Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  ORI KEJIDINLOGUN—ALATUNṢE TI ILẸ AMẸRIKA

  Ọkunrin agbẹ olododo ati olootọ ti a ṣi lọna lati ṣeyemeji lori aṣẹ Ọlọrun ninu Iwe Mimọ, sibẹ ti o fẹ mọ otitọ pẹlu gbogbo ọkan rẹ, ni ẹni ti Ọlọrun yan ni ọna pataki lati jẹ adari ninu kikede ipadabọ Jesu lẹẹkeji. Bii ti ọpọ awọn Alatunṣe iyoku, ni ibẹrẹ aye rẹ, William Miller jijadu pẹlu aini, o si ti ipasẹ eyi kọ ẹkọ nla nipa agbara ati isẹra ẹni. Awọn ara idile ti o ti jade wa ni iwa lati maṣe gbe ara le ẹnikẹni, wọn ni ẹmi ti o fẹran ominira, ẹmi iforiti ati ẹmi ifẹ ilẹ baba ẹni—awọn iṣesi ti wọn han kedere ninu iwa rẹ. Baba rẹ jẹ ọgagun ninu ẹgbẹgun Ominira, a si lè tọpasẹ ifi-ara-ẹni-rubọ rẹ ninu wahala ati ijiya àkókò lile naa ninu ibẹrẹ igbesi aye Miller ti o ni wahala.ANN 142.1

  Ara rẹ pe, ani ni igba èwe, o ṣe afihan agbara iṣọwọronu ti ki i ṣe lasan. Bi o ti n dagba ni eyi si n fi ara han si. Iye rẹ ji pepe, o si yè kooro, o n pongbẹ pupọ fun imọ. Bi o tilẹ jẹ wipe ko ni anfani lati lọ si ile ẹkọ, ifẹ rẹ fun ẹkọ ati iwa iṣọraronu ati wiwadi nnkan finifini sọ ọ di ẹni ti idajọ rẹ yè kooro, ti o si n ri nnkan kedere. O ni iwa ti a ko le gan ati orukọ ti a lè jowu fun, nitori pe a mọ ọ si olootọ, ẹni ti ki i na inakuna ati ẹni ti o lawọ. Nipasẹ agbara ati iṣẹ ṣiṣe, o tete ni oye bi o tilẹ jẹ wipe o si tẹsiwaju ninu ẹkọ kikọ rẹ. O ṣe gbogbo iṣẹ ilu ati ti ologun pẹlu oriyin ti o si dabi ẹnipe ọna ọrọ ati ọla ṣi silẹ fun.ANN 142.2

  Iya rẹ jẹ obinrin ti o ni ifọkansin ti o lagbara, ni igba ewe rẹ, o ti ni ironu lọna ẹsin. Ni igba ewe rẹ ẹwẹ, o ba ara rẹ ni awujọ awọn ti wọn gbagbọ wipe Ọlọrun ko naani aye yii mọ, ipa wọn lagbara jọjọ nitori pe pupọ ninu wọn ni o jẹ ọmọ ilu rere ti wọn si ni iwa ati inu rere. Wọn gbe ni awujọ awọn Kristẹni, nitori naa, awujọ wọn nipa lori iwuwasi wọn. Inu Bibeli ni wọn ti ri awọn iwa ti o mu ki a bọwọ fun wọn ati eyi ti o jẹ ki a fi ọkan tan wọn; sibẹ wọn ṣi awọn ẹbun rere wọnyi lo debi pe wọn fi n tako Ọlọrun. Nipa ibaṣepọ pẹlu awọn eniyan wọnyi, Miller gba iṣọwọronu wọn. Ọna ti wọn n gba tumọ Iwe Mimọ ni akoko naa fun ni awọn iṣoro kan ti o dabi ẹnipe ko le bori; sibẹ igbagbọ rẹ tuntun yii, nigba ti o ti Bibeli si ẹgbẹ kan, ko fun ni ohun ti o dara ju u lọ lati rọpo rẹ, ko si ni ifọkanbalẹ. O tẹsiwaju lati gba awọn nnkan wọnyi gbọ fun bi ọdun mejila. Ṣugbọn nigba ti o wa ni ọmọ ọdun mẹrinlelọgbọn, Ẹmi Mimọ fi ọwọ ba a lọkan lati mọ nipa ipo rẹ gẹgẹ bi ẹlẹṣẹ. O ri wipe ninu igbagbọ oun tẹlẹ yii, ko si idaniloju ayọ lẹyin isa oku. Ọjọ iwaju ṣokunkun, o kun fun ibanujẹ. Nigba ti o n sọ nipa ero rẹ ni akoko yii, o sọ wipe:ANN 142.3

  “Iparun ayeraye jẹ ero ti o tutu, ti o tu n ko otutu ba ni, tí idajọ si jẹ iparun ti o daju fun gbogbo eniyan. Awọn ọrun dabi idẹ lori mi, ti ilẹ si dabi irin labẹ ẹsẹ mi. Iye ainipekun—kini o tumọ si? Ati iku—kini o tumọ si? Bi mo ti n ronu si, bẹẹ naa ni awọn idahun mi n tuka. Mo ṣa ipa lati maṣe ronu mọ, ṣugbọn n ko le ṣe akoso lori ero mi. Mo jẹ ẹni osi, ṣugbọn mi o mọ ohun ti o fa a. Mo kùn, mo tun ṣe aroye, ṣugbọn mi o mọ ẹni ti mo n ṣe e si. Mo mọ wipe aṣiṣe wa, ṣugbọn mi o mọ bi mo ti le ri i, tabi bi mo ti le ri ohun ti o tọna. Mo kẹdun, ṣugbọn ko si ireti.”ANN 142.4

  O tẹsiwaju ninu ipo yii fun oṣu diẹ. O sọ pe: “Lọgan mo ni imọlara iwa Olugbala ninu iye mi. O dabi ẹnipe ẹnikan le wa ti o dara ti o si laanu lati le ṣe imukuro ẹṣẹ wa funra rẹ, ki o si ti ipa rẹ gba wa la lati ma baa jiya ẹṣẹ. Lọgan ni mo ni imọlara bi iru ẹni bẹẹ a ti dara to, mo si ronu wipe mo le sọ ara mi si ọwọ rẹ, ki n si gbẹkẹle aanu iru ẹni bẹẹ. Ṣugbọn ibeere ti o jade ni wipe, Bawo ni a ṣe le mọ wipe iru ẹni bẹẹ wa? Yatọ si Bibeli, mo ri wipe mi o le ri ẹri wipe iru Olugbala bẹẹ wa, tabi nipa ọjọ iwaju…ANN 142.5

  “Mo ri wipe Bibeli ṣe akajuwe iru Olugbala ti mo nilo gan an; o wa yamilẹnu wipe bawo ni iwe ti a ko mí sí ṣe le ni awọn ikọni ti wọn ba aini aye ti o ṣubu yii pade rẹgi. O di dandan fun mi lati gbagbọ wipe Iwe Mimọ nilati jẹ ifihan lati ọdọ Ọlọrun. Wọn di idunnu mi; ninu Jesu mo ri ọrẹ. Olugbala di eyi ti o lọla julọ laarin ẹgbẹẹgbẹrun; Iwe Mimo ti o ṣi ṣokunkun ti ko si ba ara mi mu tẹlẹ, wa di fitila si ẹsẹ mi ati imọlẹ si ipa ọna mi. Ọkan mi balẹ o si wa ni alaafia. Mo ri wipe Oluwa Ọlọrun jẹ Apata laarin okun aye. Bibeli wa di ohun ti mo n kọ julọ, lotitọ mo le sọ wipe, mo wá inu rẹ pẹlu ayo kikun. Mo ri wipe a koi tii sọ idaji rẹ fun mi. O yamilẹnu idi ti mi o fi ri ẹwa ati ogo rẹ tẹlẹ, o si jọmi loju wipe mo tilẹ le kọ ọ silẹ. Gbogbo ohun ti a fihan ni ọkan mi n fẹ, ti o si jẹ iwosan fun aisan ọkan mi. Mi o ni ifẹ lati ka iwe kankan mọ, mo si pese ọkan mi silẹ lati gba ọgbọn lati ọdọ Ọlọrun.”ANN 142.6

  Miller jẹwọ igbagbọ rẹ ni gbangba ninu ẹsin ti o kọ silẹ. Ṣugbọn awọn ọrẹ rẹ ti wọn jẹ alaigbagbọ kò lọra lati sọ gbogbo koko ọrọ eyi ti oun funra rẹ saba maa n lo lati tako aṣẹ Ọlọrun ninu Iwe Mimọ. Ni akoko yii, ko wa ni imuratan lati da wọn lohun; ṣugbọn o ronu wipe bi Bibeli ba jẹ ifihan lati ọdọ Ọlọrun, o nilati ba ara rẹ mu; ati nitori pe a fifunni lati jẹ ilana fun eniyan, a nilati ṣe e ki o ba oye rẹ mu. O pinnu lati kọ ẹkọ Iwe Mimọ funra rẹ, ki o si ri idaniloju boya gbogbo awọn ohun ti o jọ wipe pe wọn tako ara wọn ko le ṣe e ṣalaye.ANN 143.1

  Pẹlu akitiyan lati ti ohun gbogbo ti o mọ tì si ẹgbẹ kan, o kọ awọn alaye lori Bibeli silẹ, o fi awọn ẹsẹ Iwe Mimọ we ara wọn nipa lilo ajuwe ati atọka. O tẹsiwaju ninu ẹkọ rẹ pẹlu eto; o bẹrẹ pẹlu Jẹnẹsisi, o n ka a lẹsẹẹsẹ. Ko yara ju bi ayọka naa ba ti ṣe yee lọ ni ọna ti ko fi ni ko itiju ba. Nigba ti o ba ri ohun ti o takókó, iṣe rẹ ni lati fi we awọn ẹsẹ miran ti o dabi ẹnipe wọn ni i ṣe pẹlu ohun ti o n ṣe ayẹwo rẹ lọwọ. Gbogbo ọrọ ni o gba laaye lati ni ipa ti o tọ lori koko ẹsẹ naa, bi ero rẹ lori rẹ ba ti jọra ni apapọ pẹlu gbogbo ayọka naa, kii tun ṣe wahala mọ. Bayi nigba ti o ba ri ẹsẹ kan ti o nira lati yé ni, a wa alaye rẹ ninu awọn abala miran ninu Iwe Mimọ. Bi o ti n kọ ẹkọ pẹlu adura tọkantọkan fun ilalọyẹ lati ọdọ Ọlọrun, eyi ti o dabi ẹnipe o ṣokunkun si oye rẹ a mọlẹ kedere. O ni iriri awọn ọrọ oniO. Dafidi: “Iwọle ọrọ Rẹ n funni ni imọlẹ; o n fi oye fun òpè.” O. Dafidi 119:130.ANN 143.2

  O kẹkọ iwe Daniẹli ati Ifihan pẹlu ifẹ gbigbona, o n lo ọgbọn itumọ ti o lo ni abala ti o ku, o si ri pẹlu ayo nla wipe oye awọn ami isọtẹlẹ lè yé eniyan. O ri wipe awọn asọtẹlẹ, nibi ti a mu wọn ṣẹ de ṣẹlẹ gẹgẹ bi o ti ri gan an; wipe gbogbo àmì, àkàwé, òwe, afiwe, abbl., ni a ṣe itumọ rẹ, boya ni aarin ibi ti a ti lo wọn, tabi ki a ti ṣe itumọ ohun ti wọn n sọrọ nipa ninu abala miran ninu Iwe Mimọ, ati pe nigba ti a ba ti ṣe alaye bẹẹ, a nilati ṣe itumọ rẹ bi o ti ri gan an. O sọ wipe, “Bayi ni o ṣe tẹmilọrun wipe Bibeli jẹ eto awọn otitọ ti a fihan, ti o han gbangba wipe a fifunni, bi o ba tilẹ jẹ wipe arinrinajo naa jẹ ope, ko nilo lati kọsẹ ninu rẹ.” Ikọ́ kan lé èkejì ninu ẹ̀wọ̀n jẹ́ èrè akitiyan rẹ, bi o ti n tọpasẹ awọn akọsilẹ nla ti asọtẹlẹ. Awọn angẹli n dari iye rẹ, wọn si n fi Iwe Mimọ ye e.ANN 143.3

  Ni lilo ọna ti awọn asọtẹlẹ gbà wá si imuṣẹ ni atẹyinwa ṣe odiwọn lati ṣe ipinu awọn ti n bẹ ni ọjọ iwaju, o ri daju wipe ohun ti ọpọ eniyan gbagbọ nipa iṣejọba Kristi ni ti ẹmi—ijọba ẹgbẹrun ọdun ṣaaju opin aye—ko ni atilẹyin ọrọ Ọlọrun. Ikọni yii, ti o n tọka si ẹgbẹrun ọdun ti o kun fun ododo ati alaafia ṣaaju wiwa Oluwa funra Rẹ, sun ẹru ọjọ Ọlọrun siwaju. Ṣugbọn bi o tile wu ki o tẹnilọrun to, o tako ikọni Kristi ati ti awọn apostoli Rẹ, wọn kede wipe ki alikama ati epo maa jumọ dagba pọ titi fi di akoko ikore, opin aye; wipe “awọn ẹni buburu ati ẹlẹtan a maa buru si;” wipe “ni awọn ọjọ ikẹyin, igba ewu yoo de;” ati wipe ijọba okunkun yoo tẹsiwaju titi fi di wiwa Oluwa ti yoo si pa a run pẹlu ẹmi ẹnu Rẹ, yoo si ṣe e lọṣẹ pẹlu itansan wiwa Rẹ.” Matiu 13:30, 38—40; 2 Timoti 3:13, 1; 2 Tẹsalonika 2:8.ANN 143.4

  Ijọ Apostoli ko gba ikọni ti iyipada araye ati ti iṣakoso Kristi ni ti ẹmi. Kii ṣe gbogbo Kristẹni ni wọn gba a (ikoni yii) titi fi di ibẹrẹ ọrundun kejidinlogun. Gẹgẹ bi awọn ẹkọ eke iyoku, ohun buburu ni o yọri si. O kọ awọn eniyan lati wò jinna réré si ọjọ iwaju fun ọjọ wiwa Oluwa, o si ṣe idena fun wọn lati fi iye si awọn ami ti wọn kede wipe O ti sunmọle. O fa igboya ati aabo ti ko fẹsẹ mulẹ, o si jẹ ki ọpọlọpọ eniyan o maṣe naani imurasilẹ ti o yẹ lati ṣe lati le pade Oluwa wọn.ANN 143.5

  Miller ri wipe wiwa Kristi gẹgẹ bi eniyan, ati ni ojukoju jẹ ohun ti a kọni kedere ninu Iwe Mimọ. Pọlu sọ wipe: “Oluwa funra Rẹ yoo sọkalẹ lati ọrun pẹlu ariwo, pẹlu ohùn Olu awọn angẹli, ati kakaki Ọlọrun.” I Tẹsalonika 4:16. Bakan naa ni Olugbala sọ wipe: “Wọn yoo ri Ọmọ eniyan ti O n bọ wa lati inu ikuuku awọsanma pẹlu agbara ati ogo nla.” Matiu 24: 30, 27. Gbogbo ogun ọrun ni yoo tẹle. “Ọmọ eniyan yoo wa ninu ogo Rẹ, ati gbogbo awọn angẹli mimọ Rẹ pẹlu Rẹ.” Matiu 25:31. “Yoo si ran awọn angẹli Rẹ pẹlu ohùn kàkàkí nla, wọn o si ko gbogbo awọn ayanfẹ Rẹ jọ.” Matiu 24:31.ANN 143.6

  Ni igba wiwa Rẹ, a yoo ji awọn olododo ti wọn ti ku dide, a o si pa awọn olododo ti wọn wa laaye lara da. “Kii ṣe gbogbo wa ni yoo sun,” ni Pọlu wi, “ṣugbọn a o pa wa lara da, lọgan ni iṣẹju àaya, ni akoko ìpè ikẹyin: nitori kakaki yoo dun, a o si ji awọn oku dide ni aidibajẹ, a o si pa wa lara da. Nitori idibajẹ yii yoo gbe aidibajẹ wọ, ati ara kiku yii yoo si gbe aiku wọ.” I Kọrintin 15:51—53. Bakan naa ninu lẹta rẹ si awọn ara Tẹsalonika, lẹyin ti o ṣe alaye wiwa Oluwa, o sọ pe: “Awọn oku ninu Kristi ni yoo kọ jinde: nigba naa ni awa ti a wa laaye, ti o ku yoo lọ pade wọn ninu ikuuku awọsanma, lati pade Oluwa ninu afẹfẹ: bayii ni a o si maa wa lọdọ Oluwa titi lae.” I Tẹsalonika 4:16, 17.ANN 144.1

  O di igba ti Kristi ba wa funra Rẹ ki awọn eniyan Rẹ to le gba ijọba naa. Olugbala wipe: “Nigba ti Ọmọ eniyan yoo yọ ninu ogo Rẹ, ati gbogbo awọn angẹli mimọ Rẹ pẹlu Rẹ, nigba naa ni yoo joko lori itẹ ogo Rẹ: gbogbo awọn orilẹ ede yoo si pejọ siwaju Rẹ: yoo si pin wọn niya gẹgẹ bi oluṣọ aguntan ti n pin aguntan ati ewurẹ niya: yoo si ko awọn aguntan si ọwọ ọtun Rẹ, ati awọn ewurẹ si ọwọ osi. Nigba naa ni Ọba yoo sọ fun awọn ti wọn wa ni ọwọ ọtun rẹ wipe, Ẹ wa ẹyin alabunkun Baba Mi, ki ẹ jogun ijọba ti a ti pese fun yin lati ipilẹsẹ aye wa.” Matiu 25:31—34. A ti ri lati inu ẹsẹ Iwe Mimọ ti a ka wipe nigba ti Ọmọ eniyan ba wa, a o ji awọn oku dide ni aidibajẹ a o si pa awọn ti wọn wa laaye larada. Nipasẹ ayipada nla yii, a pese wọn silẹ lati gba ijọba naa; nitori Pọlu sọ wipe: “Ẹran ara ati ẹjẹ ko le jogun ijọba Ọlọrun; nitori idibajẹ ko le jogun aidibajẹ.” I Kọrintin 15:50. Ninu ipo ti eniyan wa loni, o le ku, o si ti dibajẹ; ṣugbọn ijọba Ọlọrun ko le dibajẹ, o wà titi lae. Nitori naa eniyan ko le wọ ijọba Ọlọrun ninu ipo ti o wa bayii. Ṣugbọn nigba ti Jesu ba de, yoo fun awọn eniyan Rẹ ni aiku; nigba naa ni yoo pe wọn lati jogun ijọba eyi ti wọn ti jẹ ajogun rẹ ki o to di akoko yii.ANN 144.2

  Awọn wọnyi ati awọn ẹsẹ miran ṣe alaye rẹ fun Miller yekeyeke wipe awọn iṣẹlẹ ti a n reti wipe yoo ṣaaju wiwa Kristi, bii iṣakoso alaafia ni gbogbo aye ati fifi idi ijọba Ọlọrun mulẹ lori aye, yoo tẹle bibọ lẹẹkeji ni. Siwaju si, gbogbo awọn ami akoko ati ipo ti aye wa bá alaye isọtẹlẹ nipa awọn ọjọ ikẹyin mu. O di dandan fun lati gba, nitori ẹkọ Bibeli nikan, wipe akoko ti a ya sọtọ fun aye yii lati tẹsiwaju ti fẹrẹ pari.ANN 144.3

  O sọ pe, “Ẹri miran ti o yamilẹnu pupọpupọ ni itoleseese akoko ninu Iwe Mimọ. . . . Mo ri wipe awọn iṣẹlẹ ti a ṣe asọtẹlẹ wọn, ti wọn si ti ṣẹlẹ lati ẹyin wa ṣẹlẹ laarin akoko kan pato. Ọgọfa ọdun ṣaaju ikun omi (Jẹnẹsisi 6:3); ọjọ meje ti yoo ṣaaju rẹ, pẹlu ogoji ọjọ ti òjò yoo fi rọ (Jẹnẹsisi 7:4); irinwo ọdun ti iru ọmọ Abrahamu a fi ṣe atipo (Jẹnẹsisi 15:13); ọjọ mẹta ti ala agbọti ati alase (Jẹnẹsisi 40:12—20); ọdun meje ti ala Farao (Jẹnẹsisi 41:28—54); ogoji ọdun ninu aginju (Numeri 14:34); ìyàn fun ọdun mẹta ati abọ (I Awọn Ọba 17:11) [wo Luku 4:25]; . . . igbekun fun aadọrin ọdun (Jeremaya 25:11); igba meje ti Nebukadnesa (Daniẹl 4:13—16); ati ọsẹ meji, ati ọgọta o le meji ọsẹ, ati ọsẹ kan, ti o jẹ aadọrin ọsẹ papọ ti a pinnu fun awọn Ju (Daniẹli 9:24—27),—awọn iṣẹlẹ ti a fi akoko ká mọ fi igba kan jẹ asọtẹlẹ, wọn si wa si imuṣẹ gẹgẹ bi a ti sọ wọn.”ANN 144.4

  Nitori naa, nigba ti o ri ọpọlọpọ ilakalẹ akoko bayii ninu ẹkọ Bibeli rẹ, ti wọn si lọ de akoko ipadabọ lẹẹkeji, gẹgẹ bi o ti ye si, ko si ohun ti o le ṣe ju ki o ka wọn si “awọn akoko ti a ti yan tẹlẹ,” eyi ti Ọlọrun ti fihan awọn iranṣẹ Rẹ. Mose sọ wipe, “Ohun ikọkọ jẹ ti Oluwa Ọlọrun wa: ṣugbọn awọn nnkan wọnni ti a fihan jẹ ti ti wa ati ti awọn ọmọ wa lae;” Oluwa tun kede nipasẹ woli Amosi wipe Oun “ko ni ṣe ohun kan, ṣugbọn yoo fi aṣiri Rẹ han awọn woli iranṣẹ Rẹ.” Diutaronomi 29:29; Amosi 3:7. Nitori naa, awọn akẹkọ ọrọ Ọlọrun le fi igboya reti iṣẹlẹ nla ti o tobi julọ lati ṣẹlẹ ninu itan eniyan, ti a fihan kedere ninu Iwe otitọ.ANN 144.5

  Miller sọ wipe, “Bi mo ti ni igbagbọ kikun wipe gbogbo Iwe Mimọ ni a fifunni nipa imisi, o si wulo (2 Timoti 3:16); wipe ko wá ni igba kan ri nipa ifẹ eniyan, ṣugbọn awọn eniyan mimọ ni wọn kọ ọ bi Ẹmi Mimọ ti mi si wọn (2 Peteru 1:21), ati pe a kọ ọ fun ‘ikọni wa, ki awa, nipasẹ suuru ati itunu Iwe Mimọ le ni ireti’ (Romu 15:4), mi o le ṣe ju ki n ri awọn abala ti wọn sọ nipa itọleseese akoko ninu Bibeli gẹgẹ bi ara ọrọ Ọlọrun, nitori naa, wọn nilo afiyesi tọkantọkan gẹgẹ bi awọn abala Iwe Mimọ miran. Nitori naa, mo ri wipe ni ṣiṣa ipa lati ni oye ohun ti Ọlọrun ri wipe o yẹ ki Oun fihan ninu aanu Rẹ, mi o ni aṣẹ lati ré awọn akoko isọtẹlẹ kọja.”ANN 145.1

  Akoko isọtẹlẹ ti o dabi ẹnipe o ṣe afihan kedere akoko ipadabọ lẹẹkeji eyi ti o wa ninu Daniẹli 8:14: “Titi di ẹgbẹrun meji le ọọdunrun (2300) ọjọ; nigba naa ni a o ya ibi mimọ si mimọ.” Ni titẹle ilana fifi Iwe Mimọ ṣe olutumọ ara rẹ, Miller kẹkọ wipe ọjọ kan ninu asọtẹlẹ ti a lo akajuwe fun tumọ si ọdun kan (Numeri 14:34; Isikiẹli 4:6); o ri wipe 2300 ọjọ ninu asọtẹlẹ, tabi iye ọdun bẹẹ, yoo gun jinna réré kọja asiko awọn Ju, nitori naa, ko le jẹ ibi mimọ ti akoko naa. Miller gbagbọ ninu igbagbọ ti o wọpọ nigba naa wipe aye ni ibi mimọ ni akoko Kristẹni, nitori naa, o ni oye wipe yiya ibi mimọ si mimọ ni Daniẹli 8:14 ṣe afihan fifọ aye mọ pẹlu ina ni igba wiwa Kristi lẹẹkeji. Nitori naa, bi a ba le mọ ibẹrẹ ti o tọna fun 2300 ọjọ, o sọ wipe, a yoo le mọ ni kiakia igba ipadabọ lẹẹkeji. Bayii ni a o ṣe fi akoko imudopin nla naa han, akoko ti a yoo mu ohun gbogbo ti akoko yii, pẹlu “gbogbo igberaga, iwuga ati asan, iwa ika ati ijẹniniya rẹ, yoo wa si opin;” nigba ti a yoo “mu ẹgan kuro lori ilẹ aye, a yoo pa iku run, a o fi èrè fun awọn iranṣẹ Ọlọrun, awọn woli, ẹni mimọ, ati awọn ti wọn bẹru orukọ Rẹ, ti a o si pa awọn ti n pa aye run run.”ANN 145.2

  Pẹlu ifọkansin tuntun ti o jinlẹ si, Miller tẹsiwaju ninu ayẹwo awọn asọtẹlẹ, tosan toru ni o fi jin fun kikẹkọ ohun ti o wa dabi ẹnipe o ṣe pataki si jọjọ, ti o si n gba gbogbo ifẹ ọkan rẹ. Ni ori kẹjọ iwe Daniẹli, ko ri ohun ti o le fi mọ ibẹrẹ 2300 ọjọ; bi o tilẹ jẹ wipe a paṣẹ fun angẹli Geburẹli lati jẹ ki iran naa o ye Daniẹli, alaye apa kan ni o fun un. Bi a ti n fi iran inunibini nla ti yoo de ba ijọ han woli naa, aarẹ mu. Ko le fi ara da a mọ, angẹli naa fi silẹ fun igba kan. Daniẹli “daku, o si ṣe aarẹ fun ọjọ diẹ.” O sọ pe, “Iran naa yami lẹnu, ṣugbọn ko ye ẹnikankan.”ANN 145.3

  Sibẹ Ọlọrun ti paṣẹ fun iranṣẹ Rẹ: “Mu ki ọkunrin yii o ni oye iran naa.” A nilati mu aṣẹ naa ṣẹ. Ni igbọran si, angẹli naa, lẹyin igba diẹ pada tọ Danieli wa, o wipe: “Mo wa lati fun ọ ni ọgbọn ati oye;” “nitori naa jẹ ki ọrọ naa ki o ye ọ, ki o si wòye iran naa.” Daniẹli 8:27, 16; 9:22, 23, 25—27. Koko ọrọ pataki kan wa ninu iran ori kẹjọ ti a koi tii ṣalaye, iyẹn ni eyi ti o ni i ṣe pẹlu akoko—akoko 2300 ọjọ; nitori eyi, angẹli naa, nigba ti o pada sinu alaye rẹ, tẹnumọ koko ọrọ nipa akoko pupọpupọ:ANN 145.4

  “Aadọrin ọsẹ ni a pinnu fun awọn eniyan rẹ, ati sori Ilu Mimọ rẹ. . . . Nitori naa, mọ ki o si ye ọ wipe lati jijade lọ aṣẹ lati mu Jerusalẹmu bọ sipo ati lati tun un kọ titi di akoko Mesaya Ọmọ alade, yoo jẹ ọsẹ meje ati ọsẹ mejilelọgọta: a yoo tun igboro ati odi rẹ ṣe, ani ni akoko wahala. Lẹyin ọsẹ mejilelọgọta, a yoo ge Mesaya kuro, ṣugbọn ki i ṣe fun ara Rẹ. . . . Yoo si fi idi majẹmu naa mulẹ pẹlu ọpọlọpọ fun ọsẹ kan; laarin ọsẹ naa, yoo mu ki irubọ ati ọrẹ ẹbọ o wa si opin.”ANN 145.5

  A ran angẹli naa wa nitori ati lè ṣe alaye koko ọrọ ti ko ye ninu iran ori kẹjọ, ọrọ ti o ni i ṣe pẹlu akoko—”titi fi di 2300 ọjọ; lẹyin naa ni a o ya ibi mimọ si mimọ.” Lẹyin ti o ti sọ fun Daniẹli “lati ni oye ọrọ naa, ki o si wòye iran naa,” awọn ọrọ akọkọ ti angẹli naa sọ ni wipe: “Aadọrin ọsẹ ni a ti pinu sori awọn eniyan rẹ ati sori Ilu Mimọ rẹ.” Ọrọ ti a tumọ si pinnu ni o tumọ si “ké kuro.” Aadọrin ọsẹ, ti o duro fun ẹẹdẹgbẹta o din mẹwa (490) ọdun, ni angẹli naa sọ wipe a gé kuro ni o ni i ṣe pẹlu awọn Ju ni ọna pataki. Ṣugbọn nibo ni a o ti gé wọn kuro? Niwọn igba ti o jẹ wipe 2300 ọjọ ni akoko kan ṣoṣo ti a mẹnuba ni ẹsẹ ikẹjọ, o gbọdọ jẹ wipe lati ara akoko naa ni a o ti gé aadọrin ọsẹ kuro; nitori naa aadọrin ọsẹ nilati jẹ ara 2300 ọjọ, ti akoko mejeeji naa si nilati bẹrẹ papọ. Angẹli naa sọ pe, aadọrin ọsẹ naa yoo bẹrẹ lati jijade lọ aṣẹ lati mu Jerusalẹmu bọ sipo ati lati tun un kọ. Bi a ba le mọ ọjọ ti a pa aṣẹ yii, a yoo le mọ ibẹrẹ akoko nla ti 2300 ọjọ.ANN 145.6

  A ri aṣẹ naa ninu ori keje iwe Ẹsra. Ẹsẹ 12-26. Ọba Artaxerxes ni o pa aṣẹ naa ni ọna ti o peye julọ ni 457 B.C. Ṣugbọn ni Ẹsra 6:14, a sọ wipe a kọ ibi mimọ ni Jerusalẹmu “gẹgẹ bi aṣẹ [“ofin”] Cyrus, ati Dariusi, ati Artaxerxes ọba Persia.” Awọn ọba mẹtẹẹta wọnyi, ní pipa aṣẹ yii, ni titun pa, ati ni pipari rẹ, fun ni awọn ohun ti asọtẹlẹ nilo lati bẹrẹ 2300 ọjọ. Bi a ba fi 457 B.C, nigba ti aṣẹ yii jade ni kikun ṣe ọjọ ti a pa aṣẹ yii, gbogbo alaye nipa asọtẹlẹ ti aadọrin ọsẹ ni a o ri wipe wọn ti wa si imuṣẹ.ANN 146.1

  “Lati igba jijadelọ aṣẹ lati tun Jerusalẹmu kọ titi di igba Mesaya Ọmọ Alade yoo jẹ ọsẹ meje ati ọgọta o le meji”—eyi ni ọsẹ mọkandinlaadọrin tabi 483 ọdun. Aṣẹ Artaxerxes bẹrẹ iṣẹ ni akoko ìkórè ni ọdun 457 B. C. Bẹrẹ lati ọjọ yii, 483 ọdun lọ dé akoko ikore A. D. 27. Ni akoko naa, asọtẹlẹ yii wa si imuṣẹ. Ọrọ ti n jẹ “Mesaya” tumọ si “Ẹni Ami òróró.” Ni akoko ikore A. D. 27, Johanu ri Kristi bọmi, O si gba ifami ororo yan ti Ẹmi. Apostoli jẹri wipe “Ọlọrun fi ami ororo yan Jesu pẹlu Ẹmi Mimọ ati agbara.” Iṣe 10:38. Olugbala funra Rẹ kede wipe: “Ẹmi Oluwa n bẹ lara Mi, nitori ti O ti fi ami ororo yan Mi lati waasu iyinrere fun awọn otoṣi.” Luku 4: 18. Lẹyin itẹbọmi Rẹ, O lọ si Galili “O n waasu iyinrere ijọba Ọlọrun, O n wipe, Akoko naa de.” Maku 1:14, 15.ANN 146.2

  “Yoo si fi idi majẹmu naa mulẹ pẹlu ọpọlọpọ fun ọsẹ kan.” “Ọsẹ” ti a n sọ nibi ni ọsẹ ti o kẹyin ninu aadọrin ọsẹ; ọdun meje ti o kẹyin ninu akoko ti a lakalẹ fun awọn Ju. Ni aarin akoko yii, ti o bẹrẹ ni A. D. 27 titi de A. D. 34, Kristi funra Rẹ ni akọkọ, ati lẹyin eyi, nipasẹ awọn ọmọ ẹyin Rẹ fi ipe iyinrere fun awọn Ju ni pataki julọ. Bi awọn apostoli ti n jade lọ pẹlu iroyin ayọ ti ijọba naa, ikilọ Olugbala ni pe: “Ẹ maṣe tọ awọn Keferi lọ, ki ẹ masi ṣe wọ ilu awọn ara Samaria: ṣugbọn ki ẹ lọ si ọdọ awọn aguntan ti o sọnu ni ile Israẹli.” Matiu 10:5, 6.ANN 146.3

  “Ni aarin ọsẹ naa, yoo mu ki ẹbọ ati ọrẹ ẹbọ o wa si opin.” Ni A. D. 31, ọdun mẹta aabọ lẹyin itẹbọmi Rẹ, a kan Oluwa wa mọ agbelebu. Pẹlu ẹbọ nla ti a ru ni ori Kalfari, eto isin irubọ ti o n tọka si Ọdọ Aguntan Ọlọrun fun ẹgbẹrun mẹrin ọdun wa si opin. Apejuwe ti pade ohun ti o n tọka si, gbogbo irubọ ati ọrẹ ati eto irubọ imukuro ẹṣẹ ni wọn wa si opin.ANN 146.4

  Aadọrin ọsẹ tabi 490 ọdun ti a ya sọtọ fun awón Ju pari, gẹgẹ bi a ti ri ni A. D. 34. Ni akoko yii, nipasẹ ipinu Sanhẹndrin awọn Ju, orilẹ ede naa fi edidi di bi o ti ṣe kọ iyinrere silẹ nipa bi o ti ṣe pa Stefanu, ti o si ṣe inunibini si awọn atẹle Kristi. Nigba naa ni iyinrere igbala ki i ti i ṣe fun awọn ti a yan nikan mọ, ti a si fifun araye. Inunibini jẹ ki awọn ọmọ ẹyin o sa kuro ni Jerusalẹmu, wọn si n “waasu ọrọ naa ni ibikibi ti wọn ba lọ.” “Filipi lọ si ilu Samaria, o si waasu Kristi fun wọn.” Lati ọrun wa, a ran Peteru lati waasu iyinrere fun Kọneliu, olubẹru Ọlọrun; a si jere Pọlu alagidi sinu igbagbọ Kristi, a fun ni ojuṣe lati gbe iroyin ayọ naa “jinna réré lọ si ọdọ awọn Keferi.” Iṣe 8:4, 5; 22:21.ANN 146.5

  Gbogbo apejuwe inu asọtẹlẹ ni wọn wa si imuṣẹ rẹgirẹgi titi débí, laiṣeyemeji, a fi idi ibẹrẹ aadọrin ọsẹ mulẹ si 457 B. C., o si pari ni A. D. 34. Lati inu alaye yii, ko nira lati mọ opin 2300 ọjọ. Nigba ti a gé aadọrin ọsẹ—490 ọjọ—kuro ninu 2300, 1810 ọjọ ni ti o ku silẹ. Lẹyin opin 490 ọjọ, 1810 ọjọ koi tii wa si imuṣẹ. Lati A. D. 34, 1810 ọdun pari si 1844. Nitori naa, 2300 ọjọ ti inu Daniẹli 8:14 pari si 1844. Ni opin akoko nla ti a sọtẹlẹ yii, lori ẹri angẹli Ọlọrun, “a o ṣe iwẹnumọ ibi mimọ.” Bayii ni a ṣe fi akoko ti a o ṣe iwẹnumọ ibi mimọ—eyi ti ọpọlọpọ eniyan gba wipe yoo ṣẹlẹ ni akoko wiwa lẹẹkeji—hàn kedere.ANN 146.6

  Miller ati awọn akẹgbẹ rẹ kọkọ gbagbọ wipe 2300 ọjọ yoo pari ni igba ọgbin ni 1844, ṣugbọn asọtẹlẹ tọka si akoko ikore ọdun naa. Iṣitumọ abala yii kó ijakulẹ ati iporuuru ọkan ba awọn ti wọn ti yan ọjọ yii gẹgẹ bi akoko wiwa Oluwa. Ṣugbọn eyi ko din agbara iṣọwọsọrọ wọn ku, eyi ti o fihan wipe 2300 pari ni 1844, ati pe iṣẹlẹ nla ti a ṣe afihan rẹ ni ṣiṣe iwẹnumọ ibi mimọ yoo ṣẹlẹ.ANN 146.7

  Ni kikọ ẹkọ Bibeli bi o ti n ṣe, lati le fihan wipe wọn jẹ ifihan lati ọdọ Ọlọrun, Miller, lati ibẹrẹ wa, ko ni ero lati ri koko ọrọ ti o ri yii. Oun funra rẹ ko le dede fi ọwọ sọya lori ayọrisi ikẹkọ rẹ. Ṣugbọn ẹri lati inu Bibeli han kedere o si lagbara ju ohun ti a le ti si ẹgbẹ kan lọ.ANN 147.1

  Ọdun meji ni o fi jin fun ẹkọ Bibeli, ni 1818, nigba ti o ri aridaju wipe nibii ọdun marundinlọgbọn si akoko yii, Kristi yoo wa fun irapada awọn eniyan Rẹ, Miller sọ wipe, “Mi o nilo lati sọ iru ayọ ti o kun ọkan mi nitori iṣẹlẹ alayọ yii, tabi iṣọna gbigbona ọkan mi lati kopa ninu ayọ awọn ti a rapada. Bibeli wa di iwe tuntun fun mi. Nitootọ, o jẹ ibi àṣè fun ironu; gbogbo ohun ti o ṣokunkun, ti ko yeni tabi ti o farasin ninu ikọni rẹ ni wọn kuro ninu ọkan mi nitori imọlẹ ti ó wa yọ lati inu oju ewé mimọ rẹ wa; ah! bawo ni otitọ rẹ ti mọlẹ to, ti o si logo to! Gbogbo itakora ati aidọgba ti mo ri ninu rẹ tẹlẹ ti lọ; lootọ ọpọ awọn abala ni oye wọn ko tẹmilọrun to, sibẹ imọlẹ ti o pọ tan jade lati inu rẹ lati tan imọlẹ si iye mi ti o ṣokunkun tẹlẹ, ti mo fi ni inudidun ni kikọ ẹkọ Iwe Mimọ ti emi ko lero tẹlẹ wipe a le ri ninu awọn ikọni rẹ.”ANN 147.2

  “Pẹlu igbagbọ wipe a ṣe isọtẹlẹ iru iṣẹlẹ nla bayii ninu Iwe Mimọ, ti yoo ṣẹlẹ ni akoko diẹ si igba ti a wa yii, ibeere wa si ọkan mi pẹlu agbara nla ti o sọ nipa ojuṣe mi si araye latari ẹri ti wọn nipa lori ọkan mi.” Ko le ṣe ki o ma ro wipe ojuṣe oun ni lati tan imọlẹ ti oun ti gba si awọn miran. O reti lati ni atako lati ọdọ awọn alaiwabiọlọrun, ṣugbọn o ni igboya wipe gbogbo Kristẹni ni yoo yọ ninu ireti lati pade Olugbala ti wọn sọ wipe wọn fẹran. Ibẹru kan ṣoṣo ti o ni ni wipe, ninu ayọ nla wọn fun ireti idande ologo, eyi ti yoo wa si imuṣẹ kiakia, ọpọlọpọ ni yoo gba ikọni naa laiṣe ayẹwo Iwe Mimọ finifini lati mọ boya o jẹ ootọ. Nitori naa, o lọra lati kede rẹ, ki o ma ba wa ninu aṣiṣe, ki o masi ṣe ṣi awọn miran lọna. Bayii ni o ṣe ṣe atunyẹwo awọn ẹri ti wọn kin awari rẹ lẹyin, ti o si wo gbogbo iṣoro ti wọn ba wa si lọkan finifini. O ri wipe awọn ibeere naa poora niwaju imọlẹ ọrọ Ọlọrun, bii kurukuru tii ṣe niwaju oorun. Ọdun marun ni o fi ṣe awọn ohun ti wọn jẹ ki o gbagbọ wipe igbagbọ oun tọna.ANN 147.3

  Bayi, ojuṣe lati sọ igbagbọ rẹ fun awọn miran, ti Bibeli fi kọni ni kedere wa kun lọkan pẹlu agbara lakọtun. O sọ pe, “Nigba ti mo ba n ṣe iṣẹ mi, o n ro gbọmọgbọmọ ni eti mi pe, ‘Lọ ki o si sọ fun araye nipa inu ewu ti wọn wa.’ Ẹsẹ yii saba maa n wa si ọkan mi: ‘Nigba ti mo ba sọ fun ẹlẹṣẹ, A! iwọ eniyan buburu, kiku ni iwọ yoo ku; bi iwọ ko ba sọrọ lati ṣe ikilọ fun ẹlẹṣẹ kuro ninu ọna rẹ, ẹlẹṣẹ naa yoo kú ninu aiṣedeede rẹ; ṣugbọn ẹjẹ rẹ ni Emi yoo beere lọwọ rẹ. Ṣugbọn bi o ba kilọ fun ẹlẹṣẹ lati yipada kuro ninu ọna rẹ, yoo ku ninu aiṣedeede rẹ, ṣugbọn iwọ ti gba ọkan rẹ la.’ Isikiẹli 33:8, 9. Mo mọ wipe bi a ba le kilọ fun awọn eniyan buburu daradara, ọpọlọpọ wọn ni yoo ronupiwada, ati pe bi mi o ba kilọ fun wọn, a o beere ẹjẹ wọn ni ọwọ mi.”ANN 147.4

  O bẹrẹ si nii sọ ohun ti o gbagbọ fun awọn eniyan lọkọọkan nigba ti o ba ri anfani, ti o si n gbadura ki awọn alufa diẹ baa le ni imọlara agbara wọn, ki wọn si fi ara wọn jin fun wiwaasu rẹ. Ṣugbọn ko le mu igbagbọ wipe oun ni ojuṣe lati fun awọn eniyan ni ikilọ kuro. Awọn ọrọ wọnyi saba maa n sọ si lọkan: “Lọ sọ fun araye; ẹjẹ wọn ni Emi yoo beere lọwọ rẹ.” Fun ọdun mẹsan, o duro, ti ẹru naa si wọ ọ lọkan, titi di 1831, nigba ti o sọ awọn ìdí fun igbagbọ rẹ ni igba akọkọ.ANN 147.5

  Gẹgẹ bi a ti pe Eliṣa lati ibi ti o ti n tẹle malu ninu oko, lati gba agbada iyasimimọ si ipo woli, bẹẹ gẹgẹ ni a pe William Miller lati kuro ni idi ohun ti o fi n ṣiṣẹ oko lati waasu awọn ohun ijinlẹ ijọba ọrun si awọn eniyan. O bẹrẹ iṣẹ rẹ pẹlu iwariri, o dari awọn olugbọ rẹ lẹsẹẹsẹ ninu awọn akoko isọtẹlẹ titi de ifarahan lẹẹkeji Kristi. Pẹlu gbogbo akitiyan o ni okun ati igboya bi o ti ri ti ifẹ fun ọrọ rẹ n gbilẹ si.ANN 147.6

  Nitori ipẹ awọn arakunrin rẹ, ninu eyi ti o ti gbọ ipe Ọlọrun, ni Miller fi gba lati sọ igbagbọ rẹ ni gbangba. Bayii o ti pe ọmọ aadọta ọdun, ko mọ bi wọn ti n sọrọ ni ita gbangba, aikunju oṣuwọn fun iṣẹ ti o wa niwaju rẹ si di ẹru wọ ọ lọrun. Ṣugbọn lati ibẹrẹ wa, a bukun iṣẹ rẹ pẹlu igbala awọn eniyan. Ẹkọ rẹ akọkọ fa isọji ninu ẹsin, ninu eyi ti idile mẹtala ronupiwada, ti o si ku eniyan meji silẹ. Lọgan ni a rọ ọ lati sọrọ ni awọn ibomiran, ati pe o fẹrẹ jẹ wipe ni ibi gbogbo, iṣẹ rẹ saba maa n yọri si isọji ninu iṣẹ Ọlọrun. Awọn ẹlẹṣẹ n yipada, awọn Kristẹni n jọwọ ara wọn silẹ fun iṣẹ Ọlọrun si, awọn ti wọn gbagbọ wipe Ọlọrun ko naani aye yii mọ ati awọn alaigbagbọ gba otitọ Bibeli ati ẹsin Kristẹni gbọ. Ẹri awọn ti o ṣiṣẹ laarin wọn ni wipe: “O de ọdọ awọn eniyan kan ti ẹlomiran ko le de.” O ṣe iwaasu rẹ lati ta iye awọn eniyan ji si ohun nla ti ẹsin ati lati da ifẹ aye ati ifẹkufẹ ara ti akoko naa duro.ANN 147.7

  O fẹrẹ jẹ wipe ni gbogbo ilu ti o lọ ọpọlọpọ eniyan, ni ibomiran, ni ọgọrọọrun, ni wọn yipada latari iwaasu rẹ. Ni ọpọlọpọ ilu wọn si ilẹkun ile ijọsin awọn Protestant silẹ fun laika ijọ wọn si, ti iwe ipe lati ṣiṣẹ si n wa ni pataki julọ lati ọdọ awọn alufa ijọ miran. O jẹ ipinu rẹ lati maṣe ṣiṣẹ nibi ti a ko ba ti pe e, sibẹ ko pẹ ti o fi ri wipe oun ko le dahun si aabọ ninu awọn iwe ipe ti wọn fun un. Ọpọ awọn ti ko gbagbọ ninu ero rẹ nipa igba gan ni pato fun ipadabọ lẹẹkeji ni igbagbọ wipe nitootọ, Kristi n bọ wa ati wipe, o sunmọle ati wipe wọn nilo imurasilẹ. Ninu awọn ilu miran, iṣẹ rẹ ni awọn ami ti o yatọ. Awọn ti n ta ọti fi ọja wọn silẹ ti wọn si sọ ibi itaja wọn di ile ipade; a tu awọn ibi ti a ti n ta tẹtẹ ka; awọn alaigbagbọ ati awọn ti wọn gbagbọ wipe Ọlọrun ko naani aye mọ, awọn ti wọn gbagbọ wipe gbogbo eniyan ni a o gbala, ani ati awọn ti wọn buru julọ ni wọn ṣe atunṣe, diẹ ninu wọn ni o jẹ wipe wọn koi tii wọ inu ile ijọsin fun ọjọ pipẹ. Oriṣiriṣi awọn ile ijọsin dá ipade adura silẹ ni ibi gbogbo, fun bi aarin wakati kọọkan, awọn oniṣowo a pejọ pọ ni ọsan fun adura ati isin. Ko si ariwo ti ko nitumọ, ṣugbọn gbogbo awọn eniyan ni wọn wa ni idakẹjẹ tọwọtọwọ. Iṣẹ rẹ, bii ti awọn Alatunṣe iṣaaju, jẹ lati ṣi eniyan loye ki o si pe ẹri ọkan si ojuṣe rẹ, kii kan i ṣe lati ru ẹmi awọn eniyan soke nikan lasan.ANN 148.1

  Ni 1833 Miller gba iwe aṣẹ lati waasu lati ọdọ ijọ Baptist, ọmọ ijọ eyi ti o n ṣe. Ọpọ awọn alufa inu ijọ rẹ naa ni wọn fi ọwọ si iṣẹ rẹ, o si tẹsiwaju ninu awọn akitiyan rẹ nitori pe wọn fi ọwọ si ni ọna ti o ba ofin mu. O rinrinajo, o si waasu laisinmi, bi o tilẹ jẹ wipe laarin New England ati Middle States nikan ni o ti n ṣiṣẹ. Fun ọdun diẹ, owo ara rẹ ni o n ná, ṣugbọn lẹyin eyi, owo ti o n ri ko to lati rin irinajo lọ si ọpọ awọn ibi ti a ti pe e. Nitori naa, iṣẹ itagbangba rẹ, dipo ki o sọ ọ di ọlọrọ, o gba awọn ohun ini rẹ ti o rọra n dinku si ni ní akoko igbe aye rẹ yii. Idile rẹ pọ, ṣugbọn nitori pe wọn n mura siṣẹ, wọn si n sọwo na, oko rẹ to gbogbo wọn jẹ.ANN 148.2

  Ni 1833, ọdun meji lẹyin ti Miller bẹrẹ si ni ṣe alaye awọn ẹri fun wiwa Kristi laipẹ ni ita gbangba, ami ti o kẹyin, eyi ti Olugbala ṣeleri gẹgẹ bi ami wiwa Rẹ lẹẹkeji, fi ara han. Jesu sọ pe: “Awọn irawọ yoo jabọ lati oju ọrun.” Matiu 24:29. Johanu ninu iwe Ifihan, bi o ti n wo awọn iran iṣẹlẹ ti yoo ṣaaju ọjọ Ọlọrun sọ wipe: “Awọn irawọ ọrun jabọ si aye, ani bi igi ọpọtọ ti i rẹ eso rẹ ti koi tii gbo nigba ti afẹfẹ nla mi i.” Ifihan 6:13. Asọtẹlẹ yii ni imuṣẹ ti o lagbara ti o si banilẹru ninu awọn “irawọ ti wọn jabọ ni November 13, 1833. Eyi ni iṣẹlẹ irawọ ti o jabọ ti o pọ ti o si yanilẹnu julọ ninu itan; “oju ọrun, ni gbogbo United Sates, fun wakati diẹ, kun fun idarudapọ imọlẹ! Ko si iru iṣẹlẹ oju ọrun bẹẹ ti o ti ṣẹlẹ ri ni orilẹ ede yii, lati igba ti a ti tẹdo si ori rẹ, awọn ẹgbẹ kan ni ilu fi tiyanutiyanu wo o, awọn miran si n fi tibẹrutibẹru wo o.” “Ọla ati iyanu ẹwa rẹ si wa ni iranti ọpọ eniyan. . . . Ojo koi tii rọ pupọ to bi irawọ ti rọ sori ilẹ aye; ila oorun, iwo oorun, ariwa ati gusu, bakan naa ni o ri. Ni ọrọ kan o dabi ẹnipe gbogbo oju ọrun n yi biri. . . . Iṣẹlẹ naa, bi Professor Silliman ti ṣe alaye rẹ ninu Journal ni a ri ni gbogbo North America. . . . Lati ago meji titi fi di oju mọnmọn, ko si ikuuku tabi idarudapọ loju awọsanma, imọlẹ ti n dan n fi ara han ni oju ọrun.”ANN 148.3

  “Nitootọ, ko si ede kan ti o le ṣe alaye didan iṣẹlẹ ogo naa; . . . ẹni ti ko ri ko le mọ bi ogo rẹ ti pọ to. O dabi ẹnipe gbogbo irawọ oju ọrun ko ara wọn jọ pọ si oju kan naa ni oke, wọn wa n jumọ jabọ papọ, pẹlu iyara mọnamọna, si gbogbo oju ilẹ; sibẹ, wọn ko tan—ẹgbẹẹgbẹrun ni wọn n tẹle ipasẹ ẹgbẹẹgbẹrun, ayafi bi ẹnipe nitori bẹẹ ni a ṣe da wọn.” “Iṣẹlẹ ti o dabi igi ọpọtọ ti n rẹ eso rẹ nigba ti afẹfẹ nla ba fẹ lu u ni lootọ, ko ṣe e ṣe lati wo o.”ANN 148.4

  Ninu New York Journal of Commerce ti November 14, 1833, ayọka gigun kan wa ti o sọ nipa iṣẹlẹ agbayanu yii, o sọ pe: “Ko si alarojinlẹ tabi ọmọwe ti o tii sọ tabi kọ iru iṣẹlẹ bii ti eyi ti o ṣẹlẹ ni aarọ àná yẹn silẹ. Woli kan, fun 1800 ọdun sẹyin sọ ọ tẹlẹ gẹẹlẹ, bi a ba maa ni iṣoro lati mọ wipe irawọ ti o n jabọ tumọ si jijabọ irawọ, . . . ni ọna ti o gba ṣẹlẹ yii nikan ni o fi le jẹ ootọ.”ANN 149.1

  Bayii ni eyi ti o kẹyin ninu awọn aami wiwa rẹ, nipa eyi ti Jesu sọ fun awọn ọmọ ẹyin Rẹ: “Nigba ti ẹyin ba ri awọn nnkan wọnyi, mo wipe o sunmọle, ani lẹnu ilẹkun.” Matiu 24:23. Lẹyin awọn aami wọnyi, Johanu kiyesi, gẹgẹ bi iṣẹlẹ nla ti o tẹle, awọn ọrun n ṣi gẹgẹ bi iwe, nigba ti ilẹ n ri, oke ati awọn erekuṣu n kuro ni ipo wọn, ti awọn ẹni buburu, nitori ẹru, n wa ọna lati sa kuro niwaju Ọmọ eniyan. Ifihan 6:12—17.ANN 149.2

  Ọpọlọpọ awọn ti wọn ri irawọ ti n jabọ wo o gẹgẹ bi akede idajọ ti n bọ, “apẹẹrẹ ti o banilẹru, atọna ti o daju, aami aanu, fun ọjọ nla ti o lẹru.” Bayi ni a ṣe dari akiyesi awọn eniyan si imuṣẹ asọtẹlẹ, eyi si jẹ ki ọpọlọpọ o tẹti si ikilọ nipa ipadabọ lẹẹkeji.ANN 149.3

  Ni ọdun 1840, imuṣẹ asọtẹlẹ ni ọna ti o yanilẹnu julọ tun jẹ ki ifẹ awọn eniyan o ru soke si. Ni ọdun meji ṣaaju, Josiah Litch, ọkan ninu awọn aṣaaju oniwaasu ti n kede ipadabọ lẹẹkeji, tẹ iwe kan jade nipa iwe Ifihan ori kẹsan, o sọ asọtẹlẹ nipa iṣubu Ottoman Empire. Gẹgẹ bi iṣiro rẹ ti sọ, a o bi agbara yii lulẹ ni A. D. 1840, ni akoko kan ninu oṣu kẹjọ;” ni ọjọ diẹ ṣaaju imuṣẹ rẹ, o kọwe wipe: “Bi a ba gba wipe abala akoko, 150 ọdun, wa si imuṣe daradara ki Deacozes to gun ori itẹ nipa aṣẹ awọn Turk, ati wipe ọdun 391 ati ọjọ marundinlogun, bẹrẹ ni opin abala akoko yii, yoo pari ni ọjọ kọkanla oṣu kẹjọ, 1840 nigba ti a n reti ki agbara Ottoman ni Consantinople o fọ. Eyi ni mo gbagbọ wipe yoo ṣẹlẹ.”ANN 149.4

  Ni akoko ti a tọka si yii gan, Turkey nipasẹ aṣoju rẹ, gba idaabobo akojọpọ agbara Europe, bayii ni o ṣe fi ara rẹ si abẹ aabo awọn orilẹ ede Kristẹni. Iṣẹlẹ yii mu ki akọsilẹ naa o wa si imuṣẹ rẹgi. Nigba ti a mọ eyi, ọpọlọpọ ni gbangba sọ wipe ilana ti a fi n tumọ isọtẹlẹ ti Miller ati awọn akẹgbẹ rẹ lo tọna, eyi si fun ẹgbẹ ti n kede ipadabọ lagbara to yanilẹnu. Awọn ọmọwe ati awọn ọtọnkulu ilu darapọ mọ Miller lati waasu ati lati ṣe itẹjade awọn ero rẹ, bayii ni iṣẹ naa ṣe tan kalẹ jọjọ lati 1840 de 1844.ANN 149.5

  William Miller ni ọpọlọ ti o yè kooro, ti o ni nipasẹ ironu ati ẹkọ; o tun fi ọgbọn ọrun kun eyi nipa siso ara rẹ pọ mọ Orisun ọgbọn. O jẹ olootọ eniyan, ti ko le ma ri ibọwọfun ati ibọlafun awọn eniyan nibikibi ti a ba ti bu ọla fun iṣotitọ ati iwa rere. Ni síso inurere ọkan tootọ pọ pẹlu irẹlẹ Kristẹni ati agbara ikoraẹni-nijanu, o jẹ olutẹtisini ti o tun ṣe e rọrun lati ba sọrọ, o ṣetan lati tẹti si ero awọn miran, ki o si gbé koko ọrọ wọn yẹwo. Laisi igbonara tabi iru-ẹmi-soke, o yẹ gbogbo ero ati ikọni wo pẹlu ọrọ Ọlọrun, iṣọwọronu rẹ ti o ye kooro ati imọ rẹ ninu Iwe Mimọ si ran an lọwọ lati tako irọ ati lati ṣe afihan èké.ANN 149.6

  Sibẹ ko ṣe iṣẹ rẹ laisi atako kíkorò. Gẹgẹ bi o ti ṣẹlẹ si awọn Alatunṣe iṣaaju, awọn olukọ ẹsin ti wọn ti di ilumọọka ko fi oju rere wo otitọ ti o n kede. Nigba ti awọn olukọ wọnyi ko le fi Iwe Mimọ gbe ara wọn lẹsẹ, wọn bere si i lo ikọni ati ọrọ eniyan, ikọni awọn Baba ijọ. Ṣugbọn ọrọ Ọlọrun nikanṣoṣo ni ẹri ti oniwaasu otitọ ti ipadabọ gba. “Bibeli, ati Bibeli nikan,” ni akọmọna wọn. Nitori ti awọn alatako ko le fi Bibeli gbe ara wọn lẹsẹ, wọn wa n lo ẹgan ati ifiniṣẹsin. Akoko, ohun ini, ati ẹbun ni a lo lati ṣe ibalorukọjẹ awọn ti o jẹ wipe ẹṣẹ wọn ko ju wipe wọn n wọna fun ipadabọ Oluwa wọn pẹlu ayọ ati pe wọn n gbiyanju lati gbe igbesi aye mimọ, ti wọn si n gba awọn iyoku niyanju lati mura silẹ fun ifarahan Rẹ.ANN 149.7

  A ṣe iṣẹ takuntakun lati yi ọkan awọn eniyan pada kuro ninu ọrọ nipa ipadabọ lẹẹkeji. A ṣe afihan rẹ bi ẹnipe ẹṣẹ ni, ohun ti o yẹ ki o ti eniyan loju ni lati kọ nipa awọn isọtẹlẹ ti wọn ni i ṣe pẹlu wiwa Kristi ati opin aye. Bayi awọn ijọ ti wọn gbajugbaja ṣe tẹ igbagbọ ninu ọrọ Ọlọrun rì. Ikọni wọn sọ ni di alaigbagbọ, ti ọpọlọpọ si yan lati rin ninu ifẹkufẹ alaiwabiọlọrun wọn. Awọn olupilẹsẹ iwa buburu si sọ wipe awọn onireti ni wọn fa a.ANN 149.8

  Nigba ti awọn ọlọgbọn n ṣe atẹlẹ rẹ ti awọn eniyan si ti n fi tọkantọkan tẹti silẹ, orukọ Miller ki i jade ninu iwe atẹjade awọn ijọ ayafi lati fi ṣe ẹlẹya tabi bi wọn ba fẹ ṣe atako rẹ. Atako awọn olukọ ẹsin ki awọn alaibikita ati alaiwabiọlọrun laya, wọn n lo ọrọ ti ko tọ, awọn awada ti ko yẹ, ti ko pọnnile, ninu akitiyan wọn lati kó iwọsi ba ati iṣẹ rẹ. A fi ẹgan pe, baba agbalagba naa, ti o fi itunu ile rẹ silẹ lati rin irinajo pẹlu owo ara rẹ lati ilu de ilu, lati ileto de ileto, ti o n ṣiṣẹ laisinmi lati jiṣe ikilọ idajọ ti o sunmọle fun araye, ní elerokero nipa ẹsin, opurọ ati ẹlẹtan eniyan.ANN 150.1

  Ẹsin, irọ ati eebu ti a fi bu jẹ ki awọn ontẹwe ti ki i ṣe ti ẹsin o fesi pẹlu ibinu. “Lati dahun si ọrọ ti o lola ti o si ni atubọtan ti o lẹru,” pẹlu ọwọ yẹpẹrẹ ati awada ni awọn aye kede wipe “kii tilẹ n ṣe wipe o n fi ero awọn ti n kede, ti wọn si n kọni nipa rẹ ṣe ẹfẹ nikan,” ṣugbọn “o tumọ si fifi ọjọ idajo ṣẹfẹ, fifi Ọlọrun funra Rẹ ṣẹfẹ, ati kikẹgan ẹru ile idajọ Rẹ.”ANN 150.2

  Olupilẹṣẹ gbogbo iwa buburu n wa ọna, ki i ṣe lati ba agbara iwaasu ipadabọ jẹ nikan, ṣugbọn lati pa ojiṣẹ naa funra rẹ. Miller jẹ ki otitọ inu Iwe Mimọ o wọ ọkan awọn olugbọ rẹ lọ, o ba ẹṣẹ wọn wi, o damu itẹraẹnilọrun wọn, awọn ọrọ taara rẹ ti n wọni lọkan si fa ikorira wọn. Atako awọn ọmọ ijọ si iṣẹ iranṣẹ rẹ mu awọn oniwaibajẹ lọkan le lati ṣe ju bẹẹ lọ; awọn ọta pero lati gba ẹmi rẹ nigba ti o fẹ kuro ni ibi ipade. Ṣugbọn angẹli mimọ pọ nibẹ, ọkan ninu wọn, ninu awọ eniyan fa iranṣẹ Oluwa lọwọ kuro lọwọ ibinu ọpọ ero lọ si ibi aabo. Koi tii pari iṣẹ rẹ, Satani ati awọn aṣoju rẹ si n baku ninu erongba wọn.ANN 150.3

  Pẹlu gbogbo atako wọnyi, ifẹ awọn eniyan ninu ẹgbẹ ti n kede ipadabọ tubọ n pọ si. Lati bii awọn eniyan diẹ, wọn ti di ẹgbẹlẹgbẹ. Wọn lọ si oriṣiriṣi ile ijọsin, ṣugbọn lẹyin igba diẹ, ẹmi atako dide si awọn ti wọn yipada, awọn ijọ si bẹrẹ si ni ba awọn ti wọn gba ero Miller gbọ wi. Iwa yii mu ki o kọwe lati fesi, ninu iwe ti o kọ si gbogbo Kristẹni, o sọ pe bi awọn ikọni oun ba jẹ irọ, ki wọn fi aṣiṣe oun han lati inu Iwe Mimọ.ANN 150.4

  O sọ wipe, “Kini a gbagbọ ti kii ṣe ọrọ Ọlọrun ni o paṣẹ fun wa lati gba a gbọ, eyi ti ẹyin gba wipe ohun ni odiwọn, odiwọn kan ṣoṣo fun igbagbọ ati iṣesi? Kini a ṣe ti o yẹ ki o mu iru ibawi nigbangba bayẹn wa ni atako si wa lati ori pẹpẹ iwaasu ati lati ile itẹwe, ti o tun fun yin ni idi ti o tọ lati yọ wa [awọn Onireti] kuro ninu ijọ ati ibaṣepọ yin?” “Bi a ba ṣe aṣiṣe, ẹ fihan wa nibi ti a ti ṣe e. Ẹ fihan wa lati inu ọrọ Ọlọrun wipe a ṣe aṣiṣe; ifiniṣẹsin yii ti to; eyi ko le mu wa gbagbọ wipe a ko tọna; ọrọ Ọlọrun nikan ni o le yi igbagbọ wa pada. A ṣe agbekalẹ ohun ti a gbagbọ pẹlu ero ati adura, bi a ti n ri ẹri rẹ lati inu Iwe Mimọ.”ANN 150.5

  Lati igba de igba iru ẹmi aigbagbọ kan naa ni awọn eniyan fi maa n gba awọn ikilọ ti Ọlọrun ran si aye nipasẹ awọn iranṣẹ Rẹ. Nigba ti ẹṣẹ awọn eniyan ti wọn wa ṣaaju ikun omi mu ki omi o kun ori ilẹ aye, O kọkọ fi erongba Rẹ han wọn, ki wọn baa le ni anfani lati yi kuro ninu ọna buburu wọn. Fun ọgọfa ọdun ni a fi kede ikilọ leti wọn wipe ki wọn ronupiwada, ki ibinu Ọlọrun ma baa wá fun iparun wọn. Ṣugbọn iṣẹ iranṣẹ naa dabi alọ ni eti wọn, wọn ko si gba a gbọ. Wọn ni igboya si ninu iwa buburu wọn, wọn fi iranṣẹ Ọlọrun ṣẹsin, wọn tẹnbẹlu ipẹ rẹ, ani wọn fi ẹsun gbigba nnkan gbọ lainidi kan an. Bawo ni ẹnikan ṣe le duro koju awọn eniyan nla aye? Bi iṣẹ iranṣẹ Noah ba jẹ otitọ, kilode ti gbogbo aye ko fi gba a gbọ? Igbagbọ ẹnikan ni atako si ọgbọn awọn ẹgbẹlẹgbẹ! Wọn ko gba ikilọ naa gbọ, bẹẹ si ni wọn ko wa aabo ninu ọkọ.ANN 150.6

  Awọn ẹlẹgan tọka si awọn ohun ti a da,—si bi igba ti n lọ ni akoko wọn laiyẹsẹ, si oju ọrun ti koi tii rọjo ri, si papako ti ìrì alẹ n bomi rin,—wọn si kigbe wipe: “Ṣe kii ṣe alọ ni o n pa bi?” Pẹlu ẹgan, wọn kede wipe oniwaasu ododo ti di onitara gbigbona to ti yan ẹhana; wọn si tẹsiwaju si ní wiwa faaji, wọn si mọọmọ rin ni ọna iwa buburu ju ti atijọ lọ. Ṣugbọn aigbagbọ wọn ko di iṣẹlẹ ti a ti sọ tẹlẹ lọwọ. Ọlọrun fi ara da iwa buburu wọn fun igba pipẹ, O n fun wọn ni anfani pupọ fun ironupiwada; ṣugbọn nigba ti akoko to, O bẹ idajọ Rẹ wo lori awọn ti wọn ti kọ aanu Rẹ silẹ.ANN 150.7

  Kristi sọ wipe iru aigbagbọ kan naa ni awọn eniyan yoo fihan nipa ipadabọ Rẹ lẹẹkeji. Gẹgẹ bi awọn eniyan ni akoko Noah “ko ti mọ titi ti ikun omi fi de, ti o si gba gbogbo wọn lọ; bẹẹ gẹgẹ,” ninu ọrọ Olugbala wa, “ni wiwa Ọmọ eniyan yoo ti ri.” Matiu 24:39. Nigba ti awọn ti wọn pe ara wọn ni eniyan Ọlọrun ba n darapọ mọ aye, ti wọn n gbe bii ti wọn, ti wọn si n dara pọ mọ wọn ninu faaji ti ko tọ; nigba ti ọrọ aye ba di ọrọ ijọ; nigba ti agogo igbeyawo ba n dun, ti gbogbo eniyan si n wo ọjọ iwaju fun ọpọ ọrọ aye—nigba naa, lọgan gẹgẹ bi mọnamọna oju ọrun, ni opin yoo de ba iran ologo ati ireti ẹtan wọn.ANN 151.1

  Bi Ọlọrun ti ran iranṣẹ Rẹ lati kilọ fun araye nipa ikun omi ti o n bọ, bẹẹ gẹgẹ ni O ran awọn iranṣẹ Rẹ ti O yan lati ṣe afihan bi idajọ ti o kẹyin ti sunmọ to. Bi awọn eniyan nigba aye Noah ti kẹgan asọtẹlẹ oniwaasu ododo, bẹẹ gẹgẹ ni akoko Miller ọpọlọpọ, ani awọn ti wọn pe ara wọn ni eniyan Ọlọrun ti ṣe kẹgan ọrọ ikilọ.ANN 151.2

  Kilo wa de ti awọn ijọ ko fi tẹwọgba ikọni ati iwaasu ipadabọ Kristi lẹẹkeji? Nigba ti o jẹ wipe wiwa Oluwa mu ègbé ati iparun ba awọn eniyan buburu, ti o si kun fun ayọ ati ireti fun awọn olododo. Otitọ nla yii ni o ti n jẹ itunu awọn olootọ Ọlọrun lati igba yii wa; kilo wa de, gẹgẹ bi Olupilẹsẹ rẹ, ti o fi di “okuta idigbolu” ati “apata ikọsẹ” si awọn eniyan Rẹ? Oluwa wa funra Rẹ ni o ṣeleri fun awọn ọmọ ẹyin Rẹ pe: “Bi mo ba lọ lati pese aye silẹ fun yin, Emi yoo pada wa lati gba yin si ọdọ Emi tikalara Mi.” Johanu 14:3. Olugbala alaanu, ti o wo idanikanwa ati ibanujẹ awọn atẹle Rẹ, ni o sọ fun awọn angẹli lati tu wọn ninu pẹlu idaniloju wipe Oun yoo pada wa ni eniyan, ani gẹgẹ bi O ti lọ si ọrun. Bi awọn ọmọ ẹyin ti n tẹju mọ oke ọrun, lati ṣe awokẹyin Ẹni ti wọn fẹran, awọn ọrọ wọnyi ni wọn gbọ: “Ẹyin ara Galili, eeṣe ti ẹyin fi n duro wo oju ọrun? Jesu yii kan naa ti a gba kuro lọwọ yin lọ si ọrun, yoo pada wa bẹẹ gẹgẹ bi ẹyin ti ri ti O lọ si ọrun.” Iṣe 1:11. Iṣẹ iranṣẹ awọn angẹli tun sọ ireti wọn ji. Awọn ọmọ ẹyin “pada si Jerusalẹmu pẹlu ayọ nla: wọn si n wa ninu tẹmpili nigba gbogbo, wọn n yin, wọn si n bukun Ọlọrun.” Luku 24:52, 53. Inu wọn ko dun nitori pe Jesu kuro ni ọdọ wọn, ti a si fi wọn silẹ lati jijakadi pẹlu wahala ati idanwo aye, ṣugbọn nitori idaniloju awọn angẹli naa wipe, yoo pada wa.ANN 151.3

  Ni akoko yii, ikede nipa wiwa Kristi yẹ ki o dabi eyi ti awọn angẹli ṣe fun awọn darandaran ti Bẹtlẹhẹmu, iroyin rere ti ayọ nla. Awọn ti wọn fẹran Olugbala nitootọ ko le ṣe ayafi ki wọn fi ayọ kede iroyin ti o da lori ọrọ Ọlọrun wipe Ẹni ti ireti wọn fun iye ainipẹkun dale lori n padabọ, kii ṣe lati kẹgan Rẹ, tabi lati kọ Ọ silẹ, tabi lati fi ṣe ẹlẹya, gẹgẹ bi o ti ṣẹlẹ ni igba wiwa Rẹ lakọkọ, ṣugbọn pẹlu agbara ati ogo lati ra awọn eniyan Rẹ pada. Awọn ti ko fẹran Olugbala ni wọn fẹ ki O duro sọhun, a ko tun le ri ẹri ti o daju miran wipe awọn ijọ ti yapa kuro lọdọ Ọlọrun ju ibinu ati ikorira ti iṣẹ iranṣẹ lati Ọrun wa yii mu wa lọ.ANN 151.4

  Awọn ti wọn gba ikọni ti ipadabọ ji dide si ironupiwada ati irẹra-ẹni-silẹ niwaju Ọlọrun. Ọpọlọpọ ni wọn duro laarin Kristi ati aye; bayii wọn ri wipe o to akoko lati pinu. “Ohun iye ainipẹkun wa jẹ otitọ fun wọn. Ọrun sunmọ wọn, wọn si ri wipe wọn jẹbi niwaju Ọlọrun.” A sọ awọn Kristẹni ji si igbesi aye ẹmi tuntun. A jẹ ki wọn mọ wipe akoko kúrú, wipe wọn nilati ṣe ohunkohun ti wọn ba fẹ ṣe fun eniyan ni kiakia. Aye fasẹyin, o dabi ẹnipe a ṣi iye ainipẹkun silẹ niwaju wọn, ati ọkan wọn, pẹlu ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu irọrun tabi wahala aye, dabi enipe ó kẹyin si ohun gbogbo ti o nii ṣe pelu aye yii. Ẹmi Ọlọrun ba le wọn O si fi agbara fun ipẹ atọkanwa wọn fun awọn arakunrin wọn, ati fun awọn ẹlẹṣẹ lati mura silẹ fun ọjọ Ọlọrun. Ẹri igbe aye ojoojumọ wọn ti ko fa ariwo jẹ ibawi atigbadegba fun awọn ọmọ ijọ lasan ati awọn ti ko ni ẹmi ifaraẹnijin. Awọn wọnyi ko fẹ ki a damu wọn ni bi wọn ti n le faaji, bi wọn ti n fẹ lati ni owo ati ifẹ wọn fun ọla aye. Eyi ni o fa ikorira ati atako fun igbagbọ nipa ipadabọ ati si awọn ti n kede rẹ.ANN 151.5

  Bi koko ọrọ ninu awọn akoko isọtẹlẹ ko ti ṣe e bi ṣubu, awọn alatako rẹ ṣa ipa lati maṣe jẹ ki awọn eniyan o ṣe ayẹwo rẹ nipa kikọ ni wipe a ti sé awọn asọtẹlẹ pa. Bayii ni awọn Protestant ṣe rin ni ilana awọn ẹlẹsin Romu. Nigba ti ijọ padi fi Bibeli pamọ kuro lọdọ awọn eniyan, awọn ijọ Protestant sọ wipe eyi ti o ṣe pataki ninu ọrọ Ọlọrun—abala eyi ti o sọ nipa awọn otitọ ti wọn ni i ṣe pẹlu akoko wa—kò le yeni.ANN 151.6

  Awọn alufa ati awọn eniyan kede wipe awọn asọtẹlẹ Daniẹli ati ti Ifihan jẹ awọn ohun ijinlẹ ti ko le yeni. Ṣugbọn Kristi dari awọn ọmọ ẹyin Rẹ si ọrọ woli Daniẹli nipa awọn iṣẹlẹ ti yoo ṣẹlẹ ni akoko wọn, O sọ pe: “Jẹ ki ẹnikẹni ti o ba ka a ki o ni oye.” Matiu 24:15. Ọrọ wipe iwe Ifihan jẹ ohun ijinlẹ ti ko le yeni, tako akọle iwe naa funra rẹ: “Ifihan Jesu Kristi, ti Ọlọrun fi fun, lati fihan awọn iranṣẹ Rẹ, awọn ohun ti yoo ṣẹlẹ laipẹ. . . . Ibukun ni fun ẹni ti o ka a, ati awọn ti wọn gbọ, ọrọ asọtẹlẹ yii, ti wọn si pa awọn ohun ti a kọ sinu rẹ mọ: nitori ti akoko sunmọ etile.” Ifihan 1:1-3.ANN 152.1

  Woli naa sọ wipe: “Ibukun ni fun ẹni ti o ka a”—awọn kan wa ti ko ni ka a; ibukun naa ki i ṣe fun wọn. “Ati awọn ti wọn gbọ”—awọn kan wa pẹlu ti wọn kọ lati gbọ ohunkohun nipa awọn asọtẹlẹ; ibukun naa ki i ṣe fun awọn ẹgbẹ yii. “Ti wọn si pa ohun ti a kọ sinu rẹ mọ”—ọpọ ni wọn kọ lati tẹti si ikilọ ati iyanju ti o wa ninu Ifihan; ko si ọkan ninu awọn wọnyi ti o le gba ibukun ti a ṣeleri. Gbogbo awọn ti wọn fi ọrọ asọtẹlẹ ṣe ẹlẹya, ti wọn fi awọn ami inu rẹ ṣe ẹsin, gbogbo awọn ti wọn kọ lati tun aye wọn ṣe ati lati mura silẹ de wiwa Ọmọ eniyan ko ni jẹ alabukunfun.ANN 152.2

  Pẹlu ẹri Imisi niwaju wa, bawo ni eniyan ṣe le koni wipe iwe Ifihan jẹ ohun ijinlẹ ti o kọja oye eniyan? O jẹ ohun ijinlẹ ti a fihan, iwe ti a ṣi silẹ. Kikọ nipa iwe Ifihan dari oye eniyan si awọn asọtẹlẹ Daniẹli, ti awọn mejeeji si ṣe afihan ikọni ti o ṣe pataki julọ, ti Ọlọrun fun eniyan, nipa awọn iṣẹlẹ ti yoo ṣẹlẹ ni opin itan aye yii.ANN 152.3

  A ṣi awọn iṣẹlẹ ti wọn jinlẹ ti wọn si ṣe pataki ninu iriri ijọ han Johanu. O ri ipo ewu, ijakadi ati idande nikẹyin fun awọn eniyan Ọlọrun. O ṣe akọsilẹ awọn iṣẹ iranṣẹ ti wọn kẹyin ti yoo mu ki ikore aye yii pọn, boya gẹgẹ bi iti fun àká ọrun ni o tabi gẹgẹ bi ohun idana fun ina apanirun. Awọn koko ọrọ ti wọn ṣe pataki jọjọ ni a fi han an, ni pataki julọ fun ijọ ti o kẹyin, pe ki awọn ti wọn ba fẹ yi kuro ninu irọ wa si otitọ le mọ nipa awọn ewu ati ijakadi ti o wa niwaju wọn. Ko si ẹni ti o yẹ ki o wa ninu okunkun nipa ohun ti n bọwa si ori ilẹ aye.ANN 152.4

  Ki lo de ti aimọkan fi wọpọ nipa abala Iwe Mimọ ti o ṣe pataki yii? Ki lo de ti awọn eniyan fi n lọra lati ṣe ayẹwo awọn ikọni rẹ? Nitori akitiyan ọmọ alade okunkun ni lati maṣe jẹ ki awọn eniyan o ri ohun ti o n ṣe afihan ẹtan rẹ. Nitori idi eyi, Kristi Onifihan, ti O ri ogun ti a o ṣi si kikẹkọ iwe Ifihan, kede ibukun si ori gbogbo awọn ti wọn yoo ka, gbọ ati ṣe awọn ọrọ asọtẹlẹ.ANN 152.5

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents