Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  ORI KEJIDINLỌGBỌN—DIDOJUKỌ AKỌSILẸ NIPA IGBESI AYE

  Woli Daniẹli sọ wipe, “Mo wo o titi ti a fi sọ awọn itẹ kalẹ, ti Ẹnikan ti i ṣe Arugbo Ọjọ si joko: aṣọ Rẹ funfun bi yinyin, irun ori Rẹ si dabi ẹgbọn owu ti o mọ; itẹ Rẹ jẹ ọwọ ina, ayika kẹkẹ Rẹ si jẹ jijo ina. Ọwọ ina n ṣẹyọ o si n tujade lati iwaju Rẹ wa: awọn ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrun si n ṣe iranṣẹ fun, ati awọn ẹgbẹẹgbarun lọna ẹgbẹẹgbarun duro niwaju Rẹ: awọn onidajọ joko, a si ṣi awọn iwe silẹ.” Daniẹli 7:9, 10.ANN 213.1

  Bayi ni a ṣe fi ọjọ nla ẹlẹru han woli naa nigba ti a o ṣe ayẹwo iwa ati igbesi aye awọn eniyan niwaju Onidajọ gbogbo aye, ti a o si fifun olukuluku “gẹgẹ bi iṣẹ rẹ.” Arugbo Ọjọ nì ni Ọlọrun Baba. OniO. Dafidi sọ wipe: “Ki awọn oke to jade wa, tabi ki iwọ tilẹ to da ilẹ ati aye, ani lati ayeraye, Iwọ ni Ọlọrun.” O. Dafidi 90:2. Oun ti i ṣe orisun gbogbo ẹda, ati orisun gbogbo ofin, ni yoo joko lati ṣe idajọ. Ati awọn angẹli mimọ gẹgẹ bi iranṣẹ ati ẹlẹri ní iye wọn to “ẹgbaarun lọna ẹgbaarun ati ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrun,” peju si ibi igbẹjọ nla yii.ANN 213.2

  “Si kiyesi, ẹnikan ti O dabi Ọmọ eniyan wa pẹlu ikuuku awọsanma, O si wa sọdọ Arugbo Ọjọ, wọn si mu U wa si ẹba Rẹ. A si fun ni agbara ijọba ati ogo ati ijọba, ki gbogbo eniyan, ati orilẹ ede, ati ede le sin in: agbara ijọba Rẹ jẹ ijọba ayeraye, ti ki yoo lopin.” Daniẹli 7:13, 14. Wiwa Kristi ti a ṣe alaye nibi ki i ṣe wiwa Rẹ sinu aye. O wa si ọdọ Arugbo Ọjọ ni ọrun lati gba agbara ijọba ati ogo ati ijọba, ti a yoo fun ni opin iṣẹ Rẹ gẹgẹ bi Olubalaja. Wiwa yii ki i ṣe wiwa Rẹ lẹẹkeji sinu aye, bikoṣe eyi ti a ṣe asọtẹlẹ rẹ ninu isọtẹlẹ lati ṣẹlẹ ni opin 2300 ọjọ ni 1844. Pẹlu awọn angẹli ọrun, Olu Alufa nla wa wọ inu ibi mimọ julọ nibẹ ni ti o fi ara han niwaju Ọlọrun lati ṣe iṣẹ iranṣẹ Rẹ ti o kẹyin fun eniyan—lati ṣe iṣẹ idajọ iyẹwewo fun gbogbo awọn ti wọn ba yẹ fun anfani rẹ.ANN 213.3

  Ninu isin ti aye awọn ti wọn ba wa siwaju Ọlọrun pẹlu ironupiwada ati iyipada ọkan, awọn ti a ti ko ẹṣẹ wọn lọ si ibi mimọ nipasẹ ẹjẹ ẹbọ ẹṣẹ nikan ni wọn nipa ninu isin Ọjọ Iwẹnumọ. Bẹẹ gẹgẹ ni ọjọ iwẹnumọ nla ti o kẹyin ati idajọ iyẹwewo awọn ẹjọ ti a o yẹwo nikan ni ti awọn ti wọn jẹ eniyan Ọlọrun. Idajọ awọn awọn eniyan buburu jẹ eyi ti o yatọ patapata, yoo si waye nikẹyin. “Idajọ nilati bẹrẹ ninu ile Ọlọrun: ti o ba kọkọ bẹrẹ pẹlu wa, ki ni yoo jẹ opin awọn ti ko gba iyinrere gbọ? 1 Peteru 4:17.ANN 213.4

  Awọn iwe akọsilẹ ni ọrun, nibi ti a kọ orukọ ati iṣe awọn eniyan si, ni yoo sọ iru ipinu idajọ. Woli Daniẹli sọ wipe: “Onidajọ joko, a si ṣi awọn iwe silẹ.” Onifihan nigba ti o n ṣe alaye iṣẹlẹ kan naa fikun pe: “A si ṣi iwe miran silẹ, eyi ti i ṣe iwe iye: a si ṣe idajọ awọn oku lati inu awọn ohun ti a kọ sinu awọn iwe wọnni, gẹgẹ bi iṣe wọn.” Ifihan 20:12.ANN 213.5

  Orukọ gbogbo ẹni ti o ba ti ṣe iṣẹ Ọlọrun ri ni o wa ninu iwe iye. Jesu sọ fun awọn ọmọ ẹyin Rẹ pe: “Ẹ yọ nitori ti a kọ orukọ yin silẹ ni ọrun.” Luku 10:20. Pọlu sọ nipa awọn oṣiṣẹ olootọ, “ti orukọ wọn wa ninu iwe iye.” Filipi 4:3. Daniẹli, nigba ti o woye de, “akoko idamu, ti koi ti i si ri,” sọ wipe a yoo gba awọn eniyan Ọlọrun là, “gbogbo ẹni ti a ba ri orukọ rẹ ninu iwe naa.” Onifihan si sọ fun wa pe kikida awọn ti yoo wọ inu ilu Ọlọrun ni awọn ti “a kọ orukọ wọn sinu iwe iye Ọdọ Aguntan.” Daniẹli 12:1; Ifihan 21:27.ANN 213.6

  A kọ “iwe iranti” niwaju Ọlọrun, nibi ti a kọ iṣẹ rere “awọn ti wọn bẹru Oluwa, ati awọn ti wọn ronu lori orukọ Rẹ” si. Malaki 3:16. Ọrọ igbagbọ wọn, iṣẹ ifẹ wọn, ni a kọ silẹ ni ọrun. Nehemaya sọ nipa eyi nigba ti o sọ pe: “Ranti mi Ọlọrun mi, . . . ki o ma si ṣe pa iṣẹ rere ti mo ti ṣe fun ile Ọlọrun mi rẹ.” Nehemaya 13:14. Ninu iwe iranti Ọlọrun gbogbo iṣẹ rere ni a kọ silẹ fun iranti titi lae. Gbogbo idanwo ti a kọju ija si, gbogbo iwa ẹṣẹ ti a bori, gbogbo ọrọ pẹlẹ ti a sọ, ni a kọ silẹ patapata. Gbogbo iṣẹ irubọ, gbogbo ijiya ati ibanujẹ ti a farada nitori Kristi, ni a kọ silẹ. OniO. Dafidi sọ wipe: “Iwọ ka irin kiri mi: fi omije mi sinu igo Rẹ: wọn ko ha si ninu iwe Rẹ bi?” O. Dafidi 56:8ANN 213.7

  Akọsilẹ ẹṣẹ awọn eniyan tun wa pẹlu. “Nitori ti Ọlọrun yoo mu iṣẹ gbogbo wa si idajọ, pẹlu gbogbo ohun ikọkọ, boya didara ni tabi buburu.” “Gbogbo ọrọ asan ti eniyan ba sọ ni yoo jiyin rẹ ni ọjọ idajọ.” Olugbala sọ pe: “Nipa ọrọ rẹ ni a o fi da ọ lare, nipa ọrọ rẹ pẹlu ni a o fi da o lẹbi.” Oniwaasu 12:4; Matiu 12:36, 37. Ète ati erongba ikọkọ wa ninu akọsilẹ ti ko le yẹ; nitori ti Ọlọrun “yoo mu gbogbo ohun ikọkọ ti okunkun wa sinu imọlẹ, yoo si fi gbogbo ero ọkan han sita.” 1 Kọrintin 4:5. “Kiyesi, a ti kọ ọ silẹ niwaju Mi, . . . awọn aiṣedeede rẹ ati aiṣedeede awọn baba rẹ papọ ni Oluwa wi.” Aisaya 65:6, 7.ANN 214.1

  Gbogbo iṣẹ eniyan ni o n lọ niwaju Ọlọrun a si n kọ ọ silẹ boya si iṣotitọ tabi aiṣotitọ. Niwaju orukọ kọọkan ninu iwe ọrun ni a kọ ọ si ni bi o ti ri gan an gbogbo ọrọ aitọ, gbogbo iwa imọ-ti-ara-ẹni-nikan, gbogbo iṣẹ ti a ko pari, gbogbo ẹṣẹ ikọkọ, pẹlu gbogbo agabagebe. Gbogbo ikilọ tabi ibawi ọrun ti a kọ silẹ, akoko ti a fi ṣofo, anfani ti a ko lo, ipa wa sí rere tabi si buburu, pẹlu atubọtan rẹ ti o lọ jinna réré, gbogbo wọn ni angẹli ti n kọwe silẹ n kọ silẹ. Ọlọgbọn ni sọ wipe: “Bẹru Ọlọrun ki ẹ si pa ofin Rẹ mọ: nitori eyi ni gbogbo ojuṣe eniyan. Nitori ti Ọlọrun yoo mu gbogbo iṣe wa si idajọ.” Oniwaasu 12:13, 14. Apostoli Jakọbu gba awọn arakunrin rẹ niyanju wipe: “Ẹ sọrọ bẹẹ ki ẹ si wuwa bẹẹ, bi ẹni ti a o fi ofin ominira da ni ẹjọ.” Jakọbu 2:12.ANN 214.2

  Awọn ti a ba “ka yẹ” ni idajọ yoo nipa ninu ajinde awọn olododo. Jesu sọ wipe: “Awọn ti a o ka yẹ lati gba aye naa ati ajinde lati inu oku, . . . yoo dabi awọn angẹli; wọn jẹ ọmọ Ọlọrun, nitori ti wọn jẹ ọmọ ajinde.” Luku 20:35, 36. O tun sọ wipe “awọn ti wọn ṣe rere” yoo jade wa si “ajinde iye.” Johanu 5:29. Awọn olododo ti wọn ti ku ki yoo jinde titi di opin idajọ nibi ti a o ti ka wọn yẹ fun “ajinde iye.” Nitori naa wọn ki yoo si nibi igbẹjọ funra wọn nigba ti a ba n yẹ iwe wọn wo ti a si n ṣe ipinu lori ẹjọ wọn.ANN 214.3

  Jesu yoo farahan bi alagbawi wọn, lati bẹbẹ fun wọn niwaju Ọlọrun. “Bi ẹnikẹni ba dẹṣẹ, a ni alagbawi kan pẹlu Baba, Jesu Kristi olododo.” 1 Johanu 2:1. “Nitori Kristi ko wọ ibi mimọ ti a fi ọwọ kọ, eyi ti n ṣe apẹẹrẹ ti otitọ; ṣugbọn sinu ọrun funra rẹ, ni akoko yii lati fi ara han niwaju Ọlọrun fun wa.” “Nitori naa O le gba wọn la titi de opin awọn ti wọn ba wa si ọdọ Ọlọrun nipasẹ Rẹ, nitori ti O wa laaye titi lae lati bẹbẹ fun wọn.” Heberu 9:24; 7:25.ANN 214.4

  Bi a ti ṣi awọn iwe akọsilẹ silẹ ni idajọ, gbogbo igbesi aye awọn ti wọn gbagbọ ninu Jesu wa siwaju Ọlọrun. Bẹrẹ pẹlu awọn ti wọn kọkọ gbe ori ilẹ aye, Alagbawi wa, gbẹjọ wọn ni iran iran, O wa pari rẹ pẹlu ti awọn alaaye. A darukọ gbogbo eniyan, a si ṣe ayẹwo gbogbo ẹjọ finifini. A gba orukọ wọle, a kọ awọn orukọ kan silẹ. Nigba ti ẹṣẹkẹṣẹ ba ṣi wa ninu iwe akọsilẹ, ni aironupiwada kuro ninu rẹ, ti a ko si dari rẹ ji, a o yọ orukọ wọn kuro ninu iwe iye, a o si pa akọsilẹ iṣẹ rere wọn rẹ kuro ninu iwe iranti Ọlọrun. Oluwa sọ fun Mose wipe: “Ẹnikẹni ti o ba ṣẹ si Mi, oun ni Emi yoo pa orukọ rẹ rẹ kuro ninu iwe Mi.” Ẹksodu 32:33. Woli Isikiẹli tun sọ wipe: “Nigba ti olododo ba yi kuro ninu ododo rẹ, ti o dẹṣẹ, . . . a ki yoo sọ nipa gbogbo ododo ti o ti ṣe.” Isikiẹli 18:24.ANN 214.5

  Gbogbo awọn ti wọn ronupiwada kuro ninu ẹṣẹ wọn nitootọ, ti wọn ti gba ẹjẹ Kristi gẹgẹ bi ẹbọ ẹṣẹ wọn nipa igbagbọ, ti wọn ti kọ idariji si ori orukọ wọn ninu iwe ọrun, niwọn igba ti wọn ti di alabapin ododo Kristi, ti iwa wọn si wa ni ibamu pẹlu ofin Ọlọrun, a yoo mu ẹṣẹ wọn kuro, a yoo si ka wọn yẹ fun iye ainipẹkun. Oluwa sọ nipasẹ woli Aisaya wipe: “Emi, ani Emi, ni O n mu irekọja rẹ kuro nitori Mi, Emi ki yoo si ranti ẹṣẹ rẹ mọ.” Aisaya 43:25. Jesu sọ wipe: “Ẹni ti o ba ṣẹgun, oun naa ni yoo wọ aṣọ funfun; Emi ki yoo si pa oruko rẹ rẹ kuro ninu iwe iye, ṣugbọn Emi yoo jẹwọ rẹ ati orukọ rẹ niwaju Baba Mi ati niwaju awọn angẹli Rẹ.” “Ẹnikẹni ti yoo ba jẹwọ Mi niwaju eniyan, oun ni Emi yoo jẹwọ rẹ niwaju Baba Mi ti n bẹ ni ọrun. Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba sẹ Mi niwaju awọn eniyan, oun ni Emi yoo sẹ niwaju Baba Mi ti n bẹ ni ọrun.” Ifihan 3:5; Matiu 10:32, 33.ANN 214.6

  Ifẹ jijinlẹ ti eniyan n fihan ninu awọn ipinu ibi igbẹjọ aye fihan lerefe ifẹ ti a fihan ni gbọngan ọrun nigba ti a ba ṣe ayẹwo awọn orukọ ti wọn wa ninu iwe iye niwaju Onidajọ gbogbo aye. Alagbawi ọrun n bẹbẹ wipe ki a dari ẹṣẹ awọn ti wọn ba ti ṣẹgun nipa igbagbọ ninu ẹjẹ Rẹ ji, pe ki a da wọn pada si ile Edẹni wọn, ki a si de wọn ni ade gẹgẹ bi ajumọjogun “ijọba akọkọ” pẹlu Rẹ. Mika 4:8. Satani, ninu akitiyan rẹ lati tannijẹ ati lati dán iran wa wò ti ro lati sọ erongba Ọlọrun ni dida eniyan di asan; ṣugbọn Kristi bayii wa n beere wipe ki a mu eto naa ṣe afi bi ẹnipe eniyan ko ṣẹ ri. Ko beere idariji ati idalare fun awọn eniyan Rẹ ni kikun ati ni pipe nikan, ṣugbọn ipin ninu ogo Rẹ ati aaye lori itẹ Rẹ.ANN 214.7

  Nigba ti Jesu n bẹbẹ fun awọn ti wọn gba oore ọfẹ Rẹ, Satani n fi ẹsun kan wọn niwaju Ọlọrun gẹgẹ bi arufin. Atannijẹ nla n wa lati dari wọn sinu aigbagbọ, lati jẹ ki wọn padanu igboya wọn ninu Ọlọrun, lati pin wọn niya kuro ninu ifẹ Rẹ, ki wọn si rú ofin Rẹ. Bayii o tọka si akọsilẹ igbesi aye wọn, si abuku inu iwa wọn, ọna ti wọn ko gba jọ Kristi, eyi ti o ko abuku ba Olurapada wọn, si gbogbo ẹṣẹ ti o dan wọn wo lati da, nitori awọn nnkan wọnyi o pe wọn ni ọmọ ijọba rẹ.ANN 215.1

  Jesu ko ṣe awawi fun wọn nitori ẹṣẹ wọn, ṣugbọn O fi ironupiwada ati igbagbọ wọn han, O si beere idariji ẹṣẹ fun wọn, O gbe ọwẹ Rẹ ti a palara soke niwaju Baba ati awọn angẹli mimọ, O n wipe: Mo mọ wọn pẹlu orukọ wọn, Mo ti kọ wọn si atẹlẹwọ Mi. “Ẹbọ Ọlọrun ni irobinujẹ ọkan, irora aya, Ọlọrun oun ni Iwọ ki yoo gan.” O. Dafidi 51:17. A wa sọ fun olufisun awọn eniyan Rẹ wipe: “Oluwa ba ọ wi, Satani; ani Oluwa ti O yan Jerusalẹmu ba ọ wi: eyi ki ha ṣe ẹka ti a yọ kuro ninu ina bi?” Sekaraya 3:2. Kristi yoo wọ awọn ti wọn jẹ olootọ si pẹlu ododo Rẹ, ki O le mu wọn wa si ọdọ Baba Rẹ “bi ijọ ologo ti ko ni abawọn tabi ibajẹ, tabi awọn nnkan bawọnni.” Efesu 5:27. Orukọ wọn duro ninu iwe iye, a si kọ nipa wọn wipe: “Wọn yoo rin pẹlu Mi ninu aṣọ funfun: nitori ti wọn yẹ.” Ifihan 3:4.ANN 215.2

  Nigba naa ni a o ri imuṣẹ ni kikun ileri majẹmu tuntun. “Emi yoo dari aiṣedeede wọn ji, Emi ki yoo si ranti ẹṣẹ wọn mọ.” “Ni awọn ọjọ naa ati ni akoko naa, ni Oluwa wi, a yoo wa aiṣedeede Israeli, a ki yoo si ri, ati ẹṣẹ Judah, a ki yoo si ri wọn.” Jeremaya 31:34; 50:20. “Ni ọjọ naa ni ẹka Oluwa yoo ni ẹwa ati ogo, eso ilẹ yoo si ni ọla, yoo si dara fun awọn ti o sa asala ni Israeli. Yoo si ṣe wipe, ẹni ti a fi silẹ ni Sioni, ati ẹni ti o kù ni Jerusalẹmu ni a o pe ni mimọ, ani orukọ olukuluku ẹni ti a kọ pẹlu awọn alaaye ni Jerusalẹmu.” Aisaya 4:2, 3.ANN 215.3

  A yoo pari iṣẹ idajọ iyẹwewo ati pipa ẹṣẹ rẹ ṣaaju wiwa Oluwa lẹẹkeji. Nigba ti o jẹ wipe a yoo ṣe idajọ awọn oku lati inu awọn ohun ti a kọ sinu iwe, a ko le pa ẹṣẹ eniyan rẹ titi fi di opin idajọ nigba ti a o ṣe ayẹwo ẹjọ wọn. Ṣugbọn apostoli Peteru sọ ọ ni kedere wipe a yoo pa ẹṣẹ awọn onigbagbọ rẹ “nigba ti akoko itura ba de lati iwaju Oluwa; yoo si ran Jesu Kristi.” Iṣe Apostoli 3:19, 20. Nigba ti idajọ iyẹwewo ba pari, Kristi yoo wa, èrè Rẹ yoo si wa pẹlu Rẹ lati fifun olukuluku bi iṣẹ rẹ yoo ti ri.ANN 215.4

  Ninu isin ti aye lẹyin ti olu alufa ba pari iwẹnumọ ẹṣẹ fun Israeli tan, yoo jade wa yoo si bukun fun ijọ eniyan. Bẹẹ gẹgẹ ni Kristi ni opin iṣẹ Rẹ gẹgẹ bi Olubalaja, yoo farahan, “laisi ẹṣẹ si igbala” (Heberu 9:28), lati bukun awọn eniyan Rẹ ti n duro pẹlu iye ainipẹkun. Ni mimu ẹṣẹ kuro ninu ibi mimọ, bi alufa ti n jẹwọ wọn si ori ẹran iya, bẹẹ gẹgẹ ni Kristi yoo ko gbogbo ẹṣẹ wọnyi si ori Satani, olupilẹsẹ ẹṣẹ ati amuniṣẹ. A ran ẹran iya lọ si “ilẹ ti a ko tẹdo” pẹlu ẹṣẹ Israeli lọrun (Lefitiku 16:22); bẹẹ gẹgẹ ni Satani, pẹlu ẹbi gbogbo ẹṣẹ ti o mu ki awọn eniyan Ọlọrun o da, a yoo se mọ inu aye yii fun ẹgbẹrun ọdun kan, nigba naa aye yoo wa ni ahoro, laisi olugbe, nikẹyin yoo jiya ẹbi ẹṣẹ ni kikun ninu ina ti yoo pa awọn eniyan buburu run. Eto irapada nla yoo wa si imuṣẹ ninu iparun ẹṣẹ nikẹyin ati idande awọn ti wọn fẹ lati kọ ẹṣẹ silẹ.ANN 215.5

  Ni akoko ti a yan fun idajọ—opin 2300 ọjọ ni 1844—iṣẹ iyẹwewo ati ìpa ẹṣẹ rẹ bẹrẹ. Gbogbo eniyan ti o ba ti gba orukọ Kristi gbọ ri ni yoo la ayẹwo finifini kọja. Ati oku ati alaaye ni a o ṣe idajọ wọn “lati inu awọn ohun ti a kọ sinu iwe, gẹgẹ bi iṣẹ wọn.”ANN 215.6

  Ẹṣẹ ti a ko ba ronipiwada kuro ninu rẹ, ti a ko si kọ silẹ ko ni ni idariji a ki yoo si pa a rẹ kuro ninu iwe akọsilẹ, ṣugbọn yoo tako ẹlẹṣẹ naa ni ọjọ Ọlọrun. O le wu iwa buburu rẹ ni ọsan gangan tabi ninu okunkun; ṣugbọn wọn han kedere niwaju Ẹni ti a n ba lò. Awọn angẹli Ọlọrun wa ni ibi ti a ti da ẹṣẹ kọọkan ti wọn si n kọ ọ silẹ sinu iwe ti ko le baku. A le fi ẹṣẹ pamọ, ki a sẹ wipe a da ẹṣẹ, ki a paamọ kuro ni oju baba, iya, iyawo, awọn ọmọ ati ojulumọ; o le jẹ awọn ti wọn jẹbi ẹṣẹ nikan ni wọn ni imọlara iwa buburu wọn; ṣugbọn o han gbangba niwaju awọn ti n bẹ ni ọrun. Okunkun oru ọganjọ, aṣiri ọgbọn ẹwẹ itanjẹ ko to lati bo ero kan mọlẹ kuro ninu imọ Ẹni Ainipẹkun. Ọlọrun ni akọsilẹ ti o peye nipa gbogbo iwa ti ko tọ, gbogbo ìbálò ti ko bojumu. Afarawe iwa ifọkansin ko le tan An jẹ. Ki i ṣe aṣiṣe nipa bi iwa eniyan ti ri. Awọn eniyan ti ọkan wọn ko mọ le tan awọn eniyan jẹ, ṣugbọn Ọlọrun ri gbogbo iboju, O si mọ iwa inu lọhun.ANN 216.1

  Ero naa ti banilẹru to! Bi ọjọ ti n gori ọjọ, to n di ayeraye ni wọn n gbe ẹru akọsilẹ wọn wọ inu iwe ọrun. Ọrọkọrọ ti a ba ti sọ, ohunkohun ti a ba ti ṣe ko ṣe e pè pada mọ. Awọn angẹli ti ṣe akọsilẹ ati rere ati buburu. Alagbara julọ lori ilẹ aye ko le pe akọsilẹ ọjọ kan ṣoṣo pada. Iṣe wa, ọrọ wa ani erongba inu ibi kọlọfin ọkan wa, gbogbo wọn ni wọn ni ipa ti wọn lati kó ninu ipinu atubọtan wa si rere tabi si ibi. Bi o tilẹ jẹ wipe a le gbagbe wọn, sibẹ wọn a ṣe ijẹri wọn lati ṣe idalare tabi idalẹbi.ANN 216.2

  Gẹgẹ bi ayaworan ti n yaworan ẹni si oju pátákó rẹ laiṣe aṣiṣe, bẹẹ gẹgẹ ni a ṣe akọsilẹ pipe nipa iwa eniyan ninu iwe loke. Sibẹ àníyàn wa ti kere to nipa akọsile ti awọn olugbe ọrun yoo ri. Bi a ba le ṣi iboju ti o pin aye yii ati aye airi niya, ti awọn ọmọ eniyan si ri angẹli bi o ti n kọ gbogbo ọrọ ati iṣe eyi ti wọn yoo ba pade ni idajọ, ọpọlọpọ ọrọ ti wọn n sọ lojoojumọ ni wọn ki yoo sọ jade, ọpọlọpọ ohun ni wọn ki yoo ṣe.ANN 216.3

  Gbogbo bi a ti lo ẹbun wa ni a yoo ṣe ayẹwo rẹ finifini ni idajọ. Bawo ni a ṣe lo ẹbun ti Ọrun fifun wa? Njẹ Oluwa yoo gba tirẹ nigba wiwa Rẹ pẹlu èlé bi? Njẹ a lo agbara ti a fifun wa, ti owó, ti ọkan, ati ti ọpọlọ, si ogo Ọlọrun ati si ibukun aye yii bi? Bawo ni a ṣe lo akoko wa, kalamu wa, ohùn wa, owó wa, ipa wa? Kini a ṣe fun Kristi lara awọn otoṣi, awọn ti iya n jẹ, awọn alailobi tabi awọn opó? Ọlọrun ti fun wa ni ọrọ mimọ Rẹ; kini a ṣe pẹlu imọlẹ ati otitọ ti a fun wa lati gbọn si igbala? Ifẹnu lasan jẹwọ igbagbọ ninu Kristi ko niyelori; ifẹ ti a fihan nipa iṣẹ nikan ni a ri ni ojulowo. Sibẹ ifẹ nikan ni o le mu ki iṣẹkiṣẹ o ni itumọ niwaju Ọrun. Ohunkohun ti a ba ṣe lati inu ifẹ, bi o tile wu ki o kere ni oju eniyan, Ọlọrun gba a, a si san an lẹsan.ANN 216.4

  Imọ-ti-ara-ẹni-nikan eniyan ti o farasin han kedere ninu awọn iwe ọrun. Nibẹ ni a ṣe akọsilẹ ojuṣe wọn fun ẹnikeji wọn ti wọn ko pari, bi wọn ti ṣe gbagbe ojuṣe wọn fun Olugbala. Nibẹ ni wọn a ti ri bi wọn ti saba maa n fun Satani ni akoko, ero ati agbara ti o jẹ ti Kristi. Akọsilẹ ti awọn angẹli n gbe lọ si ọrun jẹ eyi ti o banininujẹ. Awọn ẹda ti wọn le ronu, awọn atẹle Kristi, wọn jọwọ ara wọn silẹ fun kiko ohun aye jọ tabi igbadun faaji aye. Owo, akoko, ati okun ṣofo nitori aṣehan ati itẹra-ẹni-lọrun; ṣugbọn akoko perete ni wọn fi silẹ fun adura, fun wiwa Iwe Mimọ, fun rirẹ ọkan silẹ ati ijẹwọ ẹṣẹ.ANN 216.5

  Satani n mu ọpọlọpọ ète wá lati gba ọkan wa ki o ma baa le ronu lori iṣẹ eyi ti o yẹ ki a mọ julọ. Olutannijẹ nla korira otitọ nla ti o ṣe afihan irubọ ti o mu ẹṣẹ kuro ati olubalaja ti o ni gbogbo agbara. O mọ wipe nipa ti oun, ohun gbogbo duro lori yiyi ọkan awọn eniyan pada kuro ni ọdọ Jesu ati otitọ Rẹ.ANN 216.6

  Awọn ti wọn ba fẹ ni ipin ninu anfani ibalaja Olugbala ko gbọdọ jẹ ki ohunkohun o di ojuṣe wọn lọwọ lati sọ iwa mimọ di pípé ninu ibẹru Ọlọrun. Dipo ki a lo awọn akoko iyebiye fun faaji, aṣehan, tabi wíwá èrè, a nilati lo o fun kikọ ẹkọ ọrọ otitọ tọkantọkan pẹlu adura. O yẹ ki awọn eniyan Ọlọrun o ni oye ti o yè kooro nipa koko ọrọ ibi mimọ ati idajọ iyẹwewo. Gbogbo eniyan ni wọn nilo fun ara wọn imọ nipa ipo ati iṣẹ Olu Alufa nla wọn. Bi ko ba ri bẹẹ wọn ko ni le lo igbagbọ ti o ṣe pataki fun akoko yii tabi duro ni ipo ti Ọlọrun ti ṣeto fun wọn. Olukuluku ni o ni ọkan lati gbala tabi lati padanu. Olukuluku ni o ni ẹjọ niwaju itẹ idajọ Ọlọrun. Olukuluku ni yoo pade Adajọ lojukoju. O ti wa ṣe pataki to, nigba naa, ki olukuluku o ronu loorekoore lori ìrí ti o leru nigba ti awọn onidajọ yoo joko, ti a yoo si ṣi awọn iwe, nigba ti, pẹlu Daniẹli, olukuluku yoo duro ni ipo rẹ ni opin ọjọ.ANN 216.7

  Gbogbo awọn ti wọn ti gba imọlẹ lori awọn koko ọrọ wọnyi ni wọn nilati ṣe ijẹri awọn otitọ nla ti Ọlọrun ti fifun wọn. Ibi mimọ ni ọrun jẹ aaringungun iṣẹ Kristi fun eniyan. O kan gbogbo ẹni ti n gbe ori ilẹ aye. O ṣe afihan eto irapada, ti o gbe wa de opin akoko ti o si fi awọn koko ọrọ iṣẹgun ti ijakadi laarin ododo ati ẹṣẹ han. O ṣe pataki jọjọ ki gbogbo eniyan o ṣe ayẹwo awọn koko ọrọ wọnyi daradara ki wọn sile da ẹnikẹni ti o ba beere lọwọ wọn fun ireti ti o wa ninu wọn lohun.ANN 217.1

  Ibalaja Kristi ninu ibi mimọ loke ṣe pataki si eto igbala gẹgẹ bi iku Rẹ lori agbelebu ti ṣe. Nipa iku Rẹ, O bẹrẹ iṣẹ ti O goke lọ si ọrun lati lọ pari lẹyin ajinde Rẹ. Nipa igbagbọ, a nilati wọ inu aṣọ ikele lọ, “nibi ti aṣaju wa ti wọ lọ fun wa.” Heberu 6:20. Nibẹ ni imọlẹ lati ara agbelebu Kalfari ti n tan jade. Nibẹ ni a ti le ni oye ti o yè kooro si nipa ohun ijinlẹ irapada. Ọrun pari igbala eniyan pẹlu ohun ti a ko le diye le; irubọ ti a ṣe dọgba pẹlu ohun ti ofin Ọlọrun ti a tẹloju n beere fun. Jesu ti ṣi ọna ti o lọ si itẹ Baba silẹ, ati nipasẹ ibalaja Rẹ ifẹ ọkan tootọ gbogbo ẹni ti o ba wa si ọdọ Rẹ ninu igbagbọ ni a o gbe wa siwaju Ọlọrun.ANN 217.2

  “Ẹni ti o ba bo ẹṣẹ rẹ mọlẹ ki yoo ṣe rere: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba jẹwọ ti o si ko wọn silẹ yoo ri aanu gba.” Owe 28:13. Bi gbogbo awọn ti wọn n fi ibaku wọn pamọ, ti wọn ṣe awawi nitori ibaku wọn ba ri bi Satani ti n yọ lori wọn, bi o ti n kẹgan Kristi ati awọn angẹli mimọ nitori iwa wọn, wọn yoo yara kankan lati jẹwọ ẹṣẹ wọn ati lati kọ wọn silẹ. Nipa ibaku ninu iwa, Satani n ṣiṣẹ lati ṣe akoso gbogbo iye eniyan, o si mọ wipe bi a ba fẹran awọn ibaku wọnyi, oun yoo ṣe aṣeyege. Nitori naa o n ṣiṣẹ lati tan awọn atẹle Kristi jẹ pẹlu ọgbọn arekereke buburu rẹ ki o ma baa ṣe e ṣe fun wọn lati bori. Ṣugbọn Jesu n bẹbẹ fun wọn pẹlu ọwọ Rẹ ti a ṣa lọgbẹ, ara Rẹ ti a pa; O si sọ fun gbogbo ẹni ti yoo tẹle wipe: “Oore ọfẹ Mi to fun ọ.” 2 Kọrintin 12:9. “Ẹ gba ajaga Mi si ọrun yin, ki ẹ si kẹkọ latọdọ Mi; nitori ti Mo jẹ ọlọkan tutu ati onirẹlẹ ni ọkan: ẹyin yoo si ri isinmi fun ọkan yin. Nitori ti ajaga Mi rọrun, ẹru Mi si fuyẹ.” Matiu 11:29, 30. Ki ẹnikẹni maṣe ri ibaku rẹ gẹgẹ bi eyi ti ko le wosan. Ọlọrun yoo funni ni igbagbọ ati oore ọfẹ lati bori wọn.ANN 217.3

  Ni akoko yii, a n gbe ni ọjọ nla ti iwẹnumọ. Ninu isin ti aye, nigba ti olu alufa ba n ṣe etutu fun Israeli, gbogbo wọn ni a fẹ ki wọn jẹ ọkan wọn niya nipa ironupiwada ẹṣẹ ati irẹra ẹni silẹ niwaju Oluwa, ki a ma baa gé orukọ wọn kuro laarin awọn eniyan. Ni ọna kan naa, gbogbo awọn ti wọn ba fẹ ki orukọ wọn o wa ninu iwe iye nilati, ninu ọjọ perete ti o ku ninu akoko oore ọfẹ wọn, jẹ ọkan wọn niya niwaju Ọlọrun nipa kikaanu fun ẹṣẹ ati ironupiwada tootọ. A nilati ṣe ayẹwo ọkan pẹlu otitọ. Ẹmi ainikanṣe ti o wọpọ laarin ọpọlọpọ Kristẹni ni a nilati kọ silẹ. Ijakadi gbigbona wa niwaju gbogbo awọn ti wọn ba fẹ tẹri iwa buburu ti n jijadu fun akoso ba. Iṣẹ imurasilẹ jẹ ohun ti olukuluku nilati ṣe. A ko ni gbàwálà lẹlẹgbẹjẹgbẹ. Iwa mimọ ati ifọkansin ẹnikan ko ni wulo fun aini ẹlomiran. Bi o tilẹ jẹ wipe gbogbo orilẹ ede ni yoo la idajọ kọja niwaju Ọlọrun, sibẹ yoo yẹ ẹjọ olukuluku wo finifini a fi bi ẹni pe ko si ẹlomiran laye mọ. A nilati dan gbogbo eniyan wo ki a si ri wọn laini abawọn tabi ibaku tabi iru nnkan bawọnni.ANN 217.4

  Awọn iṣẹlẹ ti wọn so mọ opin iṣẹ iwẹnumọ ẹṣẹ jẹ eyi ti o banilẹru. Awọn ohun ti o wa ninu rẹ tobi jọjọ. Idajọ n lọ lọwọ ninu ibi mimọ loke. Fun ọpọ ọdun iṣẹ yii n tẹsiwaju. Laipẹ—ko si ẹni ti o mọ bi o ti sunmọle to—yoo kan ẹjọ awọn alaaye. Niwaju Ọlọrun to leru igbesi aye wa yoo jade fun ayẹwo. Ni akoko yii ju gbogbo akoko lọ, o yẹ ki gbogbo ọkan o tẹti si iyanju Olugbala: “Ẹ maa ṣọna ki ẹ si maa gbadura: nitori ti ẹyin ko mọ akoko naa.” Maku 13:33. “Nitori naa bi ẹ ko ba ṣona, Emi yoo de si yin bi ole, ẹyin ki yoo si mọ akoko ti Emi yoo de si yin.” Ifihan 3:3.ANN 217.5

  Nigba ti iṣẹ idajọ iyẹwewo ba pari, a yoo ṣe ipinu atubọtan olukuluku fun ìyè tabi fun iku. Igba oore ọfẹ yoo pari ni asiko kiun ṣaaju wiwa Oluwa ninu ikuuku awọsanma. Kristi ninu Ifihan, wo akoko naa ni ọjọ iwaju, sọ pe: “Ẹni ti o ba jẹ alaiṣootọ, ki o maa jẹ alaiṣootọ niṣo: ati ẹni ti o ba jẹ alaimọ, jẹ ki o jẹ alaimọ niṣo: ati ẹni ti o ba jẹ olododo, jẹ ki o jẹ olododo niṣo: ati ẹni ti o ba jẹ mimọ, jẹ ki o jẹ mimọ niṣo. Si kiyesi, Emi n bọ kankan: ere Mi si n bẹ pẹlu Mi, lati fifun olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ rẹ yoo ti ri.” Ifihan 22:11, 12.ANN 217.6

  Awọn olododo ati awọn eniyan buburu a ṣi wa laaye lori ilẹ aye pẹlu ara kiku wọn—awọn eniyan a maa gbìn, wọn a maa kọle, wọn a maa jẹ wọn a si maa mu, ti gbogbo wọn ko ni mọ wipe a ti ṣe idajọ ikẹyin ti a ko le yipada ninu ibi mimọ loke. Ki ikun omi to wa, lẹyin ti Noah wọ inu ọkọ, Ọlọrun ti i mọ inu ile, O si ti awọn alaiwabiọlọrun mọ ita; ṣugbọn fun ọjọ meje awọn eniyan, laimọ wipe a ti fi edidi di iparun wọn, tẹsiwaju ninu igbesi aye aibikita ati faaji wọn, wọn n kẹgan ikilọ idajọ ti n bọ. Olugbala sọ wipe, “Bẹẹ gẹgẹ ni wiwa Ọmọ eniyan yoo ri.” Matiu 24:39. Ni idakẹjẹ, laifiyesi gẹgẹ bi ole ọganjọ, bẹẹ ni akoko ipinu ti yoo fi edidi di atubọtan gbogbo eniyan yoo de, ti ipe aanu ko ni kọ si awọn eniyan ti wọn jẹbi mọ.ANN 218.1

  “Nitori naa ẹ maa sọna: . . . ki o ma baa wa lojiji ki o baa yin pe ẹ n sun.” Maku 13:35, 36. Ipo awọn ti wọn ba kaarẹ ni siṣọna, ti wọn si yiju si onfa aye a buru jọjọ. Nigba ti awọn oniṣowo ba gbagbe ara wọn sinu wiwa èrè, nigba ti olufẹ faaji n wọna lati tẹ ara rẹ lọrun, nigba ti ọmọbinrin ọṣọ ara ba n to ohun ọṣọ rẹ—o le jẹ akoko kan naa ni Onidajọ gbogbo aye yoo kede gbolohun pe: ” A ti wọn ọ ninu oṣuwọn, iwọ ko si to.” Danieli 5:27.ANN 218.2

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents