Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  ORI KỌKANDINLOGUN—IMỌLẸ LAARIN OKUNKUN

  Iṣẹ Ọlọrun ninu aye lati igba de igba ṣe afihan, ijọra ti o yanilẹnu ninu gbogbo iṣẹ Atunṣe nla tabi ẹgbẹ ẹsin. Awọn ipilẹ ti Ọlọrun fi n ba awọn eniyan lò ko yatọ. Awọn ẹgbẹ pataki ti asiko yii wa ni ibamu pẹlu awọn ti atẹyin wa, iriri ijọ latẹyin wa si ni ẹkọ ti o ṣeyebiye fun akoko wa yii.ANN 153.1

  Ko si otitọ ti a kọ kedere ninu Bibeli ju eyi pe Ọlọrun nipasẹ Ẹmi Mimọ Rẹ ni pataki julọ dari awọn iranṣẹ Rẹ ni aye ninu ẹgbẹ nla fun titẹsiwaju iṣẹ igbala. Awọn eniyan jẹ irin iṣẹ ni ọwọ Ọlọrun, eyi ti O n lo lati mu erongba oore ọfẹ ati aanu Rẹ ṣẹ. Olukuluku ni o ni ipa tirẹ lati ko; olukuluku ni a fun ni iwọn imọlẹ, ti o wulo fun akoko tirẹ ti o si to lati ran an lọwọ lati ṣe iṣẹ ti Ọlọrun fun lati ṣe. Ṣugbọn ko si eniyan, bi o ti wu ki Ọrun o bu ọla fun to, ti o ni oye kikun nipa eto irapada nla tabi ti o mọyi ni kikun, erongba Ọlọrun ninu iṣẹ ti akoko rẹ. Awọn eniyan ko ni oye kikun nipa ohun ti Ọlọrun fẹ ṣe nipasẹ iṣẹ ti O fun wọn lati ṣe; wọn ko ni oye iṣẹ iranṣẹ ti wọn n kede ni orukọ Rẹ, ni gbogbo ọna ti o pin si.ANN 153.2

  “Njẹ ẹ le wa Ọlọrun rí bi? Njẹ ẹ le ri Alagbara tan patapata bi?” “Ero Mi ki i ṣe ero yin, bẹẹ ni ọna Mi ki i ṣe ọna yin ni Oluwa wi. Nitori bi ọrun ti ga ju aye lọ, bẹẹ ni ọna Mi ga ju ti yin lọ ati ero Mi ga ju ero yin.” “Emi ni Ọlọrun ko si ẹlomiran bi Emi, ti o n sọ opin lati ibẹrẹ, ati lati igba atijọ awọn ohun ti koi ti i ṣẹlẹ.” Jobu 11:7; Aisaya 55:8, 9; 46:9, 10.ANN 153.3

  Ani awọn woli ti wọn ri oju rere ilalọyẹ pataki ti Ẹmi ko ni oye kikun nipa awọn ifihan ti a fifun wọn. Lati akoko kan de omiran ni a n ṣipaya itumọ rẹ, bi awọn eniyan Ọlọrun ba ti ṣe nilo awọn ilana ti o wa nibẹ.ANN 153.4

  Peteru, nigba ti o n kọ nipa igbala ti a fihan nipasẹ iyinrere sọ pe: Ni ti igbala yii “awọn woli ti beere, wọn si ti fi pẹlẹkutu wa a, ti wọn sọtẹlẹ nipa oore ọfẹ ti yoo wa si ọdọ yin; ti wọn n wa kini tabi iru igba akoko wo ni Ẹmi Kristi ti o wa ninu wọn sọ, nigba ti o sọtẹlẹ nipa ijiya Kristi ati ogo ti yoo tẹle. Awọn ti a fihan fun, ki i ṣe fun awọn, tikarawọn, ṣugbọn awa ni wọn ṣiṣẹ fun.” 1 Peteru 11:10—12.ANN 153.5

  Sibẹ, bi o ti lẹ jẹ wipe a ko gba awọn woli laaye lati ni oye kikun nipa ohun ti a fihan fun wọn, wọn n fi tọkantọkan wa lati ri gbogbo imọlẹ ti Ọlọrun fẹ lati fihan. Wọn “beere, wọn tun fi pẹlẹkutu wa,” “wọn n wa kini tabi iru igba wo ni Ẹmi Kristi ti o wa ninu wọn tọka si.” Iru ẹkọ wo ni eleyi jẹ fun awọn eniyan Ọlọrun ni akoko Kristẹni, awọn ti a titori wọn fun awọn iranṣẹ Rẹ ni asọtẹlẹ wọnyi! “Awọn ni a ṣe afihan rẹ fun, ki i ṣe fun ara wọn, bikoṣe awa ni wọn jiṣẹ fun.” Ṣe ayẹwo awọn eniyan mimọ Ọlọrun wọnyẹn bi wọn “ti n beere, ti wọn si n fi pẹlẹkutu ṣe ayẹwo” nipa awọn ifihan ti a fifun wọn fun awọn ti a koi ti i bi. Fi itara mimọ wọn we aibikita eyi ti awọn ti o kẹyin, ti a fi oju rere han si fi wo ẹbun Ọrun. Iru ibawi wo ni eyi jẹ fun aibikita ti ifẹ aye ati ifẹ irọrun fi jẹ ki eniyan o sọ pe awọn asọtẹlẹ ko le yeni!ANN 153.6

  Bi o tilẹ jẹ wipe oye kekere eniyan kò kún oju oṣuwọn lati wọ inu imọran Ẹni Ailopin, tabi ni oye kikun nipa iṣiṣẹjade erongba Rẹ, sibẹ, o saba maa n waye wipe nitori aṣiṣe tabi aikasi lati ọdọ wọn ni wọn ko fi ni oye to nipasẹ iṣẹ iranṣẹ Ọrun. Ki i ṣe igba diẹ ni iye awọn eniyan, ani ti awọn iranṣẹ Ọlọrun maa n di nitori ero eniyan, awọn aṣa ati ẹkọ eke eniyan, ti o fi jẹ wipe iwọnba perete ni wọn le ni oye rẹ mọ ninu awọn ohun nla ti O fihan ninu ọrọ Rẹ. Bakan naa ni o ṣe ṣẹlẹ pẹlu awọn ọmọ ẹyin Kristi, ani nigba ti Olugbala wa pẹlu wọn ninu ara. Iyè wọn kun fun ero ti o wọpọ nipa Mesaya gẹgẹ bi ọba aye, ti yoo gbe Israeli ga de itẹ ijọba gbogbo aye to bẹẹ gẹẹ, ti wọn ko fi le ni oye itumọ ọrọ Rẹ ti o sọtẹlẹ nipa ijiya ati iku Rẹ.ANN 153.7

  Kristi funra Rẹ ti ran wọn jade pẹlu iṣẹ iranṣẹ: “Akoko naa de, ijọba Ọlọrun ku si dẹdẹ: ẹ ronupiwada, ki ẹ si gba iyinrere gbọ.” Maku 1:15. Iṣẹ iranṣẹ yii da lori asọtẹlẹ Danieli ori kẹsan. Ọsẹ mọkandinlaadọrin (69) ti angẹli naa kede wipe yoo lọ de “Mesaya Ọmọ Alade,” pẹlu ireti giga ati iwọna pẹlu ayọ, awọn ọmọ ẹyin n fi oju sọna lati ri idasilẹ ijọba Mesaya ni Jerusalẹmu lati ṣe ijọba lori gbogbo aye.ANN 154.1

  Wọn waasu iṣẹ iranṣe ti Kristi fifun wọn, bi o tilẹ jẹ wipe wọn ṣi i tumọ. Lootọ ni ikede wọn da lori Danieli 9:25, wọn ko ri, ni ẹsẹ ti o tẹle ni ori kan naa wipe a o ge Mesaya naa kuro. Lati igba ti a ti bi wọn, a ti gbe ọkan lori ireti ogo ijọba aye, ti eyi si jẹ ki oju oye wọn o fọ si alaye asọtẹlẹ ati si awọn ọrọ Jesu pẹlu.ANN 154.2

  Wọn ṣe ojuṣe wọn nipa fifun orilẹ ede Ju ni ipe aanu, amọ, ni asiko gan ti wọn reti ki Oluwa wọn O gun ori itẹ Dafidi, wọn ri bi a ti mu bi ọdaran, a nà Á, a fi ṣẹsin, a da lẹbi, a si gbe kọ ori igi agbelebu Kalfari. Iru ibanujẹ ati iporuuru ọkan wo ni o wa lọkan awọn ọmọ ẹyin yẹn ni awọn ọjọ ti Oluwa wọn sun sinu iboji!ANN 154.3

  Kristi wa ni akoko gan ati ni ọna ti asọtẹlẹ gba sọ ọ. Ẹri Iwe Mimọ wa si imuṣẹ ni rẹgi nipa iṣẹ iranṣẹ Rẹ. O waasu iṣẹ iranṣẹ igbala, ti “ọrọ Rẹ si wa pẹlu agbara.” Ọkan awọn olugbọ Rẹ jẹri si wipe lati Ọrun ni O ti wa. Ọrọ ati Ẹmi Ọlọrun jẹri si ẹri ọrun nipa Ọmọ Rẹ.ANN 154.4

  Awọn ọmọ ẹyin si ni ifẹ ti ko le ku si Ọga wọn ti wọn fẹran. Sibẹ iyè wọn kun fun aidaniloju ati iyemeji. Ninu irora ọkan wọn, wọn ko ranti awọn ọrọ Kristi nigba naa, ti O tọka si ijiya ati iku Rẹ. Bi Jesu ti Nasarẹti ba ni Mesaya nitootọ, ṣe wọn a wà ninu ibanujẹ ati ijakulẹ bayii? Ibeere ti o damu ọkan wọn niyii nigba ti Olugbala wọn dubulẹ ninu iboji Rẹ ni akoko Ọjọ Isinmi ainireti yẹn ti o wa laarin iku ati ajinde Rẹ.ANN 154.5

  Bi o tilẹ jẹ wipe aṣalẹ ibanujẹ ko ara jọ pọ mọ awọn atẹle Kristi; sibẹ a ko fi wọn silẹ. Woli naa wi pe: “Nigba ti mo ba joko sinu okunkun, Oluwa yoo jẹ imọlẹ si mi. . . . Yoo mu mi wa sinu imọlẹ, emi yoo si ri ododo Rẹ.” “Bẹẹ ni, okunkun ko muni pamọ kuro lọdọ Rẹ; ṣugbọn aṣalẹ n tan bi ọsan ni: bakan naa ni okunkun ati imọlẹ ri ni oju Rẹ.” Ọlọrun sọrọ: “Imọlẹ dide si olododo ninu okunkun.” “Emi yoo mu afọju rin ni ọna ti wọn ko mọ; Emi yoo mu wọn rin ni oju ọna ti wọn koi tii mọ: Emi yoo sọ okunkun di imọlẹ niwaju wọn, ati ohun kọlọkọlọ yoo di nínà. Awọn nnkan wọnyi ni Emi yoo ṣe fun wọn, Emi ki yoo si kọ wọn silẹ.” Mika 7:8, 9; O. Dafidi 139:12; 112:4; Aisaya 42:16.ANN 154.6

  Ikede ti awọn ọmọ ẹyin ṣe ni orukọ Oluwa tọna ninu ohun gbogbo, awọn asọtẹlẹ ti o tọka si si n ṣẹlẹ. “Akoko naa ti di mimuṣẹ, ijọba Ọlọrun ku si dẹdẹ,” ni iṣẹ iranṣẹ wọn. Nigba ti “akoko naa” pari, 69 ọsẹ ti Danieli 9, eyi ti o lọ de ọdọ Mesaya, “Ẹni Ami Ororo”—Kristi ti gba ami ororo Ẹmi Mimọ lẹyin ti Johanu tẹ Ẹ bọmi ni Jọdani. “Ijọba Ọlọrun,” eyi ti wọn kede wipe o ku si dẹdẹ, ni iku Kristi da silẹ. Ijọba yii kii ṣe, gẹgẹ bi a ti kọ wọn lati gbagbọ, ijọba aye. Bẹẹ ni ki i ṣe ijọba ọjọ iwaju, ijọba ainipẹkun eyi ti a o gbe kalẹ nigba ti “ijọba ati agbara, ati titobi ijọba labẹ ọrun yoo jẹ ti awọn eniyan mimọ Ọga Ogo;” ijọba ainipẹkun naa, ninu eyi ti “gbogbo agbara aye yoo sin In, wọn yoo si gbọ tirẹ.” Daniẹli 7:27. Gẹgẹ bi a ti lo o ninu Bibeli, ọrọ ti a pe ni “ijọba Ọlọrun” ni a lo lati tumọ si ijọba oore ọfẹ ati ijọba ogo. Ijọba oore ọfẹ ni Pọlu ṣe alaye rẹ ninu Episteli si awọn ara Heberu. Lẹyin ti o tọka si Kristi, alagbawi alaanu, Ẹni ti o “ni imọlara ẹmi ailera wa,” apostoli naa sọ wipe: “Nitori naa, ẹ jẹ ki a fi agbara wá siwaju itẹ oore ọfẹ, ki a baa le ri aanu gba, ki a si ri oore ọfẹ.” Heberu 4:15, 16. Itẹ oore ọfẹ tumọ si ijọba oore ọfẹ; nitori ti a sọ nipa itẹ, eyi tumọ si wipe ijọba wa nibẹ pẹlu. Ninu ọpọlọpọ owe Rẹ Kristi lo ọrọ “ijọba ọrun” lati ṣe alaye iṣẹ oore ọfẹ ọrun lori ọkan awọn eniyan.ANN 154.7

  Nitori naa itẹ ogo tumọ si ijọba ogo; ijọba yii ni a sọ nipa rẹ ninu ọrọ Olugbala: “Nigba ti Ọmọ eniyan yoo wá ninu ogo Rẹ, ati gbogbo awọn angẹli mimọ pẹlu Rẹ, nigba naa ni yoo joko lori itẹ ogo Rẹ: gbogbo awọn orilẹ ede yoo si pejọ niwaju Rẹ.” Matiu 25:31, 32. Ijọba yii si wa ni ọjọ iwaju. A ko ni gbe e kalẹ titi fi di akoko ipadabọ Kristi lẹẹkeji.ANN 154.8

  A gbe ijoba oore ọfẹ kalẹ lọgan lẹyin ti eniyan ṣubu, nigba ti a ṣe eto fun irapada iran ti o jẹbi. O wà nigba naa ninu eto ati nipasẹ ileri Ọlọrun; nipa igbagbọ, awọn eniyan le di ọmọ ijọba naa. Sibẹ, a ko daa silẹ ni pato titi fi di akoko iku Kristi. Ani nigba ti o bẹrẹ iṣẹ Rẹ, Olugbala le yi pada kuro ninu ẹbọ ti Kalfari nigba ti orikunkun ati aimoore eniyan da A lagara. Ni Gestemane ago iparun mì ni ọwọ Rẹ. O le nu oogun ẹjẹ oju Rẹ kuro ki O si jẹ ki iran ti o jẹbi ṣegbe ninu aiṣedeede wọn. Bi o ba ṣe eyi, ko ni si irapada fun eniyan ti o ṣubu. Ṣugbọn nigba ti Olugbala fi ẹmi Rẹ lelẹ, pẹlu eemi ikẹyin Rẹ ti O kigbe, “O pari,” nigba naa ni a fi idi eto irapada lelẹ. A fi ontẹ lu ileri igbala ti a ṣe fun tọkọtiyawo ẹlẹṣẹ ni Edẹni. Nigba naa ni a wa gbe ijọba alaafia, eyi ti o wa tẹle nipasẹ ileri Ọlọrun kalẹ.ANN 155.1

  Nitori naa iku Kristi—iṣẹlẹ gan eyi ti awọn ọmọ ẹyin wo gẹgẹ bi iparun ti o kẹyin fun ireti wọn—ni eyi ti o fi idi rẹ mulẹ titi aye. Bi o tilẹ jẹ wipe o mu ijakulẹ kikoro ba wọn, o je ẹri ti o ga julọ wipe igbagbọ wọn tọna. Iṣẹlẹ naa ti o mu ki wọn kun fun ọfọ ati iporuuru ọkan ni eyi ti o ṣi ilẹkun ireti fun gbogbo awọn ọmọ Adamu, ati lori eyi ti aye ti n bọ ati idunu ayeraye fun gbogbo awọn olootọ Ọlọrun latẹyin wa duro le.ANN 155.2

  Awọn erongba aanu ainipẹkun n wa si imuṣẹ wọn, ani ninu ijakulẹ awọn ọmọ ẹyin. Nigba ti oore ọfẹ ọrun ati agbara ikọni Rẹ, “Ẹni ti o sọrọ bi ẹnikẹni koṣe ti i sọrọ ri” jere ọkan wọn, sibẹ wọn da idọti igberaga aye ati ọkanjuwa imọ-ti-ara-ẹni-nikan pọ mọ ifẹ didan ti wọn ni fun Jesu. Ani ninu yara ti wọn ti ṣe ajọ irekọja, ni akoko ọlọwọ naa nigba ti Ọga wọn ti n wọ inu ojiji Getsemani, “ija wa laarin wọn, lori ẹni ti o tobi ju.” Luku 22:24. Iran wọn kún fun itẹ, ade ati ogo, nigba ti o jẹ wipe niwaju wọn ni itiju ati irora ọgba, gbọngan idajọ, ati agbelebu Kalfari wa. Igberaga ọkan wọn, ongbẹ wọn fun ogo aye ni o jẹ ki wọn di mọ ẹkọ eke akoko wọn laiwẹyin, lati maṣe kiyesi awọn ọrọ Olugbala, ti o fi han wọn bi ijọba Rẹ ti ri gan an, ti o tun tọka si irora ati iku Rẹ. A si gba awọn aṣiṣe wọnyi laaye lati dan wọn wo—o ninilara, ṣugbọn wọn nilo rẹ—fun atunṣe wọn. Bi o tilẹ jẹ wipe awọn ọmọ ẹyin ṣe aṣiṣe nipa itumọ iṣẹ iranṣẹ wọn, ti ireti wọn ko si wa si imuṣẹ, sibẹ wọn waasu ikilọ ti Ọlọrun fifun wọn, Oluwa yoo si fi èrè fun igbagbọ wọn, yoo si bu ọla fun igbọran wọn. Awọn ni a fun ni iṣẹ ikede iyinrere ologo nipa ajinde Oluwa wọn fun gbogbo orilẹ ede. Lati pese wọn silẹ fun iṣẹ yii ni a fi gba iṣẹlẹ ti o dabi ẹnipe ó korò laaye.ANN 155.3

  Lẹyin ajinde Rẹ, Jesu fi ara han awọn ọmọ ẹyin Rẹ ni oju ọna lọ si Emausi, “bẹrẹ lati Mose ati gbogbo awọn woli, O ṣe alaye ohun gbogbo ti a sọ nipa Rẹ ninu Iwe Mimọ fun wọn.” Luku 24:27. Ọkan awọn ọmọ ẹyin ru soke. Igbagbọ sọji. A “tun wọn bi sinu ireti ti o wa laaye” ani ki Jesu to fi ara Rẹ han fun wọn. Erongba Rẹ ni lati tan imọlẹ si iye wọn ki O si so igbagbọ wọn mọ “ọrọ asọtẹlẹ ti o daju.” O fẹ ki otitọ o fi ẹsẹ mulẹ ninu ọkan wọn, ki i ṣe nitori pe Oun ni o sọ ọ lasan, ṣugbọn nitori ẹri ti a ko le ṣeyemeji rẹ, ti apẹẹrẹ ati ojiji ofin ati awọn asọtẹlẹ Majẹmu Laelae gbé kalẹ. O ṣe pataki ki awọn atẹle Kristi ni igbagbọ ti o duro lori oye, ki i ṣe nitori ara wọn nikan, ṣugbọn nitori ki wọn baa le fun araye ni imọ Kristi. Gẹgẹ bi ọna akọkọ ninu kikọni ni imọ yii, Jesu dari awọn ọmọ ẹyin Rẹ lọ si “Mose ati gbogbo woli.” Eyi ni ẹri ti Olugbala ti ó jinde fifunni nipa bi Iwe Majẹmu Laelae ti ṣe pataki ati bi o ti niye lori to.ANN 155.4

  Iru iyipada wo ni o ṣẹlẹ ninu ọkan awọn ọmọ ẹyin Rẹ bi wọn ti n wo oju Oluwa wọn ti wọn fẹran! Luku 24: 32. Ni ọna ti o peyeju ti tẹlẹ lọ, wọn “ri I, Ẹni ti Mose ninu ofin, ati awọn woli kọ nipa.” Idaniloju ti o peye ati igbagbọ ti o mọlẹ kedere rọpo ainidaniloju ati iporuuru ọkan. Idi abajọ ti wọn fi “wà ninu tẹmpili nigba gbogbo, ti wọn n yin, ti wọn si n bukun Ọlọrun” lẹyin ti a gba A soke tan. Awọn eniyan, ti o jẹ wipe iku atiniloju Olugbala wọn nikan ni wọn mọ, n wọna lati ri ibanujẹ, iporuuru ati ibaku loju wọn; ṣugbọn wọn ri idunnu ati iṣẹgun. Iru igbaradi wo ni awọn ọmọ ẹyin ri gba fun iṣẹ ti o wa niwaju wọn! Wọn ti la idanwo giga kọja, wọn si ri bi ọrọ Ọlọrun ti di mimuṣe ni ọna iṣẹgun, nigba ti o dabi ẹnipe ohun gbogbo baku ni oju eniyan. Lati akoko yii lọ, kini o le doju kọ igbagbọ wọn, tabi ti o le ko irẹwẹsi ba ifẹ wọn? Ninu ibanujẹ ti o pọ jọjọ, wọn ni “itunu ti o lagbara,” ireti ti o jẹ “idakọro fun ọkan, ti o ṣe e fi ọkan tan, ti o duro gbọin.” Heberu 6:18, 19. Wọn ti jẹ ẹlẹri si ọgbọn ati agbara Ọlọrun, o si ti “da wọn loju wipe, ki i ṣe iku, tabi iye, tabi awọn angẹli, tabi awọn ijoye, tabi awọn agbara, tabi ohun ti asiko yii, tabi awọn ohun ti n bọ, tabi oke, tabi ọgbun, tabi ẹda miran,” ni yoo le ya wọn nipa kuro ninu “ifẹ Ọlọrun, eyi ti o wa ninu Kristi Jesu Oluwa wa.” Wọn sọ pe, “Ninu gbogbo nnkan wọnyii, a ju aṣẹgun lọ nipasẹ Ẹni ti o fẹ wa.” Romu 8:38, 39, 37. “Ọrọ Ọlọrun duro titi lae.” 1 Peteru 1:25. Ati “tani ẹni ti n danilẹbi? Kristi ti O ku ni, bẹẹ ni, ti O jinde pẹlu, ti O wa ni ọwọ ọtun Ọlọrun ti O tun n bẹbẹ fun wa.” Romu 8:34.ANN 155.5

  Oluwa wipe: “Oju ki yoo ti awọn eniyan Mi.” Joẹli 2:26. “Ẹkun le pẹ di alẹ kan, ṣugbọn ayọ n bọ ni owurọ.” O. Dafidi 30:5. Nigba ti awọn ọmọ ẹyin wọnyi pade Olugbala wọn ni ọjọ ajinde, ti ọkan wọn n gbina ninu wọn bi wọn ti n tẹti si ọrọ Rẹ; nigba ti wọn ri ori ati ọwọ ati ẹsẹ ti a ṣa lọgbẹ fun wọn; nigba ti, ṣaaju igbasoke Rẹ, Jesu dari wọn lọ si Bẹtani, ti O gbe ọwọ Rẹ soke ni ibukun, ti O wipe, “Ẹ lọ sinu aye gbogbo, ki ẹ si waasu iyinrere,” O fikun wipe, “Kiyesii, Emi wa pẹlu yin titi lae” (Maku 16:15; Matiu 28:20); ni ọjọ Pẹntikọsti nigba ti Olutunu ti a ṣeleri sọkalẹ, ti a funni ni agbara lati oke wa, ti ọkan awọn onigbagbọ yọ pẹlu imọlara wipe Oluwa wọn ti a gba soke wà pẹlu wọn—nigba naa, bi o tilẹ jẹ wipe, gẹgẹ bii ti Rẹ, oju ọna wọn gba ifirubọ ati ijẹriku kọja, ṣe wọn a ṣe paṣiparọ iṣẹ iranṣẹ iyinrere oore ọfẹ Rẹ pẹlu “ade ododo” ti wọn yoo gba ni igba wiwa Rẹ, fun ogo itẹ aye, eyi ti o jẹ ireti wọn ni akọkọ iṣẹ ọmọ ẹyin wọn ni igba iṣaaju? Ẹni ti O “le ṣe pupọ ju eyi ti a beere lọ tabi ti a le ronu lọ,” ti fun wọn, pẹlu idapọ ijiya Rẹ, ibaṣepọ ayọ Rẹ—ayọ “mimu ọpọlọpọ ọmọ wa sinu ogo,” ayọ ti ko ṣe e fẹnu sọ, “ogo ainipẹkun ti o wuwo” ti Pọlu sọ pe “ijiya wa kekere yii, ti o wa fun igba diẹ, “ko to lati fi ṣe akawe” rẹ.ANN 156.1

  Iriri awọn ọmọ ẹyin ti wọn waasu “iyinrere ijọba naa” ni igba wiwa Kristi lakọkọ, ní afiwe ninu iriri awọn ti wọn kede iyinrere ipadabọ Rẹ lẹẹkeji. Bi awọn ọmọ ẹyin ti jade ti wọn n kede, “Akoko naa de, ijọba Ọlọrun ku si dẹdẹ,” bẹẹ gẹgẹ ni Miller ati awọn ẹlẹgbẹ rẹ kede akoko ti o gun julọ, ti o tun kẹyin ninu akoko isọtẹlẹ ti Bibeli sọ wipe o fẹ pari, wipe idajọ ku si dẹdẹ, ati pe ijọba ainipẹkun ti fẹ wọle. Iwaasu awọn ọmọ ẹyin nipa akoko duro lori aadọrin ọsẹ ti inu Daniẹli 9. Iṣẹ iranṣẹ ti Miller ati awọn akẹgbẹ rẹ waasu kede opin 2300 ọjọ ti Danieli 8:14, eyi ti aadọrin ọsẹ wa lara rẹ. Iwaasu ikọọkan wọn duro lori imuṣẹ abala ọtọọtọ ninu akọsilẹ nla kan naa.ANN 156.2

  Bi ti awọn ọmọ ẹyin akọkọ, William Miller ati awọn akẹgbẹ rẹ, funra wọn ko ni oye kikun nipa itumọ iṣẹ iranṣẹ ti wọn n waasu. Awọn aṣiṣe ti wọn ti fi idi mulẹ ninu ijọ ṣe idena fun wọn lati ri itumọ ti o tọna fun koko ti o ṣe pataki ninu asọtẹlẹ naa. Nitori naa, bi o tilẹ jẹ wipe wọn kede iṣẹ iranṣẹ ti Ọlọrun fifun wọn fun araye, sibẹ nipasẹ aṣiṣe ninu itumọ rẹ, wọn jiya ijakulẹ.ANN 156.3

  Ni ṣiṣe alaye Daniẹli 8:14, “Titi di 2300 ọjọ; nigba naa ni a o ṣe iwẹnumọ ibi mimọ,” Miller gẹgẹ bi a ti sọ ọ, gba ero ti o wọpọ wipe aye ni ibi mimọ, o si gbagbọ wipe ṣiṣe iwẹnumọ ibi mimọ tumọ si fifọ aye mọ pẹlu ina ni igba wiwa Oluwa. Nitori naa, nigba ti o ri wipe a ṣe asọtẹlẹ opin ọjọ ni pato, o pinu wipe akoko ti a fihan yii ni yoo jẹ akoko bibọ lẹẹkeji. Aṣiṣe rẹ waye latari gbigba ero ti o wọpọ nipa ohun ti ibi mimo tumọ si.ANN 156.4

  Ninu eto ti apẹẹrẹ, eyi ti o jẹ ojiji irubọ ati iṣẹ alufa Kristi, iwẹnumọ ibi mimọ ni eto ti o kẹyin tí olu-alufa maa n ṣe ninu iṣẹ rẹ lọdọọdun. O jẹ opin iṣẹ iwẹnumọ ẹṣẹ—mimu ẹṣẹ kuro ninu Israeli. O jẹ apẹẹrẹ iṣẹ ti o kẹyin ninu iṣẹ iranṣẹ Olu Alufa wa ni ọrun, ni ṣiṣe imukuro tabi fifọ ẹṣẹ awọn eniyan Rẹ mọ, ti a kọ silẹ ninu iwe ọrun. Isin yii nilo iṣẹ iyẹwewo, ati iṣẹ idajọ; wiwa Kristi ninu ikuuku awọsanma pẹlu agbara ati ogo nla ni yoo tẹle eyi; nitori nigba ti O ba de, a yoo ti ṣe ipinu lori gbogbo ọrọ. Jesu sọ wipe: “Ere Mi n bẹ pẹlu Mi, lati fifun olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ rẹ yoo ti ri.” Ifihan 22:12. Iṣẹ idajọ yii, ti yoo ṣaaju ipadabọ lẹẹkeji, ni a kede rẹ ninu iṣẹ iranṣẹ angẹli akọkọ ti Ifihan 14:7: “Bẹru Ọlọrun, ki ẹ si fi ogo fun; nitori ti wakati idajọ Rẹ de.”ANN 156.5

  Awọn ti wọn kede ikilọ yii kede iṣẹ iranṣẹ ti o yẹ ni akoko ti o yẹ. Ṣugbọn bi awọn ọmọ ẹyin akọkọ ti kede, “Akoko naa de, ijọba Ọlọrun ku si dẹdẹ,” ti o duro lori asọtẹlẹ Daniẹli 9, nigba ti wọn baku lati ni oye wipe a ṣe asọtẹlẹ iku Mesaya ninu Iwe kan naa, bẹẹ gẹgẹ ni Miller ati awọn akẹgbẹ rẹ waasu iṣẹ iranṣẹ ti o duro lori Daniẹli 8:14 ati Ifihan 14:7, ṣugbọn ti wọn ko ri awọn iṣẹ iranṣẹ miran ti a tẹ jade ninu Ifihan 14, ti o yẹ ki a fifunni pẹlu ṣaaju wiwa Oluwa. Bi awọn ọmọ ẹyin ti ṣe aṣiṣe nipa iru ijọba ti a yoo gbe kalẹ ni opin aadọrin ọsẹ, bẹẹ gẹgẹ ni awọn Onireti ṣe ṣe aṣiṣe nipa iṣẹlẹ ti yoo ṣẹlẹ ni opin 2300 ọjọ. Ninu ọrọ mejeeji, wọn gba tabi wọn ṣe igbọran si aṣiṣe ti o wọpọ, eyi ti o fọ awọn eniyan loju si otitọ. Awọn ẹgbẹ mejeeji ni wọn ṣe ifẹ Ọlọrun nipa wiwaasu, awọn mejeeji pẹlu ní ṣiṣe aṣiṣe ninu oye iṣẹ iranṣẹ wọn, wọn ri ijakulẹ.ANN 157.1

  Sibẹ, Ọlọrun mu ero aanu Rẹ ṣẹ ni jijẹ ki ikilọ idajọ o jade bi o ti ṣe jade. Ọjọ nla sunmọ etile, ninu iṣọwọṣiṣẹ Rẹ, awọn eniyan ri idanwo lori akoko kan pato lati le ṣe afihan ohun ti n bẹ ninu ọkan wọn. A gbe iṣẹ iranṣẹ naa kalẹ fun idanwo ati ifọmọ ijọ. A jẹ ki wọn ri boya ifẹ wọn wa lori aye yii, tabi lori Kristi ati ọrun. Wọn sọ wipe wọn fẹran Olugbala; bayii ki wọn wa jẹri si ifẹ wọn. Ṣe wọn ṣetan lati kọ ireti ati ifẹ aye silẹ, ki wọn si ki Oluwa wọn kaabọ pẹlu ayọ? A gbe iṣẹ iranṣẹ naa kalẹ lati le jẹ ki wọn ri ipo ti wọn wa ninu ẹmi; a ran si wọn ninu aanu lati ta wọn ji lati wa Oluwa pẹlu ironupiwada ti irẹlẹ.ANN 157.2

  Ijakulẹ naa, bi o tilẹ jẹ wipe o jẹ atubọtan iṣitumọ iṣẹ iranṣẹ ti wọn fifun ni, o ṣiṣẹ fun rere. O dan ọkan awọn ti wọn sọ wipe wọn gba ikilọ naa wo. Ninu ijakulẹ wọn, ṣe wọn a fi igbonara sọ iriri wọn nù ni, ti wọn a si sọ igbẹkẹle wọn ninu ọrọ Ọlọrun nu? a bi pẹlu adura ati irẹlẹ, wọn a wa lati mọ ibi ti wọn ti baku lati mọ itumọ asọtẹlẹ naa? Melo ninu wọn ni o jẹ wipe ibẹru ni o mu wọn lọkan, tabi ti wọn ṣiṣẹ nitori igbonara ati oofa ọkan? Melo ninu wọn ni ko fi ọkan kan ṣiṣẹ ti wọn tun jẹ alaigbagbọ? Ọpọ ero ni wọn kede wipe wọn fẹran wiwa Oluwa. Nigba ti a pe wọn lati fi ara da ẹgan ati itiju araye, ati idanwo ati ijakulẹ, ṣe wọn a kọ igbagbọ naa silẹ bi? Nitori ti bi Ọlọrun ti n ba wọn lò kò tete yé wọn, ṣe wọn a sọ otitọ, ti ẹri ti o han kedere ninu ọrọ Rẹ tilẹyin, nu bi?ANN 157.3

  Idanwo yii yoo fi okun awọn ti wọn fi igbagbọ tootọ ṣe igbọran si ohun ti wọn gbagbọ wipe o jẹ ikọni ọrọ ati Ẹmi Ọlọrun han. Yoo kọ wọn, bi iru iriri yii nikan ṣoṣo ti le kọni, ewu ti o wa ninu gbigba ero ati itumọ eniyan, dipo ki a fi Bibeli ṣe itumọ ara rẹ. Fun awọn ọmọ igbagbọ iporuuru ọkan ati ibanujẹ ti o jẹyọ latari aṣiṣe wọn yoo ṣe iṣẹ atunse ti wọn nilo. Yoo dari wọn lati kọ ẹkọ si nipa ọrọ asọtẹlẹ. Wọn yoo kọ lati fi iṣọra ṣe ayẹwo ipilẹ igbagbọ wọn, ki wọn si kọ ohun gbogbo, bi o ti wu ki gbogbo Kristeni o gba a to, ti ko si ninu Iwe Mimọ otitọ silẹ.ANN 157.4

  Pẹlu awọn onigbagbọ yii, gẹgẹ bi o ti ri pẹlu awọn ọmọlẹyin akọkọ, eyi ti o dabi ẹnipe o ṣokunkun si oye wọn ni akoko idanwo ni yoo han kedere nikẹyin. Nigba ti wọn ba ri “opin Oluwa” wọn yoo mọ wipe, pẹlu idanwo ti o jade latari aṣiṣe wọn, ero ifẹ Rẹ si wọn n wa si imuṣẹ laisi idena. Wọn yoo kọ nipasẹ iriri ibukun wipe O jẹ “oniyọnu jọjọ ati alaanu;” wipe gbogbo ọna Rẹ “jẹ aanu ati otitọ si awọn ti wọn pa majẹmu ati ẹri Rẹ mọ.”ANN 157.5

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents