Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  ORI KẸRINLELỌGBỌN—ṢE AWỌN ENIYAN WA TI WỌN TI KU LE BA WA SỌRỌ?

  Iṣe iranṣẹ awọn angẹli mimọ, bi a ti fihan ninu Iwe Mimọ, jẹ otitọ ti o tuni ninu julọ, ti o si ṣe iyebiye si gbogbo atẹle Kristi. Ṣugbọn ẹkọ ti o gbajugbaja ti ṣokunkun bo ikọni yii, ti o si tun yi pada. Ikọni wipe a bi aiku mọ eniyan, ti a kọkọ mu wa lati inu ironu awọn abọriṣa, ninu okunkun ifasẹyin nla, ti a si mu wọ inu igbagbọ Kristẹni, ti rọpo otitọ ti a kọni kedere ninu Iwe Mimọ wipe “oku ko mọ ohun kan.” Ọpọlọpọ ti gbagbọ wipe awọn ẹmi oku ni awọn “ẹmi ti n ṣe iṣẹ iranṣẹ, ti a ran jade lọ lati lọ ṣiṣẹ fun awọn ti yoo jẹ ajogun igbala.” A si ṣe eyi laika ẹri Iwe Mimọ si nipa iwalaaye awọn angẹli ọrun, ati ibaṣepọ wọn pẹlu itan eniyan, ṣaaju ki eniyan kankan to ku.ANN 246.1

  Ikọni wipe eniyan wa laaye ninu iku, paapaa julọ igbagbọ wipe ẹmi awọn ti wọn ti ku le pada wa lati ṣiṣẹ fun awọn alaaye, ti pese ọna silẹ fun ibẹmilo ode oni. Bi a ba gba awọn oku siwaju Ọlọrun ati awọn angẹli mimọ, ti wọn si ni oye ti o pọ pupọ ju eyi ti wọn ni tẹlẹ lọ, ki lo de ti wọn ko pada wa sinu aye lati wa kọ awọn alaaye ki wọn si la wọn lọyẹ? Gẹgẹ bi awọn akẹkọ nipa Ọlọrun ode oni ṣe n kọni wipe, ẹmi awọn ti wọn ti ku n rababa lori awọn ọrẹ wọn laye, kilode ti ko fi yẹ ki a gba wọn laaye lati ba wọn sọrọ, lati kì wọn nilọ nipa ibi tabi tu wọn ninu ninu ibanujẹ wọn? Bawo ni awọn ti wọn gbagbọ ninu iwalaaye eniyan ninu iku ṣe le kọ ohun ti o wa si ọdọ wọn gẹgẹ bi imọlẹ ọrun lati ọdọ awọn ẹmi ti a ṣe logo silẹ? Wọn ka ọna yii si ọna mimọ, nipasẹ rẹ ni Satani si n gba mu erongba rẹ ṣe. Awọn angẹli ti wọn ti ṣubu ti wọn n ṣe ifẹ rẹ n fi ara han gẹgẹ bi iranṣẹ lati inu aye ẹmi. Nigba ti wọn n wipe wọn n mu alaaye wa sinu iṣẹ iranṣẹ awọn oku, ọmọ alade okunkun n lo agbara buburu rẹ lori iye wọn.ANN 246.2

  O ni agbara lati mu irisi ọrẹ ẹni ti o ti ku wa siwaju eniyan. Ayederu naa peye; wọn ri irisi, ọrọ ati ohùn, gẹgẹ bi ojulowo pẹlu iyẹlenu. Ọpọlọpọ ni wọn ri itunu pẹlu idaniloju wipe awọn ololufẹ wọn n jẹgbadun alaafia ni ọrun, laini ifura ewu, wọn fi eti silẹ “si awọn ẹmi atannijẹ, ati ikọni eṣu.”ANN 246.3

  Nigba ti a mu ki wọn gbagbọ wipe awọn oku maa n pada wa lati ba wọn sọrọ lootọ, Satani mu ki awọn ti wọn ti ku laimura silẹ o jade wa. Wọn a sọ wipe inu wọn dun ni ọrun ani pe wọn wa ni ipo ọla nibẹ, bayi ni a ṣe n kọni ni aṣiṣe yii kaakiri wipe ko si iyatọ laarin olododo ati ẹni buburu. Awọn ti n dibọn bi olubẹwo lati aye ẹmi nigba miran maa n sọ akiyesi ati ikilọ ti wọn maa n jẹ otitọ. Bi wọn ba ti n fi ọkan tan wọn, wọn a mu awọn ikọni ti wọn tako igbagbọ ninu Iwe Mimọ ni ọna ti o han kedere wa. Pẹlu ifarahan wipe wọn ni ifẹ ti o jinlẹ ninu alaafia awọn ọrẹ wọn ninu aye, wọn a mu awọn aṣiṣe to lewu julọ wa. Nitori pe wọn n sọ awọn otitọ diẹ, ati pe nigba miran wọn maa n sọ asọtẹlẹ ọjọ iwaju, eyi jẹ ki o dabi ẹnipe ọrọ wọn ṣe e gbẹkẹle; ọpọlọpọ eniyan a si yara kankan gba ẹkọ eke wọn, wọn a ni igbagbọ patapata ninu wọn, a fi bi ẹnipe wọn jẹ otitọ ti o mọ julọ ninu Bibeli. A kọ ofin Ọlọrun silẹ, a kẹgan Ẹmi oore ọfẹ, wọn si ri ẹjẹ majẹmu bi ohun aimọ. Awọn ẹmi sọ wipe Kristi ki i ṣe Ọlọrun, ani wọn gbe Ẹlẹda si ipele kan naa pẹlu ara wọn. Bayii labẹ aabo ohun miran, ọlọtẹ nla naa si n tẹsiwaju ninu ijakadi rẹ pẹlu Ọlọrun, ti o bẹrẹ ni ọrun, ti o si tẹsiwaju ninu rẹ lori ilẹ aye fun bi ẹgbẹrun ọdun mẹfa.ANN 246.4

  Ọpọlọpọ ni wọn ri ifarahan ẹmi bii mọkaruuru ati itanjẹ lati ọdọ awọn ti n ba ẹmi lo. Ṣugbọn nigba ti o jẹ ootọ wipe a ti fun awọn eniyan ni ẹtan gẹgẹ bi ifarahan nitootọ, sibẹ a si ri ifihan agbara ẹmi ni ọna ti o lagbara. Ikanlẹkun kokooko eyi ti o bẹrẹ ibẹmilo ti ode oni ki i ṣe ẹtan tabi arekereke, ṣugbọn iṣẹ taara awọn angẹli buburu ni, ti wọn fi ọkan ninu awọn eke ti o ṣe aṣeyọri julọ lati pa ọkan run han. Ọpọ ni a o tanjẹ pẹlu igbagbọ wipe itanjẹ lasan ni ibẹmilo; nigba ti wọn ba ri ifarahan lojukoju ti wọn ko le ṣe ju ki wọn gba wipe o kọja agbara eniyan lọ, a o tan wọn jẹ, wọn a gba wọn gẹgẹ bi agbara nla Ọlọrun.ANN 246.5

  Awọn eniyan wọnyi fi oju fo ẹri Iwe Mimọ nipa awọn iṣẹ iyanu ti Satani ati awọn aṣoju rẹ n ṣe kọja. Nipasẹ agbara Satani ni awọn pidanpidan Farao fi le ṣe ayederu iṣẹ Ọlọrun. Pọlu jẹri si wipe ṣaaju wiwa Kristi lẹẹkeji, iru ifarahan agbara Satani bẹẹ yoo wa. “Iṣiṣẹ Satani pẹlu gbogbo agbara ati ami ati iṣẹ iyanu eke, ati pẹlu gbogbo itanjẹ aiṣododo,” yoo wa ṣaaju wiwa Oluwa. 2 Tẹsalonika 2:9, 10. Apostoli Johanu, ni ṣiṣe alaye agbara ti n ṣe iṣẹ iyanu naa sọ wipe yoo fi ara han ni ọjọ ikẹyin, o sọ wipe: “O n ṣe iṣẹ iyanu nla debi pe o mu ina sọkalẹ lati ọrun wa si ori ilẹ aye ni oju gbogbo eniyan, o si tan awọn ti n gbe ori ilẹ aye jẹ nipasẹ awọn iṣẹ iyanu wọnni ti o ni agbara lati ṣe.” Ifihan 13:13, 14. Ki i ṣe wipe a n dibọn ni a n sọ nibi. A tan awọn eniyan jẹ nipasẹ awọn iṣẹ iyanu ti awọn aṣoju Satani ni agbara lati ṣe, ki i ṣe wipe ti o dabi ẹnipe wọn ṣe.ANN 246.6

  Ọmọ alade okunkun, ti o ti n fi igba pipẹ lo agbara nla rẹ lati ṣiṣẹ itanjẹ, n fi ọgbọn mu ki idanwo rẹ o ba gbogbo eniyan mu ninu ipo ati ẹgbẹ ti wọn wa. Si awọn ọlaju, o fi ibẹmilo han ni ọna mimọ ati oye, nipa eyi a fa ọpọlọpọ sinu idẹkun rẹ. Ọgbọn ti ibẹmilo n funni ni apostoli Jakọbu ṣe alaye bi eyi ti “ko ti oke wa, ṣugbọn ti aye ni, ti ara ni, ti ẹmi eṣu si ni pẹlu.” Jakọbu 3:15. Eyi pẹlu ni atannijẹ nla naa dọwọbo, bi didọwọ bo o yoo ba ṣiṣẹ fun daradara. Ẹni ti o le fi ara han pẹlu didan serafu ọrun niwaju Kristi nigba idanwo ninu aginju, n wa si ọdọ eniyan ni ọna ti o fanimora julọ bi angẹli imọlẹ. A ṣipẹ si ironu wa nipa sisọ ohun ti o niyi; o n mu inu awọn alafẹfẹyẹyẹ dun pẹlu awọn ohun ti n fi ayọ kun ni; o n wa ifẹ eniyan nipa fifi ifẹ ati iṣeun rere han ni ọna ti o yọ lẹnu. A ru ironu eniyan ga soke, ni didari eniyan lati ni igberaga ninu ọgbọn ara wọn ki wọn baa le gan Ẹni Ayeraye ninu ọkan wọn. Alagbara nì ti o le gbe Olurapada aye lọ si ori oke giga ti o si mu ki gbogbo ijọba aye ati ogo wọn o kọja niwaju Rẹ, yoo mu idanwo wa si ọdọ eniyan ni ọna ti yoo yi ero awọn ti agbara Ọlọrun ko daabobo pada.ANN 247.1

  Satani n tan eniyan jẹ bayi bi o ti tan Efa jẹ ni Edẹni nipa iyin eke, nipa riru ifẹ lati ni imọ ti a ko faaye gba soke, nipa riru ifẹ fun igbera ẹniga soke. Ifẹ awọn iwa buburu wọnyi ni o fa iṣubu rẹ, nipasẹ wọn o lero lati pa eniyan run. “Ẹyin yoo dabi Ọlọrun” ni o wi, “ni mimọ rere ati buburu.” Jẹnẹsisi 3:5. Ibẹmilo n kọni wipe “eniyan jẹ ẹda ti n dagbasoke; wipe ayanmọ rẹ ni, lati igba ti a ti bi, lati maa dagba titi aye ainipẹkun, lati di Ọlọrun.” Siwaju si: eniyan ni yoo ṣe idajọ ara rẹ, kii si i ṣe ẹlomiran.” “Idajọ naa yoo jẹ rere, nitori pe idajọ ara ẹni ni. . . . Itẹ naa wa ninu rẹ.” Olukọ ibẹmilo kan sọ, bi “imọlara ẹmi” ṣe n dide ninu rẹ wipe: “Ẹyin ara mi, gbogbo eniyan jẹ ẹni ti o ku diẹ ki o di ọlọrun.”ANN 247.2

  Bayi, dipo ododo ati iwa pipe Ọlọrun ailopin, ohun ti o yẹ ki a bu ọla fun ni tootọ; dipo ododo pipe ofin Rẹ, odiwọn tootọ fun idagbasoke eniyan, Satani mu iwa eniyan funra rẹ, ti o kun fun ẹṣẹ ti o si baku gẹgẹ bi ohun kan ṣoṣo ti o yẹ ki a bu ọla fun, odiwọn kan ṣoṣo fun idajọ, tabi odiwọn iwa. Itẹsiwaju yii ki i ṣe lọ si oke bikoṣe lọ si isalẹ.ANN 247.3

  O jẹ ofin ti oye ati ti ẹmi wipe nipa wiwo a n yipada. Oye maa n mu ara rẹ dọgba pẹlu ohun ti o ba n ronu le lori. O maa n dabi ohun ti a ba fẹran ti a si bọwọ fun. Eniyan ko le ga ju odiwọn iwa mimọ tabi iṣẹ rere tabi otitọ rẹ lọ. Bi o ba jẹ wipe ara rẹ ni odiwọn ti o ga julọ, ko le ri ohun ti o ga ju eyi lọ. Dipo bẹẹ, a maa tẹri sodo siwaju ati siwaju si ni. Oore ọfẹ Ọlọrun nikan ni o le gbe eniyan soke. Bi a ba fi eniyan silẹ fun ara rẹ, iwa rẹ a maa lọ sodo ni laisi idaduro.ANN 247.4

  Si awọn ti wọn n tẹ ara wọn lọrun, olufẹ faaji, olufẹ ara, ibẹmilo n fi ara rẹ han labẹ iboju ti ko lagbara to ti awọn ọlaju ati amoye; ninu abala rẹ ti o buru si wọn ri ohun ti o ba ohun ti ọkan wọn fa si mu. Satani n wa gbogbo ohun ti o jọ ibaku ninu iṣẹda eniyan, o sami si awọn ẹṣẹ ti olukuluku n fẹ lati da, a wa ri wipe anfani wa lati tẹ ifẹ lati wuwa buburu lọrun. O n dan eniyan wo lati ṣe aṣeju ninu ohun ti o dara funra rẹ, nipasẹ ainiwọntuwọnsi, a mu ki wọn ko aarẹ ba agbara ti ara, ti ọpọlọ ati ti iwuwasi. O ti pa ọpọlọpọ, o si n pa ọpọlọpọ run nipasẹ titẹ ifẹ ara lọrun, nipa eyi, a sọ gbogbo iṣẹda eniyan da ti ẹranko. Lati pari iṣẹ rẹ, o sọ nipasẹ awọn ẹmi wipe “ọgbọn tootọ gbe eniyan ga ju ofin lọ;” wipe “ohunkohun ti a ba ri ni o tọna;” wipe “Ọlọrun ki i bani wi;” ati pe “gbogbo ẹṣẹ ti a ba da ko lẹbi.” Nigba ti a ba mu ki eniyan o gbagbọ wipe ifẹ ọkan ni ofin ti o ga julọ, wipe ominira ni aini akoso, ati pe ara rẹ ni eniyan yoo jiyin fun, tani o wa le yalẹnu wipe iwa ibajẹ ati iwa buburu tan kalẹ nibi gbogbo? Ọpọ ni wọn n yara kankan gba awọn ikọni ti yoo fi wọn silẹ lati ṣe igbọran si aṣẹ ọkan aimọ wọn. Wọn gbe akoso isẹra-ẹni si ori ifẹkufẹ ara, wọn mu ki agbara oye ati ọkan o tẹriba fun itẹsi ẹranko ti inu eniyan, Satani si n fi ayọ n gbá ọpọlọpọ ti wọn pe ara wọn ni atẹle Kristi sinu ẹwọn rẹ.ANN 247.5

  Ṣugbọn a ko nilo lati tan ẹnikẹni jẹ nipa awọn eke tí ibẹmilo n sọ sita. Ọlọrun ti fun araye ni imọlẹ ti o to lati jẹ ki wọn ri idẹkun naa. Gẹgẹ bi a ti fihan sẹyin ero ti o jẹ ipilẹ fun ibẹmilo n wọya ija pẹlu ọrọ ti o han kedere ninu Iwe Mimọ. Bibeli sọ wipe oku ko mọ ohun kan, wipe ero wọn ti pari, wọn ko ni ipin ninu ohunkohun ti a n ṣe labẹ oorun, wọn ko mọ ohun kan nipa ayọ ati ibanujẹ awọn ti wọn jẹ ololufẹ wọn julọ ninu aye.ANN 248.1

  Siwaju si, Ọlọrun ti fi ofin de gbogbo ohun ti o ba jọ mọ biba ẹmi ẹni ti o ti ku sọrọ. Ni akoko awọn Heberu awọn kan wa ti wọn n sọ, bi awọn abẹmilo ti n sọ loni, wipe wọn le ba oku sọrọ. Ṣugbọn “ẹmi oku” bi a ti n pe awọn olubẹwo lati aye miran yii, ni Bibeli pe ni “ẹmi eṣu.” (Ẹ wo Numeri 25:1—3; O. Dafidi 106:28; 1 Kọrintin 10:20; Ifihan 16:14.) Iṣẹ biba ẹmi awọn oku sọrọ ni Oluwa pe ni ohun irira, a ko si fi aaye gba a labẹ ijiya iku. Lefitiku 19:31; 20:27. Ni bayii a n fi oju ẹgan wo iṣẹ ajẹ. Wipe eniyan le ba ẹmi sọrọ ni a ri gẹgẹ bi itan asan ti igba oju dudu. Ṣugbọn ibẹmilo, eyi ti awọn atẹle rẹ pọ ni iye ti ri aaye wọ aarin awọn ọmọwe, o ti wọ inu ijọ, o si n ri oju rere awọn aṣofin, ani ni aafin awọn ọba—olu awọn itanjẹ yii jẹ isọji iṣẹ ajẹ ti a tako ti a si fi ofin de, ṣugbọn ni ọna tuntun.ANN 248.2

  Bi ko ba si ẹri miran nipa ohun ti ibẹmilo jẹ gan an, o to fun Kristẹni lati mọ wipe ẹmi naa ko ṣe iyatọ laarin ododo ati ẹṣẹ, laarin awọn apostoli Kristi ti wọn ni iwa mimọ ti wọn si jẹ ẹni rere ati eyi ti o ni iwa ibajẹ julọ laarin awọn iranṣẹ Satani. Nipa fifi awọn oniwa ibajẹ han wipe wọn wa ni ọrun, wipe wọn wa ni ipo giga nibẹ, Satani n sọ fun araye wipe: “Ko si bi o ti wu ki o buru to; o baa gbagbọ tabi ki o ma gbagbọ ninu Ọlọrun ati Bibeli. Gbe bi o ti wu ọ; ọrun ni ile rẹ.” Awọn olukọ onibẹmilo n sọ kedere wipe: “Gbogbo ẹni ti o ba ṣe ibi, rere ni niwaju Ọlọrun, O si ni inu didun si wọn; tabi, Nibo ni Ọlọrun idajọ gbe wa?”Malaki 2:17. Ọrọ Ọlọrun sọ wipe: “Egbe ni fun ẹni ti n pe ibi ni ire ati ire ni ibi; ti o n fi okunkun pe imọlẹ ati imọlẹ ni okunkun.” Aisaya 5:20.ANN 248.3

  Awọn apostoli ti awọn emi eke yii gbe wọ ni a jẹ ki wọn o tako ohun ti wọn kọni ni abẹ aṣẹ Ẹmi Mimọ nigba ti wọn wa laaye. Wọn sẹ wipe Bibeli ti ọdọ Ọlọrun wa, nipa eyi wọn n fa ipilẹsẹ ireti Kristẹni ya, wọn si n pa ina ti n fi ọna Ọlọrun han. Satani n mu ki awọn eniyan o gbagbọ wipe itan arosọ lasan ni Bibeli, tabi iwe ti o yẹ fun iran eniyan nigba ti koi ti i dagba, ṣugbọn bayi, a nilati fi oju tẹnbẹlu rẹ tabi ki a kọ ọ silẹ bi eyi ti ko ba igba mu. O wa n jẹ ki awọn ifarahan ẹmi o rọpo ọrọ Ọlọrun. Eyi jẹ ọna ti o wa ni abẹ iṣakoso rẹ nikan ṣoṣo, nipasẹ eyi, o le mu ki aye o gba ohun ti o ba fẹ gbọ. Iwe ti yoo da oun ati awọn atẹle rẹ lẹjọ ni o ṣu okunkun bo, nibẹ gan ni o fẹ ki o wa; o fi Olugbala aye han gẹgẹ bi eniyan lasan. Bi awọn ẹṣọ Romu ti wọn n sọ iboji Jesu ti tan iroyin irọ kalẹ eyi ti awọn alufa ati alagba fi si wọn lẹnu lati maṣe muni gbagbọ ninu ajinde Rẹ, bẹẹ gẹgẹ ni awọn ti wọn gbagbọ ninu ifarahan ẹmi ṣe n jẹ ki o han wipe ko si ohun ti o yanilẹnu ninu awọn iṣẹlẹ nipa igbesi aye Olugbala wa. Lẹyin ti wọn ti Jesu sẹyin, wọn wa n pe akiyesi si iṣẹ iyanu ara wọn, wipe awọn wọnyi ju awọn iṣẹ Kristi lọ lọna ti o ga.ANN 248.4

  Lootọ ni wipe ibẹmilo ti n yi irisi rẹ pada, ti o si n fi awọn ohun ti ko bojumu ninu rẹ pamọ, o n wa ni awọ Kristẹni. Ṣugbọn awọn ọrọ rẹ lati ori pẹpẹ, ati ile itẹwe ti wa niwaju awọn eniyan fun ọjọ pipẹ, ninu eyi ni a si ti fi iwa rẹ gan an han. A ko le fi awọn ikọni yii pamọ, bẹẹ ni a ko le sẹ wọn.ANN 248.5

  Ani ni ipo ti o wa yii, dipo ki o yẹ fun ifarada ju ti tẹlẹ lọ, o tilẹ tun wa buru si ni nitori ẹtan arekereke. Ni akọkọ, o kọ Kristi ati Bibeli silẹ, bayi o sọ pe oun gba awọn mejeeji. Ṣugbọn o tumọ Bibeli ni ọna ti o dunmọ ọkan ti a ko sọ dọtun ninu, nigba ti o n sọ awọn otitọ ọlọwọ ti wọn ṣe pataki ninu rẹ di asan. A n sọ wipe ifẹ ni iwa Ọlọrun ti o tobi julọ, ṣugbọn a rẹ ẹ silẹ di ironu ọkan alailagbara, ti ko ṣe iyatọ laarin rere ati ibi. Ododo Ọlọrun, bi o ti ba ẹṣẹ wi, ati ohun ti ofin Rẹ beere fun ni a pamọ kuro niwaju awọn eniyan. A kọ awọn eniyan lati ri Ofin Mẹwa bi iwe ti o ti ku. Awọn itan arosọ ti wọn n dun mọni, ti wọn n rani níyè n muni nigbekun o si n dari eniyan lati kọ Bibeli silẹ gẹgẹ bi ipilẹsẹ igbagbọ wọn. A ṣe Kristi bii ti akọkọ; ṣugbọn Satani ti fọ awọn eniyan loju ti wọn ko fi ri itanjẹ naa.ANN 248.6

  Awọn perete ni wọn ni oye ti o tọ nipa agbara itanjẹ ibẹmilo ati ewu ti o wa ninu bibọ si abẹ agbara rẹ. Ọpọlọpọ ni wọn n danwo lati le tẹ iwadi wọn lọrun lasan. Wọn ko ni igbagbọ tootọ ninu rẹ, ibẹru a si kun inu wọn bi wọn ba ni ero wipe wọn jọwọ ara wọn silẹ fun akoso ẹmi. Ṣugbọn wọn n wọ inu ibi ti a ka leewọ, apanirun nla naa a si lo agbara rẹ le wọn lori laiṣe wipe wọn fi ọwọ si. Ẹ jẹ ki a mu ki wọn fi iye wọn silẹ fun idari rẹ lẹẹkanṣoṣo, yoo si mu wọn ni igbekun. Ko ṣe e ṣe, ninu agbara ara wọn lati yọ kuro ninu agbara ifani ati iraniniye rẹ. Ayafi agbara Ọlọrun ti a fifunni ni idahun si adura igbagbọ atọkanwa, nikan ni o le tu awọn ọkan ti a de nigbekun silẹ.ANN 249.1

  Gbogbo awọn ti wọn n tẹsiwaju ninu iwa ẹṣẹ tabi ti wọn mọọmọ n da ẹṣẹ kan ti wọn mọ, n kọwe si idanwo Satani. Wọn ya ara wọn kuro ni ọdọ Ọlọrun ati kuro ni abẹ awọn angẹli Rẹ; bi eṣu ti n mu ẹtan re wa, wọn wa lai ni aabo, wọn a si ṣubu bi ẹran ijẹ. Awọn ti wọn n fi ara wọn si abẹ agbara rẹ ko mọ daju ibi ti iwa wọn a yọri si. Nigba ti o ti gbe wọn ṣubu, adanniwo a lo wọn bi aṣoju rẹ lati tan awọn miran sinu iparun.ANN 249.2

  Woli Aisaya sọ wipe: “Nigba ti a ba sọ fun yin, Ẹ wa awọn ti n ba oku lo, ati awọn oṣo ti n ké, to si n kùn; ko ha yẹ ki orilẹ ede o wa Ọlọrun wọn ju ki awọn alaaye o maa wa awọn oku? Si ofin ati si ẹri: bi wọn ko ba sọ gẹgẹ bi ọrọ yii nitori ti ko si imọlẹ ninu wọn ni.” Aisaya 8:19, 20. Bi awọn eniyan ba nifẹ lati gba otitọ ti a sọ kedere ninu Iwe Mimọ nipa iṣẹda eniyan ati ipo awọn oku, wọn a ri ninu ọrọ ati ifarahan awọn abokusọrọ iṣọwọṣiṣẹ Satani pẹlu agbara ati ami ati iṣẹ iyanu eke. Ṣugbọn dipo ki wọn fi ominira ti o ba ọkan idibajẹ yii mu silẹ, ki wọn si kọ ẹṣẹ ti wọn fẹran silẹ, ọpọlọpọ di oju wọn si imọlẹ wọn si n rin lọ laika ikilọ si, nigba ti Satani n fi idẹkun rẹ yi wọn ka ti wọn si n di ẹran ijẹ rẹ. “Nitori ti wọn ko gba ifẹ fun otitọ, ki a baa le gba wọn la,” nitori naa “Ọlọrun ran itanjẹ ti o lagbara si wọn, ki wọn baa le gba eke gbọ.” 2 Tẹsalonika 2:10, 11.ANN 249.3

  Awọn ti wọn n tako ikọni ibẹmilo ko ba eniyan nikan ja, bikoṣe Satani ati awọn ẹmi buburu ni ibi giga. Satani ko ni kuro ayafi bi a ba ti i sẹyin pẹlu agbara awọn iranṣẹ ọrun. Awọn eniyan Ọlọrun nilati koju rẹ, bi Olugbala wa ti ṣe, pẹlu awọn ọrọ: “A ti kọwe rẹ.” Satani le ka Iwe Mimọ sori ni akoko yii bi i ti akoko Kristi, yoo si ṣi awọn ikọni rẹ tumọ lati fi idi awọn itanjẹ rẹ mulẹ. Awọn ti yoo duro ni akoko ewu nilati ni oye ẹri Iwe Mimọ funra wọn.ANN 249.4

  Ọpọlọpọ ni awọn ẹmi eṣu yoo ko loju ti wọn yoo gbe awọn ara ile tabi ọrẹ wọn wọ ti wọn yoo si maa sọ ẹkọ odi ti o lewu julọ. Awọn olubẹwo yii yoo ṣipẹ si aanu ọkan wa ti o tutu julọ wọn yoo si ṣiṣẹ iyanu lati fi idi eke wọn mulẹ. A nilati mura silẹ lati doju kọ wọn pẹlu otitọ inu Bibeli wipe oku ko mọ ohun kankan ati wipe ẹmi eṣu ni awọn ti wọn n fi ara han yii.ANN 249.5

  “Akoko idanwo, ti yoo wa sori gbogbo aye, lati dan awọn ti n gbe ori ilẹ aye wo” (Ifihan 3:10) wa niwaju wa. A o tan gbogbo awọn ti igbagbọ wọn ko fi ẹsẹ mulẹ to ninu ọrọ Ọlọrun jẹ, a o si bori wọn. Satani “n ṣiṣẹ pẹlu gbogbo itanjẹ ni aiṣododo” lati ni akoso lori awọn ọmọ eniyan, awọn itanjẹ rẹ yoo si maa pọ si lojoojumọ. Ṣugbọn o le ṣe aṣeyọri niwọn bi awọn eniyan ba ti mọọmọ yọnda ara wọn fun awọn idanwo rẹ. Awọn ti wọn n fi tọkantọkan wa imọ otitọ ti wọn si n ṣe akitiyan lati fọ ọkan wọn mọ nipa igbọran, ti wọn n ṣe ohun ti wọn le ṣe lati pese ara wọn silẹ fun ijakadi naa yoo ri ninu otitọ ọrọ Ọlọrun, aabo tootọ. “Nitori ti iwọ pa ọrọ suuru Mi mọ, Emi yoo pa ọ mọ pẹlu” (ẹsẹ 10), ni ileri Olugbala. Yoo ran gbogbo angẹli kuro ni ọrun lati daabo bo awọn eniyan rẹ ju ki O fi ọkan kan ti o gbẹkẹle silẹ ki Satani o bori rẹ lọ. Woli Aisaya ṣe afihan itanjẹ ẹlẹru ti yoo wa si ori awọn eniyan buburu, ti yoo mu ki wọn o ro wipe wọn a ri aabo kurọ lọwọ idajọ Ọlọrun: “A ti da majẹmu pẹlu iku, a si ti ba iboji mulẹ; nigba ti pasan gigun ba kọja, ki yoo de ọdọ wa: nitori awa ti fi eke ṣe aabo wa, ati labẹ irọ ni awa fi ara wa pamọ si.” Aisaya 28:15. Ninu ẹgbẹ ti a ṣe alaye rẹ nibi ni awọn ti wọn n tẹsiwaju ninu aigbọran wọn ṣugbọn ti wọn n tu ara wọn ninu pẹlu idaniloju wipe ko si ijiya fun ẹlẹṣẹ wa; wipe gbogbo eniyan laika bi wọn ti kun fun iwa ibajẹ to, ni a o gba si ọrun, lati di angẹli Ọlọrun. Ṣugbọn ni pataki julọ ni awọn ti wọn ba iku da majẹmu ti wọn si ba ipo oku mulẹ, ti wọn kọ otitọ eyi ti Ọrun fifunni gẹgẹ bi aabo fun olododo ni ọjọ iṣoro silẹ, ti wọn si gba aabo eke Satani rọpo—ẹtan ti ibẹmilo.ANN 249.6

  Ifọju awọn eniyan iran yii kọja afẹnusọ. Ọpọlọpọ ni wọn kọ ọrọ Ọlọrun silẹ gẹgẹ bi ohun ti ko yẹ ki a gbagbọ ti wọn si n yara kankan pẹlu igboya lati gba awọn itanjẹ Satani. Awọn alaigbagbọ ati apẹgan ba awọn ti wọn n jijadu fun igbagbọ awọn woli ati awọn apostoli wi gẹgẹ bi onitara alaimoye, wọn si n da ara wọn ninu dun nipa fifi awọn ọrọ Iwe Mimọ nipa Kristi ati eto igbala ati idajọ ti a o ṣe fun awọn ti wọn kọ otitọ silẹ ṣe ẹfẹ. Wọn ṣe ikaanu nla fun iye ti o kere, ti ko lagbara ti o si n gba ohun asan gbọ ti o gba awọn ọrọ Ọlọrun ti o tun ṣiṣẹ igbọran si ofin rẹ. Wọn n fi idaniloju ti o lagbara han, afi bi ẹnipe, lootọ, wọn ti da majẹmu pẹlu iku, wọn si ti ba ipo oku mulẹ, afi bi ẹnipe wọn mọ idena ti ohunkohun ko le gbà kọja si aarin ara wọn ati igbẹsan Ọlọrun. Ko si ohun ti o le ru ibẹru wọn soke. Wọn ti fi ara wọn fun adanniwo patapata debi pe wọn wa ni ibaṣepọ timọtimọ pẹlu rẹ, wọn si kun fun ẹmi rẹ debi pe, wọn ko ni agbara ati ifẹ lati ja kuro ninu rẹ.ANN 250.1

  Fun igba pipẹ, Satani ti n mura silẹ fun akitiyan rẹ ti o kẹyin lati tan aye jẹ. A ṣe ipilẹ iṣẹ rẹ pẹlu idaniloju ti a fun Efa ni Edẹni: “Ẹyin ki yoo ku ikukiku kan.” “Ni ọjọ ti ẹyin ba jẹ ninu rẹ, nigba naa ni oju yin yoo la, ẹyin yoo si dabi Ọlọrun, ni mimọ rere ati buburu.” Jẹnẹsisi 3:4, 5. Diẹdiẹ ni o n pese ọna silẹ fun itanjẹ rẹ ti o ga julọ ninu idagbasoke ibẹmilo. Koi ti i pari ete rẹ; yoo pari rẹ ni akoko ikẹyin. Woli naa wi pe: “Mo ri awọn ẹmi aimọ mẹta bi ọpọlọ; . . . awọn ni ẹmi buburu ti n ṣiṣẹ iyanu, ti wọn jade lọ sọdọ awọn ọba aye ati ti gbogbo aye, lati gba wọn jọ si ogun ọjọ nla naa ti Ọlọrun alagbara.” Ifihan 16:13, 14. Ayafi awọn ti a fi agbara Ọlọrun pamọ nipasẹ igbagbọ ninu ọrọ Rẹ, gbogbo aye ni a o gba jọ sinu itanjẹ yii. A n jẹ ki awọn eniyan o simi ninu aabo eke, itusilẹ ibinu Ọlọrun nikan ni yoo ta wọn ji.ANN 250.2

  Oluwa Ọlọrun sọ pe: “Idajọ ni Emi o fi le ẹṣẹ pẹlu, ati ododo le oṣuwọn, yinyin yoo gba aabo eke lọ, omi yoo si kun bo ibi isasi mọlẹ. Majẹmu yin ti ẹ ba iku da ni a o sọ di asan, ati imulẹ yin pẹlu iboji ki yoo duro; nigba ti pasan gigun yoo rekọja, nigba naa ni oun yoo tẹ yin mọlẹ.” Aisaya 28:17, 18.ANN 250.3

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents