Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  ORI KARUNDINLỌGBỌN—OFIN ỌLỌRUN WA TITI LAE

  “A ṣi tẹmpili Ọlọrun silẹ ni ọrun, a ṣi ri apoti majẹmu ninu tẹmpili Rẹ.” Ifihan 11:19. Apoti majẹmu Ọlọrun wa ninu ibi mimọ julọ, abala keji ninu ibi mimọ. Ninu iṣẹ iranṣẹ ninu ibi mimọ ni aye, eyi ti o duro “gẹgẹ bi apẹẹrẹ ati ojiji awọn ohun ti ọrun,” ni Ọjọ nla ti Iwẹnumọ nikan ni a to ma a n ṣi yara yii lati lọ ṣe iwẹnumọ ibi mimọ. Nitori naa ikede wipe a ṣi tẹmpili Ọlọrun silẹ ni ọrun ati pe a ri apoti majẹmu Rẹ tọka si ṣiṣi ibi mimọ julọ ninu ibi mimọ ti ọrun silẹ ni 1844 bi Kristi ti wọ ibẹ lọ lati ṣe aṣekagba iṣẹ iwẹnumọ. Awọn ti wọn fi igbagbọ tẹle Olu Alufa nla wọn bi O ti bẹrẹ iṣẹ Rẹ ninu ibi mimọ julọ, ri apoti majẹmu Rẹ. Bi wọn ti kọ nipa koko ọrọ ibi mimọ, wọn ni oye iyipada ti o de ba iṣẹ iranṣẹ Olugbala, wọn si ri wipe O n ṣiṣẹ niwaju apoti majẹmu Ọlọrun, ti O n fi ẹjẹ Rẹ bẹbẹ nitori ẹlẹṣẹ.ANN 192.1

  Apoti ti o wa ninu agọ ti aye ní walaa okuta meji, nibi ti a kọ ilana ofin Ọlọrun si. Apoti naa jẹ ibi ti a fi walaa ofin pamọ si, awọn ilana Ọlọrun wọnyi jẹ ki o ṣe pataki, ati ki o si jẹ mimọ. Nigba ti a ṣi tẹmpili Ọlọrun silẹ ni ọrun, a ri apoti majẹmu. Ninu ibi mimọ julọ ninu ibi mimọ ni ọrun, a kọ ofin mimọ Ọlọrun sibẹ—ofin ti Ọlọrun sọ jade funra Rẹ laarin àrá ni Sinai ti O tun fi ika ara Rẹ kọ wọn si ori walaa okuta.ANN 192.2

  Ofin Ọlọrun ninu ibi mimọ ti ọrun ni ojulowo nla, eyi ti ilana ti a gbẹ si ori walaa okuta ti Mose kọ silẹ ninu Pẹntatiuku jẹ ẹda ti o peye. Gbogbo awọn ti wọn ni oye koko ọrọ pataki yii ni wọn ri wipe ofin Ọlọrun jẹ mimọ ati pe ko le yipada. Wọn ri bi ọrọ Olugbala ti lagbara to ni ọna ti wọn ko gba ri bẹẹ ri: “Titi ọrun ati aye yoo fi kọja lọ, kinkini ninu ofin ki yoo kọja lọ.” Matiu 5:18. Ofin Ọlọrun, ti i ṣe ifihan ifẹ Rẹ, ẹdakọ iwa Rẹ, gbọdọ wa titi lae, “gẹgẹ bi ẹlẹri otitọ ni ọrun.” Ko si aṣẹ kan ti a fagile; ko si kiun kan ti a yipada. Ọlọrun sọ wipe: “Titi lae Oluwa, a ti fi idi ọrọ Rẹ mulẹ ni ọrun.” “Gbogbo aṣẹ Rẹ ni wọn daju. Wọn duro titi lae ati laelae.” O. Dafidi 119:89; 111:7, 8.ANN 192.3

  Ni aarin gungun Ofin Mẹwa ni a kọ ofin kẹrin si, gẹgẹ bi a ti kọkọ kede rẹ; “Ranti ọjọ isinmi lati pa a mọ. Ọjọ mẹfa ni iwọ yoo ṣiṣẹ, ti iwọ yoo ṣe iṣẹ rẹ gbogbo: ṣugbọn ọjọ keje ni ọjọ isinmi Oluwa Ọlọrun rẹ: ninu rẹ ni iwọ ko gbọdọ ṣe iṣẹ kankan, iwọ, tabi ọmọkunrin rẹ, tabi ọmọbinrin rẹ, tabi ọmọ ọdọ rẹ ọkunrin tabi ọmọ ọdọ rẹ obinrin, tabi malu rẹ tabi ajeji ti n bẹ lẹnu ilẹkun rẹ: nitori ni ọjọ mẹfa ni Oluwa da ọrun ati aye, ati okun, ati ohun gbogbo ti n bẹ ninu wọn, O si sinmi ni ọjọ keje: nitori naa Oluwa bukun Ọjọ Isinmi, O si ya a si mimọ.” Eksodu 20:8—11.ANN 192.4

  Ẹmi Ọlọrun fi ọwọ ba ọkan awọn akẹkọ ọrọ Rẹ. A tẹ ẹ mọ wọn lọkan wipe wọn ti fi aimọkan ru ilana yii nipa ṣiṣe aibikita nipa ọjọ Isinmi Ẹlẹda. Wọn bẹrẹ si i wa idi fun pipa ọjọ kini ọsẹ mọ dipo ọjọ ti Ọlọrun ya sọtọ. Wọn ko le ri idi kan ninu Iwe Mimọ wipe a ti pa ofin kẹrin rẹ tabi wipe a ti yi ọjọ isinmi pada, a koi tii mu ibukun ti a ṣe si ori ọjọ keje kuro. Wọn ti n fi tọkantọkan wa lati mọ ati lati ṣe ifẹ Ọlọrun; ni bayi ti wọn ri ara wọn gẹgẹ bi arufin Rẹ, ibanujẹ kun ọkan wọn, wọn si fi igbọran wọn han si Ọlọrun nipa pipa ọjọ Isinmi mọ.ANN 192.5

  Ọpọ akitiyan ni a ṣe lati bi igbagbọ wọn lulẹ. Ko si ẹni ti ko ni ṣai ri wipe bi ibi mimọ ni aye ba jẹ apẹẹrẹ ti ọrun, ofin ti a fi sinu apoti ni aye yoo jẹ ẹda gan ti ofin ti o wa ni ọrun; ati pe gbigba otitọ nipa ibi mimọ ni ọrun kan gbigba aṣẹ ofin Ọlọrun ati ojuṣe ọjọ Isinmi ti ofin kẹrin. Eyi ni aṣiri bi a ti ṣe atako kikoro si alaye Iwe Mimọ nipa ọna ti o wa ni irẹpọ lati ṣe alaye iṣẹ iranṣẹ Kristi ninu ibi mimọ ti ọrun. Awọn eniyan n wọna lati ti ilẹkun ti Ọlọrun ṣi silẹ, ati lati ṣi ilẹkun ti O ti tì. Ṣugbọn “Ẹni ti O ṣi, ti ẹnikẹni ko le ti, ti O ti ti ẹnikẹni ko le ṣi,” ti sọ pe: “Kiyesi, mo ti gbe ilẹkun ti a ṣi ka iwaju rẹ, ti ẹnikẹni ko le ti.” Ifihan 3:7, 8. Kristi ti ṣi ilẹkun naa, tabi iṣẹ iranṣẹ, ti ibi mimo julọ silẹ, imọlẹ n tan lati ibi ilẹkun ibi mimọ ti a ṣi silẹ ni ọrun, a si fihan wipe ofin kẹrin wa ninu awọn ofin ti a kọ sibẹ; ohun ti Ọlọrun ti fi idi rẹ mulẹ, ko si ẹni ti o le bi i wo.ANN 192.6

  Awọn kan ti wọn gba imọlẹ nipa ibalaja Kristi ati wipe ofin Ọlọrun wa titi lae ri wipe awọn otitọ wọnyi wa ninu Ifihan 14. Awọn iṣẹ iranṣẹ ori iwe yii ni ikilọ mẹta ti yoo pese awọn olugbe aye silẹ fun wiwa Oluwa lẹẹkeji. Ikede wipe, “Wakati idajọ Rẹ de,” tọka si iṣẹ aṣekagba ti iṣe iranṣẹ Kristi fun igbala eniyan. O kede otitọ ti a nilati kede titi ti Olugbala a fi pari ẹbẹ Rẹ ti yoo si pada wa sinu aye lati ko awọn eniyan Rẹ lọ si ọdọ ara Rẹ. Iṣẹ idajọ ti o bẹrẹ ni 1844 yoo tẹsiwaju titi ti a o fi ṣe ipinu lori gbogbo ọrọ, ati ti alààyè ati ti oku; nitori naa yoo tẹsiwaju titi fi di opin akoko oore ọfẹ fun eniyan. Ki eniyan baa le wa ni imurasilẹ lati le duro ni ọjọ idajọ, iṣẹ iranṣẹ naa pa wọn lase lati “bẹru Ọlọrun, ki wọn si fi ogo fun,” “ki wọn si jọsin Ẹni ti O da ọrun, ati aye, ati okun ati awọn orisun omi.” Abayọri gbigba awọn iṣẹ iranṣẹ wọnyi ni a funni pẹlu ọrọ yii: “Iwọnyi ni awọn ti n pa ofin Ọlọrun mọ ati igbagbọ Jesu.” Lati le mura silẹ fun ọjọ idajọ, o ṣe pataki ki awọn eniyan pa ofin Ọlọrun mọ. Ofin naa ni yoo jẹ odiwọn fun iwuwasi ni idajọ. Apostoli Pọlu sọ wipe: “Iye awọn ti wọn ṣẹ ninu ofin ni a o fi ofin da lẹjọ, . . . ni ọjọ ti Ọlọrun yoo ṣe idajọ aṣiri awọn eniyan nipasẹ Jesu Kristi.” O tun sọ wipe “awọn oluṣe ofin ni a o da lare.” Romu 2:12—16. Igbagbọ se pataki lati le pa ofin Ọlọrun mọ; nitori laisi igbagbọ ko ṣe e ṣe lati wu u.” Ati pe “ohunkohun ti ko ba i ṣe ti igbagbọ, ẹṣẹ ni.” Heberu 11:6; Romu 14:23.ANN 193.1

  Nipasẹ angẹli akọkọ, a pe awọn eniyan lati “bẹru Ọlọrun ki wọn si fi ogo fun” ki wọn si jọsin Rẹ gẹgẹ bi Ẹlẹda ọrun ati aye. Lati le ṣe eyi wọn nilati ṣe igbọran si ofin Rẹ. Ọlọgbon nì sọ wipe: “Bẹru Ọlọrun ki ẹ si pa ofin Rẹ mọ: nitori eyi ni gbogbo ojuṣe eniyan.” Oniwasu 12:13. Laisi igbọran si ofin Rẹ, ko si ijọsin ti o le dun mọ Ọlọrun ninu. “Eyi ni ifẹ Ọlọrun wipe a pa ofin Rẹ mọ.” “Ẹnikẹni ti o ba yi eti rẹ kuro ninu gbigbọ ofin, ani adura rẹ yoo jẹ ohun irira.” 1 Johanu 5:3; Owe 28:9.ANN 193.2

  Ojuṣe lati jọsin Ọlọrun duro lori koko ọrọ wipe Oun ni Ẹlẹda ati wipe awọn ẹda yoku wa laaye nipasẹ Rẹ. Nibikibi ti O ba ti sọ wipe Oun yẹ fun ijọsin ati ibọwọfun ju awọn ọlọrun keferi lọ ninu Bibeli, O maa n sọ nipa ẹri agbara atida Rẹ. “Ère ni gbogbo awọn Ọlọrun orilẹ ede: ṣugbọn Oluwa ni O da awọn ọrun.” O. Dafidi 96:5. “Tani ẹyin i ba wa fi Mi we, tabi tani o ba Mi dọgba? ni Ẹni Mimọ wi. Ẹ gbe oju yin soke, ki ẹ si wo, tani o da awọn nnkan wọnyi.” “Bayi ni Oluwa ti O da awọn ọrun wi, Ọlọrun funra Rẹ ti O da aye ti o si ṣe e: . . . Emi ni Oluwa; ko si si ẹlomiran.” Aisaya 40:25, 26; 45:18. Olorin sọ wipe: “Ẹ mọ wipe Oluwa Oun ni Ọlọrun: Oun ni O da wa, ki i si i ṣe awa funra wa.” “Ẹ wa, ẹ jẹ ki a jọsin, ki a tẹriba: ẹ jẹ ki a kunlẹ niwaju Oluwa Ẹlẹda wa.” O. Dafidi 100:3; 95:6. Awọn ẹda mimọ ti wọn n jọsin Ọlọrun ni ọrun sọ, gẹgẹ bi idi ti wọn fi n sin wipe: “Iwọ ni o yẹ Oluwa lati gba ogo, ati ọla, ati agbara: nitori Iwọ ni o da ohun gbogbo.” Ifihan 4:11.ANN 193.3

  Ni Ifihan 14, a pe awọn eniyan lati jọsin Ẹlẹda; asọtẹlẹ naa si ṣe afihan ẹgbẹ kan ti n pa ofin Ọlọrun mọ nitori iṣẹ iranṣẹ onipele mẹta naa. Ọkan ninu awọn ofin yii tọka taara si Ọlọrun gẹgẹ bi Ẹlẹda. Ilana kẹrin sọ wipe: “Ọjọ keje ni ọjọ Isinmi Oluwa Ọlọrun rẹ: . . . nitori ni ọjọ mẹfa ni Ọlọrun da ọrun ati aye, okun ati ohun gbogbo ti o wa ninu wọn, O si sinmi ni ọjọ keje: nitori naa Oluwa bukun ọjọ Isinmi, O si ya a si mimọ.” Eksodu 20:10, 11. Nipa ọjọ isinmi, Oluwa tẹsiwaju lati sọ wipe, o jẹ “ami, . . . ki ẹyin baa le mọ wipe Emi ni Oluwa Ọlọrun yin.” Isikiẹli 20:20. Idi rẹ si ni wipe: “Nitori ni ọjọ mẹfa ni Oluwa da ọrun ati aye, O sinmi ni ọjọ keje, O si tura.” Eksodu 31:17.ANN 193.4

  “Pataki ọjọ isinmi gẹgẹ bi iranti iṣẹ dida ni wipe ni gbogbo igba ni o n sọ fun wa idi tootọ ti ijọsin fi yẹ fun Ọlọrun”—nitori pe Oun ni Ẹlẹda, awa si ni ẹda Rẹ. “Nitori naa ọjọ isinmi jẹ ipilẹ fun ijọsin Ọlọrun, nitori ti o fi otitọ nla yii kọni ni ọna ti o lọwọ, ko si si agbekalẹ miran ti o ṣe eyi. Idi tootọ fun ijọsin Ọlọrun, ki i ṣe ni ọjọ keje lasan, ṣugbọn fun gbogbo ijọsin ni a ri ninu iyatọ ti o wa laarin Ẹlẹda ati ẹda Rẹ. Otitọ nla yii ko le parẹ laelae, a ko si gbọdọ gbagbe rẹ.” Ọlọrun fi Isinmi lelẹ ninu Edẹni lati le jẹ ki otitọ yii o le maa wa ninu ọkan gbogbo eniyan; niwọn igba ti bi O ti jẹ Ẹlẹda wa ba si jẹ idi fun wa lati sin In, bẹẹ naa ni ọjọ Isinmi yoo tẹsiwaju lati jẹ ami ati ohun iranti. Bi o ba ṣe wipe gbogbo aye ni o n pa ọjọ Isinmi mọ ni, ero ati ifẹ eniyan i ba lọ si ọdọ Ẹlẹda gẹgẹ bi Ẹni ti o yẹ fun ijọsin, bẹẹ si ni ki ba ti si abọriṣa, alaigbagbọ ninu iwalaaye Ọlọrun tabi alaigbagbọ. Pipa ọjọ isinmi mọ jẹ ami igbọran si Ọlọrun tootọ, “Ẹni ti O da ọrun ati aye ati okun ati awọn orisun omi.” O tọna wipe iṣẹ iranṣẹ ti o pa eniyan laṣẹ lati sin Ọlọrun, ti o tun sọ wipe ki wọn pa ofin Rẹ mọ yoo pe wọn lati pa ofin kẹrin mọ.ANN 193.5

  Ni iyatọ si awọn ti wọn pa ofin Ọlọrun mọ, ti wọn tun ni igbagbọ Jesu, angẹli kẹta tọka si ẹgbẹ miran, eyi ti a ṣe ikilọ ọlọwọ ti o si banilẹru fun aṣiṣe wọn: “Bi ẹnikẹni ba jọsin ẹranko naa ati aworan rẹ, ti o si gba ami rẹ siwaju ori rẹ, tabi si ọwọ rẹ, oun pẹlu yoo mu ninu waini ibinu Ọlọrun.” Ifihan 14:9, 10. Itumọ ti o tọna fun awọn ami ti a lo ṣe pataki lati le ni oye iṣẹ iranṣẹ yii. Kini a fi ẹranko, aworan ati ami ṣe apejuwe?ANN 194.1

  Abala asọtẹlẹ ti a ti lo awọn ami yii bẹrẹ pẹlu Ifihan 12, pẹlu dragoni ti o n wa lati pa Kristi nigba ti a bi. A sọ wipe Satani ni dragoni naa (Ifihan 12:9), oun ni o mi si Hẹrodu lati pa Olugbala. Ṣugbọn aṣoju nla fun Satani lati ba Kristi ati awọn eniyan Rẹ jagun ni ọrundun akọkọ ni akoko Kristẹni ni ijọba Romu, ninu eyi ti ẹsin ibọriṣa fi ẹsẹ mulẹ. Nitori naa, nigba ti dragoni naa kọkọ duro fun Satani, ni idakeji ẹwẹ, o duro fun ijọba Romu abọriṣa.ANN 194.2

  Ni ori kẹtala (ẹsẹ 1—10) a ṣe alaye ẹranko miran, “ti o dabi amọtẹkun,” eyi ti dragoni naa fun ni “agbara rẹ, ati ibujoko rẹ, ati aṣẹ nla.” Ami yii, bi ọpọ awọn Protestant ti ṣe gbagbọ, duro fun ijọ padi, eyi ti o gba agbara ati ibujoko ati aṣẹ ti ijọba Romu igbaani fi igba kan ni. A sọ nipa ẹranko ti o dabi amọtẹkun nì pe: “A fun ni ẹnu ti o n sọ awọn ohun nla ati ọrọ odi. . . . O si la ẹnu rẹ ni sisọ ọrọ odi si Ọlọrun, lati sọ ọrọ odi si orukọ Rẹ, ati agọ Rẹ, ati awọn ti n gbe ni ọrun. A si fifun lati ba awọn eniyan mimọ jagun, ati lati ṣẹgun wọn: a si fi agbara fun lori gbogbo ẹya ati ede ati orilẹ ede.” Asọtẹlẹ yii, eyi ti o fẹrẹ ba alaye iwo kekere ti Daniẹli 7 mu patapata, laijiyan tọka si ijọ padi.ANN 194.3

  “A fun ni agbara lati tẹsiwaju fun ogoji oṣu le meji.” Woli naa sọ pe, “Mo ri ọkan ninu awọn ori rẹ bi ẹnipe a ṣa a pa.” Ati pe, “Ẹni ti o ba koni ni igbekun yoo lọ si igbekun: ẹni ti o ba fi ida pani ni a yoo fi ida pa.” Ogoji oṣu le meji jẹ nnkankan naa pẹlu “akoko ati awọn akoko ati idaji akoko,” ọdun mẹta aabọ, tabi 1260 ọjọ ti Daniẹli 7—akoko ti agbara ijọ padi yoo ni awọn eniyan Ọlọrun lara. Akoko yii, bi a ti sọ ni awọn apa iṣaaju, bẹrẹ pẹlu iṣakoso ijọ padi ni 538, o si dopin ni 1798. Ni akoko naa awọn ẹgbẹgun France mu popu ni igbekun, agbara ijọ padi gba ọgbẹ aṣapa rẹ, a si mu asọtẹlẹ naa ṣẹ wipe, “Ẹni ti n muni ni igbekun yoo lọ si igbekun.”ANN 194.4

  Nibi a funni ni ami miran. Woli naa sọ pe: “Mo si wo o ẹranko miran jade wa lati inu ilẹ; o ni iwo meji bi ti ọdọ aguntan.” Ẹsẹ 11. Ifarahan ẹranko yii ati ọna ti o gba dide fihan wipe orilẹ ede ti o duro fun yatọ si awọn ti a fi ami tẹlẹ ṣe apejuwe. Awọn ijọba nla ti wọn ṣe akoso aye ni a ṣe afihan wọn fun Daniẹli gẹgẹ bi ẹranko ti n jẹ ẹran, ti wọn n dide nigba ti “afẹfẹ mẹrẹẹrin ọrun ba fẹ lori okun nla.” Daniẹli 7:2. Ninu Ifihan 17 angẹli kan ṣe alaye wipe omi duro fun “awọn eniyan, ati ọpọ eniyan, ati orilẹ ede, ati ede.” Ifihan 17:15. Afẹfẹ duro fun wahala. Afẹfẹ mẹrin ọrun ti n fẹ lori okun nla tumọ si iṣẹlẹ ti o banilẹru ti iṣẹgun ati idoju ijọba bolẹ nipasẹ eyi ti awọn ijọba fi de ipo agbara.ANN 194.5

  Ṣugbọn ẹranko ti o ni iwo bi ọdọ aguntan ni a ri “ti o n jade wa lati inu ilẹ.” Dipo bíbi agbara miran wó lati fi idi ara rẹ mulẹ, orilẹ ede ti a ṣe afihan rẹ bayii gbọdọ dide nibi ti eniyan ko gbe ri, ki o si dagba diẹdiẹ pẹlu alaafia. Nitori naa, ko le dide laarin awọn orilẹ ede Europe ti wọn n jijakadi laarin ara wọn—okun onirudurudu ti “awọn eniyan, ati ọpọ eniyan, ati orilẹ ede ati ede.” A nilati ri laarin awọn orilẹ ede ti wọn wa ni iha iwọ oorun.ANN 194.6

  Orilẹ ede wo, ni Ilẹ Tuntun, ni o n di alagbara ni 1798, ti o n ni irisi agbara ati titobi, ti o si n ri afiyesi araye? Itumọ ami naa ko nilo ibeere. Orilẹ ede kan ṣoṣo ni asọtẹlẹ yii ba mu; laiṣe aniani, o tọka si United States ti Amẹrika. Lati igba de igba ero, ti o fẹrẹ dọgba tan pẹlu ọrọ onkọwe mimọ ni awọn sọrọsọrọ ati opitan ti lo laimọ, ni ṣiṣe alaye bi orilẹ ede yii ti dide ati idagbasoke rẹ. A ri ẹranko naa “ti o n goke lati inu ilẹ;” gẹgẹ bi awọn olutumọ ti sọ ọ, ọrọ ti a pe ni “goke wa” nibi tumọ si “didagba soke tabi riru bi eweko.” Bi a si ti ri, orilẹ ede naa nilati dide nibi ti ero ko pọ si. Onkọwe gbajugbaja kan, nigba ti o n ṣe alaye bi United States ti dide sọ nipa “aṣiri jijade rẹ lati inu ofifo,” o tun sọ wipe: “Bi eso ni idakẹrọrọ, o dagba di ijọba nla.” Iwe ilewọ ti ilẹ Europe kan ni 1850 sọ nipa United States gẹgẹ bi ijọba nla ti o jẹ agbayanu, ti o n “dide” ati laarin idakẹjẹ aye lojoojumọ o n fi kun agbara ati igberaga rẹ.” Edward Everett, ninu ọrọ nipa awọn Arinrinajo ti wọn tẹ ilu yii do sọ wipe: “Ṣe wọn wa ibi ti o farasin, ti ko ni wahala latari ifarasin rẹ, ti o ni aabo nitori ti o jinna rere, nibi ti ijọ kekere ti Leyden ti le jẹ anfani ominira ẹri ọkan? Kiyesi agbegbe nla nibi ti, pẹlu iṣẹgun pẹlu alaafia, wọn ti gbe ọpagun agbelebu!”ANN 194.7

  “O si ni iwo meji bi ọdọ aguntan.” Iwo bi ọdọ aguntan ṣe fihan wiwa ni ọdọ, alailẹṣẹ, suuru, eyi ti o ṣe alaye ni rẹgi, iwa United States nigba ti a fihan woli naa nigba ti o n “goke wa” ni 1798. Laarin awọn Kristẹni ti a le kuro ni ilu ti wọn kọkọ sa wa si Amẹrika, ti wọn wa aabo kuro lọwọ ininilara ọba ati ainifarada awọn alufa ni ọpọlọpọ ti wọn pinu lati da ijọba silẹ lori ipilẹ nla ominira ti iṣelu ati ẹsin. Igbagbọ wọn wa ninu Ikede Ominira, eyi ti o ṣe alaye otitọ nla nì wipe, “gbogbo eniyan ni a da dọgba” ti a si fun wọn ni ẹtọ abínimọ si “iwalaaye, ominira ati wiwa idunnu.” Iwe ofin si gba awọn eniyan laaye si ẹtọ lati ṣe ijọba ara wọn, pẹlu wipe awọn aṣoju ti a yan sipo pẹlu ìbò ti o pọ julọ ni yoo ṣe ofin. A tun fun awọn eniyan ni ominira ti igbagbọ, a gba gbogbo eniyan laaye lati sin Ọlọrun gẹgẹ bi ẹri ọkan wọn ti sọ fun wọn. Aṣa ailọba ati ẹsin Protestant jẹ ipilẹ fun orilẹ ede naa. Awọn ipilẹ wọnyi si ni aṣiri agbara ati ibukun rẹ. Awọn ti a nilara ati awọn ti a jẹniya ni gbogbo ilẹ ti n ṣe ẹsin Kristẹni ni wọn yiju si ilẹ yii pẹlu ifẹ ọkan ati ireti. Ẹgbẹẹgbẹrun ni wọn wa si bèbè rẹ ti United States si goke de ibi ti o ni apẹẹrẹ laarin awọn orilẹ ede alagbara aye.ANN 195.1

  Ṣugbọn ẹranko ti o ni iwo bi ọdọ aguntan naa “sọrọ bi dragoni. O si lo gbogbo agbara ẹranko iṣaaju niwaju rẹ, o si mu ki aye ati awọn ti n gbe inu rẹ o jọsin ẹranko iṣaaju, eyi ti a ti wo ọgbẹ aṣapa rẹ san; . . . o n sọ fun awọn ti n gbe ori ilẹ aye wipe ki wọn o yá aworan fun ẹranko naa, ti o ni ọgbẹ ida ti o si yè.” Ifihan 13:11—14.ANN 195.2

  Iwo ti o dabi ti aguntan ati ohùn dragoni apejuwe naa tọka si iyatọ lọna ti o han kedere laarin ohun ti o sọ wipe oun jẹ ati iwuwasi orilẹ ede ti a ṣe afihan rẹ. “Iṣọwọsọrọ” awọn orilẹ ede ni iṣesi ile aṣofin ati aṣẹ eto idajọ rẹ. Nipa iwuwasi rẹ, ki yoo tẹle awọn agbekalẹ alaafia ati ominira ti o pe ni ipilẹ iṣofin rẹ. Asọtẹlẹ ti o wipe yoo sọrọ “bi dragoni” yoo si lo “gbogbo agbara ẹranko iṣaaju” sọtẹlẹ ni kedere idagbasoke ẹmi ainifarada ati inunibini ti awọn orilẹ ede ti a ṣe afihan wọn pẹlu dragoni ati ẹranko bi amọtẹkun naa fihan. Gbolohun wipe ẹranko naa ti o ni iwo meji “mu ki aye ati awọn ti n gbe inu rẹ o jọsin ẹranko iṣaaju” fihan wipe a yoo lo aṣẹ orilẹ ede yii lati ṣe awọn ofin kan ti yoo jẹ igbọran si ofin ijọ padi.ANN 195.3

  Iru iwa bayi yoo jẹ atako taara si ẹkọ ipilẹ ijọba yii, si ọgbọn awọn agbekalẹ olominira rẹ, si ẹjẹ ọlọwọ ti Ikede Ominira ati si iwe ofin iṣejọba. Awọn ti wọn tẹ orilẹ ede yii do fi ọgbọn wa ona lati maṣe lo agbara ijọba nitori ijọ, pẹlu abayọri rẹ ti a ko le fe ku—ainifarada ati inunibini. Iwe ofin iṣejọba sọ wipe: “Ile igbimọ aṣofin ko gbọdọ ṣe ofin nipa idasilẹ ẹsin, bẹẹ ni ko gbọdọ dí ẹnikẹni lọwọ nipa rẹ,” ati pe “a ko gbọdọ dan ẹnikẹni wo lori ẹsin ki o to le kun oju oṣuwọn fun ipo ilu ni United States.” Ayafi ni afojudi si awọn ohun aabo fun ominira orilẹ ede yii ni a fi le lo aṣẹ ilu lati mu ki ẹnikẹni o ṣe ojuṣe ẹsin kankan. Ṣugbọn aidọgba iru iwa yii ba apẹẹrẹ ti a fi ṣe alaye naa mu. Ẹranko ti o ni iwo bi ọdọ aguntan—ni ọrọ, o mọ, o ni suuru, ko le ṣeni ni jamba—ni o n sọrọ bi dragoni.ANN 195.4

  “O n sọ fun awọn ti n gbe ilẹ aye, pe ki wọn yá aworan fun ẹranko naa.” Nibi a ṣe afihan iṣọwọṣejọba eyi ti agbara ati iṣofin wa ni ọdọ awọn eniyan, ẹri ti o han daju wipe United States ni orilẹ ede ti asọtẹlẹ n sọ. Ṣugbọn kini “aworan ẹranko naa”? bawo si ni a yoo ṣe ṣe? Ẹranko oniwo meji ni o ya aworan naa, o si jẹ aworan si ẹranko naa. A tun pe e ni aworan ti ẹranko naa. Nitori naa lati mọ ohun ti aworan naa jẹ ati bi a yoo ti ṣe e, a nilati kọ nipa iwuwasi ẹranko naa funra rẹ—ijọ padi.ANN 195.5

  Nigba ti ijọ iṣaaju bajẹ nipa yiya kuro ninu otitọ iyinrere, ti o si gba awọn aṣa ati iṣesi ibọriṣa, o padanu Ẹmi ati agbara Ọlọrun; lati le dari ẹri ọkan awọn eniyan, o wa atilẹyin agbara aye. Ayọrisi rẹ ni ijọ padi, ijọ ti o n dari agbara ilu ti o si n lo o fun anfani ara rẹ, ni paapa julọ lati jẹ “ẹlẹkọ odi” niya. Ki United States to le yá aworan fun ẹranko naa, agbara ẹsin nilati ṣe akoso ijọba ilu debi pe ijọ yoo lo aṣe ilu pẹlu lati mu erongba ara rẹ ṣẹ.ANN 196.1

  Nibikibi ti ijọ ba ti gba agbara iṣelu, o maa n lo o lati jẹ awọn ti ko gba ohun kan naa gbọ pẹlu rẹ niya. Awọn ijọ Protestant ti wọn tẹle apẹẹrẹ Romu nipa fifọwọsọwọpọ pẹlu agbara aye ti fi iru ifẹ bakan naa han—lati maṣe faaye gba ominira ẹri ọkan. A ṣe apẹẹrẹ eyi ninu inunibini ọlọjọ gbọọrọ ti ijọ England ṣe si awọn ti wọn ko gba ohun kan naa gbọ pẹlu rẹ. Ni akoko ọrundun kẹrindinlogun ati ikẹtadinlogun, ọpọ awọn alufa ti wọn ko tẹriba fun ilana ijọ ni wọn sa kuro ninu ijọ wọn, ti ọpọlọpọ, ati alufa ati awọn eniyan san owo itanran, wọn lọ sinu ọgba ẹwọn, a jẹ wọn niya, a si pa awọn miran.ANN 196.2

  Iyapa ni o mu ki ijọ iṣaaju o wa iranlọwọ ijọba aye, eyi si pese ọna silẹ fun idagbasoke ijọ padi—ẹranko naa. Pọlu sọ wipe “Iyapa yoo wa, . . . a yoo si fi ọkunrin ẹṣẹ naa han.” 2 Tẹsalonika 2:3. Nitori naa iyipada ninu ijọ yoo pese ọna silẹ fun aworan ẹranko naa.ANN 196.3

  Bibeli kede wipe ki Oluwa o to wa, ifasẹyin ni ipo ẹsin yoo wa, eyi ti yoo dabi ti ọrundun akọkọ. “Ni igba ikẹyin akoko ewu yoo wa. Nitori ti awọn eniyan yoo jẹ olufẹ ara wọn, olojukokoro, afunnu, agberaga, asọrọ odi, aṣaigbọran si obi, alailọpe, alaimọ, alainifẹ, alailedarijini, abatẹnijẹ, alailekoraẹninijanu, onroro, alainifẹ ohun rere, onikupani, alagidi, ọlọkan giga, olufẹ faaji ju olufẹ Ọlọrun lọ; awọn ti wọn ni afarawe iwabiọlọrun, ṣugbọn ti wọn sẹ agbara rẹ.” 2 Timoti 3:1—5. “Ṣugbọn Ẹmi n tẹnumọ wipe, ni igba ikẹyin awọn miran yoo kuro ninu igbagbọ, wọn yoo si maa tẹle ẹmi ti n tanni jẹ ati ẹkọ awọn ẹmi eṣu.” 2 Timoti 4:1. Satani yoo ṣiṣẹ “pẹlu gbogbo agbara ati ami ati iṣẹ iyanu eke, pẹlu gbogbo itannijẹ ninu aiṣododo.” Ati gbogbo awọn “ti ko gba ifẹ fun otitọ, ki a baa le gba wọn là” a yoo fi wọn silẹ lati gba “itanjẹ nla, ki wọn baa le gba èké gbọ.” 2 Tẹsalonika 2:9—11. Nigba ti a ba de ipo aiwabiọlọrun yii, abayọri kan naa ni yoo tẹle, gẹgẹ bii ti ọrundun akọkọ.ANN 196.4

  Iyatọ ti o wa ninu igbagbọ awọn ijọ Protestant ni awọn miran ro wipe o jẹ idi fun wọn lati gbagbọ wipe ko si ohun kan ti o le pa wọn pọ ṣọkan. Ṣugbọn fun ọpọ ọdun, ninu awọn ijọ Protestant, ifẹ ti o lagbara ti o si n dagba si ti wà ti o fẹ ibaṣepọ lori awọn ohun ikọni ti wọn jumọ gbagbọ papọ. Lati le ni ibaṣepọ yii, a ki yoo mẹnuba awọn koko ọrọ ti gbogbo wọn ko fẹnu ṣọkan le lori—bi o ti wu ki o ṣe pataki ninu Bibeli to.ANN 196.5

  Charles Beecher, sọ ninu iwaasu kan ni 1846 wipe iṣẹ iranṣẹ “awọn ijọ Protestant oniwaasu” ki i ṣe “wipe a da silẹ latari ibẹru eniyan nikan, ṣugbọn wọn n gbe, wọn n rin, wọn si n mí ninu ipo ti o kun fun iwa ibajẹ ti o si n mi si ẹran ara wọn nigba gbogbo lati pa otitọ lẹnu mọ, lati tẹ eekun wọn ba fun agbara ifasẹyin. Ṣe kii ṣe bi nnkan ti ri pẹlu Romu niyi? Ṣe kii ṣe wipe a n tun igbesi aye rẹ gbe bi? Ki ni a wa n wo niwaju wa? Ipade gbogboogbo miran! Apero agbaye! Ibaṣepọ awọn ijọ oniwaasu, ati ọrọ igbagbọ gbogboogbo!” Nigba ti a ba n ṣe eyi lati le ni ifọwọsowọpọ, wọn yoo fi ipa mu ni.ANN 196.6

  Nigba ti awọn ijọ ti wọn gbajugbaja ni United States ba wa ni iṣọkan lori awọn koko ẹkọ ti wọn fi ohùn ṣọkan le lori, wọn yoo mu ki ijọba ilu o mu ofin wọn ṣẹ lati mu agbekalẹ wọn duro, nigba naa ni Protestant Amẹrika yoo di aworan ijọ Romu, o daju wipe ifiyajẹ awọn ti ko ba tẹle wọn ni yoo tẹle.ANN 196.7

  Ẹranko naa pẹlu iwo meji “jẹ ki [paṣẹ ki] gbogbo eniyan, ati kekere ati nla, ọlọrọ ati talaka, ominira ati onde, lati gba ami kan ni ọwọ ọtun wọn, tabi niwaju ori wọn: ki ẹnikẹni ma baa le rà tabi tà, ayafi awọn ti wọn ba ni ami naa, tabi orukọ ẹranko naa, tabi iye orukọ rẹ.” Ifihan 13:16, 17. Ikilọ angẹli kẹta ni wipe: “Bi ẹnikẹni ba jọsin ẹranko naa ati aworan rẹ, ti o si gba ami rẹ siwaju ori rẹ, tabi si ọwọ rẹ, oun naa ni yoo mu ninu ọti waini irunu Ọlọrun.” “Ẹranko naa” ti a mẹnuba ninu iṣẹ iranṣẹ yii, ti ẹranko oniwomeji fi ipa muni jọsin rẹ, ni ẹranko akọkọ, tabi ẹranko ti o dabi amọtẹkun ti Ifihan 13—ijọ padi. “Aworan ẹranko naa” duro fun ijọ Protestant ti o ti fà sẹyin ti yoo fi ara han nigba ti ijọ Protestant ba wá iranlọwọ agbara ijọba lati mu ẹkọ rẹ ṣẹ. A koi tii sọ nipa “ami ẹranko naa.”ANN 197.1

  Lẹyin ikilọ lati maṣe jọsin ẹranko naa ati aworan rẹ asọtẹlẹ sọ wipe: “Awọn wọnyi ni wọn pa ofin Ọlọrun mọ ati igbagbọ Jesu.” Niwọn igba ti a ṣe afiwe awọn ti wọn pa ofin Ọlọrun mọ ni atako si awọn ti wọn jọsin ẹranko naa ati aworan rẹ ti wọn si gba ami rẹ, o nitumọ bi a ba sọ wipe pipa ofin Ọlọrun mọ ní ọna kan, ati riru ofin Ọlọrun ni ọna miran ni yoo jẹ iyatọ laarin awọn olujọsin Ọlọrun ati awọn olujọsin ẹranko naa.ANN 197.2

  Iwa ẹranko naa ti o ṣe pataki, ati nitori naa ti aworan rẹ ni titẹ ofin Ọlọrun loju. Daniẹli sọ nipa iwo kekere naa, ijọ padi wipe: “Yoo rò lati yi awọn akoko ati ofin pada.” Daniẹli 7:25. Pọlu pe agbara kan naa ni “ẹni ẹṣẹ” ti yoo gbe ara rẹ ga ju Ọlọrun lọ. Asọtẹlẹ kan ran omiran lọwọ ni. Nipa yiyi ofin Ọlọrun pada nikan ni ijọ padi fi le gbe ara rẹ ga ju Ọlọrun lọ; ẹnikẹni ti o ba si mọọmọ pa ofin naa mọ gẹgẹ bi a ti ṣe yi pada yii yoo ma fi ọwọ ti o ga julọ fún agbara naa ti o yi pada. Iru igbọran yii si ofin ijọ padi yoo jẹ ami igbọran si popu dipo Ọlọrun.ANN 197.3

  Ijọ padi ti rò lati yi ofin Ọlọrun pada. Ofin keji ti ko faaye gba ijọsin ère ni a mu kuro ninu ofin ti a si yi ofin kẹrin pada ni ọna ti yoo gba fi aṣẹ fun pipa ọjọ kini mọ dipo ọjọ keje gẹgẹ bi ọjọ isinmi. Ṣugbọn awọn atẹle popu sọ wipe idi ti wọn fi yọ ofin keji silẹ ni wipe ko si idi fun, nitori pe o wa ninu ofin akọkọ, ati wipe wọn n funni ni ofin naa bi Ọlọrun ti ṣe fẹ ki o yeni ni. Eyi ko le jẹ iyipada ti woli naa sọtẹlẹ. A ṣe alaye iyipada ti a mọọmọ ṣe pẹlu igboya: “Yoo si rò lati yi awọn akoko ati ofin pada.” Iyipada ninu ofin kẹrin ni o mu asọtẹlẹ yii ṣẹ pẹkipẹki. Nitori eyi nikan ni ijọ sọ wipe nipasẹ aṣẹ oun ni o fi ṣẹlẹ. Nibi aṣẹ ijọ paadi mọọmọ gbe ara rẹ ga ju Ọlọrun lọ.ANN 197.4

  Nigba ti a yoo da awọn olujọsin Ọlọrun mọ ni ọna pataki nipa bi wọn ti bọwọ fun ofin kẹrin,—nitori eyi ni ami agbara rẹ lati da ati ẹri fun ẹtọ Rẹ si ọwọ ati ijọsin eniyan,— a yoo da awọn olujọsin ẹranko naa mọ pẹlu akitiyan wọn lati bi ohun iranti Ẹlẹda wo lulẹ, lati le gbé aṣẹ Romu ga. Romu kọkọ ṣe ifọnnu rẹ nipa Sọnde ni igba ti o kọkọ lo agbara iṣelu, o lo o lati fi fi ipa muni lati pa ọjọ Sọnde mọ gẹgẹ bi “ọjọ Oluwa.” Ṣugbọn Bibeli tọka si ọjọ keje ọsẹ, kii si i ṣe ọjọ kini gẹgẹ bi ọjọ Oluwa. Kristi sọ wipe: “Ọmọ eniyan pẹlu ni Oluwa ọjọ Isinmi.” Ofin kẹrin sọ wipe: “Ọjọ keje ni ọjọ Isinmi Oluwa.” Nipasẹ woli Aisaya, Oluwa pe e ni: “Ọjọ mimọ Mi.” Maku 2:28; Aisaya 58:13.ANN 197.5

  Ọrọ ti a saba maa n sọ wipe Kristi ti yi ọjọ Isinmi pada ni ko le duro latari ọrọ ara Rẹ. Ninu iwaasu Rẹ lori oke, o sọ pe: “Maṣe ro wipe mo wa lati pa ofin ati awọn woli run: Emi ko wa lati parun, bikoṣe lati mu ṣe. Nitori lootọ ni mo wi fun yin, Titi ti ọrun ati aye yoo fi kọja lọ, kinkinni ninu ofin ki yoo kọja lọ laiṣẹ. Nitori naa ẹnikẹni ti o ba ru eyi ti o kere julọ ninu awọn ofin wọnyi, ti o si n kọni bẹẹ, oun ni a o pe ni kinkinni ni ijọba ọrun: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba ṣe wọn, ti o si fi kọni, oun ni a o pe ni titobi ni ijọba Ọlọrun.” Matiu 5:17—19.ANN 197.6

  Awọn Protestant gba wipe Iwe Mimọ ko funni ni aṣẹ lati yi ọjọ isinmi pada. A sọ eyi kedere ninu atẹjade ti American Tract Society and the American Sunday School Union tẹ jade. Ọkan ninu awọn iṣẹ yii gba wipe “Majẹmu Tuntun dakẹ patapata nipa aṣẹ ti o han kedere nipa ọjọ isinmi [Sunday, ọjọ kini ọsẹ] tabi aṣẹ kan pato lati paamọ.ANN 197.7

  Omiran sọ wipe: “Titi di akoko iku Kristi, ko si iyipada kan ti a se lori ọjọ naa;” ati pe, “bi akọsilẹ ti fihan, wọn [awọn apostoli] ko . . . funni ni aṣẹ kan lati pa ọjọ keje tì, lati le pa ọjọ kini ọsẹ mọ.”ANN 198.1

  Awọn Roman Katoliki gba wipe ijọ wọn ni o ṣe ayipada ọjọ Isinmi, wọn si sọ wipe nipa pipa ọjọ Sọnde mọ, awọn Protestant n bọwọ fun agbara wọn. Ninu Catholic Catechism of Christian Religion, ni idahun si ibeere nipa ọjọ ti o yẹ ki a pa mọ ni igbọran si ofin kẹrin, a sọ gbolohun yii: “Ni akoko ofin atijọ, a ya Satide si mimọ; ṣugbọn ijọ ti o n gba ikọni Kristi, ti Ẹmi Ọlọrun si n dari fi ọjọ Sọnde rọpo Satide niori naa bayii, a ko ya ọjọ keje si mimọ bikoṣe ọjọ kini. Nisinsinyii, Sọnde tumọ si, bayi, oun si ni ọjọ Oluwa.”ANN 198.2

  Gẹgẹ bi ami aṣẹ ijọ Katoliki, awọn onkọwe ijọ padi sọ wipe, “yiyi ọjọ Isinmi pada si Sọnde, eyi ti awọn Protestant fi ọwọ si; . . . nitori pe nipa pipa Sọnde mọ, wọn gba agbara ijọ lati paṣẹ ọjọ ayẹyẹ ati lati sọ wipe wọn wa labẹ ẹṣẹ.” Ki wa ni yiyi ọjọ Isinmi pada, bi ko ba n ṣe ami, tabi ohun idanimọ fun aṣẹ ijọ Romu—”ami ẹranko naa”?ANN 198.3

  Ijọ Romu koi tii ṣiwọ pipe ara rẹ ni ọga; nigba ti araye ati awọn ijọ Protestant ba gba ọjọ isinmi rẹ, ti wọn si kọ ọjọ Isinmi ti Bibeli silẹ, wọn fi ọwọ si ifọnu rẹ yii. Wọn le maa lo aṣẹ aṣa tabi awọn Baba ijọ ti wọn fi yi pada; ṣugbọn ni ṣiṣe eyi wọn n kọ ipilẹ ẹkọ gan an ti o pin wọn niya pẹlu Romu silẹ—wipe “Bibeli, ani Bibeli nikan ṣoṣo, ni ẹsin awọn Protestant.” Awọn atẹle popu ri wipe wọn n tan ara wọn jẹ, wọn mọọmọ n diju wọn si otitọ ti o wa ninu ọrọ naa. Bi a ba ti n fi oju rere wo awọn ẹgbẹ ti wọn n fẹ ki a pa ọjọ Sọnde mọ si, inu rẹ a dun, ọkan rẹ a balẹ wipe, laiṣe aniani, gbogbo ijọ Protestant yoo wa si abẹ asia Romu.ANN 198.4

  Awọn ara Romu sọ wipe “bi awọn Protestant ti n pa Sọnde mọ jẹ igbọran ti wọn n se laika ọrọ wọn si, si aṣẹ ijọ [Katoliki]. Fifi ipa muni lati pa ọjọ Sọnde mọ ti awọn Protestant ṣe jẹ fifi ipa muni ṣe ijọsin ijọ padi—ẹranko naa. Awọn ti wọn ni oye aṣẹ ofin kẹrin ṣugbọn ti wọn yàn lati pa ọjọ isinmi eke mọ dipo ọjọ Isinmi tootọ n ṣe ijọsin agbara ti o pa a laṣẹ. Ṣugbọn nipa fifi ipa muni ṣe ojuṣe ẹsin nipasẹ agbara ijọba aye, awọn ijọ sọ ara wọn di aworan ẹranko naa; nitori naa fifi ipa muni pa ọjọ Sọnde mọ ní United States yoo jẹ fifi ipa muni jọsin ẹranko naa ati aworan rẹ.ANN 198.5

  Ṣugbọn awọn Kristẹni lati atẹyinwa pa ọjọ Sọnde mọ, wọn si ro wipe wọn n pa ọjọ Isinmi ti Bibeli mọ ni ṣiṣe eyi; ọpọlọpọ Kristẹni tootọ ṣi wà ninu gbogbo ijọ, laiyọ Roman Katoliki silẹ, ti wọn fi tọkantọkan gbagbọ wipe Sọnde ni ọjọ Isinmi ti Ọlọrun yan. Ọlọrun gba iṣotitọ erongba ati iduroṣinṣin wọn niwaju Rẹ. Ṣugbọn nigba ti a ba fi ofin muni pa ọjọ Sọnde mọ, ti araye si ti ni oye nipa ojuṣe ti ọjọ Isinmi tootọ, nigba naa, ẹnikẹni ti o ba ru ofin Ọlọrun, lati ṣe igbọran si ilana ti o wá lati ọdọ aṣẹ ti ko ju ti Romu lọ, yoo bọwọ fun aṣa popu ju ti Ọlọrun lọ. O n jọsin Romu ati agbara ti o n fi ipa muni ṣe igbọran si agbekalẹ Romu. O n jọsin ẹranko naa ati aworan rẹ. Nigba naa, bi awọn eniyan ti n kọ agbekalẹ ti Ọlọrun kede wipe o jẹ ami aṣẹ Rẹ silẹ, ti wọn si n bọwọ fun eyi ti Romu yan gẹgẹ bi ami agbara rẹ rọpo, nipa eyi wọn a gba ami igbọran si Romu—”ami ẹranko naa.” O ṣi di igba ti a ba gbe ọrọ naa ka iwaju awọn eniyan, ti o di dandan fun wọn lati yan laarin ofin Ọlọrun ati ofin eniyan, ki awọn ti wọn tẹsiwaju ninu aigbọran o to gba “ami ẹranko naa.”ANN 198.6

  Ikilọ ti o banilẹru julọ ti a ṣe fun eniyan wà ninu iṣẹ iranṣẹ angẹli kẹta. Ẹṣẹ ti yoo fa ibinu Ọlọrun laini aanu nilati jẹ ẹṣẹ ti o lagbara. A ko fi awọn eniyan sinu okunkun nipa ọrọ pataki yii; a nilati ṣe ikilọ nipa ẹṣẹ yii fun araye ki idajọ Ọlọrun to bẹ wọn wo, ki gbogbo wọn le mọ idi ti a fi n jẹ wọn niya, ki wọn si ni anfani lati sá àsálà. Asọtẹlẹ sọ wipe angẹli akọkọ yoo ṣe ikede rẹ si “gbogbo orilẹ ede, ati ẹya ati ede ati eniyan.” Ikilọ angẹli kẹta, eyi ti i ṣe ara iṣẹ iranṣẹ onipele mẹta naa yoo lọ kaakiri bẹẹ gẹgẹ. A ṣe afihan rẹ ninu asọtẹlẹ wipe angẹli ti o n fo ni agbede meji ọrun kede rẹ pẹlu ohùn ariwo; gbogbo aye ni yoo fiyesi.ANN 198.7

  Ninu koko ijakadi naa, gbogbo ẹlẹsin Kristẹni ni yoo pin si meji—awọn ti wọn n pa aṣẹ Ọlọrun mọ ati igbagbọ Jesu, ati awọn ti wọn n jọsin ẹranko naa ati aworan rẹ ti wọn si gba ami rẹ. Bi o tilẹ jẹ wipe ijọ ati ijọba yoo pa agbara wọn pọ lati fi ipa mu “gbogbo eniyan, ati kekere ati nla, ati ọlọrọ ati otoṣi, ati ominira ati onde” (Ifihan 13:16), lati gba “ami ẹranko naa,” sibẹ awọn eniyan Ọlọrun ki yoo gba a. Woli ti Patmosi ri “awọn ti wọn ni iṣẹgun lori ẹranko naa, ati lori aworan rẹ, ati lori ami rẹ, ati lori iye oruko rẹ, wọn duro lori okun digi, pẹlu duru Ọlọrun” wọn si n kọ orin Mose ati ti Ọdọ Aguntan. Ifihan 15:2, 3.ANN 199.1

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents