ORI KỌKANLELOGOJI—ILE AYE DI AHORO
ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA
- Contents- ORI KINI—ÌPARUN JÉRÚSÁLẸMÙ
- ORI KEJI— INÚNIBÍNI NÍ ỌGỌRUN ỌDÚN ÀKỌKỌ
- ORI KẸTA—ÀKÓKÒ ÒKÙNKÙN TI ẸMÍ
- ORI KẸRIN—AWỌN WALDENSES
- ORI KARUN—JOHN WYCLIFFE
- ORI KẸFA—HUSS ATI JEROME
- ORI KEJE—ÌYAPA LUTHER KÚRÒ NI ROMU
- ORI KẸJỌ—LUTHER NIWAJU ÌGBÌMỌ
- ORI KẸSAN—ALATUNṢE TI ILẸ SWISTZERLAND
- ORI KẸWA—ÌDÀGBÀSOKÈ IṢẸ ÀTUNṢE NÍ GERMANY
- ORI KỌKANLA—AWỌN IJOYE FI ẸHONU HAN
- ORI KEJILA—IṢẸ ÀTUNṢE NI ORILẸ-EDE FRANCE
- ORI KẸTALA—NETHERLANDS ATI SCANDINAVIA
- ORI KẸRINLA—ALATUNṢE IKẸYIN NI ENGLAND
- ORI KARUNDINLOGUN—BIBELI ATI IDOJU IJỌBA BOLẸ NI FRANCE
- ORI KẸRINDINLOGUN—AWỌN BABA ARINRIN-AJO
- ORI KẸTADINLOGUN—AWỌN AKÉDE ÒWÚRỌ
- ORI KEJIDINLOGUN—ALATUNṢE TI ILẸ AMẸRIKA
- ORI KỌKANDINLOGUN—IMỌLẸ LAARIN OKUNKUN
- ORI OGUN—ISỌJI NLA TI ẸSIN
- ORI KỌKANLELOGUN—IKILỌ TI A KỌ SILẸ
- ORI KEJILELOGUN—AWỌN ASỌTẸLẸ WA SI IMUṢẸ
- ORI KẸTALELOGUN—KINI IBI MIMỌ?
- ORI KẸRINLELOGUN—NINU IBI MIMỌ JULỌ
- ORI KARUNDINLỌGBỌN—OFIN ỌLỌRUN WA TITI LAE
- ORI KẸRINDINLỌGBỌN—IṢẸ ATUNṢE
- ORI KẸTADINLỌGBỌN—ISỌJI TI ODE ONI
- ORI KEJIDINLỌGBỌN—DIDOJUKỌ AKỌSILẸ NIPA IGBESI AYE
- ORI KỌKANDINLỌGBỌN—IPILẸSẸ IWA BUBURU
- ORI ỌGBỌN—IKORIRA LAARIN ENIYAN ATI SATANI
- ORI KỌKANLELỌGBỌN—AṢOJU AWỌN ẸMI EṢU
- ORI KEJILELỌGBỌN—AWỌN IDẸKUN SATANI
- ORI KẸTALELỌGBỌN—ITANJẸ NLA AKỌKỌ
- ORI KẸRINLELỌGBỌN—ṢE AWỌN ENIYAN WA TI WỌN TI KU LE BA WA SỌRỌ?
- ORI KARUNDINLOGOJI—IGBOGUNTI OMINIRA ẸRI ỌKAN
- ORI KẸRINDINLOGOJI—IKỌLU TI N BỌ
- ORI KẸTADINLOGOJI—IWE MIMỌ GẸGẸ BI AABO
- ORI KEJIDINLOGOJI—IKILỌ IKẸYIN
- ORI KỌKANDINLOGOJI—AKOKO IDAMU
- ORI OGOJI—A GBA AWỌN ENIYAN ỌLỌRUN SILẸ
- ORI KỌKANLELOGOJI—ILE AYE DI AHORO
- ORI KEJILELOGOJI—ARIYANJIYAN NAA PARI
Search Results
- Results
- Related
- Featured
- Weighted Relevancy
- Content Sequence
- Relevancy
- Earliest First
- Latest First
- Exact Match First, Root Words Second
- Exact word match
- Root word match
- EGW Collections
- All collections
- Lifetime Works (1845-1917)
- Compilations (1918-present)
- Adventist Pioneer Library
- My Bible
- Dictionary
- Reference
- Short
- Long
- Paragraph
No results.
EGW Extras
Directory
ORI KỌKANLELOGOJI—ILE AYE DI AHORO
“Ani awọn ẹṣẹ rẹ ti ga de ọrun, Ọlọrun si ti ranti awọn aiṣedeede rẹ. . . . Ẹ kún ago ti o ti kún, ẹ kun fun ni ilọpo meji. Niwọn bi o ti yin ara rẹ logo to, ti o si gbe igbe aye adun, niwọn bẹẹ ni ki ẹ daa loro ki ẹ si fun ni ibanujẹ: nitori ti o wi ni ọkan rẹ pe, Mo joko bi ọbabinrin, emi ki i si i ṣe opó, emi ki yoo si ri ibanujẹ lae. Nitori naa ni ijọ kan ni iyọnu rẹ yoo de, iku ati ibanujẹ ati iyan; a o si fi ina sun un patapata: nitori pe alagbara ni Oluwa Ọlọrun ti n ṣe idajọ rẹ. Awọn ọba aye, ti wọn n ba ṣe agbere, ti wọn si n gbe igbesi aye adun pẹlu rẹ yoo ṣọfọ, wọn yoo si pohun rere ẹkun le lori . . . wọn o maa wipe, o ṣe, o ṣe fun ilu nla naa, Babiloni, ilu alagbara nì! nitori ni wakati kan ni idajọ rẹ de.” Ifihan 18:5—10.ANN 290.1
“Awọn oniṣowo aye,” ti wọn ti “di ọlọrọ jọjọ nipasẹ ọpọlọpọ adun rẹ,” “yoo duro si okere réré nitori ibẹru idaloro rẹ, wọn yoo maa sọkun wọn yoo si maa ṣọfọ, wọn o maa wipe, O ṣe, o ṣe fun ilu nla ni, ti a wọ ni aṣọ ọgbọ wiwẹ, ati elese aluko, ati ti ododo, eyi ti a fi wura ṣe lọṣọ, pẹlu okuta iyebiye ati okuta paali! Nitori ni wakati kan ni ọrọ ti o pọ to bẹẹ di asan.” Ifihan 18:11, 3, 15—17.ANN 290.2
Iru awọn idajọ ti o wa si ori Babiloni ni ọjọ ibẹwo ibinu Ọlọrun niyii. O ti kun iwọn aiṣedeede rẹ patapata; akoko rẹ ti de, o ti pọn fun iparun.ANN 290.3
Nigba ti ohùn Ọlọrun yi igbekun awọn eniyan Rẹ pada, itaji ẹlẹru bẹ silẹ laarin awọn ti wọn padanu ninu ijakadi nla ti ẹmi. Ni akoko oore ọfẹ itanjẹ Satani fọ wọn loju, wọn ṣe idalare fun iwa ẹṣẹ wọn. Awọn ọlọrọ gbe ara wọn ga lori wipe wọn san ju awọn ti ko lọrọ to wọn lọ; ṣugbọn wọn ko ọrọ jọ nipa titẹ ofin Ọlọrun loju. Wọn ko naani lati bọ awọn ti ebi n pa, lati wọṣọ fun awọn ti wọn wa ni ihoho, lati wuwa ododo, ati lati fẹran aanu. Wọn wa lati gbe ara wọn ga ati lati gba ijọsin awọn ẹda bii ti wọn. Ni akoko yii, a ti gba gbogbo ohun ti wọn fi jẹ eniyan nla, wọn wa di alaini lai ni aabo. Wọn wo iparun awọn oriṣa ti wọn fẹran ju Ẹlẹda wọn lọ pẹlu ibẹru. Wọn ti ta ọkan wọn fun ọrọ ati igbadun aye, wọn ko wa lati di ọlọrọ si Ọlọrun. Abayọri rẹ nipe igbesi aye wọn a jẹ ibaku; faaji wọn ti di kikoro, ohun alumọni wọn dibajẹ. A gba gbogbo ere ọjọ aye wọn lọ ni iṣẹju kan. Awọn ọlọrọ kẹdun fun iparun ile nla wọn, fun bi a ti fọn wura ati fadaka wọn ka. Ṣugbọn wọn dakẹ ipohunrere ẹkun wọn nitori ibẹru wipe awọn pẹlu a ṣègbé pẹlu awọn oriṣa wọn.ANN 290.4
Awọn eniyan buburu kabamọ, ki i ṣe nitori ẹṣẹ wipe wọn ko naani Ọlọrun ati awọn eniyan ẹlẹgbẹ wọn, ṣugbọn nitori Ọlọrun ti ṣẹgun. Wọn kẹdun wipe èsì ri bi o ti ri; ṣugbọn wọn ko ronupiwada kuro ninu iwa buburu wọn. Wọn ko ni fi ohun kan silẹ lati le ri iṣẹgun bi wọn ba le ṣe bẹẹ.ANN 290.5
Wọn ri awọn ẹgbẹ gan an ti wọn kẹgan, ti wọn fi ṣẹfẹ, ti wọn si fẹ lati parun, ti wọn la ajakalẹ arun, iji ati ilẹ riri kọja laifarapa. Ẹni ti O jẹ ina ajonirun fun awọn ti n ru ofin Rẹ, ni O jẹ agọ aabo fun awọn eniyan Rẹ.ANN 290.6
Oniwaasu ti o fi otitọ silẹ lati jeere ojurere awọn eniyan wa ri ohun ti ikọni oun jẹ ati ipa rẹ. O farahan wipe oju ti o mọ ohun gbogbo n tẹle bi o ti duro lori pẹpẹ, bi o ti n rin loju popona, bi o ti n darapọ mọ awọn eniyan ninu oriṣiriṣi iṣẹlẹ aye. Gbogbo imọlara ọkan rẹ, gbogbo ohun ti o kọ silẹ, gbogbo ọrọ ti o sọ, gbogbo iwa ti o mu ki eniyan o sinmi ninu aabo eke, jẹ eso ti a fọnka, bayi o ri ikore rẹ ninu awọn ọkan otoṣi ti wọn yi ka.ANN 290.7
Oluwa wipe: “Wọn ti wo ipalara ọmọbinrin eniyan Mi wo diẹ, wọn n wipe, Alaafia, alaafia; nigba ti ko si alaafia.” “Wọn fi irọ ba ọkan olododo jẹ, ẹni ti Emi ko ba ninu jẹ; wọn si fun ọwọ awọn ẹni buburu lokun, ki o ma baa kuro ninu ọna buburu rẹ, nipa ṣiṣe ileri iye fun.” Jeremaya 8:11; Isikiẹli 13:22.ANN 290.8
“Egbe ni fun ẹyin oluṣọ aguntan ti n pa aguntan papa Mi run, to si n tu wọn ka! . . . Kiyesi, Emi yoo fi iwa buburu yin bẹ yin wo.” “Ẹ ké ẹyin oluṣọ aguntan, ki ẹ si sọkun ki ẹ fi ara yin yilẹ ninu eeru, ẹyin ọlọla agbo ẹran: nitori ọjọ atipa yin ati lati tu yin ka pe; . . . awọn oluṣọ aguntan ki yoo si ri ọna lati sa lọ, bẹẹ si ni awọn ọlọla agbo ẹran ki yoo le sa asala.” Jeremaya 23:1, 2; 25:34, 35.ANN 291.1
Awọn alufa ati awọn eniyan ri wipe wọn ko ni ibaṣepọ ti o dara pẹlu Ọlọrun. Wọn ri wipe wọn ṣọtẹ si Olupilẹsẹ gbogbo ofin otitọ ati ododo. Kikọ ofin mimọ silẹ ni o fa ọpọ iwa buburu, ija, ikorira, ati aiṣedeede, titi ti aye fi di oju ija nla, ti o tẹri sinu iwa ibajẹ. Ohun ti awọn ti wọn kọ ọtitọ silẹ ti wọn yan eke yoo mọ niyi. Ko si ede ti o le ṣe alaye ẹdun ọkan awọn alaigbọran ati alaiṣootọ fun ohun ti wọn padanu titi lae—iye ainipẹkun. Awọn eniyan ti araye n jọsin fun nitori ẹbun ati titayọ wọn wa ri awọn nnkan wọnyi gẹgẹ bi wọn ti jẹ lootọ. Wọn ri ohun ti wọn padanu nipasẹ ẹṣẹ, wọn ṣubu si ẹsẹ awọn ti wọn kẹgan iṣotitọ wọn, ti wọn si fi ṣẹfẹ, wọn si jẹwọ wipe Ọlọrun fẹran wọn.ANN 291.2
Awọn eniyan ri wipe a ti tan wọn jẹ. Wọn n fi ẹsun kan ẹnikeji wọn wipe o dari wọn sinu iparun, ṣugbọn gbogbo wọn ni wọn parapọ lati da awọn alufa lẹbi. Awọn alufa eke ṣe asọtẹlẹ ọrọ to dun n gbọ leti, wọn jẹ ki awọn olugbọ wọn o sọ ofin Ọlọrun di asan, ki wọn si ṣe inunibini si awọn ti n pa a mọ. Bayi, ninu ainireti wọn, awọn olukọ wọnyii jẹwọ iṣẹ ẹtan wọn niwaju araye. Awọn eniyan kun fun ibinu. Wọn n kigbe, “A ti ṣegbe, ẹyin ni o si ṣe okunfa iparun wa,” wọn si yiju si awọn oluṣọ aguntan eke. Awọn ti wọn fẹran wọn julọ ni yoo fi wọn gegun julọ. Awọn ọwọ gan to fun wọn ni ami ẹyẹ iṣẹgun ni a o na soke fun iparun wọn. Awọn ida ti a ba fi pa awọn eniyan Ọlọrun ni a o wa lo lati pa awọn ọta wọn run. Ni ibi gbogbo ni ija ati itajẹsilẹ wa.ANN 291.3
“Ariwo kan yoo wa ani titi de opin aye; nitori ti Oluwa ni ariyanjiyan pẹlu awọn orilẹ ede, yoo ba gbogbo ẹran ara ja; yoo fi awọn eniyan buburu le ida lọwọ.” Jeremaya 25:32. Fun ẹgbẹrun ọdun mẹfa ijakadi pẹlu agbara nla n tẹsiwaju; Ọmọ Ọlọrun ati awọn iranṣẹ Rẹ ọrun wa ninu ijakadi pẹlu agbara ẹni buburu ni, lati ṣe ikilọ fún, lati la loye ati lati gba awọn ọmọ eniyan la. Bayii gbogbo eniyan ni wọn ti ṣe ipinu wọn; awọn eniyan buburu ti darapọ mọ Satani ni kikun ninu ijakadi rẹ pẹlu Ọlọrun. Akoko to fun Ọlọrun lati da aṣẹ ofin Rẹ ti a tẹ loju lare. Bayi ijakadi naa ki i ṣe pẹlu Satani nikan bikoṣe pẹlu awọn eniyan. “Oluwa ni ariyanjiyan pẹlu awọn orilẹ ede;” “Yoo fi awọn eniyan buburu le ida lọwọ.”ANN 291.4
Ati fi ami idande si ori awọn ti wọn “gbin ti wọn si sọkun nitori gbogbo irira ti a ti ṣe.” Bayi angẹli iku jade wa, ti a fihan ninu iran Isikiẹli bi awọn eniyan ti wọn ni ohun ija apanirun, awọn ti a paṣẹ fun wipe: “Pa patapata, ati ogbó ati ọdọ, ati ọdọmọbinrin ati ọdọmọde ati obinrin: ṣugbọn maṣe pa ẹnikẹni ti o ba ni ami naa ni ori rẹ; ki o si bẹrẹ lati inu ile Mi.” Woli naa wipe: “Wọn bẹrẹ pẹlu awọn ẹni ogbó ti wọn wa niwaju ile naa.” Isikiẹli 9:1—6. Iṣẹ iparun bẹrẹ pẹlu awọn ti wọn n pe ara wọn ni atọna ẹmi fun awọn eniyan. Awọn aṣọna eke ni wọn kọkọ ṣubu. Ko si ẹni ti a o ṣe ikaanu fun tabi dasi. Awọn ọkunrin, obinrin, ọdọmọbinrin, ati ọdọmọde ni wọn yoo ṣegbe papọ.ANN 291.5
“Oluwa jade lati ibugbe Rẹ wa lati jẹ awọn olugbe aye niya nitori aiṣedeede wọn: nitori aye pẹlu ki yoo fi itajẹsilẹ rẹ pamọ, ki yoo si bo oku rẹ mọlẹ mọ.” Aisaya 26:21. “Eyi si ni iyọnu eyi ti Oluwa yoo fi kọlu gbogbo awọn ti wọn ti ba Jerusalẹmu jagun; ẹran ara wọn yoo jẹra nigba ti wọn duro lori ẹsẹ wọn, oju wọn yoo si jẹra ninu iho rẹ, ahọn wọn yoo si jẹra ni ẹnu wọn. Yoo si ṣe ni ọjọ naa, rogbodiyan nla lati ọdọ Oluwa yoo wa laarin wọn; olukuluku wọn yoo si di ọwọ ẹnikeji rẹ mu, yoo si gbe ọwọ rẹ ga si ọwọ ẹnikeji rẹ.” Sekaraya 14:12, 13. Awọn eniyan buburu ti n gbe inu aye—alufa, alaṣẹ ati awọn eniyan, ọlọrọ ati talaka, ati ẹni giga ati ẹni irẹlẹ ṣubu ninu ijakadi buburu naa lati inu ifẹ gbigbona ọkan wọn ati ibinu ẹlẹru Ọlọrun ti a tu jade laini abula. “Awọn ẹni pipa Ọlọrun ni ọjọ naa yoo wa lati igun aye kan ani de igun aye ikeji: a ki yoo kẹdun fun wọn, tabi ko wọn jọ pọ tabi sin wọn.” Jeremaya 25:33.ANN 291.6
Ni igba wiwa Kristi, a o pa awọn eniyan buburu run kuro lori ilẹ aye—eemi ẹnu Rẹ yoo pa wọn, yoo si pa wọn run pẹlu itansan ogo Rẹ. Kristi a ko awọn eniyan Rẹ lọ si Ilu nla Ọlọrun, ile aye yoo ṣofo, laisi olugbe kankan ninu rẹ. “Kiyesi Oluwa sọ aye di ofo, O paa run, O da ori rẹ kọdo, O tu awọn olugbe inu rẹ ka jinna réré.” “Ilẹ naa yoo ṣofo patapata, a o pa a run patapata: nitori Oluwa ni O sọ eyi.” “Nitori ti wọn ti re awọn ofin kọja, wọn ti yi ilana pada, wọn si ti ba majẹmu jẹ. Nitori naa ni egun a ṣe jẹ aye run, ti awọn olugbe inu rẹ si di ahoro: nitori naa ni a fi fi ina sun awọn olugbe ile aye.” Aisaya 24:1, 3, 5, 6.ANN 292.1
Gbogbo ile aye dabi aginju ti a sọ di ahoro. Alapa awọn ilu nla ati ileto ti ilẹ riri parun, awọn igi ti a fa tu, awọn apata ti a sọ sinu okun tabi ti a fatu kuro ninu ilẹ funra rẹ, fọnka oju ilẹ, iho nla si ṣe ami si ibi ti a ti fa awọn oke naa tu lati ibi ipilẹ wọn.ANN 292.2
Bayi ni iṣẹlẹ ti a ṣe afihan rẹ ninu eto ti o kẹyin ni ọjọ Iwẹnumọ a wa ṣẹlẹ. Nigba ti a ba ti pari iṣẹ iranṣẹ ninu ibi mimọ julọ, ti a si ti ko ẹṣẹ awọn ọmọ Israeli kuro ni ibi mimọ nipasẹ ẹjẹ ọrẹ ẹṣẹ, nigba naa ni a o mu ẹran iya wa siwaju Oluwa laaye; niwaju ijọ eniyan, olu alufa a jẹwọ le lori “gbogbo aiṣedeede awọn ọmọ Israeli, ati irekọja wọn ninu gbogbo ẹṣẹ wọn, yoo ko wọn si ori ewurẹ naa.” Lefitiku 16:21. Bẹẹ gẹgẹ, nigba ti a ba pari iṣẹ iwẹnumọ ninu ibi mimọ ni ọrun, nibẹ niwaju awọn angẹli ọrun ati ogun awọn ti a gbala, a o ko ẹṣẹ awọn eniyan Ọlọrun le Satani lori; yoo jẹbi gbogbo iwa ẹṣẹ ti o mu wọn da. Bi a ti ran ẹran iya naa lọ sinu ilẹ ti a kii gbe, bẹẹ gẹgẹ ni a o le Satani sori ilẹ aye ti a sọ di ahoro, aginju ẹlẹru ti a ko gbe.ANN 292.3
Onifihan sọ asọtẹlẹ lílé Satani si aye ati ipo rudurudu isọdahoro eyi ti ile aye yoo wa, o tun sọ wipe yoo wa ni ipo yii fun ẹgbẹrun ọdun kan. Lẹyin ti o ṣe alaye iṣẹlẹ wiwa Oluwa lẹẹkeji ati iparun awọn eniyan buburu, asọtẹlẹ naa tẹsiwaju wipe: “Mo ri angẹli kan ti ọrun sọkalẹ wa, ti o ni kọkọrọ ọgbun ainisalẹ ati ẹwọn nla ni ọwọ rẹ. O si di dragoni mu, ejo laelae ni, eyi ti i ṣe eṣu, ati Satani, o si de e fun ẹgbẹrun ọdun, o si sọ sinu ọgbun ainisalẹ, o si dee pa, o si fi edidi di i, ki o ma baa tan awọn orilẹ ede jẹ mọ, titi ti ẹgbẹrun ọdun naa yoo fi pe: lẹyin eyi a yoo tu silẹ fun igba diẹ.” Ifihan 20:1—3.ANN 292.4
Wipe ọrọ ti a pe ni “ọgbun ainisalẹ” duro fun aye ni ipo rudurudu ati okunkun fi ara han lati inu ẹri awọn ẹsẹ miran ninu Iwe Mimọ. Nipa ipo ti aye wa “ni atetekọṣe,” akọsilẹ Bibeli sọ wipe “o wa ni juujuu o si ṣofo, okunkun si wa ni oju ibu.” Jẹnẹsisi 1:2. Asọtẹlẹ fi kọni wipe a o da a pada, bi ko tilẹ jẹ ni patapata si ipo yii. Ni wiwo ọjọ iwaju fun ọjọ nla Ọlọrun, woli Jeremaya sọ wipe: “Mo si wo aye, si kiyesi, o wa ni juujuu, o si ṣofo; ati awọn ọrun wọn ko si ni imọlẹ. Mo wo awọn oke, si kiyesii, wọn wariri, a si ṣi gbogbo awọn oke keekeke nipo. Mo wo o, si kiyesi ko si eniyan, ati gbogbo eye oju ọrun sa lọ. Mo wo si kiyesi, awọn ilẹ eleso di aginju, gbogbo awọn ilu nla si wo lulẹ.” Jeremaya 4:23—26.ANN 292.5
Eyi ni yoo jẹ ile Satani pẹlu awọn angẹli buburu rẹ fun ẹgbẹrun ọdun kan. A ha mọ aye yii, ko ni ni anfani si awọn aye miran lati dan wọn wo ati lati bí awọn ti koi tii ṣubu ri ninu. Ni ọna yii ni a gba sọ wipe a de e: ko si ẹni to ku sori ilẹ aye ti o le lo agbara rẹ le lori. A ge kuro ninu iṣẹ itanjẹ ati iparun eyi ti o jẹ ohun idunnu rẹ kan ṣoṣo fun ọpọ ọdun.ANN 292.6
Woli Aisaya, ni wiwo ọjọ iwaju si akoko ti a o bi Satani ṣubu, sọ wipe: “Bawo ni iwọ ti ṣe ṣubu lati ọrun, Lusiferi, ọmọ owurọ! Bawo ni a ti ṣe ge ọ lulẹ, iwọ ti n ṣẹ awọn orilẹ ede ni apa! . . . Iwọ ti wi ni ọkan rẹ pe, emi yoo goke re ọrun, emi yoo gbe itẹ mi ga ju irawọ Ọlọrun lọ: . . . Emi yoo dabi Ọga Ogo. Ṣugbọn a o mu ọ sọkalẹ si iboji, si iha iho. Awọn ti o ri ọ yoo tẹju mọ ọ, wọn yoo si ronu rẹ wipe, Eyi ha ni ọkunrinn ti o mu aye wariri, ti o mi ilẹ ọba tìtì; ti o sọ aye dabi aginju, ti o si pa awọn ilu nla ibẹ run; ti ko ṣi ile awọn onde rẹ silẹ?” Aisaya 14:12—17.ANN 292.7
Fun ẹgbẹrun ọdun mẹfa, iṣẹ iṣọtẹ Satani “ti mu ki aye o wariri.” O ti “mu ki aye o di agunju, o si pa awọn ilu nla rẹ run.” Ko si ṣi awọn onde rẹ silẹ.” Fun ẹgbẹrun ọdun mẹfa awọn eniyan Ọlọrun ti wa ninu ile tubu rẹ, i ba si mu wọn ni igbekun titi lae; ṣugbọn Kristi ti ja ide rẹ, O si ti da awọn onde rẹ silẹ lọfẹ.ANN 293.1
Ani awọn eniyan buburu ko si ni arọwọto agbara Satani nisinsinyii, ni oun nikan pẹlu awọn angẹli buburu rẹ, a ronu lori egun ti ẹṣẹ ti mu wa. “Awọn ọba awọn orilẹ ede, ani gbogbo wọn, ti wọn ti sun ninu ogo, olukuluku ninu ile ara rẹ. Ṣugbọn a le ọ jade kuro ninu iboji rẹ bi ẹka irira. . . . Iwọ ki yoo dapọ mọ wọn ni isinku, nitori ti iwọ ti pa ilẹ naa run, o si ti pa awọn eniyan rẹ.” Aisaya 14:18—20.ANN 293.2
Fun ẹgbẹrun ọdun kan, Satani yoo rin siwa rin sẹyin ninu aye ti a sọdahoro lati fiye si abayọri iṣọtẹ rẹ si ofin Ọlọrun. Ni akoko yii, ijiya rẹ yoo pọ jọjọ. Lati igba ti o ti ṣubu, igbe aye iṣẹ aisinmi rẹ ko jẹ ki o ronu; ṣugbọn nisinsinyii, a gba agbara kuro ni ọwọ rẹ, a si fi silẹ lati ronu lori ipa ti o ko lati igba ti o ti ṣọtẹ si ijọba ọrun, ki o si wo ọjọ iwaju ẹlẹru pẹlu iwariri ati ẹru nigba ti yoo jiya fun gbogbo iwa buburu ti o wu, ti a o si jẹ ẹ niya fun eyi ti o mu ki ẹlomiran o wu.ANN 293.3
Imu-Satani-nigbekun yoo fi ayọ kun inu awọn eniyan Ọlọrun, yoo si mu inu wọn dun. Woli naa sọ pe: “Yoo si ṣe ni ọjọ naa ti Jehofa yoo fun yin ni isinmi kuro ninu ibanujẹ yin ati kuro ninu iṣoro yin, ati kuro ninu iṣẹ lile yin eyi ti a fi yin ṣe, ti ẹyin yoo si pa owe yii si Babiloni [nibi o tumọ si Satani], wipe, Bawo ni aninilara ṣe dawọ duro! . . . Jehofa ti ṣẹ ọpa aṣẹ ẹni buburu, ọpa aṣẹ awọn alaṣẹ, ti o n na awọn eniyan ninu ibinu ni aiṣiwọ, ti o n ṣe akoso awọn orilẹ ede ninu ibinu, pẹlu inunibini ti ẹnikẹni ko da duro.” Ẹsẹ 3—6.ANN 293.4
Ni aarin ẹgbẹrun ọdun naa laarin ajinde akọkọ ati ekeji, a o ṣe idajọ awọn eniyan buburu. Apostoli Pọlu tọka si idajọ yii bi iṣẹlẹ ti o tẹle wiwa lẹẹkeji. “Maṣe ṣe idajọ ohunkohun ṣaaju akoko ti Oluwa yoo fi de, Ẹni ti yoo mu gbogbo ohun ti o pamọ ninu okunkun wa sinu imọlẹ, ti yoo si fi imọran ọkan han.” 1 Kọrintin 4:5. Nigba ti Arugbo Ọjọ ni de, Daniẹli sọ wipe, a fun awọn eniyan mimọ Ẹni Giga julọ ni idajọ.” Daniẹli 7:22. Ni akoko yii awọn olododo a ṣe akoso bi ọba ati alufa si Ọlọrun. Johanu ninu Ifihan sọ wipe: “Mo ri awọn itẹ, ati awọn ti wọn joko lori wọn, a si fi idajọ fun wọn.” “Wọn yoo jẹ alufa Ọlọrun ati ti Kristi, wọn yoo si jọba pẹlu Rẹ fun ẹgbẹrun ọdun.” Ifihan 20:4, 6. Ni akoko yii gẹgẹ bi Pọlu ti sọ ọ tẹle, ni “awọn ẹni mimọ yoo ṣe idajọ aye.” 1 Kọrintin 6:2. Ni iṣọkan pẹlu Kristi wọn a ṣe idajọ awọn eniyan buburu, wọn a fi iwa wọn wé odiwọn, Bibeli, wọn a si ṣe ipinu ohun gbogbo gẹgẹ bi ohun ti wọn ṣe ninu ara. Nigba naa ni a o ṣe odiwọn abala iya ti yoo jẹ awọn eniyan buburu, gẹgẹ bi iṣẹ wọn, a yoo si kọ ọ siwaju orukọ wọn ninu iwe iku.ANN 293.5
Kristi ati awọn eniyan Rẹ ṣe idajọ Satani ati awọn angẹli buburu pẹlu. Pọlu sọ wipe: “Ẹyin ko ha mọ wipe ẹyin ni yoo ṣe idajọ awọn angẹli bi?” Ẹsẹ 3. Juda si sọ wipe “awọn angẹli ti ko duro ni ipo wọn akọkọ, ṣugbọn ti wọn fi ibugbe wọn silẹ ni O pamọ sinu ẹwọn ayeraye labẹ okunkun titi di idajọ ọjọ nla.” Juda 6.ANN 293.6
Ni opin ẹgbẹrun ọdun naa, ajinde keji a waye. Nigba naa ni a o ji awọn ẹni buburu dide kuro ninu oku wọn yoo si farahan niwaju Ọlọrun fun imuṣẹ “idajọ ti a kọ silẹ.” Lẹyin ti o ṣe alaye ajinde awọn olododo tan, onifihan sọ bayii pe: “Awọn ti o ku ninu awọn oku ko si wa laaye titi ti ẹgbẹrun ọdun naa fi pari.” Ifihan 20:5. Aisaya pẹlu sọ nipa awọn eniyan buburu wipe: “A o ko wọn jọ. Bi a ti n ko awọn onde jọ sinu iho, a o si ti wọn mọ inu tubu, lẹyin ọjọ pupọ a o si bẹ wọn wo.” Aisaya 24:22.ANN 293.7