Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORI KARUN—JOHN WYCLIFFE

    Ṣaaju akoko Atunṣe awọn akoko kan wa ti o jẹ wipe awọn ẹda Bibeli perete ni wọn wa, ṣugbọn Ọlọrun ko jẹ ki a pa ọrọ Oun run patapata. Awọn otitọ rẹ ko le fi ara sin titi lae. O rọrun fun lati tu ọrọ iye silẹ bi o ti ṣe rọrun fun lati ṣi ilẹkun tubu silẹ, ki O ṣi awọn ilẹkun irin silẹ lati tu awọn iranṣẹ Rẹ silẹ. Ni awọn oriṣiriṣi orilẹ-ede ni Europe, Ẹmi Ọlọrun n mi si awọn eniyan lati wa otitọ bi ohun iṣura ti a ko pamọ. Agbara Ọlọrun dari wọn sinu Iwe Mimọ, wọn kọ awọn abala mimọ rẹ pẹlu ifẹ ọkan gbigbona. Wọn ṣetan lati gba imọlẹ laika ohun ti yoo ná wọn si. Bi o tilẹ jẹ wipe wọn ko le ri ohun gbogbo kedere, wọn ri ọpọ awọn otitọ ti a ti rì mọlẹ fun igba pipẹ. Bi ojiṣẹ ti a ran lati Ọrun, wọn jade lọ, wọn n ja ide aṣiṣe ati igbagbọ asan, wọn si n pe awọn ti a ti di ni igbekun fun igba pipẹ lati dide lati gba ominira wọn.ANN 33.1

    Ayafi laarin awọn Waldenses, ede ti awọn ọmọwe ni oye rẹ nikan ni a fi kọ ọrọ Ọlọrun; ṣugbọn akoko ti to lati tumọ Iwe Mimọ ki a si fifun awọn eniyan ni ilẹ gbogbo ni ede abinibi wọn. Ọganjọ oru aye ti kọja. Akoko okunkun n kọja lọ, a si n ri ami ọjọ ti n yọ ni ibi pupọ.ANN 33.2

    “Irawọ owurọ iṣẹ Atunṣe” yọ ni England ni ọrundun kẹrinla. John Wycliffe jẹ akede atunṣe, ki i ṣe fun England nikan, bikoṣe fun gbogbo ilẹ ti n ṣe ẹsin Kristẹni. A ko le pa ọrọ àtakò nla ti a gba a laaye lati sọ si Romu lẹnu mọ laelae. Atako naa ni o bẹrẹ ijijadu ti o yọri si idasilẹ ẹnikọọkan, awọn ijọ, ati awọn orilẹ ede.ANN 33.3

    Wycliffe gba ẹkọ aye, ibẹru Ọlọrun si ni o jẹ ipilẹsẹ ọgbọn fun. A da mọ ni ile ẹkọ giga fun ifọkansin, awọn ẹbun titayọ, ati ijafafa ninu iwe rẹ. Ninu ongbẹ rẹ fun imọ o fẹ lati ni oye nipa gbogbo ẹka ẹkọ. O kẹkọ nipa imọ ẹkọ ironujinlẹ, nipa awọn ofin ijọ, ati awọn ofin iṣelu, paapa julọ ti orilẹ ede rẹ. Ninu awọn iṣẹ rẹ ni ọjọ iwaju itumọ ẹkọ ti o kọ lati ilẹ wa fi ara han. Imọ kikun nipa iṣọwọronujinlẹ ti akoko rẹ ran an lọwọ lati fi awọn aṣiṣe rẹ han; nipasẹ ẹkọ rẹ nipa ofin ilu ati ti ijọ, o ṣetan lati ṣiṣẹ ninu ijakadi nla fun ominira iṣelu ati ẹsin. Nigba ti o lè lo ohun ija ti a mu jade lati inu ọrọ Ọlọrun, o ni oye ẹkọ ile iwe, o si ni oye nipa ète awọn ọmọwe. Agbara ijafafa rẹ ati okun imọ rẹ jẹ ki awọn ọta ati ọrẹ rẹ o bọwọ fun. Awọn atẹle rẹ ri pẹlu itẹlọrun wipe ọga wọn tayọ laarin awọn ọlọpọlọ pipe orilẹ ede naa; awọn ọta rẹ ko sile kẹgan iṣẹ atunṣe rẹ nipa fifi aimọkan ati ibaku oniwaasu rẹ han.ANN 33.4

    Nigba ti Wycliffe si wa ni ile ẹkọ giga, o bẹrẹ si ni i kọ ẹkọ Iwe Mimọ. Ni awọn akoko naa ti o jẹ wipe ede atijọ nikan ni a fi kọ Bibeli, awọn ọmọwe ni anfani lati de idi orisun otitọ, ṣugbọn awọn ti ko mọwe ko ni iru anfani yii. Nipa eyi ná, a ti pese ọna silẹ fun Wycliffe lati ṣe iṣẹ rẹ ni ọjọ iwaju gẹgẹ bi Alatunṣe. Awọn ọmọwe ti kẹkọ ọrọ Ọlọrun wọn si ti ri otitọ nla nipa oore ọfẹ Rẹ ti a fihan nibẹ. Ninu awọn ikọni wọn, wọn tan imọ nipa otitọ yii kálẹ, wọn si jẹ ki awọn miran o yipada si ọrọ iye.ANN 33.5

    Nigba ti Wycliffe dari iyè rẹ si Iwe Mimọ, o kọ ẹkọ rẹ pẹlu iru awofin ti o ran-an lọwọ lati ni oye ẹkọ rẹ ni ile ẹkọ. Ki o to di akoko yii, o ni imọlara àìní ti ẹkọ iwe tabi ikọni ijọ kò lè tẹ lọrun. O ri ohun ti o n ṣe òpò lasan lati ni ninu ọrọ Ọlọrun. Nibi ó ri ifihan ètò igbala, a si fi Kristi han gẹgẹ bi alagbawi kan ṣoṣo fun eniyan. O fi ara rẹ jin fun iṣẹ Kristi o si pinnu lati kede awọn otitọ ti o ri.ANN 33.6

    Bii ti awọn alatunṣe ti o tẹle, Wycliffe ko mọ ibi ti iṣe oun yoo gbé oun lọ nigba ti o n bẹrẹ rẹ. Ko mọọmọ duro lati tako Romu. Ṣugbọn ifọkansin si otitọ ko le ṣe ki o ma mu wọya ija pẹlu irọ. Bi o ti n ri awọn aṣiṣe ijọ padi daradara si, bẹẹ ni o n fi ifọkansin waasu ikọni Bibeli si. O ri wipe Romu ti kọ ọrọ Ọlọrun silẹ lati gba ikọni eniyan; laibẹru, o fi ẹsun kan awọn alufa wipe wọn ti kọ Iwe Mimọ silẹ, o sọ wipe ki a fun awọn eniyan ni Bibeli ki a si da pada si ipo alaṣẹ ninu ijọ. O jẹ olukọ ti o da ṣaka ati oniwaasu ti ẹnu rẹ yọ, igbesi aye rẹ si jẹ ifihan awọn otitọ ti o n waasu. Imọ rẹ ninu Iwe Mimọ, agbara iṣọwọronu rẹ, igbe aye iwa mimọ rẹ, ati igboya ati iṣotitọ rẹ ti ko le yẹ jẹ ki gbogbo eniyan o bọwọ fun, wọn si ni igbẹkẹle ninu rẹ. Ọpọlọpọ awọn eniyan ni igbagbọ wọn tẹlẹ ko tẹ lọrun mọ bi wọn ti n ri iwa ẹṣẹ ti o n gbilẹ ninu Ijọ Romu, wọn si gba awọn otitọ ti Wycliffe n waasu rẹ pẹlu ayọ ti wọn ko le pa mọra; ṣugbọn inu bi awọn olori ijọ paadi nigba ti wọn ri wipe Alatunṣe yii n lokiki ju wọn lọ.ANN 33.7

    Wycliffe jẹ ẹni ti o saba maa n da irọ mọ, o si fi aibẹru tako ọpọ awọn aṣiṣe ti aṣẹ Romu fi ọwọ si. Nigba ti o n ṣiṣẹ gẹgẹ bi oniwaasu fun ọba, o fi igboya tako sisan owo orí ti ọba England n san fun popu o si fi han wipe bi popu ti n lo aṣẹ lori awọn ọba tako ironu eniyan ati ifihan. Awọn ohun ti popu beere fun fa ibinu nla, awọn ikọni Wycliffe si ni ipa lori awọn adari orilẹ ede naa. Ọba ati awọn ijoye rẹ fi ohun ṣọkan lati tako bi popu ṣe n lo aṣẹ ọba, ati lati san owo ori. Bayi ni a ṣe ṣe ikọlu nla si aṣẹ popu ni England.ANN 34.1

    Iwa buburu miran ti Alatunṣe naa gbe ogun aidẹyin tì ni ẹgbẹ awọn alufa oníbárà. Awọn ọmọ ẹgbẹ yii pọ bi eṣú ni England, wọn si n ko àbàwọn bá titobi ati ọrọ aje ilẹ naa. Ibaku n de ba iṣẹ ọwọ, ètò ẹkọ ati ilana iwùwàsí. Ki i ṣe wipe igbe aye ọlẹ ati oníbárà awọn ajẹjẹ ẹsin yii n gbá ọrọ awọn eniyan lọ nìkan, ṣugbọn o n jẹ ki a gan iṣẹ ṣiṣe. O sọ awọn ọdọ di alailagbara ati oniwa-ibajẹ. Ọpọlọpọ awọn eniyan ni wọn ti ipasẹ awọn ẹgbẹ ẹsin yii wọ inu ile ẹsin ti wọn si fi ara wọn jin fun igbesi aye àdánìkàngbé, wọn n ṣe eyi laiṣe wipe awọn obi wọn fi ọwọ si, ati ni igba miran, laijẹ ki wọn mọ, tabi ni àtakò si aṣẹ wọn. Ọkan lara awọn Baba Ijọ akọkọ sọ wipe igbesi aye adanikangbe ga ju ifẹ ati ojuṣe ẹni fun ara ile ẹni lọ; o sọ wipe: “Bi baba rẹ ba dubulẹ si ẹnu ilẹkun ti o n sọkun ti o si n kigbe, ti iya rẹ si yọ ara ti o fi bi ọ silẹ ati ọyan ti o fi tọ ọ, ri i wipe o tẹ wọn mọlẹ, ki o si lọ taara si ọdọ Kristi. Nipasẹ “iwa ika alailaanu” yii, bi Luther ti ṣe pe e, “ti o jọ ti kọlọkọlọ ati ti onroro, ju ti Kristẹni ati ti eniyan lọ” ni a n gba fi sé ọkan awọn ọmọ le si awọn obi wọn. Bi awọn adari ijọ paadi, bii awọn Farisi ti igbaani, ṣe n sọ ofin Ọlọrun di asan nipasẹ ofin wọn niyi. Bayi ni a ṣe n sọ ilé di ahoro ti awọn obi kò si ni ri ibakẹgbẹ awọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin mọ.ANN 34.2

    Afihan èké awọn alufa onibara yii tan awọn ọmọ ile ẹkọ giga paapa jẹ ti wọn si da ara pọ mọ awọn ẹgbẹ wọn. Ọpọlọpọ ni wọn yipada kuro ninu igbesẹ yii, nigba ti wọn ri wipe wọn ti kó abawọn ba igbesi aye ara wọn, ti wọn si ti ko ibanujẹ ba awọn obi wọn. Ṣugbọn nigba ti wọn ba ti wọ inu ẹwọn wọn, ko le ṣe e ṣe fun wọn lati gba ominira wọn. Ọpọ obi, nitori ibẹru awọn alufa onibara, kọ lati ran awọn ọmọ wọn lọ si ile ẹkọ giga. Iye awọn akẹkọ ti wọn wa ninu awọn ile ẹkọ giga dinku gan-an ni. Awọn ile ẹkọ n jiya, aimọkan si wọpọ.ANN 34.3

    Popu ti fun awọn alufa wọnyi ni aṣẹ lati gbọ ijẹwọ ẹṣẹ ati lati dari ẹṣẹ jini. Eyi si jẹ orisun iwa buburu nla. Wọn pinnu lati jẹ ki èrè wọn o pọ si, awọn alufa wọnyi ṣetan lati funni ni idariji ẹṣẹ debi pe gbogbo ọdaran ni ibi gbogbo ni wọn n lọ si ọdọ wọn, nitori idi eyi, iwa ọdaran ti o buru jai gbilẹ si. A fi awọn alaisan ati awọn alaini silẹ lati jiya, awọn ẹbun ti a ba lo lati ran aini wọn lọwọ lọ si ọdọ awọn alufa ti wọn maa n hale mọ awọn eniyan lati le gba ẹbun lọwọ wọn, ti wọn si n bu ẹnu atẹ lu ainifọkansin awọn ti ko ba fun ẹgbẹ wọn ni ẹbun. Pẹlu bi wọn ti n sọ wipe wọn jẹ otoṣi, ọrọ awọn alufa yii tubọ n pọ si nigba gbogbo ni; awọn ile nla wọn ati tabili onjẹ aladidun wọn ṣe afihan aini orilẹ ede naa ti n pọ si. Nigba ti wọn n lo akoko wọn ninu igbadun ati faaji, wọn a ran awọn eniyan alaimọkan jade, ti wọn ko mọ ju lati pa alọ, lati sọ itan ti o yanilẹnu, ati lati ṣe ẹfẹ ti yoo pa awọn eniyan lẹrin lọ, ti wọn yoo si jẹ ki wọn tubọ jẹ òpè si ọgbọn ẹwẹ awọn alufa wọnyi si. Sibẹ awọn alufa wọnyi tubọ n ni agbara lori awọn ọpọ eniyan alaimọkan si ni, wọn n jẹ ki wọn gbagbọ wipe gbogbo ohun ti a nilo ninu iṣẹ isin ko ju ki a gba aṣẹ popu, ki a jọsin awọn eniyan mimọ ti wọn ti ku, ki a si fun awọn alufa ni ẹbun lọ, eyi to lati fun wọn ni aaye ni ọrun.ANN 34.4

    Awọn ọmọwe ati olufọkansin ti ṣiṣẹ laini ayọrisi lati ṣe atunṣe ninu awọn ẹgbẹ ajẹjẹ ẹsin wọnyi; ṣugbọn Wycliffe, pẹlu oye ti o yè kooro kọlu gbongbo iwa ibi naa, o sọ wipe ilana naa funra rẹ jẹ irọ ati wipe wọn nilati pa a rẹ. Ijiroro ati iwadi ba bẹrẹ. Bi awọn alufaa yii ti n la orilẹ ede naa kọja, ti wọn n ta idariji popu, ọpọlọpọ wa n ṣe iyemeji boya o ṣe e ṣe lati ra idariji ẹṣẹ pẹlu owo, wọn wa n beere boya o yẹ ki wọn wa idariji lati ọdọ Ọlọrun dipo lati ọdọ alufa Romu. Ọpọlọpọ ni ẹnu yà nitori ilọnilọwọgba awọn alufaa yii, awọn ti o dabi ẹnipe iwa wọbia wọn ko ṣe e tẹ lọrun. Wọn sọ wipe: “Awọn ajẹjẹ ẹsin ati alufa Romu n jẹ wa bi aisan jẹjẹrẹ. Ọlọrun nilati gba wa, tabi ki awọn eniyan o ṣegbe.” Lati le fi iwa ojukokoro wọn yii pamọ, awọn ajẹjẹ ẹsin oníbárà yii n sọ wipe wẹn n tẹle apẹẹrẹ Olugbala ni, wọn n sọ wipe oju rere awọn eniyan ni o gbe Jesu ati awọn ọmọ ẹyin Rẹ ró. Oro yii ni o ko ijamba ba iṣe wọn, nitori ti o dari ọpọlọpọ awọn eniyan sinu Bibeli lati kọ nipa otitọ funra wọn— ayọrisi eyi ti Romu ko fẹ rara. Ọkan awọn eniyan yi si Orisun otitọ, eyi ti i ṣe erongba rẹ lati fi pamọ.ANN 34.5

    Wycliffe bẹrẹ si ni i kọ iwe pelebe o si n tẹ ẹ jade lati fi tako awọn alufa oníbárà naa, ki i ṣe lati ba wọn wọ inu ariyanjiyan, bikoṣe lati dari ọkan awọn eniyan si awọn ẹkọ inu Bibeli ati si Ẹni ti O kọ ọ. O sọ wipe agbara lati darijini tabi agbara lati léni kuro ninu ijọ wa lọwọ popu ni iwọn kan naa ti o fi wa lọwọ awọn alufa lasan, ati pe ko si ẹni ti a lè lé kuro ninu ijọ ayafi bi o ba ti kọkọ fa idajọ Ọlọrun wa si ori ara rẹ. Ko si ọna ti o dara ju eyi lọ lati bi ajaga ẹmi ati ti ara eyi ti popu gbe kalẹ ti a si fi di ọpọlọpọ ni igbekun ni emi ati ni ara wó.ANN 35.1

    A pe Wycliffe lati wa wi awijare nipa ẹtọ ọba England lati tako ijẹgaba Romu; nitori pe o je aṣoju ọba, o lo ọdun meji ni Netherlands ninu apero pẹlu awọn aṣoju popu. Nibi o ni ijiroro pẹlu awọn oloye ijọ lati France, Italy, ati Spain, o tun ni anfani lati ri ohun ti o n ṣẹlẹ ni ikọkọ, o si ni oye nipa ọpọlọpọ awọn nnkan ti i ba ṣokunkun si ni England. O kọ nipa awọn ohun ti yoo fun iṣẹ rẹ lokun ni ọjọ iwaju. O kọ nipa afojusun ati bi awọn ilana ijọ ti ri gan-an ninu awọn aṣoju ti wọn wa lati aafin popu wọnyi. O pada si England lati tẹnumọ awọn ikọni rẹ tẹlẹ pẹlu itara ti o pọ si, o n sọ wipe, ojukokoro, igberaga ati ẹtan ni awọn ọlọrun Romu.ANN 35.2

    Ninu ọkan ninu awọn iwe pelebe rẹ, o sọ nipa popu ati awọn ti n ba gba owo ni ọna yii: “Wọn n ko onjẹ oojọ awọn alaini ati ẹgbẹẹgbẹrun lati inu owo ọba kuro ni ilẹ wa lọdọọdun fun ami majẹmu ati awọn ohun ẹmi, ti ẹkọ odi ríra ohun ẹmi ti a fi gegun, ti o si n jẹ ki gbogbo awọn Kristẹni o fi ọwọ si ẹkọ odi yii ti wọn si i n gbe larugẹ. Ti o fi jẹ pe bi o tilẹ jẹ wipe agbegbe wa ni òkè nla ti o kun fun wura, ẹnikẹni ko gbọdọ fi ọwọ kan-an ayafi awọn alufa alafẹ aye agberaga wọnyi; bi akoko ṣe n lọ, oke yii yoo tan; nitori gbogbo igba ni o n ko owo jade kuro ni ilẹ wa, ti ko si da ohunkohun pada ayafi egun Ọlọrun fun idokoowo ninu ohun ẹmi yii.”ANN 35.3

    Laipẹ ti o pada wa si England, Wycliffe gba ipe lati ọdọ ọba lati jẹ olori ile ijọsin ti Lutterworth. Eyi jẹ idaniloju wipe ọba koi ti i binu si isọwọ-sọ-otitọ rẹ. Ari ipa Wycliffe ninu awọn ipinu ti wọn n ṣe ninu aafin ọba, ati ninu awọn igbagbọ orilẹ ede naa.ANN 35.4

    Laipẹ awọn ijọ paadi kọju ibinu si. A rán aṣẹ mẹta wa si England—si ile ẹkọ giga, si ọba ati si awọn alufa,—ti gbogbo wọn n paṣẹ pe ki a ṣa gbogbo ipa lati pa ẹlẹkọ odi yii lẹnu mọ. Ki aṣẹ yii to de, awọn biṣọbu, ninu itara wọn, ti pe Wycliffe siwaju wọn fun igbẹjọ. Ṣugbọn meji ninu awọn ijoye ti wọn lagbara julọ ninu ijọba naa ni wọn tẹle wa si ibi igbẹjọ; ẹru ba awọn adajọ naa ti o fi jẹ wipe wọn dawọ eto igbẹjọ naa duro nigba ti o ṣe, nitori ọpọ awọn eniyan ti wọn yi ile igbẹjọ naa ka, ti wọn lọ ti wọn si n bọ, a jẹ ki o maa lọ ni alaafia. Laipẹ pupọ, Edward III, ẹni ti awọn alufa n wa ọna lati yi ọkan rẹ pada ni atako si Alatunṣe naa ni ọjọ ogbó rẹ ku, ẹni ti o n daabo bo Wycliffe tẹlẹ wa di adele fun ijọba naa.ANN 35.5

    Ṣugbọn awọn aṣẹ ti popu ran wa si gbogbo England ti o si fẹ ki a muṣẹ kankan sọ wipe ki a mu ẹlẹkọ odi naa ki a si ti i mọle. Awọn aṣẹ wọnyi n tọka taara si ibi ìdánásunni. O dabi ẹnipe Wycliffe yoo subu bi ẹran ijẹ si ọwọ ibinu igbẹsan Romu. Ṣugbọn Ẹni ti O sọ fun ẹni igba atijọ ni wipe, “Ma bẹru: . . . Emi ni apata rẹ” (Jẹnẹsisi 15:1), tun na ọwọ Rẹ lati daabo bo iranṣẹ Rẹ. Ki i ṣe Alatunṣe naa ni iku mu lọ, bikoṣe popu ti o paṣẹ iparun rẹ. Gregory XI ku, awọn alufa ti wọn pejọ pọ lati ṣe igbẹjọ Wycliffe si tu ka.ANN 35.6

    Agbara Ọlọrun tun ṣiṣẹ ninu awọn iṣẹlẹ ni ọna ti o fun iṣẹ Atunṣe ni anfani lati dagba. A yan popu meji ti wọn jijọ n figagbaga si ori oye lẹyin iku Gregory. Awọn agbara meji ti wọn n kọju ija si ara wọn yii, ti olukuluku si n sọ wipe òhun ko le baku wa n fẹ ki a ṣe igbọran si wọn. Olukuluku wọn n pe awọn olootọ lati ran oun lọwọ lati ba ikeji ja, wọn n fi egun buburu ti aṣẹ wọn lati tako ẹnikeji wọn lẹyin, wọn si n ṣe ileri ẹbun ni ọrun fun awọn atẹle won. Iṣẹlẹ yii ko ibaku nla ba agbara ijọ padi. Awọn ẹgbẹ mejeeji yii ṣe ohun gbogbo ti o wa ni ikawọ wọn lati kọ oju ija si ara wọn, fun igba diẹ, Wycliffe ni akoko fun isinmi. Egun ati ifẹsunkanni n kọja lọ lati ọdọ popu kan si ikeji, ti àgbàrá ẹjẹ si n san lati le fi idi ọrọ wọn mulẹ. Rogbodiyan ati iwa ọdaran gbilẹ kan ninu ijọ. Ṣugbọn Alatunṣe naa ninu idakẹjẹ rẹ ni ile ijọsin rẹ ni Lutterworth n ṣiṣẹ takuntakun lati yi oju awọn eniyan kuro ni ọdọ awọn popu ti n ba ara wọn ja si ọdọ Jesu, Ọmọ alade Alaafia.ANN 36.1

    Iyapa yii, pẹlu gbogbo rogbodiyan ati iwa ibajẹ ti o fa, pese ọna silẹ fun iṣẹ Atunṣe nipa fifun awọn eniyan ni anfani lati ri ohun ti ijọ padi jẹ gan-an. Ninu iwe pelebe kan ti o tẹ jade, On the Schism of the Popes, (Lori iyapa laarin awọn Popu) Wycliffe pe gbogbo awọn eniyan lati wo o boya awọn alufa mejeeji yii ko sọ otitọ ni pipe ara wọn ni asodi si Kristi. O sọ wipe, “Ọlọrun ko ni jẹ ki ẹmi eṣu o jọba ninu alufa kan ṣoṣo mọ, ṣugbọn . . . O mu iyapa ba awọn meji, ki awọn eniyan, ni orukọ Kristi, le bori wọn pẹlu irọrun.”ANN 36.2

    Wycliffe, bi i ti Ọga rẹ, waasu iyinrere si awọn otoṣi. Titan imọlẹ naa ka ninu ile awọn ọmọ ijọ rẹ ni Lutterworth ko tẹ ẹ lọrun, o pinnu pe a nilati tan an ka gbogbo England. Lati le ṣe eyi, o ko ẹgbẹ oniwaasu jọ, awọn ti wọn jẹ olootọ ati olufọkansin, ti wọn fẹran otitọ, ti wọn si fẹran ki wọn tan an kalẹ ju ohunkohun lọ. Awọn wọnyi lọ si ibi gbogbo, wọn n kọni ni aarin ọja, ni awọn adugbo awọn ilu nla, ati ninu awọn ileto. Wọn wa awọn arugbo, awọn alaisan, ati awọn otoṣi lọ, wọn si n ṣi iroyin ayọ oore ọfẹ Ọlọrun fun wọn.ANN 36.3

    Gẹgẹ bi ọjọgbọn ninu ẹkọ ọrọ Ọlọrun ni Oxford, Wycliffe n waasu ọrọ Ọlọrun ninu awọn gbọngan ile ẹkọ giga naa. O fi tọkantọkan waasu otitọ fun awọn akẹkọ abẹ rẹ debi pe wọn fun ni àpèlé “oniṣegun iyinrere.” Ṣugbọn iṣẹ rẹ ti o tobi julọ ni bi o ti ṣe itumọ Iwe Mimọ si ede oyinbo. Ninu iṣe kan ti o pe ni, On the Truth and Meaning of the Scripture, (Lori Otitọ ati Itumọ Iwe Mimọ) o sọ nipa erongba rẹ lati ṣe itumọ Bibeli, ki gbogbo eniyan ni England ba a le ka iṣẹ iyanu Ọlọrun ni ede ti a gbe bi wọn.ANN 36.4

    Ṣugbọn lojiji a da iṣẹ rẹ duro. Bi o tilẹ jẹ wipe koi ti i to ọmọ ọgọta ọdun, iṣẹ àṣeìwẹyìn, ẹkọ, ati ipenija awọn ọta rẹ ṣe e lópò, wọn si jẹ ki o di arugbo laitọjọ. Aisan ti o lewu ni o kọ lu u. Iroyin yii mu ayọ ba awọn alufa onibara. Ni akoko yii, wọn ro wipe yoo ronupiwada nitori iwa ibi ti o wu si ijọ, wọn si yara kankan lọ si iyẹwu rẹ lati lọ gbọ ijẹwọ ẹṣẹ rẹ. Awọn aṣoju lati inu ẹgbẹ ẹsin mẹrẹẹrin, pẹlu awọn alakoso mẹrin ni wọn yi ọkunrin ti wọn ro wipe o n ku lọ yii ka. Wọn sọ wipe: “Iku ni o wa ni ẹnu rẹ yii, jẹ ki awọn aṣiṣe rẹ o fi ọwọ ba ọ lọkan, ki o si ko awọn ọrọ ti o ti sọ ni ipalara wa jẹ niwaju wa.” Alatunṣe naa tẹti silẹ pẹlu idakẹjẹ; o ni ki awọn ti wọn n tọju òhun o gbe oun dide joko ni ori ibusun oun, o tẹ oju mọ wọn bi wọn ti n reti ki o ko ọrọ rẹ jẹ, pẹlu ohùn nla ti o maa n dẹru ba wọn, o sọ wipe: “Emi ki yoo ku bikoṣe yiye; lati kede iwa ibi awọn alufa oníbárà.” Pẹlu itiju ati iyalẹnu, awọn alufa wọnyi yára kankan kuro ninu iyẹwu rẹ.ANN 36.5

    Awọn ọrọ Wycliffe wa si imuṣẹ. O wa laaye lati fi ohun ija ti o lagbara julọ lati kọju ija si Romu le ọwọ awọn ọmọ orilẹ ede rẹ lọwọ—lati fun wọn ni Bibeli, aṣoju ti Ọrun yan lati ṣe itusilẹ, ilalọyẹ ati ijere ọkan awọn eniyan. Awọn idena ti wọn tobi ti wọn si pọ ni o wa lati la kọja lati le ṣe iṣẹ yii. Aisan bo Wycliffe mọlẹ; o mọ wipe ọdun diẹ ni o ku fun ohun lati ṣiṣẹ; o ri awọn atako ti yoo doju kọ; ṣugbọn o tẹsiwaju laibẹru, pẹlu atilẹyin awọn ileri ọrọ Ọlọrun. Pẹlu okun agbara ironu rẹ ti o peye, ti o si kun fun iriri, agbara Ọlọrun pataki ti pa a mọ, o si ti pese rẹ silẹ fun eleyii, eyi ti o tobi julọ ninu awọn iṣẹ rẹ. Nigba ti rogbodiyan gba awọn ilẹ ti n ṣe ẹsin Kristẹni kan, Alatunṣe naa, ni ibi iṣẹ rẹ ni Lutterworth, laikọbi ara si iji ti n ja ni ìta, fi ara rẹ jin fun iṣẹ ti o yan laayo.ANN 36.6

    Lẹyin-ọrẹyin, iṣẹ naa pari—Bibeli akọkọ ti a tumọ ni ede Gẹẹsi. A ṣi ọrọ Ọlọrun silẹ fun England. Alatunṣe naa ko bẹru ina tabi ọgba ẹwọn mọ nisinsinyii. O ti gbe ina ti a ko le pa ku si ọwọ awọn eniyan England. Ni fifun awọn eniyan orilẹ ede rẹ ni Bibeli, o ṣe iṣẹ lati ja ẹwọn aimọkan ati iwa ibajẹ, lati tu orilẹ ede rẹ silẹ ati lati fa wọn soke, ju eyi ti iṣẹgun ti o dara julọ lori papa ogun le ṣe lọ.ANN 37.1

    Nitori ti a koi ti i jagbọn iwe titẹ, nipasẹ iṣẹ ti n yọlẹ to si n ko aarẹ bani nikan ni a file sọ ẹda Bibeli di pupọ. Ifẹ awọn eniyan lati ni iwe naa pọ debi pe ọpọlọpọ ni wọn fi tayọtayọ funra wọn da a kọ, ṣugbọn pẹlu inira ni awọn ti n da a kọ fi le fun awọn ti wọn fẹ ra a ni iye ti wọn n fẹ. Diẹ lara awọn ọlọrọ ti wọn fẹ ra a fẹ lati ni gbogbo Bibeli naa. Awọn miran fẹ abala diẹ. Ni ọpọlọpọ igba awọn idile diẹ a para pọ lati ra odindi kan. Bayi ni Bibeli Wycliffe ṣe ri aaye wọ inu ile awọn eniyan.ANN 37.2

    Ipenija lati ronu ji wọn dide kuro ninu gbigba awọn ẹkọ ijọ paadi laiwoye. Wycliffe wa n kọni ni awọn ikọni ti wọn mu ki igbagbọ Protestant o yatọ—igbala nipa igbagbọ ninu Kristi, ati wipe Iwe Mimọ nikan ni ko le baku. Awọn oniwaasu ti o ran jade pin Bibeli ati awọn iwe Alatunṣe naa ka, wọn si ṣe aṣeyọri debi pe idaji awọn eniyan England ni wọn fẹrẹ gba igbagbọ tuntun yii.ANN 37.3

    Bi Iwe Mimọ ti jade kó iporuuru ọkan ba awọn alaṣẹ ijọ. Bayi wọn nilati doju kọ aṣoju ti o lagbara ju Wycliffe lọ—aṣoju ti ohun ija wọn kò lè ni agbara lé lórí. Ko si ofin kankan ti o de Bibeli ni England ni akoko yii, nitori ti a koi tii tẹ ẹ jade ni ede awọn eniyan ri. A ṣe iru awọn ofin wọnyi nigba ti o yá, a si lo wọn gidigidi. Sibẹsibẹ, pẹlu gbogbo awọn akitiyan awọn alufa, fun igba diẹ, akoko wa lati pin ọrọ Ọlọrun kaakiri.ANN 37.4

    Awọn adari ijọ paadi tun pa ète miran lati pa Alatunṣe naa lẹnu mọ. A pe e siwaju igbimọ igbẹjọ lẹẹmẹta ni sisẹ n tẹle, ṣugbọn wọn ko ri aṣeyọri kan. Ni akoko igbimọ awọn biṣọbu sọ wipe awọn iwe rẹ ni ẹkọ odi, nipa jijere ọba ọdọmọde ni, Richard II si ọdọ wọn, wọn gba aṣẹ ọba lati ti gbogbo awọn ti wọn ba gbagbọ ninu awọn ikọni ti a ko fẹ yii mọlé.ANN 37.5

    Wycliffe pe ẹjọ kotẹmilọrun lati ọdọ igbimọ awọn biṣọbu lọ si ile igbimọ aṣofin; laibẹru, o pe awọn oloye ijọ lẹjọ niwaju igbimọ orilẹ ede, o si beere ki a ṣe atunṣe si awọn aṣiṣe nla ti ijọ fi ọwọ si. Pẹlu agbara ifọrọyeni, o fi ijẹgaba ati iwa ibajẹ ijọ paadi han. Idarudapọ de ba awọn ọta rẹ. A ti fi ipa mu awọn ọrẹ ati alatilẹyin Wycliffe lati fa sẹyin, a si ti fi igboya reti wipe Alatunṣe naa, ni ọjọ ogbé rẹ, laini ọrẹ ati ni ohun nikan, yoo tẹriba fun apapọ aṣẹ ọba ati ti ijọ. Ṣugbọn dipo eyi, awọn atẹle popu ni wọn ri ijakulẹ. Igbimọ aṣofin taji si awọn ọrọ alagbara ti Wycliffe sọ, wọn yi aṣẹ oninunibini naa pada, Alatunṣe naa si wa ni ominira.ANN 37.6

    A tun pe e fun igbẹjọ ni igba kẹta, ni akoko yii, siwaju ajọ igbẹjọ ẹsin ti o ga julọ ni orilẹ ede naa. Nibi a ko ni fi aanu han fun ẹkọ odi. Romu yoo ri iṣẹgun nibi ni ikẹyin, a o si dawọ iṣẹ Alatunṣe naa duro. Bi awọn atẹle popu ti rò niyi. Bi wọn ba le mu erongba wọn ṣẹ, yoo pan dandan fun Wycliffe lati yan boya ki o kọ awọn ikọni rẹ silẹ, tabi ki o fi aafin silẹ lọ si inu ina.ANN 37.7

    Ṣugbọn Wycliffe ko yi ọrọ rẹ pada; ko ni dibọn. Laifoya o fi idi awọn ikọni rẹ mulẹ o si fọn awọn ẹsun ti awọn oninunibini rẹ fi kan-an kaá. Laiwo ara rẹ, ipo rẹ, ati ibi ti o wa, o pe awọn olugbọ reẹ siwaju ibujoko igbẹjọ Ọlọrun, ki wọn si wọn ẹtan ati arumọjẹ wọn wo ninu iwọn otitọ ayeraye. A ni imọlara agbara Ẹmi Mimọ ninu yara igbimọ naa. Agbara lati ọrun wa ṣubu lu awọn olugbọ rẹ. O dabi ẹnipe wọn ko ni agbara lati kuro nibẹ. Ọrọ Alatunṣe naa wọ inu ọkan wọn bi ọfa lati inu apó Oluwa. Pẹlu agbara iṣọwọsọrọ ti o ga o da ẹsun ẹkọ odi ti a fi kan-an pada lu wọn. O beere, kini o fun wọn ni igboya lati tan awọn aṣiṣe wọn kalẹ? Nitori èrè, ẹ n ta oore ọfẹ Ọlọrun?ANN 37.8

    Nikẹyin, o sọ pe “Tani ẹ ro wipe ẹ n ba ja? agbalagba ti o ti sunmọ eti iboji? Rara! pẹlu Otitọ—Otitọ ti o tobi ju yin lọ, yoo si bori yin.” Lẹyin ti o sọ eyi tan, o kuro ninu ajọ naa, kò sì sí ọkan ninu awọn ọta rẹ ti o da a duro.ANN 38.1

    Iṣẹ Wycliffe ti fẹrẹ pari; ọpagun otitọ ti o ti gbe fun igba pipẹ yoo bọ kuro ni ọwọ rẹ laipẹ; ṣugbọn lẹẹkan si yoo ṣe ijẹri si iyinrere. A yoo polongo otitọ naa ni ile iṣọ agbara ijọba ẹtan. A pe Wycliffe lati wa jẹjọ niwaju igbimọ igbẹjọ popu ni Romu, igbimọ ti o ti fi ọpọ igba ta ẹjẹ awọn eniyan mimọ silẹ. Ko ṣe aimọkan nipa ewu ti o fẹ wu u, sibẹ i ba lọ bi kii ba ṣe gìrì arun ẹgba ti o di i lọwọ lati lọ si irin ajo naa. Ṣugbọn bi o tilẹ jẹ wipe a ko ni gbọ ohùn rẹ ni Romu, o le sọrọ pẹlu lẹta, eyi ni o si pinnu lati ṣe. Lati inu ile ijọsin rẹ, Alatunṣe naa kọ iwe si popu, eyi ti o kọ pẹlu apọnle ati ẹmi Kristẹni, ṣugbọn ti o ṣe ibawi ti o nipọn si iwuga ati igberaga popu.ANN 38.2

    O sọ wipe, “Nitootọ inu mi dun lati kede igbagbọ ti mo gba fun gbogbo eniyan, ati ni pataki julọ si biṣọbu Romu: nitori bi mo ti ro wipe o peye ti o si jẹ otitọ, yoo fi tọkantọkan fi idi igbagbọ mi yii mulẹ, tabi bi o ba jẹ èké, yoo ṣe atunṣe rẹ.ANN 38.3

    “Ni akọkọ, emi ro wipe iyinrere Kristi ni akotan gbogbo ofin Ọlọrun. . . . Emi si ro wipe biṣọbu Romu, niwọn igba ti o jẹ wipe oun ni aṣoju Kristi ni aye yii, yoo ṣe igbọran si ofin iyinrere yii ju ẹnikẹni lọ. Nitori titobi laarin awọn ọmọ ẹyin Kristi kii ṣe nipa ọla ati ọrọ aye yii, ṣugbọn ni sisunmọ ati titẹle Kristi ninu igbesi aye ati iwa Rẹ laiyẹsẹ. . . . Ni akoko irin ajo Rẹ nihin yii, Kristi jẹ otoṣi; O ṣaata iṣakoso ati ọrọ aye, O si korira rẹ. . . .ANN 38.4

    “Ko si onigbagbọ kan ti o yẹ ki o tẹle popu funra rẹ tabi eyikeyi ninu awọn eniyan mimọ, ayafi ni bi o ba ṣe tẹle Jesu Kristi Oluwa; nitori Peteru ati awọn ọmọ Sebede, nipa fifẹ ọrọ aye, eyi ti o tako apẹẹrẹ Kristi, wọn dẹṣẹ, nitori naa a ko gbọdọ tẹle wọn ninu awọn aṣiṣe wọnyi. . . .ANN 38.5

    “O yẹ ki Popu o fi gbogbo aṣẹ ati iṣakoso aye silẹ fun awọn alaṣẹ aye, ki o si gba gbogbo awọn alufa rẹ niyanju daradara lati ṣe bẹẹ; nitori bẹẹ ni Kristi ati ni paapa julọ awọn apostoli Rẹ ti ṣe. Nitori naa bi mo ba ṣẹ ninu awọn nnkan wọnyi, mo fi tọwọtọwọ tẹriba lati ṣe atunṣe, ani titi de iku bi a ba nilo lati ṣe bẹẹ; bi mo ba sile fi ara mi ṣiṣẹ gẹgẹ bi ero ọkan tabi ifẹ mi, n ba funra ra mi wa siwaju biṣọbu Romu; ṣugbọn Ọlọrun bẹmiwo ni ọna ti o yatọ, O si ti kọ mi lati ṣe igbọran si Ọlọrun ju eniyan lọ.”ANN 38.6

    Ni akotan o sọ wipe: “Ẹ jẹ ki a gbadura si Ọlọrun wa, ki o ru ọkan Popu wa Urban VI soke, bi o ti bẹrẹ, wipe ki oun pẹlu awọn alufa rẹ le tẹle Jesu Kristi Oluwa ninu iwa ati iṣe; ki wọn ba a le kọ awọn eniyan daradara, ki awọn pẹlu le fi otitọ tẹle apẹẹrẹ wọn lati ṣe bẹẹ.”ANN 38.7

    Ọna yii ni Wycliffe gba lati fi irẹlẹ ati ọkan tutu Kristi han popu ati awọn kadina rẹ, o fi iyatọ ti o wa laarin wọn ati Ọga ti wọn n sọ wipe wọn jẹ aṣoju Rẹ han wọn ati gbogbo awọn Kristẹni.ANN 38.8

    Wycliffe ni ireti kikun wipe ẹmi oun ni yoo jẹ ohun ti oun yoo fi silẹ nitori iṣotitọ oun. Ọba, popu ati awọn biṣọbu parapọ lati wa iparun rẹ, o si dabi ẹnipe lẹyin oṣu diẹ, a o mu lọ si ibi ti a o ti dana sun-un. Ṣugbọn ọkan rẹ kò mì. O sọ wipe, “Kilo de ti ẹ n sọrọ nipa wiwa ade ajẹriku ni ọna jijin rere?” “Ẹ waasu iyinrere Kristi si awọn alufa onigberaga, ijẹriku ko si ni baku lati ba a yin. En! Ki n wa laaye, ki n si dakẹ? . . . Rara o! Ẹ jẹ ki wahala o wa, mo duro de e.”ANN 38.9

    Ṣugbọn agbara Ọlọrun tun daabo bo iranṣẹ Rẹ. Ẹni ti o fi gbogbo ọjọ aye rẹ fi igboya gbeja otitọ, pẹlu ewu ti o n wu ẹmi rẹ lojoojumọ, ko ni ṣubu labẹ ikorira awọn ọta rẹ. Wycliffe ko ṣa ipa lati daabo bo ara rẹ, ṣugbọn Oluwa ni o jẹ aabo rẹ; bayi nigba ti awọn ọta rẹ ri daju wipe wọn ni ẹran ijẹ wọn ni ikawọ wọn, Ọlọrun mu kuro ni arọwọto wọn. Ninu ile ijọsin rẹ ni Lutterworth, bi o ti fẹ pin ara Oluwa, o ṣubu nigba ti arun ẹgba kọ lu u, lẹyin akoko diẹ, o ku.ANN 38.10

    Ọlọrun ti fun Wycliffe ni iṣẹ rẹ. O fi ọrọ otitọ si lẹnu, o si daabo bo o ki ọrọ yii le de ọdọ awọn eniyan. A daabo bo ẹmi rẹ, a si jẹ ki iṣẹ rẹ o gun, titi ti a fi fi ipilẹ iṣẹ nla ti Atunṣe lelẹ.ANN 39.1

    Wycliffe wá lati inu okunkun Igba Oju Dudu. Ko si ẹni ti o ṣiṣẹ ṣaaju rẹ ti o le fi ṣe awokọṣe ilana atunṣe tirẹ. A gbe dide gẹgẹ bi Johanu Onitẹbọmi lati ṣe iṣẹ pataki kan, o nilati kede igba ọtun. Sibẹ ilana otitọ ti o gbe kalẹ peye o si wa ni iṣọkan; ti awọn Alatunṣe ti wọn tẹle ko kọja rẹ, awọn miran ko tilẹ de bẹ ani lẹyin ọgọrun ọdun. Ipilẹ ti a gbe kalẹ naa jin o si fẹ, ilana naa lagbara o si jẹ otitọ, ti o fi jẹ wipe awọn ti wọn wa lẹyin rẹ ko nilo lati tun un kọ.ANN 39.2

    Ẹgbẹ nla ti Wycliffe ko jọ, ti yoo ṣe idande fun ọkan ati oye awọn eniyan, ti yoo tu awọn orilẹ ede ti a ti de mọ ọkọ iṣẹgun Romu fun igba pipẹ silẹ, ní ipilẹ rẹ ninu Bibeli. Nibi ni a ti ri orisun omi iye ibukun, ti o san lati ọrundun kẹrinla titi de ọjọ iwaju, bi omi iye. Wycliffe fi igbagbọ gba Iwe Mimọ gẹgẹ bi ifihan ifẹ Ọlọrun ti a mi si, eyi ti o to lati ṣe odiwọn igbagbọ ati iṣesi. A ti kọ ọ lati ri Ijọ Romu gẹgẹ bi aṣẹ Ọlọrun ti ko le baku, ki o si fi tọwọtọwọ gba awọn ikọni ati aṣa ti a ti fi lelẹ fun ọpọ ọdun lai ni ibeere; ṣugbọn o yi oju kuro ninu gbogbo awọn nnkan wọnyi lati tẹti si ọrọ mimọ Ọlọrun. Aṣẹ yii ni o n rọ awọn eniyan lati gbà. Dipo ijọ ti o n sọrọ nipasẹ popu, o sọ wipe aṣẹ tootọ ni ohùn Ọlọrun ti n sọrọ nipasẹ ọrọ Rẹ. O tun kọ awọn eniyan wipe, ki i ṣe wipe Bibeli jẹ ifihan pipe nipa ifẹ Ọlọrun nikan, ṣugbọn Ẹmi Mimọ nikan ṣoṣo ni olutumọ rẹ, ati wipe gbogbo eniyan nilati kọ nipa ojuṣe ara rẹ funra rẹ nipa kikọ awọn ikọni rẹ. Ọna yii ni o gba lati yi ọkan awọn eniyan pada kuro ni ọdọ popu ati Ijọ Romu si inu ọrọ Ọlọrun.ANN 39.3

    Wycliffe jẹ ọkan lara awọn Alatunṣe ti wọn tobi julọ. Ni titobi laakaye, ni iṣọwọ ronu ti o mọ gaara, ni diduro gbọin pẹlu otitọ, ati ni gbigbeja rẹ pẹlu igboya, awọn perete ni wọn dabi rẹ ninu awọn ti wọn tẹle. Igbe aye iwa mimọ, aikaarẹ ninu ẹkọ ati iṣẹ, iṣotitọ ti ko le ṣègbè ati ifẹ bi i ti Kristi ati iṣotitọ ninu iṣẹ iranṣẹ ni wọn jẹ iwa Alatunṣe akọkọ. O si ni gbogbo iwọnyi pẹlu aimọkan ati iwa ibajẹ ti wọn gbilẹ kan ni akoko ti o dide.ANN 39.4

    Iwa Wycliffe jẹ ẹri si agbara Iwe Mimọ lati kọni ati lati yi ni lọkan pada. Bibeli ni o sọ ọ da ẹni ti o jẹ. Agbara lati ni oye awọn otitọ nla ifihan n fun ọgbọn orí ni isọdọtun ati agbara. O n lani lọyẹ, o n sọ ironu di pipe, o si n muni ṣe ipinu ti o mu ọgbọn dani. Ẹkọ Bibeli yoo gbe gbogbo ero, ifẹ ọkan ati afojusun eniyan ga ju eyikeyi ninu ẹkọ miran ti a le kọ lọ. O n fi idi erongba mulẹ, o n fun ni ni igboya, suuru, ati ipamọra; o n sọ iwa di ọtun o si n sọ ọkan di mimọ. Kikọ ẹkọ Iwe Mimọ tọwọtọwọ pẹlu ifọkansin, gbigbe oye akẹkọ wá tààrà siwaju òye ayereye, yoo fun araye ni awọn eniyan ti òye wọn gbooro ti o si n ṣiṣẹ, ti wọn ni erongba ti o dara, ju eyi ti ẹkọ ti o ga julọ ninu imọ eniyan le fun ni lọ. OniO. Dafidi nì wipe, “Ifihan ọrọ Rẹ funni ni imọlẹ; o n fi oye fun awọn òpè.” O. Dafidi 119:130.ANN 39.5

    Awọn ẹkọ ti Wycliffe fi kọni n tan kalẹ lẹyin igba diẹ; awọn atẹle rẹ ti a mọ si Wycliffites ati Lollards, kò rìn kaakiri England nikan, ṣugbọn wọn fọn kaakiri lọ si awọn ilẹ miran, wọn gbe imọ iyinrere pẹlu wọn. Ni akoko yii ti a ti mu adari wọn kuro, awọn oniwaasu naa ṣiṣẹ pẹlu itara ti o ju ti tẹlẹ lọ, ti ọpọlọpọ si n rọ wá lati gbọ ikọni wọn. Awọn ọlọrọ, ani iyawo ọba, wa lara awọn ti wọn jèèrè ọkan wọn. Ni ọpọlọpọ ilu, a ri ami atunṣe ti o han gedegbe ninu iṣesi awọn eniyan, a si mu awọn ami ibọriṣa ẹsin Romu kuro ninu awọn ile ijọsin. Ṣugbọn laipẹ, ìjì inunibini ti ko laanu bì lu awọn ti wọn ni igboya lati gba Bibeli gẹgẹ bi atọna wọn.ANN 39.6

    Lati le fi idi agbara wọn mulẹ nipa titẹle Romu, awọn ọba England ko lọra lati kọ oju ija si awọn Alatunṣe. Fun igba akọkọ ninu itan England, a pa aṣẹ lati dana sun awọn atẹle iyinrere. Ijẹriku n tẹle ijẹriku. Ọlọrun awọn ọmọ ogun nikan ni awọn akede otitọ ti a n da lẹbi ti a si n jẹniya lè kigbe si. A n dọdẹ wọn bi ọta ijọ ati aṣọtẹ si ilu, wọn tẹsiwaju lati waasu ninu awọn ibi ti o fi ara sin, wọn n ri ibugbe ninu ile awọn talaka, wọn si n sapamọ sinu awọn iho inu ilẹ ati iho inu apata ni ọpọlọpọ igba.ANN 39.7

    Laika ibinu inunibini si, igbogunti iwa ibajẹ ninu ẹsin igbagbọ ti o wọpọ ni akoko naa n lọ pẹlu suuru, ifọkansin ati laisi ariwo fun ọpọ ọdun. Oye awọn Kristẹni nipa otitọ ni akoko naa ko kun tó, ṣugbọn wọn kọ lati fẹran ati lati ṣe igbọran si ọrọ Ọlọrun,wọn si fi suuru jiya nitori rẹ. Bi awọn ọmọ ẹyin ni akoko awọn apostoli, ọpọlọpọ ni wọn padanu ọrọ aye nitori iṣẹ Kristi. Awọn ti a gba laaye lati gbe ninu ibugbe wọn fi tayọtayọ gba awọn arakunrin wọn ti a le jade si ile wọn, nigba ti a ba si le awọn naa sita, wọn a fi tayọtayọ gba ìpín awọn alarinkiri. Lootọ ni wipe ọpọlọpọ ni wọn bẹru nitori ibinu awọn oninunibini, ti wọn kọ igbagbọ wọn silẹ lati le gba ominira wọn, ti wọn jade kuro ninu ọgba ẹwọn pẹlu aṣọ ironupiwada lọrùn lati kede ironupiwada wọn. Ṣugbọn ki i ṣe awọn eniyan perete—laarin awọn ọlọrọ ati awọn otoṣi—ni wọn fi igboya jẹri si otitọ ninu ile tubu, ninu “awọn ile Lollard,” ati laarin ifiyajẹni ati ninu ina, ti wọn n yọ wipe a ka wọn yẹ lati mọ “ibakẹgbẹ ijiya Rẹ.”ANN 40.1

    Awọn ọmọ ijọ paadi kuna lati ṣe ifẹ inu wọn si Wycliffe nigba aye rẹ, wọn ko sile tẹ ikorira wọn lọrun nigba ti ara rẹ ba si wa ni alaafia ninu iboji. Nipasẹ aṣẹ igbimọ Constance, ni ogoji ọdun lẹyin iku rẹ, a wu egungun rẹ sita, a dana sun-un nigbangba, a wa da eeru rẹ sinu odo ti o wa lẹba wọn. Onkọwe agba kan sọ wipe, “Odò yii ti gbe eeru rẹ lọ si Avon, lati Avon lọ si Severn, lati Severn lọ si inu awọn okun kekeeke, ati lati ibẹ lọ si inu agbami okun. Bayii ni eeru Wycliffe ti o jẹ ami awọn ikọni rẹ ṣe fọn kaakiri gbogbo aye.” Awọn ọta rẹ ko ni oye pupọ nipa bi iwa ika wọn ti ṣe ni itumọ to.ANN 40.2

    Nipasẹ awọn iwe Wycliffe ni John Huss ti Bohemia fi kọ ọpọlọpọ awọn aṣiṣe ẹsin Romu silẹ ti o si bẹrẹ iṣẹ atunṣe. Bayi ni a ṣe gbin irugbin otitọ ni awọn orile ede mejeeji ti wọn jinna si ara wọn wọnyi. Lati Bohemia, iṣẹ naa tan de awọn ilẹ miran. Ọkan awọn eniyan yi si ọrọ Ọlọrun ti a ti gbagbe fun ọjọ pipẹ. Ọwọ Ọlọrun n pese ọna silẹ fun iṣẹ Atunṣe Nla.ANN 40.3

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents