Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  ORI KẸRIN—AWỌN WALDENSES

  Ninu okunkun ti ó bo aye mọlẹ ni akoko gigun tí ijọ paadi fi ṣe akoso, ina otitọ kò ku tan patapata. Ni gbogbo igba, Ọlọrun maa n ni awọn olujẹri—awọn ti wọn mu igbagbọ ninu Kristi gẹgẹ bi alagbawi kan ṣoṣo laarin Ọlọrun pẹlu eniyan lọkunkundun, ti wọn gba Bibeli gẹgẹ bi odiwọn fun igbesi aye, ti wọn si bọwọ fun ọjọ Isinmi tootọ. Arọmọdọmọ ko le mọ ohun ti ayé ní nipasẹ awọn eniyan wọnyi. A pe wọn ni ẹlẹkọ odi, a ṣe atako erongba wọn, a sọ ọrọ buburu nipa iwa wọn, a fi ipa tẹ akọsilẹ wọn rì, a ṣe afihan wọn ni ọna ti ko tọ, tabi ki a pa wọn run. Sibẹ wọn duro gbọin, lati iran de iran, wọn pa igbagbọ mọ ninu ailabawọn rẹ, gẹgẹ bi ohun ajogunba mimọ fun iran ti n bọ.ANN 25.1

  A kọ itan awọn eniyan Ọlọrun ni akoko okunkun ti o tẹle iṣakoso Romu si ọrun, bi o tilẹ jẹ wipe wọn ko ni aaye ti o pọ ninu akọsilẹ eniyan. Akọsilẹ perete ni a le ri nipa igbesi aye wọn, ayafi eyi ti a ri ninu ifẹsunkan awọn ti n ṣe inunibini si wọn. Iwa Romu ni lati pa gbogbo akọsilẹ awọn ti ko gba ikọni tabi aṣẹ rẹ rẹ. O n wọna lati pa ohunkohun ti o ba jẹ mọ ẹkọ òdì run, i baa jẹ eniyan tabi akọsilẹ. Fifi iyemeji han tabi bibeere ibeere lori aṣẹ awọn ikọni ijọ paadi to lati mu ni padanu ẹmi ẹni i baa jẹ ọlọrọ tabi talaka, ẹni giga tabi ẹni rirẹlẹ. Romu tun ṣe akitiyan lati pa gbogbo akọsilẹ iwa ika rẹ si awọn ti wọn tako o run. Igbimọ ijọ paadi pa aṣẹ wipe ki a sọ gbogbo iwe ati akọsilẹ ti wọn ba ni iru akọsilẹ bayi sinu ina. Ṣaaju ki a to ṣe ẹrọ itẹwe sita, awọn iwe kere niye, wọn tun wa ni ọna ti a ko fi le pa wọn mọ; nitori naa iwọnba ohun perete ni a le ṣe lati di awọn atẹle Romu lọwọ lati gbe erongba wọn jade.ANN 25.2

  Ko si ijọ kankan ni arọwọto aṣẹ Romu ti a fi silẹ fun igba pipẹ lati jẹ igbadun ominira ẹri ọkan. Lọgan ti ijọ paadi gba agbara, ó na ọwọ rẹ lati ṣe ipalara fun awọn ti wọn kọ lati gba aṣẹ rẹ, ni meni meji, awọn ijọ si n tẹriba fun aṣẹ rẹ.ANN 25.3

  Ni Great Britain ẹsin Kristẹni ti igba atijọ tete fi ẹsẹ mulẹ. Iyinrere ti awọn ara Britain gba ni ọrundun kini kò ni abawọn iyapa Romu. Inunibini lati ọdọ awọn ọba abọriṣa, ti o de awọn ilẹ jijin wọnyi nikan ni ẹbun ti awọn ijọ akọkọ ni Britain gba lọwọ Romu. Ọpọlọpọ awọn Kristẹni ti wọn n sa fun inunibini ni England ri aabo ni Scotland; lati ibẹ ni a ti gbe otitọ lọ si Ireland, wọn si fi ayọ gba a ni gbogbo awọn orilẹ ede wọnyi.ANN 25.4

  Nigba ti awọn Saxons kọlu awọn Britain, ẹsin ibọriṣa gba àkóso. Awọn aṣẹgun korira ki awọn ẹrú wọn o kọ wọn, eyi mu ki awọn Kristẹni o salọ si aarin awọn oke ati aginju. Sibẹ imọlẹ, ti o fi ara pamọ fun igba diẹ, tẹsiwaju lati tan. Ni ọgọrun ọdun lẹyin eyi, ni Scotland, itansan rẹ mọlẹ de awọn ilẹ jijinna réré. Columba olufọkansin ati awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ wa lati Ireland, wọn ko awọn onigbagbọ ti wọn fọn kaakiri mọra si erekuṣu Iona, ibujoko iṣẹ ijere ọkan rẹ. Ẹni ti o n pa ọjọ Isinmi Bibeli mọ wà lara awọn ajiyinrere wọnyi, bayi ni otitọ yii ṣe wọ aarin awọn eniyan naa. A da ile-iwe silẹ ni Iona, nibi ti awọn ajere ọkan ti jade lọ si Scotland ati England, ani lọ si Germany, Switzerland, ani titi de Italy.ANN 25.5

  Ṣugbọn Romu ti kọ oju rẹ si Britain, o si ti pinu lati mu u wa si abẹ iṣakoso rẹ. Ni ọrundun kẹfa, awọn ajere ọkan rẹ ṣiṣẹ ijere ọkan awọn Saxons ti wọn jẹ abọriṣa. Awọn agberaga ti ko laju yii gba wọn pẹlu oju rere, wọn si jẹ ki ọpọlọpọ wọn o gba igbagbọ Romu. Bi iṣẹ naa ti n tẹsiwaju, awọn adari ijọ paadi ati awọn ti wọn yipada wa ṣe alabapade awọn Kristẹni ti wọn gba igbagbọ igba atijọ. Wọn yatọ si ara wọn patapata. Awọn kan jẹ onirẹlẹ, olootọ, ti ìwà, ikọni, ati iṣesi wọn si ba Iwe Mimọ mu, nigba ti awọn keji fi aimọkan, iwuga ati igberaga ẹsin popu han. Awọn aṣoju Romu paṣẹ ki awọn ijọ Kristeni wọnyi o tẹriba fun aṣẹ popu. Awọn ara Britain fi irẹlẹ dahun wipe wọn nifẹ lati fẹran gbogbo eniyan, ṣugbọn popu ko ni ẹtọ si ipo ti o ga julọ ninu ijọ, ati wipe wọn a fun ni itẹriba ti o yẹ fun gbogbo atẹle Kristi. Ọpọlọpọ akitiyan ni a ṣe lati le ri wipe wọn ṣe igbọran si Romu; ṣugbọn awọn Kristẹni onirẹlẹ, ti ẹnu yà nitori igberaga ti awọn aṣoju Romu fihan yii, dahun pẹlu iduroṣinṣin wipe wọn ko mọ oluwa miran ayafi Kristi. Ni bayii ẹmi ijọ paadi nitootọ wa fi ara han. Adari Romu sọ wipe: “Bi ẹ ko ba ni gba awọn ara ti wọn mu alaafia wa fun yin, ẹ yoo gba awọn ọta ti yoo wa ko ogun ja yin. Bi ẹ ko ba ni da ara pọ mọ wa lati fi ọna iye han awọn ara Saxon, ẹ yoo gba pasan iku lati ọdọ wọn.” Eyi ki i ṣe ihalẹ lasan. Ogun, iditẹ ati ẹtan ni a lo lati ṣe atako si awọn ẹlẹri si igbagbọ Bibeli wọnyi, titi ti a fi pa awọn ijọ Britain run, tabi ti a fi fi ipa mu wọn lati tẹriba fun aṣẹ popu.ANN 25.6

  Fun ọpọlọpọ ọdun awọn agbajọ Kristẹni kan wa ti wọn ko nipa ninu iwa ibajẹ Romu ninu awọn ilẹ ti aṣẹ Romu ko de. Ẹsin ibọriṣa ni o yi wọn ka, bi ọjọ si ti n lọ wọn kopa ninu awọn aṣiṣe rẹ; ṣugbọn wọn gba Bibeli gẹgẹ bi odiwọn igbagbọ, wọn si gbagbọ ninu ọpọlọpọ otitọ to wa ninu rẹ. Awọn Kristẹni wọnyi gbagbọ wipe ofin Ọlọrun duro titi lae wọn si pa ọjọ Isinmi ofin kẹrin mọ. Awọn ijọ ti wọn si dirọ mọ igbagbọ ati iṣesi yii wa ni Central Africa, ati awọn Armenia ni Asia.ANN 26.1

  Ṣugbọn laarin awọn ti wọn kọju ija si ijẹgaba agbara popu, awọn Waldenses duro tayọ. Ninu ilẹ naa ti ẹsin popu fi ibujoko rẹ si, nibẹ ni a ti kọju ija si èké ati iwa ibajẹ rẹ julọ. Fun ọpọ ọdun awọn ijọ Piedmont wà ni ominira; ṣugbọn àkoko dé lẹyin-ọrẹyin ti Romu pọn-ọn ni dandan fun wọn lati tẹriba fun oun. Lẹyin ti wọn koju ija si iwa onroro rẹ ṣugbọn ti o jasi pabo, awọn adari ijọ wọnyi fi ilọra tẹriba fun agbara ti o dabi ẹnipe gbogbo aye n fi ori balẹ fun. Ṣugbọn awọn kan wa ti wọn kọ lati tẹriba fun aṣẹ popu tabi ti biṣọbu. Wọn pinnu lati ṣe igbọran si Ọlọrun ati lati duro ninu iṣotitọ ati iwa mimọ igbagbọ wọn. Ipinya ṣẹlẹ. Awọn ti wọn tẹle igbagbọ atijọ wá fà sẹyin; awọn miran kọ òkè Alps, ilẹ abinibi wọn silẹ, wọn gbe ọpagun otitọ soke ni ilẹ ajeji; awọn miran lọ sinu awọn pẹtẹlẹ ti wọn farasin ati sinu apata laarin awọn oke, nibẹ wọn pa ominira wọn lati jọsin Ọlọrun mọ.ANN 26.2

  Igbagbọ ti awọn Kristẹni Waldenses gba ti wọn si fi kọni fun ọpọlọpọ ọdun yatọ patapata si ikọni èké ti Romu gbe sita. Igbagbọ esin wọn duro lori ọrọ Ọlọrun, ilana tootọ fun ẹsin Kristẹni. Ṣugbọn awọn aroko onirẹle wọnyẹn, ninu ibi aabo wọn ti o farasin, ti ko ri aaye yọju si araye, ti wọn ko ni ohun miran lati ṣe ju ki wọn maa ṣiṣẹ ojumọ wọn laarin awọn agbo aguntan ati ọgba ajara, ko ri otitọ funra ara wọn ni atako si igbagbọ ati ẹkọ èké ijọ apẹyinda. Igbagbọ won ki i ṣe eyi ti wọn ṣẹṣẹ gba lakọtun. Igbagbọ ẹsin wọn jẹ ajogunba lati ọdọ awọn baba wọn. Wọn jijadu fun igbagbọ ijọ apostoli,—”igbagbọ ti a fi lé awọn eniyan mimọ lọwọ lẹẹkan ṣoṣo.” Juda 3. “Ijọ ninu aginju,” olupamọ ohun alumọni otitọ ti Ọlọrun fifun awọn eniyan Rẹ lati fifun araye, ni ijọ Kristi tootọ, ki i si i ṣe alaṣẹ agberaga ti o joko lori itẹ ni olu ilu nla ijọba aye.ANN 26.3

  Kókó lara awọn ohun ti o mu ki ijọ tootọ o yapa kuro ni ọdọ Romu ni bi o ti ṣe ni ikorira fun ọjọ Isinmi inu Bibeli. Gẹgẹ bi asọtẹlẹ ti sọ ọ, agbara ijọ paadi yoo wo otitọ lulẹ. A tẹ ofin Ọlọrun mọlẹ ninu erupẹ, nigbati a n gbe aṣa ati iṣesi eniyan ga. A tètè fi ipa mu awọn ijọ ti wọn wa labẹ akoso ijọ paadi lati bọwọ fun ọjọ Sunde gẹgẹ bi ọjọ mimọ. Laarin èké ati aṣiṣe ti o gbilẹ kan, ọpọlọpọ, ani laarin awọn eniyan Ọlọrun tootọ pẹlu, ni nnkan daru mọ loju debi pe nigba ti wọn n pa ọjọ Isinmi mọ, wọn ki i ṣe iṣẹ ni ọjọ Sunde pẹlu. Ṣugbọn eyi ko tẹ awọn adari ijọ paadi lọrun. Wọn pa á laṣẹ pe ki i ṣe wipe ki a bọwọ fun ọjọ Sunde nikan, ṣugbọn ki a ba ọjọ Isinmi jẹ pẹlu; wọn si ṣe idalẹbi fun ẹnikẹni ti o ba ni igboya lati bọwọ fun ni ọna ti o lagbara. Nipa sisa kuro labẹ agbara Romu nikan ni ẹnikẹni fi le pa ofin Ọlọrun mọ pẹlu alaafia.ANN 26.4

  Awọn Waldenses wa lara awọn eniyan akọkọ ni Europe ti wọn ni itumọ Iwe Mimọ ni ede wọn. Fun ọpọ ọdun ṣaaju iṣẹ Atunṣe, wọn ni ẹda Bibeli ti a fi ọwọ kọ ni ede abinibi wọn. Wọn ni otitọ ni ailabawọn, eyi si jẹ ki a fi oju si wọn lara gẹgẹ bi awọn ti a n korira ti a si n ṣe inunibini si. Wọn sọ wipe Ijọ Romu ni Babiloni apẹyinda ti iwe Isọtẹlẹ, pẹlu ewu lori ẹmi wọn, wọn duro lati kọju ija si awọn iwa ibajẹ rẹ. Labẹ inunibini ọlọjọgbọọrọ, awọn kan fa sẹyin ninu igbagbọ wọn, wọn si n fi awọn kókó ẹkọ inu rẹ silẹ diẹdiẹ, awọn yoku di otitọ mu ṣinṣin. Ni gbogbo àkókò okunkun ati ifasẹyin yii, awọn Waldenses kan wà ti wọn kọ lati gba aṣẹ Romu, ti wọn ko gba titẹriba fun ère nitori ti o jẹ ibọriṣa, ti wọn si pa ọjọ Isinmi tootọ mọ. Labẹ ìjì atako líle, wọn pa igbagbọ wọn mọ. Bi o tilẹ jẹ wipe a fi ọkọ Savoyard gun wọn, ti a si fi ina Romu sun wọn, wọn duro nitori ọrọ Ọlọrun ati fun iyi Rẹ laibẹru.ANN 26.5

  Awọn Waldenses ri aabo lẹyin ibi aabo awọn oke giga—ibi aabo fun awọn ti a n ṣe inunibini si ti a si n fi iya jẹ ni gbogbo igba. Imọlẹ otitọ n tan nibi laarin okunkun Igba Ojú Dúdú. Nibi, awọn ẹlẹri fun otitọ di igbagbọ atijọ mu fun ẹgbẹrun ọdun. Ọlọrun pèsè ibi aabo ẹlẹru fun awọn eniyan Rẹ, eyi ti o yẹ fun otitọ nla ti a fi le wọn lọwọ. Si awọn olootọ ti a le kuro ni ilu wọnyi, awọn oke jẹ ami ododo Ọlọrun ti a ko le ṣi nidi. Wọn tọka awọn ọmọ wọn si awọn oke giga ti ogo wọn ko yipada, wọn a sọ nipa Ẹni ti ko ni ayidayida tabi ojiji iyipada, ti ọrọ Rẹ wa titi lae bi awọn òkè ainipẹkun. Ọlọrun tẹ awọn oke dó, O si fi okun ṣe ikẹ wọn; ko si ọwọ naa, ayafi ti Agbara Ainipekun ti o le ṣi wọn kuro ni ipo wọn. Bẹẹ gẹgẹ ni o ṣe gbe ofin Rẹ kalẹ, ipilẹ ijọba Rẹ ni ọrun ati ni aye. Ọwọ eniyan le to awọn eniyan bii tirẹ, ki o si pa wọn; ṣugbọn ọwọ naa a le fa awọn oke tu lati ipilẹ wọn, ki o si sọ wọn si inu okun, ni ọna kan naa ti o fi le yi ilana kan ninu ofin Jehofa pada, tabi ki o pa ọkan lara awọn ileri Rẹ fun awọn ti wọn ba ṣe ifẹ Rẹ rẹ. Ninu iṣotitọ wọn si ofin Rẹ, awọn iranṣẹ Ọlọrun nilati duro gbọin bi awọn oke ti ko le yi pada.ANN 27.1

  Awọn oke ti wọn daabo bo afonifoji wọn jẹ ẹri atigbadegba si agbara Ọlọrun lati ṣẹda, ati idaniloju ti ko le baku nipa idaabobo Rẹ. Awọn arinrinajo kọ lati fẹran awọn ami ti wọn fi ara sin wọnyi nipa iwapẹlu Jehofa. Wọn ko ṣe aroye nitori inira wọn; wọn ko wa ni awọn nikan laarin awọn oke ti wọn dakẹrọrọ. Wọn dupẹ lọwọ Ọlọrun wipe O fun wọn ni aabo kuro lọwọ ibinu ati iwa onroro eniyan. Inu wọn dun nitori ominira wọn lati jọsin niwaju Rẹ. Ni ọpọ igba ti ọta wọn ba lé wọn, agbara awọn oke maa n jẹ aabo ti o daju. Lati ori awọn gegele okuta wọn kọ orin iyin si Ọlọrun, awọn ẹgbẹgun Romu ko si le pa orin ọpẹ wọn lẹnu mọ.ANN 27.2

  Ifọkansin awọn atẹle Kristi wọnyi jẹ eyi ti o mọ, ti ko ni abula, ti o si gbona. Ẹkọ otitọ niye lori loju wọn ju ilẹ ati ile, ọrẹ, ojulumọ, ani ju ẹmi funra rẹ lọ. Wọn n fi tọkantọkan wá lati tẹ awọn ikọni wọnyi mọ ọkan awọn èwe wọn. A n fi Iwe Mimọ kọ awọn ọdọ lati igba èwe wá, a si kọ wọn lati fi tọwọtọwọ gba ofin Ọlọrun. Ẹda Bibeli ko wọpọ; nitori naa wọn kọ awọn ọrọ iyebiye inu rẹ sori. Ọpọ ninu wọn le ka abala pupọ ninu Majẹmu Laelae ati Tuntun sori. A so awọn ero nipa Ọlọrun pọ mọ awọn iṣẹda ati pẹlu awọn ibukun kekeeke ojoojumọ. Awọn ọmọde kọ lati wo Ọlọrun pẹlu imoore gẹgẹ bi Ẹni ti n funni ni oju rere gbogbo ati itunu gbogbo.ANN 27.3

  Pẹlu bi awọn obi ti tutu, ti wọn si nifẹ to, wọn fẹran awọn ọmọ wọn pẹlu ọgbọn ju ki wọn jẹ ki itẹra-ẹni-lọrun o mọ wọn lara lọ. Igbe aye idanwo ati inira, boya iku ajẹriku wa niwaju wọn. A kọ wọn lati ọmọde wa lati fi ara da inira, ki wọn tẹriba fun akoso, sibẹ ki wọn ronu, ki wọn si wùwà fun ara wọn. Lati kekere wa, a kọ wọn lati gbe ẹrù iṣẹ, lati sọ ọrọ wọn, ki wọn si ni oye ọgbọn ti o wa ninu idakẹjẹ. Ọrọ aimoye kan ti o ba bọ si eti awọn ọta wọn le ma wu ẹmi ẹni ti o sọ ọ nikan lewu, ṣugbọn ati ti ọpọlọpọ awọn arakunrin rẹ pẹlu; nitori bi ikooko ti n dọdẹ ẹran ije rẹ ni ọta otitọ ṣe n le awọn ti wọn gboya lati sọ wipe wọn ni ominira igbagbọ ẹsin kiri.ANN 27.4

  Awọn Waldenses padanu ọrọ aye nitori otitọ, pẹlu suuru oniforiti wọn ṣiṣẹ fun ounje wọn. Gbogbo ilẹ ti o ba ṣe e ro laarin awọn oke ni wọn lo daradara; wọn jẹ ki awọn afonifoji ati awọn ilẹ ti ko lọra pupọ o mu eso wọn jade ni kikun pẹlu. Ìsúnlò ati iṣera-ẹni wa lara ẹkọ ti awọn ọmọ wọn gba gẹgẹ bi ohun ajogunba wọn. A kọ wọn wipe Ọlọrun ṣe e ki a gbe igbesi aye wa pẹlu ikora-ẹni-nijanu, ati wipe wọn le pese fun aini ara wọn nipasẹ iṣẹra-ẹni, irotẹlẹ, pẹlẹkutu, ati igbagbọ nikan. Ilana yii nira o si n kaarẹ bani, ṣugbọn o peye, ohun ti eniyan nilo ni ipo iṣubu rẹ, ile ẹkọ ti Ọlọrun ti pese fun itọni ati idagba soke rẹ. Nigba ti o mọ awọn ọdọ lara lati ṣiṣẹ ati lati fi ara da ijiya, wọn ko fi ẹkọ ọpọlọ silẹ. A kọ wọn wipe gbogbo agbara wọn jẹ ti Ọlọrun, ati wipe gbogbo wọn ni wọn ni lati tọju, ki wọn si jẹ ki wọn dagbasoke fun iṣẹ Rẹ.ANN 27.5

  Awọn ijọ Vaduois fi ara jọ ijọ ni akoko awọn apostoli ninu iwa mimọ ati iṣotitọ wọn. Wọn ko gbagbọ ninu ìjẹgàba popu ati awọn alufa, wọn si gbagbọ ninu Bibeli gẹgẹ bi aṣẹ ti o ga julọ ti ko si le baku. Awọn alufa wọn ko dabi awọn alufa Romu ti n jẹ gàba, ṣugbọn wọn tẹle apẹẹrẹ Oluwa wọn, ti “kò wa ki a le ṣe iranṣẹ fun, ṣugbọn ki o le ṣe iranṣẹ.” Wọn bọ agbo Ọlọrun, wọn n dari wọn si papa oko tutu ati si orisun omi iye ti ọrọ mimọ Rẹ. Wọn jinna réré si ami ìwúga ati igberaga eniyan; awọn eniyan naa pejọ pọ, ki i ṣe ninu awọn ile ijọsin titobi ati katidra nla, ṣugbọn labẹ ojiji awọn oke, ninu awọn afonifoji oke Alp, tabi ni akoko ewu, ninu awọn ibi aabo ninu awọn apata, wọn pejọ pọ lati gbọ ọrọ otitọ lati ẹnu awọn iranṣẹ Kristi. Ki i ṣe wipe awọn alufa waasu iyinrere nikan, ṣugbọn wọn bẹ awọn alaisan wo, wọn kọ awọn ọmọde, wọn gba awọn ti n ṣina niyanju, wọn si ṣiṣẹ lati pari aawọ ati lati jẹ ki iṣọkan ati ife o tẹsiwaju. Ọrẹ àtinúwá awọn eniyan ni wọn n ná ni akoko alaafia; ṣugbọn, bi i Pọlu apagamọ, olukuluku wọn ni o kọ iṣẹ tabi okoowo, eyi ti wọn lo lati tọju ara wọn bi wọn ba nilo lati ṣe bẹẹ.ANN 28.1

  Awọn ọdọ n gba ikọni lati ọdọ awọn alufa. Bi o tilẹ jẹ wipe wọn n kẹkọ ẹka gbogbo ẹkọ, Bibeli ni kókó ohun ti wọn n kọ. Wọn n kọ awọn Iyinrere ti Matiu ati ti Johanu sori, pẹlu ọpọ awọn Episteli. Wọn n kọ Iwe Mimọ silẹ pẹlu. Awọn iwe miran ni gbogbo Bibeli ninu, awọn miran ni abala diẹ, ti awọn ti wọn le ṣe alaye Iwe Mimọ ṣe alaye diẹ sí ninu. Bayi ni wọn ṣe n gbe alumọni otitọ sita ti awọn ti wọn n wa lati gbe ara wọn ga ju Ọlọrun lọ ti n fi pamọ fun igba pipẹ.ANN 28.2

  Pẹlu suuru, iṣẹ aikaarẹ, nigba miran ninu okunkun ihò ilẹ, wọn a lo imọlẹ fitila, a kọ Iwe Mimọ jade, lẹsẹẹsẹ ati ni isọri isọri. Bayi ni iṣẹ naa ṣe n tẹsiwaju, ti ifẹ Ọlọrun ti a fihan n tan jade bi wura pipe; awọn ti wọn ṣe iṣẹ naa nikan ni wọn le mọ bi o ti lagbara, bi o ti mọlẹ, ti o si mọ gaara tó, nitori idanwo ti wọn la koja nitori rẹ. Awọn angeli lati ọrun wa n rọgba yi awọn oṣiṣẹ olootọ wọnyi ka.ANN 28.3

  Satani lo awọn alufa ati alaṣẹ ijọ paadi lati tẹ ọrọ otitọ rì sinu panti ẹkọ odi, èké, ati igbagbọ asan; ṣugbọn a pa a mọ ni ọna ailabawọn ni gbogbo akoko oju dudu ni ọna ti o yanilẹnu julọ. Ko ni ami aṣẹ eniyan bikoṣe ti Ọlọrun. Awọn eniyan n da ara wọn laamu ninu akitiyan wọn lati ti itumọ Iwe Mimọ ti o han kedere, ti ko si ni wahala rì sinu okunkun, ki wọn ba a le tako ẹri ara wọn. Ṣugbọn bi ọkọ Noah lori igbi omi, ọrọ Ọlọrun la iji ti o fẹ pa a run kọja. Bi iho ilẹ ti kun fun wura ati fadaka ti wọn pamọ si abẹ rẹ, ti gbogbo awọn ti wọn ba fẹ ri ohun iyebiye inu rẹ si nilati gbẹ ilẹ, bẹẹ gẹgẹ ni Iwe Mimọ ṣe ni ohun iṣura otitọ ti o jẹ wipe awọn ti wọn fi tọkantọkan, irẹlẹ ati adura wa nikan ni a fi i han fun. Ọlọrun ṣe Bibeli lati jẹ iwe ẹkọ fun gbogbo eniyan, fun ọmọde, ọdọ, ati agbalagba, ki a si maa kọ ọ ni gbogbo igba. O fi ọrọ Rẹ fun eniyan gẹgẹ bi ifihan ara Rẹ. Gbogbo otitọ tuntun ti a ba ri jẹ ifihan tuntun nipa iwa Ẹni ti O kọ ọ. Nipa kikọ Iwe Mimọ ni ọna ti Ọlọrun yan lati so awọn eniyan papọ mọ Ẹlẹda wọn ati lati fun wọn ni imọ ti o yè kooro nipa ifẹ Rẹ. O jẹ ọna ibanisọrọ laarin Ọlọrun ati eniyan.ANN 28.4

  Nigba ti awọn Waldenses ri ibẹru Ọlọrun gẹgẹ bi ipilẹsẹ ọgbọn, oju wọn ko fọ lati mọ bi ibaṣepọ pẹlu araye, imọ nipa eniyan ati igbesi aye iṣẹ ṣiṣe ti ṣe pataki to lati lani lọyẹ ati lati funni ni oye ti o yè kooro. Lati inu ile iwe wọn ninu awọn oke, wọn ran diẹ lara awọn ọdọ wọn lọ si ile ẹkọ giga ni awọn ilu nla ni France tabi Italy, nibi ti ẹka ẹkọ, ìwòye, ati ironu pọ si ju ti ilẹ Alps wọn lọ. Awọn ọdọ ti a ran jade bayi maa n ri idanwo, wọn n ri iwa ibajẹ, wọn n ṣe alabapade awọn aṣoju Satani ti wọn jẹ alarekereke, ti wọn n fi awọn ẹkọ odi ti wọn farasin ati itanjẹ ti o buru julọ kọ wọn. Ṣugbọn ẹkọ wọn lati ọmọde wa jẹ eyi ti o pèsè wọn silẹ fun gbogbo nnkan wọnyi.ANN 28.5

  Wọn ko gbọdọ ni ẹni ti wọn le fi ọkan tan ninu awọn ile ẹkọ ti wọn n lọ. A ran aṣọ wọn ni ọna ti yoo fi le mu ohun iṣura wọn ti o tobi julọ—awọn ẹda Iwe Mimọ ti wọn ṣe iyebiye—pamọ. Wọn gbe awọn eso wahala ọpọlọpọ oṣu ati ọdun wọnyi dani pẹlu wọn, nibikibi ti wọn ba si ti le ṣe e laiṣe wipe à á fura si wọn, wọn a rọra fi diẹ si oju ọna awọn ti wọn mọ wipe ọkan wọn ṣetan lati gba otitọ. A ti kọ awọn ọdọ Waldenses pẹlu ojuṣe yii lati ori eekun iya wọn wa; wọn ni oye iṣẹ wọn, wọn si ṣe e pẹlu otitọ. Awọn eniyan yipada sinu igbagbọ tootọ ninu awọn ile ẹkọ wọnyi, ikọni wọn si wọ aarin gbogbo ile ẹkọ; sibẹ awọn adari ijọ paadi ko le tọ ẹsẹ ibi ti ohun ti wọn n pe ni ẹkọ odi yii ti n wá, pẹlu gbogbo iwadi finifini wọn.ANN 28.6

  Ẹmi ajiyinrere ni ẹmi Kristi. Ero akoko ti yoo sọ ninu ọkan ti a sọ di ọtun ni lati mu awọn miran wa si ọdọ Olugbala. Iru ẹmi ti awọn Kristẹni Vadois ni niyi. Wọn mọ wipe Ọlọrun fẹ ki wọn ṣe ju ki wọn pa otitọ mọ ninu iwa mimọ rẹ ninu ijọ wọn lasan lọ; wipe wọn ni ojuṣe nla lati jẹ ki imọlẹ wọn o tan si awọn ti wọn wa ninu okunkun; pẹlu agbara nla to wa ninu ọrọ Ọlọrun wọn wọna lati ja ide ti Romu fi deni. A kọ awọn alufa Vadois lati jẹ oniṣẹ iranṣẹ, ẹnikẹni ti o ba fẹ wọ inu iṣẹ iranṣẹ nilati kọkọ ni iriri gẹgẹ bi ajiyinrere. Olukuluku wọn nilati ṣiṣẹ ìjèrè ọkan fun ọdun mẹta ni ita ki wọn to wa di ijọ mu ni ile. Iru iṣẹ yii, ti o nilo iṣẹra-ẹni ati ifara-ẹni-rubọ lati ibẹrẹ wa, jẹ itọkasi ti o yẹ fun iṣẹ alufa fun awọn akoko ti n dan ọkan awọn eniyan wo. Awọn ọdọ ti a n gbe ọwọ le lori sinu iṣẹ mimo yii ko ri anfani lati ni ọrọ aye ati ogo niwaju wọn, bikoṣe wahala ati ewu, ati bi o ba ṣe e ṣe, atubọtan ajẹriku. Awọn oniṣẹ-iyinrere n jade ni mejimeji, bi Jesu ti ran awọn ọmọ ẹyin Rẹ jade. A saba maa n so ọdọ papọ mọ agbalagba ti o ti ni iriri, ọdọ naa yoo wa labẹ itọsọna ẹnikeji rẹ, ti o ni ojuṣe fun itọsọna rẹ, oun naa si nilo lati gba itọni rẹ. Awọn ajumọ ṣiṣẹ pọ yii ki i saba maa n wa papọ, ṣugbọn loorekoore, wọn maa n pade lati gba adura ati fun igbaniyanju, nipa eyi, wọn n fun ara wọn ni okun ninu igbagbọ.ANN 29.1

  Kikede afojusun iṣẹ wọn yoo mu ibaku wa; nitori naa, wọn fi ohun ti wọn jẹ gan-an pamọ. Gbogbo awọn alufa ni wọn ni imọ iṣẹ kan tabi okoowo, awọn oniṣẹ-iranṣẹ yii si n ṣe iṣẹ wọn nipa fifi iṣẹ aye boju. Wọn saba maa n ṣiṣẹ okoowo tabi akiri ọja. “Wọn ni aṣọ, ohun ẹsọ ara, ati awọn ohun èlò miran, ti wọn ko le ṣa dede ra ni akoko naa, ayafi ni awọn ọja ti wọn jinna réré; a si n tẹwọ gba wọn gẹgẹ bi olokoowo ni awọn ibi ti à bá ti ta wọn nu gẹgẹ bi oniṣẹ-iyinrere.” Ni gbogbo akoko yii, wọn a gbe ọkan wọn soke si Ọlọrun fun ọgbọn lati funni ni ohun iṣura ti o ju wura tabi okuta iyebiye lọ. Wọn a rọra gbe ẹda Bibeli dani, boya abala diẹ, tabi gbogbo rẹ; nibikibi ti wọn ba sì ti ri aaye, wọn a pe akiyesi awọn onibara wọn si awọn iwe wọnyi. Ni ọpọ igba ifẹ lati ka ọrọ Ọlọrun ma n ti ipa eyi sọji, wọn a si fi tayọtayọ fi abala diẹ silẹ pẹlu awọn ti wọn ba fẹ lati gba a.ANN 29.2

  Iṣẹ awọn oniṣẹ iyinrere wọnyi bẹrẹ ni awọn pẹtẹlẹ ati afonifoji labẹ awọn oke ara wọn, ṣugbọn o tan kalẹ kọja awọn ilẹ wọnyi. Laiwọ bata, ati pẹlu aṣọ ṣágiṣàgi ti o ni abawọn nitori irin ajo, bi i ti Ọga wọn, wọn la awọn ilu nla kọja, wọn si wọ awọn ilẹ jijinna réré lọ. Wọn fọn irugbin iyebiye kaakiri ibi gbogbo. Awọn ijọ n dide ni oju ọna wọn, ẹjẹ awọn ajẹriku si n ṣe ijẹri si otitọ. Ọjọ Ọlọrun yoo fi ikore nla ọkan ti awọn eniyan olootọ yii ṣajọ pẹlu iṣẹ wọn han. Laifi ara han, ati ni idakẹrọrọ, ọrọ Ọlọrun n ri aaye wọ inu ẹsin Kristẹni, ti awọn ilẹ ati ọkan eniyan si n fi ayọ gba a.ANN 29.3

  Awọn Waldenses ko ri Iwe Mimọ gẹgẹ bi akọsilẹ nipa bi Ọlọrun ti ṣe si awọn eniyan ni atẹyinwa, ati ifihan iṣẹ ati ojuṣe ti isisinyii nikan, ṣugbọn bi ifihan awọn ewu, ati ogo ọjọ iwaju. Wọn gbagbọ wipe opin ohun gbogbo ko jinna mọ, bi wọn si ti n kẹkọ Bibeli pẹlu adura ati omije, awọn ọrọ iyebiye inu rẹ ati ojuṣe wọn lati jẹ ki awọn miran o mọ otitọ inu rẹ ti n gbanila tubọ n tẹ mọ wọn lọkan si. Wọn ri wipe a fi eto igbala han kedere ninu awọn oju ewé mimọ rẹ, wọn si ri itunu, ireti, ati alaafia nipa gbigbagbọ ninu Jesu. Bi imọlẹ ti n wọ inu oye wọn ti o si n mu ọkan wọn yọ, wọn fẹ lati tan itansan rẹ si awọn ti wọn wa ninu okunkun aṣiṣe ijọ paadi.ANN 29.4

  Wọn ri wipe labẹ itọsọna popu ati alufa, ọpọ awọn eniyan n ṣiṣẹ lasan lati ri idariji nipa jijẹ ara wọn niya fun ẹṣẹ ọkan wọn. A kọ wọn lati wo iṣẹ rere wọn lati gba wọn la, wọn n wo ara wọn ni gbogbo igba, wọn n ronu lori ipo ẹṣẹ wọn, wọn ri ti ibinu Ọlọrun wa lori wọn, wọn n jẹ ọkan ati ara wọn niya, sibẹ wọn ko ri itusilẹ. Bayi ni ẹkọ Romu ṣe di awọn olufọkansin mọ inu igbekun. Ọpọlọpọ ni wọn fi ọrẹ ati ibatan wọn silẹ, ti wọn si n gbe igbesi aye wọn ninu ile tubu awọn ajẹjẹ ẹsin. Pẹlu awẹ atigbadegba ati ifiyajẹni nla, pẹlu iṣọ oru, nipa sisun sori ilẹ tutu ilé wọn ti o ṣokunkun ti o n rin fun omi fun ọpọlọpọ wakati, pẹlu irinajo gigun gbọọrọ, pẹlu ironupiwada ti o fini ṣẹsin ati ijẹniniya ti o dẹru bani, ọpọlọpọ n ṣiṣẹ lasan lati ri alaafia ọkan. Imọlara ẹṣẹ n fi iya jẹ wọn, ẹru ibinu igbẹsan Ọlọrun n lé wọn kiri, ọpọlọpọ n jiya lọ bayii, titi ti wọn yoo fi gbẹmi mi, laisi itansan imọlẹ tabi ireti kan, wọn ri sinu iboji.ANN 29.5

  Awọn Waldenses n fẹ lati bu akara iye fun awọn ọkan ti ebi n pa wọnyi, lati ṣi iṣẹ iranṣẹ alaafia ninu awọn ileri Ọlọrun fun wọn, ati lati tọka wọn si Kristi gẹgẹ bi ireti wọn kan ṣoṣo fun igbala. Wọn gbagbọ wipe ikọni ti o sọ wipe iṣẹ rere le ṣe iwẹnumọ fun riru ofin Ọlọrun duro lori èké. Gbigbẹkẹle iṣẹ eniyan tako igbagbọ ninu ifẹ Kristi ti ko lopin. Jesu ku gẹgẹ bi irubọ fun eniyan nitori eniyan ẹlẹṣẹ ko le ṣe ohun kan lati le ri itẹwọgba lọdọ Ọlọrun. Iṣẹ Olugbala ti a kan mọ agbelebu ti O si jinde ni ipilẹ igbagbọ Kristẹni. Ọkàn nilati gbẹkẹle Kristi ni ọna ti o jẹ ojulowo, ki o si wa ni iṣọkan pẹlu Rẹ, bi apá ti jẹ si ara, tabi ẹka si ajara.ANN 30.1

  Awọn ikọni popu ati awọn alufa jẹ ki awọn eniyan o ri iwa Ọlọrun, ani ti Kristi paapa, bi ti onroro, onirobinujẹ, ati oluṣẹrubani. A fi Olugbala han gẹgẹ bi ẹni ti ko ni ibanikẹdun pẹlu eniyan ninu ipo iṣubu rẹ debi pe a nilati wa ibalaja awọn alufa ati awọn eniyan mimọ. Awọn ti ọrọ Ọlọrun ti la lọyẹ n fẹ lati tọka awọn ọkan wọnyi si Jesu gẹgẹ bi Olugbala ti O nifẹ ti O si n kaanu fun wọn, ti O n duro pẹlu ọwọ Rẹ ti o ṣi silẹ, ti O n pe gbogbo eniyan wa pẹlu ẹru ẹṣẹ, aniyan, ati ikaarẹ wọn wa si ọdọ Oun. Wọn fẹ lati ko awọn idena ti Satani to jọ kuro eyi ti o di awọn eniyan lọwọ lati maṣe jẹ ki wọn o ri awọn ileri wọnyi, ki wọn si wa si ọdọ Ọlọrun taara, ni jijẹwọ ẹṣẹ wọn, ki wọn si gba idariji ati alaafia.ANN 30.2

  Tọkantọkan ni awọn oniṣẹ-iyinrere awọn ara Vadois fi ṣe alaye awọn otitọ iyebiye iyinrere si ẹnikẹni ti o ba fẹ lati mọ. A rọra mu awọn abala Iwe Mimọ ti a fi pẹlẹkutu kọ sita. Ohun ti o funni ni ayọ julọ ni lati fun ọkan olootọ ti ẹṣẹ ti di ẹru wuwo le lori, ẹni ti ko ri ohun miran ju igbẹsan Ọlọrun ti n duro lati ṣe idajọ, ni ireti. Pẹlu ete ti o n gbọn pẹpẹ ati oju ti o kun fun omije, ni ọpọ igba lori eekun rẹ, a ṣi awọn ileri iyebiye ti o fi ireti kan ṣoṣo ti ẹlẹṣẹ ni han arakunrin rẹ. Bayi ni imọlẹ otitọ ṣe n wọ inu ọpọ ọkan ti wọn ṣokunkun, ti o n gbá ikuuku dudu sẹyin, titi ti Oorun Ododo fi tan sinu ọkan pẹlu iwosan ninu itansan Rẹ. Ni ọpọ igba a maa n ka awọn abala Iwe Mimọ kan ni àkàtúnkà, ti olugbọ naa a fẹ ki a tun ka lẹẹkan si, afi bi ẹnipe o fẹ fi da ara rẹ loju bi oun ba gbọ daradara. A n fẹ ki a tun awọn ọrọ wọnyi ka ni pataki julọ: “Ẹjẹ Jesu Kristi Ọmọ Rẹ fọ wa mọ kuro ninu ẹṣẹ gbogbo.” 1 Johanu 1:7. “Bi Mose ti gbe ejo soke ni aginju, bẹẹ gẹgẹ ni a nilati gbe Ọmọ eniyan soke: pe ẹnikẹni ti o ba gba A gbọ ki yoo ṣegbe, ṣugbọn yoo ni iye ainipẹkun.” Johanu 3:14, 15.ANN 30.3

  Ọpọlọpọ ni wọn ri otitọ nipa ohun ti Romu n sọ. Wọn ri bi ìbálàjà eniyan tabi ti angẹli nitori ẹlẹṣẹ ti jẹ asan to. Bi imọlẹ tootọ ti wọ inu ọkan wọn, wọn kigbe pẹlu ayọ wipe: “Kristi ni alufa mi; ẹjẹ Rẹ ni irubọ mi; pẹpẹ Rẹ ni ibi ijẹwọ ẹṣẹ mi.” Wọn gbe ara wọn si ori iṣẹ Jesu patapata, wọn si n sọ awọn ọrọ wọnyi ni atunsọ, “Laisi igbagbọ, ko ṣe e ṣe lati wu U.” Heberu 11:6. “Ko si orukọ miran labẹ ọrun ti a fifun eniyan, nipasẹ eyi ti a fi le gba wa la.” Iṣe 4:12.ANN 30.4

  Idaniloju ifẹ Olugbala dabi eyi ti o pọju fun diẹ lara awọn ọkan otoṣi ti igbi n bi kiri yii lati gbagbọ. Alaafia nla ni o mu wa si ọkan wọn, itansan imọlẹ ti o tan si wọn pọ to bẹẹ gẹẹ ti o fi dabi ẹnipe a gba wọn si ọrun. Wọn fi ifọkantan gbe ọwọ wọn le ọwọ Kristi; wọn gbe ẹsẹ wọn le ori Apata Ayeraye. Gbogbo ibẹru iku salọ. Wọn wa n fẹ lati ni ọgba ẹwọn, ati idana-sunni bi eyi yoo ba fi ọla fun orukọ Olurapada wọn.ANN 30.5

  Bayi ni a ṣe n mu ọrọ Ọlọrun jade ti a si n ka a ni ibi ti o farasin, nigba miran, si ẹnikan ṣoṣo, nigba miran si ẹgbẹ kekere ti wọn fẹ imọlẹ ati otitọ. Ni ọpọ igba a maa n lo gbogbo oru bayi. Iyalẹnu ati ijọloju awọn olugbọ maa n pọ to bẹẹ gẹẹ ti wọn saba maa n da oniṣẹ iranṣẹ aanu duro ninu iwe kika rẹ titi ti oye wọn a fi le mọ itumọ iroyin ayọ igbala. Ni ọpọ igba wọn saba maa n sọ wipe: “Ṣe Ọlọrun yoo gba ọrẹ mi lootọ? Ṣe yoo rẹrin si mi? Ṣe yoo dari ẹṣẹ mi jin mi? A a ka idahun naa si wọn wipe: “Ẹ wa si ọdọ Mi gbogbo ẹyin ti n ṣiṣẹ ti a si di ẹru wuwo le lori, Emi yoo si fi isinmi fun yin.” Matiu 11:28.ANN 30.6

  Igbagbọ di ileri naa mu, a si gbọ esi ayọ wipe: “N ko nilo lati ṣe irin ajo ẹsin gigun mọ; ko si irin ajo inira lọ si awọn ojubọ mimọ mọ. Mo le wa si ọdọ Jesu bi mo ti ri, ni ẹlẹṣẹ ati alaimọ, ko si ni ta adura fun ironupiwada danu. ‘Ati dari ẹṣẹ rẹ ji ọ.’ Temi, ani ti temi, a le dari rẹ ji!”ANN 31.1

  Igbi ayọ mimọ kun inu ọkan wọn, wọn si gbe orukọ Jesu ga pẹlu ọpẹ ati iyin. Awọn ọkan alayọ wọnyi pada lọ si ile wọn lati tan imọlẹ naa ka, lati tun iriri wọn sọ fun awọn miran ni ọna ti wọn fi le sọ ọ daradara; wipe wọn ti ri Ọna tootọ ati iye. Agbara ti o lọwọ, ti o si ṣe ajeji wa ninu ọrọ Iwe Mimọ ti o n sọ ọrọ taara si ọkan awọn ti wọn n fẹ otitọ. Ohun Ọlọrun ni, o si n fun awọn ti wọn ba gbọ ni idaniloju.ANN 31.2

  Ojiṣẹ otitọ ba ọna rẹ lọ; ṣugbọn irisi irẹlẹ, iṣotitọ, itara ati ifọkansin rẹ saba maa n jẹ koko fun ijiroro. Ni ọpọ igba, awọn olugbọ rẹ ki i beere ibi ti o ti wa tabi ibi ti o n lọ ni ọwọ rẹ. Wọn kọkọ kun fun iyalẹnu, lẹyin eyi wọn kun fun ọpẹ ati ayọ, ti o fi jẹ wipe wọn ko ronu lati bi i leere. Nigba ti wọn ba rọ ọ lati tẹle wọn lọ si ile wọn, a fesi wipe oun nilati bẹ awọn aguntan ti wọn sọnu ninu agbo wo. Wọn a sọ wipe: Abi o le jẹ angẹli lati ọrun wa?ANN 31.3

  Ni ọpọ igba a kò ni ri ojiṣẹ otitọ mọ. Boya o ti lọ si ilẹ miran, tabi o n ku lọ ninu tubu ti a ko mọ, tabi egungun rẹ ti n funfun nibi ti o ti jẹri si otitọ. Ṣugbọn a ko le pa ọrọ ti o ti sọ silẹ run. Wọn n ṣiṣẹ wọn ninu ọkan awọn eniyan; a o mọ ayọrisi alabukun wọn ni idajọ.ANN 31.4

  Awọn oniṣẹ iyinrere ara Waldenses n ko ogun ja ijọba Satani, agbara okunkun si wa ni ifura ti o ga si. Gbogbo akitiyan lati jẹ ki otitọ o tẹsiwaju ni ọmọ alade iwa ibi n wo ti o si n ru ibẹru awọn aṣoju rẹ soke. Awọn adari ijọ padi ri ewu ti o lagbara si iṣẹ wọn ninu iṣẹ awọn alarinkiri otoṣi wọnyi. Bi a ba jẹ ki imọlẹ otitọ o tan laisi idiwọ, yoo gbá ikuuku aṣiṣe nla ti o bo awọn eniyan mọlẹ kuro. Yoo dari ọkan awọn eniyan si Ọlọrun nikan ṣoṣo, yoo si ba agbara Romu jẹ.ANN 31.5

  Iwalaaye awọn eniyan ti wọn di igbagbọ ijọ atijọ mu yii jẹ ẹri atigbadegba si iyapa Romu, nitori naa, o ru inunibini ati ikorira kikoro soke. Bi wọn ti kọ lati kọ Iwe Mimọ silẹ jẹ iwa ẹṣẹ ti Romu ko le fi ara mọ. O pinnu lati pa wọn rẹ kuro lori ilẹ aye. Bayi ni a ṣe ko ogun ẹsin kikan bá awọn eniyan Ọlọrun ninu ilẹ wọn laarin awọn oke. Awọn oluwadi igbagbọ n le wọn kiri, iṣẹlẹ bi Abeli alaiṣẹ ti ṣubu niwaju Keeni apaniyan tun ṣẹlẹ laimoye igba.ANN 31.6

  Latigbadegba, a n sọ ilẹ ọlọra wọn di ahoro, a wo ibugbe ati ile ijọsin wọn lulẹ, ti o fi jẹ wipe nibi ti papa oko tutu ati ile awọn alaiṣẹ, awọn eniyan ti n mura siṣẹ fi igba kan wa ri, wa di kiki da aṣalẹ. Bi inu ẹranko buburu ti n ru soke si nigba ti o ba tọ ẹjẹ wo, bẹẹ ni ijiya awọn wọnyi ṣe n ru ibinu awọn ọmọ ijọ padi soke. A le ọpọlọpọ awọn ẹlẹri fun igbagbọ mimọ yii wọ inu awọn oke, a si dọdẹ wọn ninu afonifoji ti wọn sapamọ si, nibi ti igbo nla ati gegele okuta fi wọn pamọ si.ANN 31.7

  Ko si ohun kan ti a le ri wi si nipa iwa awọn ti a fi ofin dè wọnyi. Ani awọn ọta wọn funra wọn sọ wipe wọn jẹ alalaafia, eniyan jẹjẹ ti o jẹ olufọkansin. Ẹṣẹ nla ti wọn ṣẹ ni wipe wọn ko sin Ọlọrun gẹgẹ bi ifẹ popu. Gbogbo ifisẹsin, ibaku ati ifiyajẹni ti awọn eniyan tabi ẹmi eṣu le gbero ni a ṣe si wọn nitori iwa eṣe yii.ANN 31.8

  Ni igba kan ti Romu pinu lati pa ẹgbẹ ti a korira yii run, popu pa aṣẹ kan ti o da wọn lẹbi gẹgẹ bi ẹlẹkọ odi, o si fi aye silẹ ki a pa wọn. A ko fi ẹsun kan wọn gẹgẹ bi ọlẹ, tabi alaiṣootọ, tabi mọdaru; ṣugbọn a sọ wipe wọn ni irisi ifọkansin ati iwa mimọ ti o n tan “awọn aguntan agbo tootọ jẹ.” Nitori naa popu pa aṣẹ “ki a pa awọn ẹgbẹ ẹlẹgbin, elero buburu ati onirira wọnyi bi ejò olóró bi wọn ba kọ lati yipada.” Njẹ ọba agberaga yii ronu lati ṣe alabapade awọn ọrọ rẹ wọnyi lẹẹkansi? Njẹ o mọ wipe a kọ wọn silẹ ninu awọn iwe ọrun, lati le doju kọ oun ni idajọ? “Niwọn igba ti ẹyin ti ṣe e si eyi ti o kere julọ ninu awọn arakunrin Mi wọnyi,” Jesu wipe, “ẹyin ti ṣe e si Mi.” Matiu 25:40.ANN 31.9

  Aṣẹ naa pe gbogbo awọn ọmọ ijọ lati da ara pọ lati ja ogun ẹsin ni atako si awọn ẹlẹkọ odi. Lati le fun wọn ni imoriya fun iṣẹ laabi yii, o “fun wọn ni ominira kuro ninu irora ati ijiya ẹsin, ni ti gbogboogbo ati ni pato; o tú gbogbo awọn ti wọn ba da ara pọ mọ ija ẹsin yii kuro ninu gbogbo ẹjẹ ti wọn ba ti jẹ; o fun wọn ni aṣe lati ni ohunkohun ti wọn ba gba ni ọna aitọ; o si ṣe ileri idariji ẹṣẹ fun gbogbo ẹṣẹ awọn ti wọn ba pa ẹlẹkọ odi. O fagile gbogbo adehun ti a ba ṣe ti awọn Vadois ba le ri èrè nibẹ, o paṣẹ ki gbogbo awọn alabagbe wọn o fi wọn silẹ, o ki gbogbo eniyan nilọ lati maṣe fun wọn ni iranlọwọ kankan, o si fun gbogbo eniyan ni anfani lati ko gbogbo dukia wọn.” Akọsilẹ yii fi iru ẹmi ti o n ṣiṣẹ labẹlẹ han. Ki i ṣe ohùn Kristi bikoṣe igbe dragoni naa ni a n gbọ ninu rẹ.ANN 32.1

  Awọn adari ijọ paadi ko le jẹ ki iwa wọn o dọgba pẹlu odiwọn nla ofin Ọlọrun, ṣugbọn wọn gbe odiwọn ti o ba ara wọn mu kalẹ, wọn si pinu lati fi ipa mu gbogbo eniyan lati pa a mọ nitori pe Romu fẹ bẹẹ. A ṣe awọn ofin ti wọn buru julọ. Awọn alufa ati popu oniwa-ibajẹ ati asọrọ-odi n ṣe iṣẹ ti Satani yan fun wọn lati ṣe. Aanu ko ri aaye ninu aye wọn. Iru ẹmi kan naa ti o kan Kristi mọ agbelebu ti o tun pa awọn apostoli, iru ẹmi kan naa ti o mi si Nero mujẹmujẹ lati tako awọn olootọ ni akoko rẹ, ni o n ṣiṣẹ lati pa awọn ti Ọlọrun fẹran run kuro ninu aye. Awọn ti wọn bẹru Ọlọrun fi ara da inunibini ti a ṣe si wọn fun ọpọlọpọ ọdun pẹlu suuru ati iduroṣinṣin ti o bu ọla fun Olurapada wọn. Pẹlu gbogbo ogun ẹsin ti a ko ja wọn, ati ipakupa ti a pa wọn, wọn tẹsiwaju lati rán awọn oniṣẹ-iyinrere wọn jade lati tan otitọ iyebiye kalẹ. A dọdẹ wọn de oju iku; sibẹ, ẹjẹ wọn bu omi rin irugbin ti a gbin, ko si baku lati so eso. Bayi ni awọn Waldenses ṣe ṣe ijẹri fun Ọlọrun ni ọpọ ọdun ṣaaju ki a to bi Luther. Wọn gbin irugbin iṣẹ Atunṣe ti o bẹrẹ ni akoko Wycliffe kaakiri ilẹ gbogbo, ti o tobi ti o si fi ẹsẹ rinlẹ ni akoko Luther, ti yoo si tẹsiwaju titi de opin akoko nipasẹ awọn ti wọn ba ṣetan lati jiya ohun gbogbo nitori “ọrọ Ọlọrun, ati fun ẹri Jesu Kristi.” Ifihan 1:9.ANN 32.2

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents