ijoye Germany. Bi imọlẹ naa si ti n tàn lati inu ọrọ Ọlọrun, Ẹmi Rẹ bẹbẹ pẹlu ọpọlọpọ ninu apero naa fun igba ikẹyin. Bi Pilatu ti jẹ ki igberaga ati ifẹ eniyan o sé ọkan oun mọ Olurapada aye ni ọpọ ọdun sẹyin; bi Felix nigba ti o n wariri, ti sọ fun iranṣẹ otitọ naa wipe, “Maa lọ ná; nigba ti o ba wọ fun mi, maa ranṣẹ si ọ;” bi ọba Agrippa onigberaga ti jẹwọ wipe, “O fẹrẹ sọ mi di Kristẹni tan” (Iṣe 24:25; 26:28); sibẹ ti o yi kuro ninu iṣẹ iranṣẹ ti a ran lati ọrun—bẹẹ gẹgẹ ni Charles V, ni titẹle igberaga ati ilana aye, ṣe pinu lati kọ imọlẹ otitọ silẹ.ANN 71.4

    Iroyin nipa ohun ti wọn yoo ṣe si Luther ti tan kalẹ, o si ti fa irọkẹkẹ ni gbogbo ilu naa. Alatunṣe naa ti ni ọpọlọpọ ọrẹ, ti wọn mọ iwa ẹtan ati iwa ika ti Romu maa n wu si ẹnikẹni ti o ba gboya lati tu aṣiri awọn iwa ibajẹ rẹ, wọn pinu wipe a ko gbọdọ ta ẹjẹ rẹ silẹ. Ọgọrọ awọn ijoye ni wọn pinu lati daabo bo o. Ki i ṣe awọn perete ni wọn bu ẹnu atẹ lu iṣẹ iranṣẹ ọba wipe o fi itẹriba lọna ailagbara han si aṣẹ Romu. A lẹ oriṣiriṣi awọn akọle mọ ara ilẹkun ile ati ni ojutaye, awọn kan ba Luther wi, ti awọn miran si ti i lẹyin. A kọ ọrọ ti o ni itumọ lati inu ọrọ ọlọgbọn ni sinu ọkan ninu wọn bayii wipe: “Ègbé ni fun ọ, ilẹ naa, ti ọba rẹ jẹ ọmọde.” Oniwasu 10:16. Ifẹ ti wọn ni si Luther ni gbogbo Germany pọ to bẹẹ gẹẹ ti o fi da ọba ati awọn ọmọ igbimọ loju wipe bi wọn ba wu iwa aiṣootọ kan si, yoo pa alaafia ijọba, ati itẹ ọba lara.ANN 71.5

    Frederick ti Saxony mọọmọ ma fi ero rẹ nipa Alatunṣe naa han sita, ṣugbọn o n ṣọ lọwọ lẹsẹ, o n wo gbogbo irinsi rẹ ati ti awọn ọta rẹ. Ṣugbọn awọn kan wa ti wọn ko janpata lati fi ikaanu wọn fun Luther pamọ. Awọn ijoye, awọn ọlọrọ ati alaṣẹ, ati awọn eniyan pataki miran, ninu ijọ ati ninu ilu. Spalatin kọwe wipe, “Yàrá ọmọwe naa ko le gba gbogbo awọn alejo ti wọn wa.” Awọn eniyan wo o afi bi ẹnipe ki i ṣe eniyan lasan. Ani awọn ti wọn ko gbagbọ ninu awọn ikọni rẹ ko le ṣe aifi ifẹ wọn han si iduroṣinṣin rẹ ti o fun ni igboya lati doju kọ iku dipo ki o tako ẹri ọkan rẹ.ANN 71.6

    A ṣe akitiyan lọpọlọpọ lati ri wipe Alatunṣe naa ba Romu laja. Awọn ijoye ati alaṣẹ ṣe alaye fun wipe bi o ba tẹsiwaju lati gbe ipinu rẹ ga ni atako si ti ijọ ati ti igbimọ, a yoo le kuro ninu ijọba naa laipẹ, ko si ni ni aabo. Luther fesi si ọrọ yii wipe: “A ko le waasu iyinrere Kristi laini ọta. . . . Bawo ni ibẹru ewu ti n bọ yoo ṣe ya mi kuro ni ọdọ Oluwa, ati ọrọ mimọ ni, ti i ṣe wipe oun nikan ṣoṣo ni otitọ? Rara; mo yan lati fi ara, ẹjẹ, ati ẹmi mi lelẹ.”ANN 71.7

    A tun rọ ọ lati gba idajọ ọba, ki yoo si ni ohun kan lati bẹru. O dahun wipe, “Pẹlu gbogbo ọkan mi, mo faramọ ki ọba, awọn ijoye, ani eyi ti o kere julọ ninu ẹsin Kristẹni o yẹ awọn iṣẹ mi wo, ki o si ṣe idajọ le wọn lori; ṣugbọn lori ohun kan ni, ki wọn lo ọrọ Ọlọrun gẹgẹ bi odiwọn wọn. Eniyan ko ni ohunkohun lati ṣe ju ki o ṣe igbọran si lọ. Ẹ maṣe wuwa ipa si ọkan mi, eyi ti a ti so papọ mọ Iwe Mimọ.”ANN 72.1

    O dahun si ipẹ miran wipe: “Mo gba lati kọ iwe idaabobo mi silẹ. Mo fi ara mi ati ẹmi mi si ọwọ ọba, ṣugbọn ọrọ Ọlọrun—láyé!” O sọ ifẹ rẹ lati gba ipinu igbimọ apapọ lori ohun kan, ki igbimọ o ṣe ipinu rẹ ni ibamu pẹlu Iwe Mimọ. O fikun wipe, “Ninu ohun ti o ni i ṣe pẹlu ọrọ Ọlọrun ati igbagbọ, gbogbo Kristẹni ni wọn le ṣe idajọ gẹgẹ bi popu ti le ṣe, bi ẹgbẹgbẹrun igbimọ ba tilẹ ti i lẹyin.” Lẹyin-ọrẹyin, awọn ọta ati awọn ọrẹ rẹ gba wipe asan ni yoo jasi bi wọn ba tubọ n rọ ọ lati ba Romu laja.ANN 72.2

    Bi o ba ṣe wipe Alatunṣe naa yẹsẹ ninu gbolohun ọrọ kan ṣoṣo ni, Satani ati awọn ọmọ ogun rẹ i ba ṣẹgun. Ṣugbọn iduroṣinṣin rẹ laiyẹsẹ ni a lo fun itusilẹ ijọ, ati ibẹrẹ igba ọtun ti o dara. Ipa ọkunrin kan ṣoṣo yii, ti o gboya lati ronu ati lati wuwa funra rẹ lori ọrọ ẹsin, yoo nipa lori ijọ ati araye, ki i ṣe ni akoko tirẹ nikan, ṣugbọn titi de ọjọ iwaju. Iduroṣinṣin rẹ ati iṣotitọ rẹ yoo fun gbogbo ẹni ti yoo ba la iru iriri kan naa kọja lokun, titi de opin aye. Agbara ati ọla Ọlọrun ga ju imọran eniyan lọ, o ga ju agbara nla Satani lọ.ANN 72.3

    Laipe, ọba paṣẹ ki Luther o pada sile, o si mọ wipe idalẹbi oun yoo tẹle aṣẹ yii kankan. Ikuuku ẹlẹru bo oju ọna rẹ; ṣugbọn bi o ti n kuro ni Worms, ọkan rẹ kun fun ayọ ati iyin. O sọ wipe, “Eṣu funra rẹ sọ ile agbara popu; ṣugbọn Kristi da alafo nla si inu rẹ, o si pọn dandan fun Satani lati ṣe ijẹwọ wipe Oluwa ni agbara ju oun lọ.”ANN 72.4

    Lẹyin ti o kuro, nitori pe ko fẹ ki a tumọ iduroṣinṣin oun si iṣọtẹ, Luther kọwe si ọba. O sọ wipe, “Ọlọrun ti o n yẹ ọkan wo ni ẹlẹri mi wipe mo ṣetan lati fi tọkantọkan ṣe igbọran si ọlanla rẹ, ninu ọwọ ati ailọwọ, ninu iye tabi iku, laifi ohunkohun silẹ, ayafi ọrọ Ọlọrun, nipa eyi ti eniyan n wa laaye. Ninu gbogbo ọrọ aye yii, iṣotitọ mi ko ni yẹ, nitori boya a jere tabi a padanu nihin ko ni itumọ si igbala. Ṣugbọn nigba ti o ba ni i ṣe pẹlu iye ainipẹkun, Ọlọrun ko fẹ ki eniyan o tẹriba fun eniyan. Nitori iru itẹriba yii ninu ọrọ ẹmi ni ijọsin tootọ, eyi ti o yẹ ki a fifun Ẹlẹda nikan ṣoṣo.”ANN 72.5

    Bi a ti ṣe gba Luther nigba ti o n kuro ni Worms tun larinrin ju igba ti o lọ sibẹ lọ. Awọn ijoye ijọ tẹwọ gba ajẹjẹ ẹsin ti a ti le kuro ninu ijọ naa, awọn alaṣẹ ilu si tẹwọ gba ẹni ti ọba ti da lẹbi. A pe e ki o wa waasu, bi o tilẹ jẹ wipe ọba ti sọ wipe ki o ma waasu, o tun gun ori pẹpẹ iwaasu. O sọ wipe, “Mi o jẹjẹ lati fi ẹwọn de ọrọ Ọlọrun, bẹẹ ni mi o ni jẹ iru ẹjẹ yii.”ANN 72.6

    Ko pẹ ti o kuro ni Worms ti awọn atẹle popu fi jẹ ki ọba o fi ofin de e. Ninu aṣẹ yii, a pe Luther ni “Satani funra rẹ ninu irisi eniyan, ti o wọ aṣọ ajẹjẹ ẹsin.” A paṣẹ wipe ni kete ti agbara iwe idaabobo rẹ ba ti tan, ohun gbogbo ti a ba ri ni ki a lo lati da iṣẹ rẹ duro. A sọ wipe ẹnikẹni ko gbọdọ gba a sile, tabi fun ni ounjẹ tabi omi, a ko gbọdọ ran an lọwọ tabi ti i lẹyin ninu ọrọ tabi iṣe, ni ita gbangba tabi ninu ile. A nilati fi ipa mu nibikibi ti o ba wa, ki a si fi le awọn alaṣẹ lọwọ. Bakan naa, ki a fi awọn atẹle rẹ si atimọle, ki a si fi ipa gba ohun ini wọn. Ki a pa awọn iwe rẹ run, ati pe aṣẹ yii yoo ni agbara lori ẹnikẹni ti o ba tako o.ANN 72.7

    Afọbajẹ ti Saxony ati awọn ijoye ti wọn fẹran Luther ti kuro ni Worms ni kete ti o kuro nibẹ, awọn ọmọ igbimọ si fi ọwọ si aṣẹ ọba. Inu awọn ẹlẹsin Romu wa dun nisinsinyii. Wọn ro wipe opin ti de ba iṣẹ Atunṣe.ANN 72.8

    Ọlọrun ti pese ọna abayọ fun iranṣẹ Rẹ ninu akoko ewu yii. Ẹṣọ kan n wo gbogbo irin Luther, awọn ọkan tootọ ti wọn ni iyin si ti pinu lati daabo bo o. O ti han gedegbe wipe iku rẹ nikan ni o le tẹ Romu lorun; nipa pipa a mọ nikan si ni a fi le mu kuro lẹnu kiniun. Ọlọrun fun Frederick ti Saxony ni ọgbọn lati pete bi a o ti ṣe pa Alatunṣe naa mọ. A mu ero afọbajẹ naa ṣe pẹlu ifọwọsọwọpọ awọn ọrẹ tootọ, a si gbe Luther pamọ kuro ni ọdọ awọn ọrẹ ati ọta. A mu nigba ti o n lọ sile, a gba a kuro lọdọ awọn ọrẹ rẹ, a si yara gbe gba inu igbo kan lọ si ile iṣọ ti o wa ni Wartburg, ile iṣọ ti o danikan wa ni ori oke. Bi a ti mu, ati ibi ti a gbe si ṣe ajeji to bẹẹ gẹẹ ti Frederick funra rẹ ko mọ ibi ti a gbe pamọ si fun igba pipẹ. Idi si wa fun aimọkan yii; niwọn igba ti afọbajẹ naa ko ba mọ ohunkohun nipa ibi ti Luther wa, ko le sọ ohunkohun nipa rẹ. O tẹ lọrun wipe Alatunṣe naa wa nibi aabo, imọ yii si fi ọkan rẹ balẹ.ANN 72.9

    Ọdun yipo tan, Luther si wa ni ipamọ. Inu Aleander ati awọn ẹlẹgbẹ rẹ dun wipe ina iyinrere ti fẹrẹ ku. Ṣugbọn dipo eyi, Alatunṣe naa n fikun imọlẹ rẹ lati inu ile iṣura otitọ; imọlẹ rẹ yoo si tan pẹlu itansan ti o pọ si.ANN 73.1

    Ni ibi aabo rẹ ni Wartburg, inu Luther dun fun igba diẹ wipe oun bọ kuro ninu ina ati wahala ogun. Ṣugbọn laipẹ, idakẹjẹ ati isinmi ko fun ni ifọkanbalẹ mọ. Igbesi aye wahala ati idamu ti mọ lara, ko le fi ara da a mọ laiṣiṣe. Ni awọn ọjọ ti o danikanwa yii, o wo ipo ijọ, o si kigbe pẹlu iporuuru ọkan wipe: “O maṣe o! Ko si ẹnikan ni akoko ikẹyin ibinu rẹ, lati duro bi ogiri niwaju Oluwa, ki o si gba Israeli la!” O tun ro nipa ara rẹ, o wa bẹru ki a ma baa pe e ni ojo nitori pe o kuro ni oju ija. O wa ba ara rẹ wi nitori iwa ọlẹ rẹ, ati bi o ṣe n tẹ ara rẹ lọrun. Sibẹ o n ṣe iṣẹ ti o dabi ẹnipe o pọ ju ẹnikan lati ṣe lọ lojoojumọ. Nigba ti awọn ọta rẹ n dun ara wọn ninu wipe a ti pa a lẹnu mọ, iyalẹnu ati idarudapọ ba wọn nigba ti wọn mọ daju wipe o si n ṣiṣẹ. A pin awọn iwe ilewọ pupọ ti o kọ kaakiri ilẹ Germany. O tun ṣe iṣẹ ti o dara julọ fun awọn ara ilu rẹ nipa ṣiṣe itumọ Majẹmu Tuntun ni ede ilẹ Germany. Lati ilẹ olokuta Patmos rẹ, fun bi ọdun kan o tẹsiwaju lati maa waasu iyinrere ati lati maa ṣe ibawi ẹṣẹ ati awọn aṣiṣe akoko naa.ANN 73.2

    Ki i ṣe lati pa ẹmi Luther mọ kuro ni ọwọ ibinu awọn ọta rẹ, tabi lati fun ni akoko idakẹjẹ fun awọn iṣẹ pataki rẹ yii nikan ni Ọlọrun fi mu iranṣẹ Rẹ kuro ni ojutaye. Yoo yori si awọn aṣeyọri ti wọn ṣe iyebiye ju eyi lọ. Ninu idanikangbe ati ifarasin rẹ ni ibi ipamọ ori oke yii, a mu Luther kuro ninu iranlọwọ aye ati iyin eniyan. Nipa eyi, a gba a kuro lọwọ igberaga ati igbẹkẹle ara ẹni ti aṣeyọri saba maa n mu wa. Nipa ijiya ati irẹsilẹ rẹ, a pese rẹ silẹ lati rin ni alaafia ni ori oke giga ti a ṣẹṣẹ gbe si.ANN 73.3

    Bi awọn eniyan ti n yọ ninu ominira ti otitọ fun wọn, wọn saba maa n fẹ lati gbe awọn ti Ọlọrun lo lati ja ìdè èké ati igbagbọ asan ga. Satani n wa lati dari ero ati ifẹ eniyan kuro ni ọdọ Ọlọrun, ki o si tẹ ẹ mọ ara eniyan; o n dari wọn lati bu iyin fun ohun èlò lasan, ki wọn si kọ Ẹni ti o dari ohun gbogbo silẹ. Ni ọpọ igba awọn adari ẹsin ti a n yin, ti a si n bọwọ fun bayii maa n gbagbe igbẹkẹle wọn ninu Ọlọrun, wọn a si maa gbẹkẹle ara wọn. Nipasẹ eyi wọn a maa wa lati dari ọkan ati iyè awọn eniyan ti wọn fẹ lati maa wo wọn fun itọsọna dipo ki wọn maa wo ọrọ Ọlọrun. Iṣẹ atunṣe saba maa n fa sẹyin nitori pe awọn atẹle rẹ saba maa n ni iru ẹmi yii. Ọlọrun fẹ daabo bo iṣẹ Atunṣe kuro ninu ewu yii. Ko fẹ ki iṣẹ naa o gba ami eniyan bikoṣe ti Ọlọrun. Awọn eniyan ti yi oju si ọdọ Luther bi ẹni ti n waasu otitọ; a mu kuro ki oju wọn baa le yi si ọdọ Olupilese otitọ ayeraye.ANN 73.4

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents