Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORI KỌKANLELOGUN—IKILỌ TI A KỌ SILẸ

    Ni wiwaasu ikọni ti ipadabọ lẹẹkeji, William Miller ati awọn ẹmẹwa rẹ ṣiṣẹ pẹlu erongba lati ta awọn eniyan ji lati mura silẹ fun idajọ. Wọn wa ọna lati ta awọn ẹlẹsin ji si ireti tootọ ti ijọ ati sí bi wọn ti nilo iriri Kristẹni ti o jinlẹ tó; wọn ṣiṣẹ lati ta awọn ti koi tii ronupiwada ji si ojuṣe wọn lati yipada lọgan ki wọn si ronupiwada si ọdọ Ọlọrun. “Wọn ko ṣa ipa lati yi awọn eniyan pada sinu ẹgbẹ kankan ninu ẹsin. Nitori naa, won ṣiṣẹ laarin gbogbo awọn eniyan lai fọwọ kan eto tabi iṣesi wọn.”ANN 167.1

    Miller sẹ wipe, “Ninu gbogbo iṣẹ mi, mi o ni ifẹ tabi ero lati da ijọ kankan silẹ lati inu awọn ijọ ti wọn wa nilẹ, tabi lati jẹ ki ọkan o jere lati ara ekeji. Ipinu mi ni lati ṣe gbogbo wọn loore. Bi o ba jẹ wipe gbogbo Kristẹni ni o yọ ninu ero ti wíwá Kristi, ati wipe ifẹ awọn ti ko wòye bi mo ti woye ko dinku si awọn ti wọn gba ikọni yii, mi o ro wipe a maa nilo lati ni ipade ọtọ. Erongba mi ni ifẹ lati yi awọn ọkan pada si Ọlọrun, lati sọ fun araye nipa idajọ ti n bọ, ati lati jẹ ki awọn eniyan o pese ọkan silẹ, eyi ti yoo jẹ ki wọn le pade Ọlọrun wọn pẹlu alaafia. Ọpọlọpọ awọn ti wọn yipada nitori iṣẹ mi darapọ mọ awọn ijọ ti wọn wa nilẹ tẹlẹ ni.ANN 167.2

    Nitori ti iṣẹ rẹ jẹ ki awọn ijọ o tẹsiwaju, a fi oju rere wo o fun igba diẹ. Ṣugbọn nigba ti awọn alufa ati adari ẹsin pinu lati tako ikọni nipa ipadabọ ti wọn si tẹ gbogbo ibeere lori ọrọ naa rì, ki i ṣe wipe wọn tako o lati ori pẹpẹ iwaasu nikan, ṣugbọn wọn ko fun awọn ọmọ ijọ wọn ni anfani lati lọ si ibi iwaasu ipadabọ lẹẹkeji, tabi sọ nipa ireti wọn ninu awọn ipade ijọ. Bayii ni awọn onigbagbọ ṣe ba ara wọn ni ipo idanwo nla ati iporuuru ọkan. Wọn fẹran ijọ wọn, wọn ko si ro lati kuro nibẹ; ṣugbọn bi wọn ti n ri ti wọn n tẹ ẹri ọrọ Ọlọrun rì ti wọn tun n fi ẹtọ wọn lati ṣe ayẹwo asọtẹlẹ dun wọn, wọn ri wipe igbọran wọn si Ọlọrun ko gba wọn laaye lati gbọ ti ijọ. Wọn ko le gba awọn ti wọn n kọ ẹri ọrọ Ọlọrun silẹ gẹgẹ bi ara Kristi, “opo ati ipilẹsẹ otitọ.” Nitori naa, wọn ri wipe wọn ko jẹbi bi wọn ba kuro ninu ijọ wọn. Ni igba ẹrun ni 1844, bi ẹgbẹrun lọna aadọta awọn eniyan ni wọn kuro ninu awọn ijọ.ANN 167.3

    Ni akoko yii, iyatọ nla farahan ninu ọpọlọpọ ijọ ni United States. Fun ọpọ ọdun sẹyin, diẹdiẹ, awọn ijọ ti n tẹle iwa ati iṣesi aye, ti iná igbe aye ẹmi wọn si n jo ajorẹyin; ṣugbọn ni ọdun naa awọn ẹri wà ti wọn fihan wipe lojiji gbogbo ilẹ naa ni ifasẹyin ti fẹrẹ bá tán. Nigba ti ko si ẹni ti o le sọ ohun ti o fa a, ati ile itẹwe ati lati ori pẹpẹ iwaasu ni a ti fiyesi, ti a tun n sọ nipa iṣẹlẹ naa.ANN 167.4

    Ni ipade awọn alagba ni Philadelphia, Mr. Barnes, ẹni ti o kọ iwe ti o gbajugbaja lori Bibeli ti o tun jẹ alufa ninu ọkan lara awọn ijọ ti o tobi julọ ninu ilu naa “sọ wipe, oun ti wà ninu iṣẹ alufa fun ogun ọdun, koi ti i ṣẹlẹ ri, titi fi di igba onjẹ alẹ Oluwa ti o kẹyin, ki oun ṣe eto naa laigba awọn eniyan sinu ijọ. Ṣugbọn bayii, ko si isọji, ko si iyipada, ko si idagbasoke kan gboogi ninu oore ọfẹ ti a le tọkasi ninu awọn olujọsin, ko si si ẹni ti o lọ ba ni ibi ikẹkọ rẹ lati ba jiroro nipa igbala ọkan wọn. Bi oko òwò ti n gberu si, ti ọjọ iwaju eto ìtajà ati ile iṣẹ n dan si, bẹẹ ni ifẹ aye n pọ si. Bayii ni o ṣe ri ninu gbogbo ijọ.”ANN 167.5

    Ni oṣu February ọdun kan naa, Ọjọgbọn Finney ti Oberlin College sọ pe: “O ye wa kedere wipe ni akotan, gbogbo ijọ Protestant ti orilẹ ede wa, ni wọn ko kọbi ara si tabi ni wọn ṣe atako si gbogbo atunṣe iṣesi ti akoko yii. Awọn kan wa ti wọn yatọ, ṣugbọn awọn wọnyi ko pọ to lati yi koko ọrọ naa pada kuro ni akotan. A tun ni awọn koko ọrọ miran lati gbe e lẹyin: aisi ipa isọji ninu awọn ijọ. Aikọbi ara si ohun ti ẹmi ti fẹrẹ bo gbogbo ilẹ, ti o si wọpọ ni ọna ti o banilẹru; bayii ni gbogbo awọn iwe atẹjade awọn ijọ ni gbogbo ilẹ naa ṣe sọ. . . . O wọpọ ki awọn ọmọ ijọ o di olujọsin ọṣọ ara,—wọn fọwọsowọpọ mọ awọn alaiwabiọlọrun ninu ariya faaji, ijó ajọdun, ati bẹẹbẹẹlọ... Ṣugbọn a ko nilati fẹ ọrọ ti n dunni lọkan yii loju. Ẹ jẹ ki a mọ wipe ẹri naa pọ, wọn si ṣubowa mọlẹ, eyi ti o fihan wipe, ni akotan, awọn ijọ, (pẹlu ẹdun ọkan,) ti dibajẹ. Wọn ti jinna réré sí Oluwa, Oun si ti ya ara Rẹ kuro ni ọdọ wọn.”ANN 167.6

    Onkọwe kan ninu Religious Telescope jẹri wipe: “A koi tii ri ifasẹyin ninu ijọ gẹgẹ bi a ti ri ni akoko yii ri. Ni tootọ, o yẹ ki ijọ o taji, ki o si mọ okunfa ijiya yii; nitori bi ijiya ni o ṣe yẹ ki gbogbo ẹni ti o fẹ Sioni o ri. Nigba ti a ba wòye bi iyipada tootọ ti kere to, ati aironupiwada, ati bi ọkan awọn ẹlẹṣẹ ti yigbi tó, lairotẹlẹ, a fẹrẹ le kigbe wipe, ‘Ṣe Ọlọrun ti gbagbe lati fi oore ọfẹ han ni? tabi, njẹ ilẹkun aanu ti tì ni?’”ANN 168.1

    Iru ipo yii kii waye laisi idi fun ninu ijọ funra rẹ. Okunkun ẹmi ti o n ṣubu sori awọn orilẹ ede, awọn ijọ, ati sori ẹnikọọkan, kii ṣe wipe Ọlọrun mọọmọ dawọ iranlọwọ oore ọfẹ Rẹ duro, ṣugbọn nitori pe eniyan ko naani imọlẹ ọrun, o si ti kọ ọ silẹ. Apẹẹrẹ otitọ ti o han kedere yii ni a ri ninu itan awọn Ju ni akoko Kristi. Nipa bi wọn ti gbaju mọ aye ti wọn si gbagbe Ọlọrun ati ọrọ Rẹ, iyè wọn ṣokunkun, ọkan wọn kun fun ifẹ aye ati ifẹkufẹ ara. Wọn wa ni aimọkan nipa wiwa Mesaya, wọn si kọ Olugbala silẹ nitori igberaga ati aigbagbọ wọn. Ni asiko yii gan an, Ọlọrun ko kuku tii gé orilẹ ede Ju kuro ninu imọ ati ikopa ninu ibukun igbala. Ṣugbọn awọn ti wọn kọ otitọ silẹ sọ gbogbo ifẹ fun ibukun Ọlọrun nu. Wọn ti fi “okunkun pe imọlẹ ati imọlẹ pe okunkun,” titi ti imọlẹ ti o wa ninu wọn fi di okunkun; okunkun naa ti ṣe pọ to!ANN 168.2

    O tẹ Satani lọrun ki awọn eniyan o ni afarawe ẹsin, ṣugbọn ki wọn ma ni ẹmi agbara iwabiọlọrun. Nigba ti wọn kọ iyinrere silẹ, awọn Ju tẹsiwaju lati fi itara di awọn aṣa igba atijọ mú, wọn fi gbogbo agbara ya orilẹ ede wọn sọtọ, nigba ti awọn funra wọn mọ wipe Ọlọrun ko si ni aarin wọn. Asọtẹlẹ Daniẹli tọka kedere si asiko wiwa Mesaya, o tun sọ nipa iku Rẹ, wọn ko jẹ ki awọn eniyan o ṣe ayẹwo eleyi, nikẹyin, awọn rabbi fi ẹnikẹni ti o ba ṣe akitiyan lati ka akoko naa gégun. Pẹlu ifọju ati aironupiwada, fun ọpọ ọdun, awọn eniyan Israeli duro laikọbi ara si ẹbun oore ọfẹ igbala, wọn ko fi iye si awọn ibukun iyinrere, ikilọ ọlọwọ ti o si lẹru nipa ewu ti o wa ninu kikọ imọlẹ lati ọrun silẹ.ANN 168.3

    Nibikibi ti iru iṣẹlẹ yii ba wa, iru atubọtan kan naa ni yoo tẹle. Ẹnikẹni ti o ba mọọmọ ṣe ọkan rẹ le nipa ojuṣe rẹ nitori pe o tako ifẹ ọkan rẹ, yoo padanu agbara lati mọ iyatọ laarin otitọ ati irọ. Iye rẹ a ṣokunkun, ẹri ọkan rẹ a yigbi, ọkan rẹ a le, yoo si yapa kuro ni ọdọ Ọlọrun. Ni ibi ti a ba ti gan, tabi kọ iṣẹ iranṣẹ otitọ ọrun silẹ, okunkun a bo ijọ naa mọlẹ; igbagbọ ati ifẹ a di tutu, iyapa ati arankan a bẹ silẹ. Awọn ọmọ ijọ a ko gbogbo ifẹ wọn sori ohun aye, ọkan awọn ẹlẹṣẹ a si yigbi ninu aironupiwada wọn.ANN 168.4

    A pète iṣẹ iranṣẹ angẹli akọkọ ti Ifihan 14, ti o kede wakati idajọ Ọlọrun ti o n pe awọn eniyan lati bẹru ki wọn si jọsin Rẹ, lati ya awọn eniyan Ọlọrun sọtọ kuro ninu ipa iwa ibajẹ aye ki o si tawọn ji lati ri ipo ifẹ aye ati ifasẹyin ti wọn wa gan an. Ninu iṣẹ iranṣẹ yii, Ọlọrun ran ikilọ sinu ijọ, eyi ti o jẹ wipe bi wọn ba gba a, yoo ṣe atunṣe awọn iwa buburu ti n mu wọn pamọ kuro niwaju Rẹ. Bi o ba jẹ wipe wọn gba iṣẹ iranṣẹ lati ọrun, ti wọn tẹri ọkan wọn ba niwaju Oluwa, ti wọn fi tọkantọkan mura silẹ lati duro niwaju Rẹ ni, Ẹmi ati agbara Ọlọrun i ba fi ara han laarin wọn. Lẹẹkansi ijọ i ba de ipele alabukun ti iṣọkan, igbagbọ ati ifẹ ti o wa ni akoko awọn apostoli, nigba ti awọn onigbagbọ “ni ọkan kan ati iye kan,” ti “wọn fi igboya sọ ọrọ Ọlọrun,” nigba ti “Oluwa n fi awọn ti a gbala kun ijọ lojoojumọ.” Iṣe 4:32, 31; 2:47.ANN 168.5

    Bi awọn eniyan Ọlọrun yoo ba gba imọlẹ bi o ti n tan si wọn lati inu ọrọ Rẹ, wọn yoo de ipo iṣọkan eyi ti Kristi gbadura fun, eyi ti apostoli ṣe alaye rẹ bayii, “iṣọkan ti Ẹmi ninu akopọ alaafia.” O sọ pe, “Ara kan ni n bẹ, ati Ẹmi kan, ani bi a ti pe yin ninu ireti kan ti ìpè yin; Oluwa kan, igbagbọ kan, itẹbọmi kan.” Efesu 4:3—5.ANN 168.6

    Iru awọn ayọrisi alabukun ti awọn ti wọn gba iṣẹ iranṣẹ ipadabọ rí niyii. Wọn wa lati oriṣiriṣi ijọ, a bi idiwọ tí ijọ mu wa lulẹ; awọn ikọni ti wọn yatọ ni a pin si yẹlẹyẹlẹ; a kọ ireti ijọba ẹgbẹrun ọdun ninu aye yii silẹ, a ṣe atunṣe awọn ero ti ko tọna nipa ipadabọ lẹẹkeji, a gbá igberaga ati ibarẹ aye kuro; a ṣe atunṣe iwa ti ko tọ; awọn ọkan wa ni iṣọkan ninu ibaṣepọ ti o dun julọ, ifẹ ati ayọ si n jọba laisi idiwọ. Bi ikọni yii ba ṣe eyi fun awọn perete ti wọn gba a, bakan naa ni i ba ṣe ṣiṣẹ, bi gbogbo eniyan ba gba a.ANN 168.7

    Ṣugbọn lapapọ ijọ ko gba ikilọ naa. Awọn alufa wọn, ti wọn dabi alore “si awọn ọmọ Israeli,” ni o yẹ ki wọn kọkọ ri ami wiwa Jesu, ṣugbọn wọn baku lati kẹkọ otitọ lati ara awọn ami akoko. Bi ireti ati ifẹ aye ti kun ọkan, ifẹ fun Ọlọrun ati igbagbọ ninu ọrọ Rẹ di tutu; nigba ti a waasu ikọni nipa ipadabọ, o ru ẹtanu ati aigbagbọ wọn soke lasan ni. Nitori pe awọn ọmọ ijọ (ki i si i ṣe awọn alufa) ni wọn ṣiṣẹ pupọ julọ ninu iwaasu naa wà lara awọn ohun ti wọn fi tako o. Bi igba atijọ, ẹri ọrọ Ọlọrun ti o han kedere ni a fi ibeere yii dahun si: “N jẹ ọkan ninu awọn alaṣẹ tabi awọn Farisi ti gbagbọ?” Nigba ti wọn ri bi o ti nira to lati tako koko ọrọ ti wọn mu jade lati inu awọn akoko isọtẹlẹ, ọpọ bu ẹnu àtẹ lu kikẹkọ nipa isọtẹlẹ, ti wọn si n kọni pe a ti sé awọn iwe isọtẹlẹ pa ati pe kò le yeni. Ọgọọrọ awọn eniyan ti wọn fi ọkan tan alufa wọn kọ lati tẹti si ikilọ naa; awọn miran, bi o tilẹ jẹ wipe wọn gbagbọ wipe otitọ ni, wọn kọ lati ṣe ijẹwọ rẹ, ki a ma baa “le wọn jade ninu sinagọgu.” Iṣẹ iranṣẹ ti Ọlọrun ran fun idanwo ati ifọmọ ijọ fihan ni kedere bi ọpọlọpọ ti fi ifẹ wọn si inu ohun aye ju sí inu Kristi lọ. Ohun ti o so wọn pọ mọ aye lagbara ju onfa ti ọrun lọ. Wọn yan lati tẹti si ohùn ọgbọn aye, wọn si pẹyinda si iṣẹ iranṣẹ otitọ ti n yẹ ọkan wo.ANN 169.1

    Ni kikọ ikilọ angẹli akọkọ silẹ, wọn kọ ọna ti Ọrun là kalẹ fun imubọsipo wọn silẹ. Wọn gan iṣẹ iranṣẹ oloore ọfẹ ti i ba ṣe atunṣe iwa buburu ti o ya wọn kuro ni ọdọ Ọlọrun, pẹlu itara nla wọn lọ wa ibadọrẹ aye. Eyi ni ohun ti o fa ipo ifẹ aye, ifasẹyin, ati iku ẹmi ti o wa ninu awọn ijọ ni 1844.ANN 169.2

    Ninu Ifihan 14 iṣẹ iranṣẹ angẹli keji ni o tẹle iṣẹ iranṣẹ angẹli kini, ti o n kede wipe: “Babiloni wo, o wo, ilu nla ni, nitori ti o mu gbogbo orilẹ ede mu ninu ọti waini ibinu agbere rẹ.” Ifihan 14:8. Ọrọ ti a pe ni “Babiloni” ni a mu lati inu “Babeli,” ti o tumọ si idarudapọ. A lo o ninu Bibeli lati ṣe akawe oriṣiriṣi ẹsin eke tabi eyi ti o yan apẹyinda. Ni Ifihan 17, a lo Babiloni lati tumọ si obinrin kan—akawe ti a lo ninu Bibeli ti o tumọ si ijọ, obinrin rere ni o tumọ si ijọ mimọ nigba ti obinrin pansaga tumọ si ijọ ti o yan apẹyinda.ANN 169.3

    Ninu Bibeli ibaṣepọ ti o jẹ mimọ ti o si nipọn ti o wa laarin Kristi ati ijọ Rẹ ni a fi igbeyawo ṣe akajuwe rẹ. Oluwa ti so awọn eniyan Rẹ pọ mọ ara Rẹ pẹlu majẹmu mimọ, O n ṣeleri lati jẹ Ọlọrun wọn, awọn naa si jẹjẹ lati jẹ ti Rẹ ani ti Rẹ nikan. O sọ pe: “Emi yoo gbe ọ ni aya titi lae; bẹẹ ni, Emi yoo gbe ọ ni aya ni ododo ati ni idajọ, ati ni ifẹ ati ni aanu.” Hosia 2:19. Ati pẹlu “Emi ti gbe ọ niyawo.” Jeremaya 3:14. Pọlu lo iru akajuwe kan naa ninu Majẹmu Tuntun nigba ti o sọ wipe: “Emi ti fi ọ mọ ọkọ kan, ki emi le fi ọ han fun Kristi bi wundia mimọ.” 2 Kọrintin 11:2.ANN 169.4

    Aiṣotitọ ijọ si Kristi nipa jijẹ ki igbẹkẹle ati ifẹ rẹ o yi kuro ni ọdọ Rẹ, ti o wa jẹ ki ifẹ ohun aye o gba ọkan rẹ ni a fi wé titapa si ẹjẹ igbeyawo. Ẹṣẹ Israeli ni yiya kuro ni ọdọ Oluwa ni a ṣe alaye rẹ pẹlu apẹẹrẹ yii; ati ifẹ agbayanu ti Ọlọrun ti wọn ko naani ni a ṣe alaye rẹ ni ọna ti o wọnilọkan bayii: “Mo bura fun ọ, mo si da majemu pẹlu rẹ, ni Oluwa wi, iwọ si di temi.” “Iwọ si jẹ arẹwa jọjọ, iwọ si tobi di ijọba kan. Okiki rẹ si jade lọ si ọdọ awọn alaigbagbọ nitori ẹwa rẹ: nitori ti o pé nipasẹ ẹwa Mi, eyi ti mo fi si ọ lara. . . . Ṣugbọn iwọ gbẹkẹle ẹwa rẹ, iwọ si di pansaga nitori okiki rẹ.” “Bi iyawo ti n fi aiṣootọ kuro ni ọdọ ọkọ rẹ, bẹẹ gẹgẹ ni ẹyin ṣe aiṣootọ si mi, ẹyin ile Israeli, ni Oluwa wi;” “bi iyawo ti o ṣe agbere, ti o n tẹle ajeji dipo ọkọ rẹ!” Isikiẹli 16:8, 13—15, 32; Jeremaya 3:20.ANN 169.5

    Ninu Majẹmu Tuntun, iru ede ti o jọra bakan naa ni a lo fun Kristẹni ti o ba n wa ibadọre aye yii ju oju rere Ọlọrun lọ. Apostoli Jakobu wipe: “Ẹyin alagbere lọkunrin ati lobinrin, njẹ ẹyin ko mọ wipe ibarẹ aye, iṣọta ni si Ọlọrun? nitori naa, ẹnikẹni ti yoo ba jẹ ọrẹ aye yoo di ọta Ọlọrun.”ANN 169.6

    Obinrin (Babiloni) ti Ifihan 17 ni a ṣalaye wipe “o wọ aṣọ elése aluko, ati aṣọ ọgbọ, ti a fi wura ati pearli ati okuta olowo iyebiye ṣe lọṣọ, ti o ni ago wura ni ọwọ rẹ ti o kun fun eeri ati aimọ: . . . ati ni iwaju ori rẹ ni a kọ orukọ kan si, Ohun ijinlẹ, Babiloni nla, iya awọn panṣaga. Woli naa wipe: “Mo ri obinrin naa ti o mu ẹjẹ awọn eniyan mimọ yó, pẹlu ẹjẹ awọn ajẹriku fun Jesu.” Siwaju sii, a sọ wipe Babiloni jẹ “ilu nla ni, ti o n ṣakoso lori awọn ọba aye.” Ifihan 17:4—6, 18. Romu agbara ti o ṣakoso bi onroro lori awọn ọba ile Kristẹni fun ọpọ ọdun. Aṣọ ọgbọ ati elese aluko, wura ati okuta olowo iyebiye ati pearli, fihan ni kedere ọla ati iwuga ti o ju ti awọn ọba lọ eyi ti Romu n jẹgbadun. Ko si si agbara miran ti a le sọ ni otitọ wipe “o mu ẹjẹ awọn eniyan mimọ yo” bi ijọ naa ti o fi iwa ika ṣe inunibini si awọn atẹle Kristi. A tun fi ẹsun ẹṣẹ ibaṣepọ ti ko bofinmu pẹlu “awọn ọba aye” kan Babiloni. Nipasẹ yiyapa kuro ni ọdọ Oluwa, ati ibaṣepọ pẹlu awọn alaigbagbọ ni o sọ ijọ Ju di panṣaga; Romu pẹlu ni biba ara rẹ jẹ ni ọna kan naa nipa wiwa atilẹyin agbara aye gba iru ibawi kan naa.ANN 169.7

    A sọ wipe Babiloni ni “iya awọn pansaga.” Awọn ọmọbinrin rẹ ni a yoo ṣe afihan wọn gẹgẹ bi awọn ijọ ti wọn dirọ mọ awọn ikọni ati aṣa rẹ, ti wọn si n tẹle apẹẹrẹ rẹ nipa kikọ otitọ ati ilana Ọlọrun silẹ, lati le ni ibaṣepọ ti ko bofin mu pẹlu aye. Iṣẹ iranṣẹ Ifihan 14, ti o kede iṣubu Babiloni nilati sọ nipa gbogbo ẹgbẹ ẹsin ti wọn fi igba kan jẹ mimọ, ṣugbọn ti wọn ti di eléeri. Nitori wipe ikilọ idajọ ni o tẹle iṣẹ iranṣẹ yii, a nilati ṣe iwaasu rẹ ni akoko ikẹyin; nitori naa, ki i ṣe ijọ Romu nikan ni o bawi, nitori pe ijọ naa ti wà ni ipò iṣubu fun ọpọ ọdun. Siwaju sii, ni ori kejidinlogun iwe Ifihan, a pe awọn eniyan Ọlọrun lati jade kuro ninu Babiloni. Gẹgẹ bi ẹsẹ yii ti sọ, ọpọlọpọ awọn eniyan Ọlọrun ni wọn yoo si wa ninu Babiloni. Ninu ẹgbẹ ẹsin wo ni a ti le ri pupọ ninu awọn atẹle Kristi loni? Laiṣe aniani, ninu oriṣiriṣi ijọ ti wọn n jẹri igbagbọ Protestant ni. Ni igba ti wọn ṣẹṣẹ n dide, awọn ijọ wọnyi duro gbọin fun Ọlọrun ati otitọ, ibukun Rẹ si wa pẹlu wọn. Ani awọn alaigbagbọ aye jẹri si ibukun ti o n tẹle gbigba awọn ikọni iyinrere. Ninu ọrọ woli naa si Israeli, “Okiki rẹ rekọja lọ si ọdọ awọn alaigbagbọ nitori ẹwa rẹ: nitori ti o peye latari ẹwa Mi, eyi ti mo dabo ọ, ni Oluwa wi.” Ṣugbọn wọn ṣubu nitori ifa ọkan kan naa ti o jẹ egun ati iparun fun Israeli—ifẹ lati tẹle apẹẹrẹ awọn alaiwabiọlọrun ati lati ba wọn dọrẹ. “Iwọ gbẹkẹle ẹwa rẹ, iwọ si ṣe panṣaga nitori okiki rẹ.” Isikiẹli 16:14, 15.ANN 170.1

    Ọpọ awọn ijọ Protestant n tẹle apẹẹrẹ aiṣedeede Romu nipa ibaṣepọ pẹlu “awọn ọba aye”—awọn ijọ ilu, nipasẹ ibaṣepọ wọn pẹlu ijọba, ati awọn ijọ miran nipa wiwa oju rere aye. “Babiloni” ti o tumọ si rudurudu ba awọn ẹgbẹ wọnyi mu, gbogbo wọn n sọ wipe wọn ri ikọni wọn lati inu Bibeli, sibẹ wọn pin yẹlẹyẹlẹ si oriṣiriṣi ẹgbẹ ti ko ṣe e kà, pẹlu awọn ikọni ati ironu ti wọn tako ara wọn.ANN 170.2

    Yatọ si ifọwọsowọpọ ti o jẹ ẹṣẹ pẹlu aye, awọn ijọ ti wọn yapa kuro lọdọ Romu si ni awọn iwa rẹ miran.ANN 170.3

    Iṣẹ Katoliki ti Romu kan sọ wipe “bi ijọ Romu ba fi igba kan ri jẹbi ibọriṣa nitori awọn eniyan mimọ, ọmọbinrin rẹ, Ijọ England, jẹbi ẹṣẹ kan naa, ẹni ti o ya ile ijọsin mẹwa sọtọ si Maria fun ẹyọkan ti a ya sọtọ si Kristi.”ANN 170.4

    Dr Hopkins pẹlu, ninu “A Treatise on the Millenium” (Akọsilẹ lori Ẹgbẹrun Ọdun) sọ wipe: “Ko sí ìdí fun wa lati ro wipe Ijọ Romu nikan ni o ni ẹmi ati iṣesi ti o lodi si ẹsin Kristẹni. Awọn ijọ Protestant ni ọpọlọpọ aṣodisi-kristi ninu wọn, a ko si fọ wọn mọ rárá kuro ninu . . . iwa ibajẹ ati iwa buburu rẹ.”ANN 170.5

    Nipa bi Ijọ Presbyterian ti kuro ninu Romu, Dr Guthrie kọwe pe: “Ni ọgọrun ọdun mẹta sẹyin, ijọ wa, pẹlu Bibeli ti a ṣi silẹ lori asia rẹ, pẹlu ọrọ akọle yii, ‘Wá inu Iwe Mimọ’ lori iwe rẹ, jade kuro lati ẹnu ọna Romu.” Lẹyin eyi o bere ibeere ti o ṣe pataki yii: “Ṣe wọn jade kuro ninu Romu pẹlu ara mimọ bi?”ANN 170.6

    Spurgeon sọ wipe, “O dabi ẹnipe titẹle ami majẹmu ti jẹ Ijọ England ra; ṣugbọn o dabi ẹnipe aitẹriba-fun-ilana-ijọ kun fun ero aigbọran bakan naa. Awọn ti a n fi oju rere wo n yipada lẹyọ kọọkan kuro ninu agbekalẹ igbagbọ. Laiṣe aniani, mo gbagbọ wipe, ọkan England kun fun aigbọran gbogbo ti o tun ni igboya lati lọ si ori pẹpẹ iwaasu lati pe ara rẹ ni Kristẹni.”ANN 170.7

    Kini ipilẹsẹ iyapa nla? Bawo ni ijọ ṣe kọkọ yipada kuro ninu iyinrere alailabawọn? Nipa titẹle iṣesi ẹsin ibọrisa ni, lati le mu ki awọn alaigbagbọ o gba ẹsin Kristẹni. Apostoli Pọlu sọ, ani ni igba aye rẹ, wipe “Ohun ijinlẹ ẹṣẹ ti n ṣiṣẹ ná.” 2 Tẹsalonika 2:7. Ni akoko awọn apostoli, ijọ wa ni mimọ. Ṣugbọn “nigba ti ọrundun keji n lọ si opin ọpọ ninu awọn ijọ ni wọn ni irisi tuntun; otitọ ti igba iṣaaju poora, laikọbiarasi, bi awọn ọmọlẹyin akọkọ ti n lọ si ibojì wọn, awọn ọmọ wọn, pẹlu awọn ti a jere sinu ijọ, . . . jade siwaju wọn si sọ wipe iṣẹ naa ti di tuntun.” Lati le jẹ ki awọn ọmọlẹyin o duro, a fa odiwọn giga ti igbagbọ Kristẹni wa silẹ, latari eyi, “agbara ẹsin ibọriṣa san wọ inu ijọ, o si ko aṣa, iṣesi, ati ère rẹ dani.” Bi ẹsin Kristẹni ti ri oju rere ati atilẹyin awọn alaṣẹ aye, ọpọlọpọ awọn eniyan ni wọn fi ẹnu lasan gba a; ṣugbọn nigba ti wọn fi oju jẹ Kristẹni, ọpọlọpọ wọn “ni wọn si jẹ abọriṣa ninu iwa wọn, ni pataki julọ ti wọn n jọsin ère wọn ni idakọnkọ.”ANN 170.8

    Ṣe iru igbesẹ kan naa ko ti fẹrẹ fi ara rẹ han tan ninu gbogbo ijọ ti wọn pe ara wọn ni Protestant? Bi awọn oludasilẹ, awọn ti wọn ni ẹmi afọmọ tootọ, ti n kọjalọ, awọn ọmọ wọn a jade siwaju, wọn a si “sọ iṣẹ naa di tuntun.” Nipa siso mọ igbagbọ awọn baba wọn ni aironu ti wọn si kọ lati gba otitọ miran ni afikun si ohun ti wọn ri, awọn ọmọ awọn alatunṣe yapa jinna réré kuro ninu apẹẹrẹ irẹlẹ, isera ẹni, ati kikọ aye silẹ. Bayi ni “iṣotitọ akọkọ ti ṣe parẹ.” Agbara ifẹ aye ti o n san wọ inu ijọ si ko “pẹlu rẹ, awọn aṣa, iṣesi, ati ère rẹ.”ANN 171.1

    O ṣe ni laanu bi ibarẹ aye eyi ti i ṣe “iṣọta si Ọlọrun” ti jinlẹ to lọna ti o banilẹru, eyi ti o wa wọpọ laarin awọn atẹle Kristi! Awọn ijọ ti wọn lokiki ninu ẹsin Kristẹni ti yapa kuro ninu odiwọn irẹlẹ, isera-ẹni, iṣotitọ ati iwabiọlọrun ti inu Bibeli to! John Wesley, ni sisọ nipa lílo owó ni ọna ti ko tọ sọ pe: “Maṣe fi eyikeyi ninu ẹbun ti o ṣeyebiye nì ṣofo, nitori titẹ ifẹ oju lọrun lasan, nipa aṣọ olowo iyebiye, tabi ohun ọṣọ ti ko wulo. Maṣe fi ohunkohun ṣofo ninu rẹ nipa ṣiṣe ile rẹ lọṣọ ni ọna àrà; nipa awọn ohun èlò ile olowo iyebiye; nipa awọn aworan ati ohun olowo iyebiye ti a n gbekọ ile. . . . Maṣe ṣe ohunkohun lati tẹ igberaga aye lọrun, lati ri ifẹ tabi iyin eniyan. . . . ‘Niwọn igba ti o ba ti n ṣe rere si ara rẹ, awọn eniyan yoo sọ nipa rẹ ni rere.’ Niwọn igba ti o ba n ‘wọ aṣọ ọgbọ wiwẹ,’ ti o si n gbé ni ‘pọpọ ṣinṣin lojoojumọ,’ laiṣeyemeji ọpọ ni yoo sọ nipa bi o ti n fẹ ohun giga to, ati ilawọ ati igbanilalejo rẹ. Ṣugbọn maṣe ra isọrọ rere wọn bi o ti wu ki o dara to. Dipo eyi, jẹ ki iyì ti o wa lati ọdọ Ọlọrun o tẹ ọ lọrun.” Ṣugbọn ninu ọpọ awọn ijọ loni, a ti kọ iru awọn ikọni wọnyi silẹ.ANN 171.2

    Fifi ẹnu jẹ ẹlẹsin ti di gbajugbaja ninu awọn ijọ loni. Awọn alaṣẹ, oloṣelu, agbẹjọro, oniṣegun, oniṣowo, darapọ mọ ijọ gẹgẹ bi ohun elo lati ri ibọwọfun ati ifọkantan ni awujọ, ati lati le tẹsiwaju ninu ifẹ aye wọn. Bayi ni wọn ṣe n fi awọn iwa aiṣododo wọn pamọ sabẹ Kristẹni afẹnujẹ. Ọpọ awọn ẹgbẹ ẹsin ti wọn ni agbara latari ọrọ ati orukọ awọn olufẹ aye ti wọn ṣe itẹbọmi yii, tun ṣe akitiyan si lati ni okiki ati iranlọwọ. Awọn ile ijọsin ti wọn tobi, ti a ṣe lọṣọ lọna ti o nani lowo julọ, ni a kọ si awọn adugbo ti wọn lokiki. Awọn olujọsin n ṣe ara wọn lọṣọ pẹlu aṣọ asiko to jẹ olowo iyebiye. Owo oṣu gọbọi ni a n san fun awọn oniwaasu to ni ẹbun lati le dawọn lara ya ati lati le pe awọn eniyan wá. Awọn iwaasu rẹ ko gbọdọ fẹnu ba awọn ẹṣẹ ti wọn wọpọ, ṣugbọn o nilati ṣe jẹjẹ ki o si dun mọni leti. Bayi ni a ṣe ni awọn ẹlẹṣẹ ti wọn gbajumọ ninu iwe ijọ, ti a si fi awọn ẹṣẹ ti wọn gbajumọ pamọ si abẹ afarawe iwabiọlọrun.ANN 171.3

    Ni sisọ nipa iwuwasi awọn Kristẹni si aye ni akoko yii, iwe atẹjade kan ti ki i ṣe ti ẹsin sọ wipe: “Laimọ ijọ ti juwọ silẹ fun ẹmi akoko yii, o si ti jẹ ki ilana ijọsin rẹ o ba ifẹ asiko yii mu.” “Ni tootọ, ohun gbogbo ti yoo mu ki ẹsin o joju ni gbese, ni ijọ n lo gẹgẹ bi ohun elo.” Onkọwe kan ninu New York Independent sọ nipa ijọ Methodist bayi: “Ìlà ti o ya awọn oniwabiọlọrun ati awọn alailẹsin ti fẹrẹ parẹ tan, awọn onitara laarin awọn mejeeji n ṣe akitiyan lati mu gbogbo iyatọ ti o wa laarin iṣesi ati igbadun wọn kuro.” “Bi ẹsin ba ti lokiki to dabi ẹnipe o n jẹ ki iye awọn ti wọn fẹ ri èrè rẹ laiṣe ojuṣe rẹ o pọ si ni.ANN 171.4

    Howard Crosby sọ wipe: “O jẹ ohun ti o kan ni gbọngbọn wipe ijọ Kristi ko mura to lati mu erongba Oluwa rẹ ṣẹ. Gẹgẹ bi awọn Ju igbaani ti ṣe jẹ ki ibaṣepọ wọn pẹlu awọn orilẹ ede abọriṣa o yi ọkan wọn kuro lọdọ Ọlọrun, . . . bẹẹ gẹgẹ ni ijọ Kristi ti n ṣe bayii, pẹlu ibaṣepọ rẹ eyi ti ko tọna pẹlu aye alaigbagbọ ti o kọ ilana ọrun fun igbesi aye otitọ rẹ silẹ, o n jọwọ ara rẹ lọwọ fun awọn iwa buburu awujọ ti ko ni Kristi, o n sọ iru ọrọ kan naa, o si n ri awọn idahun ti wọn ṣajeji si ifihan Ọlọrun, ti wọn tako gbogbo idagbasoke ninu oore ọfẹ.”ANN 171.5

    Ninu igbi ifẹ aye ati ifẹ faaji yii, isẹ-ara-ẹni ati ifi-ara-ẹni rubọ nitori Kristi ti fẹrẹ parun tan. “Diẹ lara awọn ọkunrin ati obinrin ti wọn n ṣiṣe ninu awọn ijọ ni a kọ nigba ti wọn wa ni ọmọde lati fi ara wọn rubo lati le fi ohun kan silẹ tabi ṣe ohun kan fun Kristi.” Ṣugbọn “bi ko ba si owó, . . . a ko gbọdọ pe ẹnikẹni lati fi silẹ. Rara o! ẹ ṣe ajọdun, àpéwò, àṣè, tabi ohunkohun lati jẹ—ohunkohun lati da awọn eniyan lara ya.”ANN 172.1

    Gomina Washburn ti Winsconsin ninu iṣẹ iranṣẹ ọdun rẹ, ni January 9, 1873 sọ bayi: “O dabi ẹnipe a nilo ofin diẹ lati tú awọn ile ẹkọ ti a ti n kọ awọn onitẹtẹ ká. Wọn wa ni ibi gbogbo. Ani ijọ paapa (boya laimọ) ni igba miran n ṣiṣẹ fun eṣu. Iré orin nibi ti a ti n funni ni ẹbun, ẹbun tẹtẹ, ni igba miran lati ran iṣẹ ẹsin tabi iṣẹ aanu lọwọ, ṣugbọn ni ọpọ igba fun awọn idi ti ko nitumọ pupọ, tẹtẹ, ifunni ni ẹbun, ati bẹẹbẹẹ lọ, jẹ ọna lati gba owo ti a ko ṣiṣẹ fun. Ko si ohun ti o bani niwajẹ tabi ti o n pani bi ọti, paapaa julọ fun awọn odo bi i níní owo tabi ohun ini laiṣiṣẹ. Awọn eniyan pataki ti wọn n kopa ninu iru tẹtẹ yii, wọn n pa ẹri ọkan wọn lẹnu mọ pẹlu ero wipe iṣẹ rere ni wọn maa fi owo naa ṣe, ko yanilẹnu wipe awọn ọdọ ipinlẹ yii saba maa n ṣubu sinu iwa ti ifẹ ere ti o lewu saba maa n fà.”ANN 172.2

    Ẹmi ifẹ aye n wọnu awọn ijọ kaakiri ninu ẹsin Kristẹni. Robert Atkins ninu iwaasu ti o ṣe ni London, ṣe apejuwe ifasẹyin ẹmi ti o gbilẹ ni England: “Awọn ti wọn jẹ olododo lootọ n parẹ kuro ninu aye, ko si si ẹni ti o ro o ninu ọkan rẹ. Awọn ti wọn n pe ara wọn ni ẹlẹsin ni ode oni yii, ni gbogbo ijọ jẹ olufẹ aye, awọn ti n ṣe bi aye, olufẹ idẹra, ti wọn nifẹ si ibọwọfun eniyan. A pe wọn lati jiya pẹlu Kristi, ṣugbọn wọn sa fun itiju. . . . Ipẹyinda, ipẹyinda, ipẹyinda, ni a kọ siwaju gbogbo ile ijọsin; bi wọn ba ni imọlara rẹ ni, ireti i ba wa; ṣugbọn, o maṣe o! wọn n kigbe, ‘A jẹ ọlọrọ, a si n pọ si ni ọrọ, a ko si nilo ohun kan.’”ANN 172.3

    Ẹsun ẹṣẹ nla ti a fi kan Babiloni ni pe o “mu gbogbo orilẹ ede mu ninu ọti waini ibinu agbere rẹ.” Ago ipanilọti eyi ti o fun araye tumọ si ẹkọ eke ti o gba latari ibaṣepọ ti ko bojumu rẹ pẹlu awọn ẹni nla aye. Ibarẹ aye ti ba igbagbọ rẹ jẹ, ni ipa tirẹ, o ni ipa buburu lori aye nipa kikọ awọn ikọni ti wọn tako ọrọ kedere ti o wa ninu Iwe Mimọ.ANN 172.4

    Romu fi Bibeli pamọ kuro ni ọdọ awọn eniyan o si fẹ ki gbogbo eniyan o gba ikọni rẹ rọpo. Iṣẹ Atunṣe ni lati dari awọn eniyan pada sinu ọrọ Ọlọrun; ṣugbọn njẹ ki i ṣe wipe ootọ ni wipe ninu awọn ijọ loni, a n kọ awọn eniyan lati gbe igbagbọ wọn si ori igbagbọ ati ikọni ijọ wọn dipo si ori Iwe Mimọ? Charles Beecher sọ nipa awọn ijọ Protestant bayii: “Wọn kọ lati sọ ọrọ lile si awọn igbagbọ kan pẹlu iṣọra eyi ti awọn baba mimọ i ba fi kọ lati sọ ọrọ lile lati tako ijọsin awọn ẹni mimọ ati ajẹriku ti o ṣẹṣẹ n bẹrẹ eyi ti wọn fi n kọni. . . . Awọn ijọ oniwaasu Protestant ti so ọwọ ara wọn ati ti ẹnikeji papọ debi pe, laarin gbogbo wọn, eniyan ko le di oniwaasu rara, lai gba awọn iwe kan ni afikun si Bibeli. . . . Ki i ṣe ero lasan ni wipe agbara akọsilẹ igbagbọ ti bẹrẹ si nii ko Bibeli ni papa mọra bi Romu ti ṣe, bi o tilẹ jẹ wipe o n ṣẹlẹ ni bonkẹlẹ.”ANN 172.5

    Nigba ti awọn olukọ tootọ ba n ṣe alaye ọrọ Ọlọrun, awọn ọmọwe ati alufa ti wọn sọ wipe wọn ni oye Iwe Mimọ a dide, wọn a pe ẹkọ ti o yè kooro ni èké, bayi ni wọn a ṣe yi awọn ti n wa otitọ pada kuro ni ọna otitọ. Ti kii ba n ṣe wipe aye ti kun fun ọti waini Babiloni laisi ireti mọ, ọgọọrọ eniyan ni i ba gbagbọ ti wọn a si yipada nipasẹ otitọ ti o han kedere ninu ọrọ Ọlọrun. Ṣugbọn o dabi ẹnipe ọrọ ẹsin igbagbọ ko ye ara wọn mọ ti awọn eniyan ko si mọ ohun ti o yẹ ki wọn gbagbọ gẹgẹ bi otitọ. Ẹṣẹ aironupiwada araye wa ni ẹnu ọna ijọ.ANN 172.6

    Iṣẹ iranṣẹ angẹli keji ti Ifihan 14 ni a kọkọ waasu rẹ ni igba ẹrun 1844, nigba naa o ba awọn ijọ United States mu gan an ni, ni ibi ti a ti kede ikilọ nipa idajọ kaakiri julọ, ti a si ti fẹrẹ kọ ọ silẹ tan patapata, ati nibi ti ifasẹyin awọn ijọ ti ṣẹlẹ kankan. Ṣugbọn iṣẹ iranṣẹ angẹli keji ko wa si imuṣẹ tan ni 1844. Nigba naa, awọn ijọ ti ṣubu ninu iwa latari bi wọn ti kọ imọlẹ iṣẹ iranṣẹ ipadabọ silẹ; ṣugbọn wọn ko ṣubu tan patapata. Bi wọn ti n tẹsiwaju lati kọ awọn otitọ pataki fun akoko yii silẹ bẹẹ ni wọn tubọ n ṣubu si. Amọ a koi tii le sọ wipe “Babiloni ti ṣubu , . . . nitori o mu gbogbo orilẹ ede mu ninu ọti ibinu agbere rẹ.” Koi tii mu ki gbogbo orilẹ ede ṣe eyi. Ẹmi titẹle aye ati aikọbiarasi otitọ idanniwo fun akoko yii si wa, o si n gbilẹ si ninu awọn ijọ Protestant ni gbogbo orilẹ ede ti n ṣe ẹsin Kristẹni; awọn ijọ yii si wa ninu ibawi ẹlẹru ti angẹli keji. Ṣugbọn iṣẹ ifasẹyin koi tii pari.ANN 172.7

    Bibeli sọ wipe ṣaaju wiwa Oluwa, Satani yoo ṣiṣẹ “pẹlu gbogbo agbara ati ami eke iyanu, ati pẹlu gbogbo itanjẹ ti aiṣododo gbogbo;” ati awọn ti wọn “ko gba ifẹ fun otitọ ki wọn baa le di ẹni igbala” ni a yoo fi silẹ lati gba “itanjẹ ti o lagbara ki wọn baa le gba irọ gbọ.” 2 Tẹsalonika 2:9:11. O di igba ti wọn ba de ipo yii, ti ibaṣepọ ijọ pẹlu aye ba fẹsẹmulẹ daradara kaakiri ilẹ Kristẹni ki Babiloni to ṣubu patapata. Labalalabala ni iyipada yii n wa, imuṣẹ Ifihan 14:8 ni kikun si wa ni ọjọ iwaju.ANN 173.1

    Laika okunkun ẹmi ati iyapa kuro ni ọdọ Ọlọrun ti o wa ninu awọn ijọ ti wọn parapọ di Babiloni si, ẹgbẹ awọn atẹle Kristi ni tootọ si wa ninu wọn. Ọpọlọpọ wa ninu awọn wọnyi ti wọn koi tii ri otitọ pataki fun akoko yii ri. Ki i ṣe diẹ ninu wọn ni ipo ti wọn wa bayi ko tẹ lọrun ti wọn si n fẹ imọlẹ si. Lasan ni wọn n wa aworan Kristi ninu awọn ijọ ti wọn n lọ. Bi awọn ẹgbẹ wọnyi ba ti n yapa jina réré kuro ni ọdọ otitọ, ti wọn si n dara pọ mọ aye si, iyatọ ti o wa laarin awọn ẹgbẹ mejeeji a tubọ farahan si, nikẹyin, yoo yọri si ipinya. Akoko n bọ nigba ti awọn ti wọn fẹran Ọlọrun ju ohunkohun lọ ko ni le ni ibaṣepọ mọ pẹlu awọn “olufẹ faaji ju olufẹ Ọlọrun lọ; ti wọn ni afarawe iwabiọlọrun, ṣugbọn ti wọn sẹ agbara rẹ.”ANN 173.2

    Ifihan 18 tọka si akoko ti, nitori bi wọn ti kọ ikilọ mẹtẹẹta ti Ifihan 14:6—12 silẹ, ni kikun, ijọ yoo wa ni ipo tí angẹli keji sọ tẹlẹ, a yoo si pe awọn eniyan Ọlọrun ti wọn wa ni Babiloni lati jade kuro ninu rẹ. Iṣẹ iranṣẹ yii ni eyi ti o kẹyin ti a yoo fun araye; yoo si ṣe iṣẹ ti a fẹ ki o ṣe. Nigba ti a ba fi awọn ti “ko gba otitọ gbọ, ti wọn ni inu didun si aiṣododo” (2 Tẹsalonika 2:12) silẹ lati gba itanjẹ nla ati lati gba eke gbọ, nigba naa ni imọlẹ otitọ yoo tan si awọn ti ọkan wọn ṣi silẹ lati gba a, gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun ti wọn wa ni Babiloni yoo si dahun si ìpè naa: “Ẹ jade kuro ninu rẹ, ẹyin eniyan Mi.” Ifihan 18:1.ANN 173.3

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents