Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  ORI KẸRINDINLOGOJI—IKỌLU TI N BỌ

  O jẹ erongba Satani lati bi ofin Ọlọrun wo lulẹ lati igba ti ijakadi nla naa ti bẹrẹ ni ọrun. Nitori a ti le ṣe eleyi, ni o fi ṣọtẹ si Ẹlẹda, bi o tilẹ jẹ wipe a le kuro ni ọrun, o mu ki ijakadi kan naa o tẹsiwaju lori ilẹ aye. Lati le tan eniyan jẹ ati lati dari wọn lati ru ofin Ọlọrun, ni afojusun ti o n le laifasẹyin. Boya a ṣe eyi nipa kikọ gbogbo ofin silẹ, tabi kikọ ọkan ninu awọn ilana rẹ silẹ, ohun kan naa ni yoo jasi nikẹyin. Ẹni ti o ba jẹbi “ninu ohun kan” kẹgan gbogbo ofin, ipa ati apẹẹrẹ wa ni ẹba irekọja; o “jẹbi gbogbo rẹ.” Jakọbu 2:10.ANN 259.1

  Ni wiwa lati ko ẹgan ba ofin Ọlọrun, Satani ti yi awọn ikọni Bibeli sodi, nipa eyi a si ti fi eke sinu igbagbọ ọpọlọpọ ti wọn sọ pe awọn gba Iwe Mimọ gbọ. Ijakadi nla ti o kẹyin laarin otitọ ati eke jẹ ijakadi ti o kẹyin ninu ijakadi ọlọjọ pipẹ nipa ofin Ọlọrun. A n wọ inu ogun naa lọ bayii—ogun laarin ofin eniyan ati ilana Jehofa, laarin ẹsin Bibeli ati ẹsin aṣa ati itan arosọ.ANN 259.2

  Awọn agbara ti yoo parapọ lati tako otitọ ati ododo ninu ijakadi yii n fi gbogbo agbara ṣiṣẹ bayii. A ko ka ọrọ mimọ Ọlọrun, ti a fi fun wa pẹlu iye owo ijiya ati ẹjẹ si. Bibeli wa ni arọwọto gbogbo eniyan, ṣugbọn iwọnba awọn perete ni wọn gba a gẹgẹ bi adari igbesi aye. Aigbagbọ n gbilẹ ni ọna ti o banilẹru, ki i ṣe ninu aye nikan, ṣugbọn ninu ijọ pẹlu. Ọpọlọpọ ni wọn n sẹ awọn igbagbọ ti wọn jẹ opo igbagbọ Kristẹni. Itan dida aye, bi awọn onkọwe ti a mi si ti gbe kalẹ, iṣubu eniyan, iwẹnumọ, ati bi ofin Ọlọrun ti wa titi lae ni awọn ti wọn pe ara wọn ni Kristẹni ti kọ silẹ, boya ni gbogbo rẹ pata tabi ni abọ. Ọgọọrọ awọn ti wọn n gbe ara wọn ga ninu ọgbọn ati ominira wọn ri gẹgẹ bi ami ailera lati ni igbẹkẹle patapata ninu Bibeli, wọn ro wipe ami ẹbun ti o ga ati imọ ni lati ṣe awawi eke si Iwe Mimọ, ati lati ṣe alaye awọn otitọ nla inu rẹ gẹgẹ bi ohun ẹmi ti ko ni i ṣe pẹlu wa. Ọpọ awọn oniwaasu ni wọn n kọ awọn eniyan wọn, ti ọpọlọpọ ọjọgbọn ati olukọ n kọ awọn akẹkọ wọn, wipe a ti yi ofin Ọlọrun pada tabi pe a ti sọ di asan, a si ro wipe awọn ti wọn ri ohun ti o wi gẹgẹ bi eyi ti o si lagbara ti o si yẹ ki a ṣe igbọran si wọn bi wọn ti sọ ni o yẹ fun ẹgan ati ifi-ṣe-ẹlẹya.ANN 259.3

  Ni kikọ otitọ silẹ, awọn eniyan n kọ Ẹni ti O kọ ọ silẹ. Ni titẹ ofin Ọlọrun loju, wọn n sẹ aṣẹ Ẹni ti O n funni lofin. O rọrun lati sọ igbagbọ ati ero eke di oriṣa gẹgẹ bi a ti n ṣe si okuta tabi igi. Nipa fifi Ọlọrun han ni ọna ti ko tọ, Satani n dari eniyan lati wo O pẹlu iwa ti ko bojumu. Pẹlu ọpọlọpọ, a ti gbe oriṣa ironujinlẹ ka ori itẹ dipo Jehofa; nigba ti o jẹ wipe awọn perete ni wọn n jọsin Ọlọrun alaaye, gẹgẹ bi a ti fihan ninu ọrọ Rẹ, ninu Kristi, ati ninu iṣẹ ohun ti a da. Ọpọ eniyan ni wọn n sọ ẹda di Ọlọrun ti wọn si n ṣe Ọlọrun gẹgẹ bi ẹda. Ẹsin ibọriṣa wa ninu ẹsin Kristẹni loni gẹgẹ bi o ti wa laarin awọn ọmọ Isreali ni akoko Elija, bi o tilẹ jẹ wipe o wa ni ọna ti o yatọ. Ọlọrun ọpọlọpọ awọn ti wọn pe ara wọn ni ọlọgbọn eniyan, awọn alaronujinlẹ, akewi, oloṣelu, akọroyin—ọlọrun awọn ẹgbẹ ọlaju, ti ile ẹkọ giga ati kọlẹji, ati ti awọn ile ẹkọ miran ti a ti n kọni nipa Ọlọrun—fi diẹ san ju Baali, ọlọrun oorun awọn ara Foenisia lọ.ANN 259.4

  Ko si aṣiṣe ti awọn Kristẹni gba ti o fi igboya tako aṣẹ Ọrun, ko si eyi ti o tako iṣọwọronu, ko si eyi ti o lewu ninu ayọrisi rẹ, bi ikọni ode oni, ti o yara kankan n tan kalẹ, wipe ofin Ọlọrun ko ni aṣẹ lori eniyan mọ. Gbogbo orilẹ ede ni o ni ofin rẹ, eyi ti a gbọdọ bọwọ fun, ki a si ṣe igbọran si; ko si ijọba ti o le wa laisi wọn; njẹ a wa le ro wipe Ẹlẹda ọrun ati aye ko ni ofin lati ṣe akoso awọn ohun ti a da bi? Ẹ jẹ ki a ro o wipe alaṣẹ nla kan sọ ọ ni gbangba wipe awọn ofin to n ṣe akoso ilẹ wọn ti o tun daabo bo ẹtọ awọn ọmọ ilu ko ni aṣẹ mọ—wipe wọn din ominira awọn eniyan ku, nitori naa a ko gbọdọ ṣe igbọran si wọn, bawo ni a o ti gba a laaye lori pẹpẹ to? Ṣugbọn ṣe o jẹ ẹṣẹ ti o lewu ki a kọ ofin ilu ati ti orilẹ ede silẹ, ju ki a tẹ awọn ofin ti wọn jẹ ipilẹ fun gbogbo ijọba silẹ lọ?ANN 259.5

  Yoo dara ki awọn orilẹ ede o pa ofin wọn run, ki wọn si gba awọn eniyan laaye ki wọn ṣe bi wọn ti fẹ ju ki Alaṣẹ gbogbo aye o fagi le ofin Rẹ lọ, ki o si fi aye silẹ laini odiwọn lati da ọdaran lẹbi ati lati da olugbọran lare. Ṣe a fẹ mọ ayọrisi sisọ ofin Ọlọrun di asan? A ti dan wo ri. Awọn ohun ti wọn ṣẹlẹ ni France nigba ti igbagbọ wipe ko si Ọlọrun jẹ agbara iṣakoso jẹ eyi to banilẹru. Nigba naa ni a fihan araye wipe lati kọ idena ti Ọlọrun gbe kalẹ silẹ ni lati gba aṣẹ lọwọ onroro ti o nika julọ. Nigba ti a ba kọ odiwọn otitọ silẹ, a ṣi ọna silẹ fun ọmọ alade iwa buburu lati fi idi agbara rẹ mulẹ ninu aye.ANN 260.1

  Nibikibi ti a ba ti kọ ilana Ọlọrun silẹ, ẹṣẹ ko ni fi ara han bi ẹṣẹ mọ, bẹẹ ni ododo ko ni wuni. Awọn ti wọn kọ lati tẹriba fun iṣejọba Ọlọrun ko yẹ rararara lati ṣe akoso ara wọn. Nipasẹ ikọni buburu wọn a n gbin ẹmi aigbọran sinu ọkan awọn ọmọde ati ọdọ, ti wọn ko ni suuru lati gba ki a dari wọn tẹlẹ; awujọ ti ko ni ofin, ti ko si ni akoso ni yoo jẹ ayọrisi rẹ. Nigba ti wọn n kẹgan igbagbọ awọn ti wọn ṣe igbọran si ọrọ Ọlọrun, ọpọ awọn eniyan n yara kankan lati gba itanjẹ Satani. Wọn jọwọ ara wọn fun ifẹkufẹ ara ati awọn ẹṣẹ ti wọn pe idajọ wa si ori awọn alaigbagbọ.ANN 260.2

  Awọn ti wọn kọni lati fi oju tinrin wo ofin Ọlọrun n gbin aigbọran lati kore aigbọran. Ẹ jẹki a kọ idiwọ ti ofin Ọlọrun ṣe funni silẹ patapata, laipẹ a o si kọ ofin eniyan silẹ. Nitori pe Ọlọrun ko fi aaye gba iwa aiṣootọ, oju kokoro, irọ, ati irẹnijẹ, awọn eniyan ṣetan lati tẹ ofin Rẹ loju nitori ti o jẹ idiwọ fun kíkó aye ti wọn fẹran jọ; ṣugbọn ayọrisi kikọ awọn ofin yii silẹ yoo jẹ eyi ti wọn ko ni ireti. Bi ofin ko ba de eniyan, kilode ti a o fi nilati bẹru lati dẹṣẹ? Ko ni si aabo fun ohun ini mọ. Awọn eniyan yoo gba ohun ini ẹnikeji wọn pẹlu ipa, awọn to ba lagbara julọ ni yoo jẹ ọlọrọ julọ. A ko ni bọwọ fun ẹmi funra rẹ. Ẹjẹ igbeyawo ko ni duro gẹgẹ bi aabo mimọ lati daabo bo idile mọ. Ẹni ti o ba ni agbara, bi o ba fẹ, yoo fi ipa gba iyawo alabagbe rẹ. A o kọ ofin karun silẹ pẹlu ikẹrin. Awọn ọmọ ko ni bẹru lati gba ẹmi awọn obi wọn bi wọn yoo ba ri ifẹ ọkan idibajẹ wọn ṣe nipa ṣiṣe bẹẹ. Aye ọlaju yoo di iwo ọlọṣa ati apaniyan, alaafia, isinmi ati iduunu yoo kuro lori ilẹ aye.ANN 260.3

  Gẹgẹ bi a ti ri na, ikọni wipe eniyan ko nilo lati ṣe igbọran si ofin Ọlọrun mọ ti ko aarẹ ba agbara ojuṣe iwa rere, o si ṣi ilẹkun agbara ẹṣẹ sori aye. Ailofin, imuti, ati iwa ibaje n wọle wa gẹgẹ bi igbi omi àgbàrá. Ninu idile, Satani n ṣiṣẹ. Asia rẹ n fẹ lẹlẹ, ani ninu ile awọn ti wọn pe ara wọn ni Kristẹni. Ilara, ero buburu, iwa agabagebe, iyapa, ijowu, ija, aika ifọkantan ọlọwọ si, titẹ ifẹkufẹ ara lọrun n wa. Gbogbo ilana igbagbọ ẹsin ati ikọni, eyi ti i ba jẹ ipilẹ ati ilana fun awujọ, dabi ẹru nla ti n mi dugbẹdugbẹ ti o ṣetan lati wo lulẹ. Nigba ti a ba ju eyi ti o buru julọ ninu awọn ọdaran sinu ọgba ẹwọn fun ẹṣẹ wọn, a n fiyesi wọn, a si n fun wọn ni ẹbun afi bi ẹnipe wọn ṣe ohun ti o dara. A n ṣe ikede iwa ati ẹṣẹ wọn lona ti o ga. Awọn ile itẹwe n ṣe atẹjade iwa buburu ti o ṣi ni lara ni kikun, nipa eyi wọn n fi iwa irẹnijẹ, ole, ati ipaniyan n lọ awọn miran, Satani si n yọ ninu aṣeyọri ète buburu rẹ. Onfa iwa ibi, pipaniyan lainidi, bi iwa ailekora-ẹni-nijanu ti pọ ni ọna ti o lewu, ati iwa aiṣedeede ni iye rẹ ati ni ipele rẹ, yẹ ki o ta gbogbo ẹni ti o ba bẹru Ọlọrun ji, lati beere ohun ti a le ṣe lati dawọ igbi iwa buburu duro.ANN 260.4

  Ile idajọ kun fun iwa ibajẹ. Awọn alaṣẹ n ṣiṣẹ nitori ifẹ fun ere ati ifẹ faaji. Ailekora-ẹni-nijanu ti fọ ọpọlọpọ niye debi pe Satani ti fẹrẹ gba akoso lori wọn tan patapata. Awọn onidajọ ti dibajẹ, wọn n gba abẹtẹlẹ, a si n tan wọn jẹ. Iwa ọmuti ati ainiwọntuwọnsi, ifẹ ara, ilara, aiṣootọ loriṣiriṣi, ni o wa laarin awọn ti n ṣiṣẹ ofin. “Idajọ duro jinna réré: nitori ti otitọ ti ṣubu ninu ilu; idọgba ko si le wọle.” Aisaya 59:14.ANN 260.5

  Ẹṣẹ ati okunkun ẹmi ti o gbilẹ labẹ akoso Romu jẹ abayọri ti a ko le dena nitori bi o ti ṣe tẹ Iwe Mimọ ri; ṣugbọn nibo ni a ti le ri idi fun aigbagbọ ti o gbilẹ kan, kikọ ofin Ọlọrun silẹ, ati iwa ibajẹ ti o tẹle, labẹ ina iyinrere ti n jo kikankikan ni akoko ominira ẹsin? Ni bayi, Satani ko le fi aye si abẹ akoso rẹ nipa fifi Iwe Mimọ pamọ, o wa ọna miran lati ṣe ohun kan naa. Biba igbagbọ inu Bibeli jẹ yoo ran an lọwọ bi pipa Bibeli run funra rẹ. Nipa mimu igbagbọ wipe ofin Ọlọrun ko lagbara mọ wa, o n ṣe aṣeyege ni didari awọn eniyan lati dẹṣẹ bi ẹnipe wọn jẹ alaimọkan patapata si awọn ilana rẹ. Ni akoko yii, bii ti awọn igba to ti kọja, o ṣiṣẹ nipasẹ ijọ lati mu ero rẹ ṣẹ. Ẹgbẹ ẹsin ti ode oni kọ lati tẹti si awọn otitọ ti ko gbajugbaja ti a fihan kedere ninu Iwe Mimọ, ati pe ni titako wọn, wọn lo iṣọwọtumọ ati ọrọ ti o gbin irugbin aigbagbọ kaakiri. Ni rirọ mọ aṣiṣe ijọ padi niti wipe a bi aiku mọni ati pe eniyan si ni imọ ninu iku, wọn ti kọ aabo kan ṣoṣo ti wọn ni lati tako ẹtan ibẹmilo silẹ. Ikọni ijiya ainipẹkun ti mu ki ọpọlọpọ o sẹ igbagbọ ninu Bibeli. Ati bi a ti n kọ awọn eniyan ni ojuṣe wọn si ofin kẹrin, a ri wipe a sọ funni lati pa ọjọ keje mọ, gẹgẹ bi ọna kan ṣoṣo lati yọ ara wọn kuro ninu ojuṣe ti wọn ko fẹ ṣe, ọpọ awọn olukọ ti wọn lokiki sọ wipe ofin Ọlọrun ko ni aṣẹ mọ. Wọn ju ofin Ọlọrun ati ọjọ Isinmi sọnu papọ. Bi iṣẹ atunṣe nipa ọjọ Isinmi ti n tẹsiwaju, ikọsilẹ ofin Ọlọrun yii lati maṣe pa ọjọ Isinmu mọ yoo fẹrẹ di kari aye. Awọn ikọni awọn olori ẹsin ti ṣi ilẹkun silẹ fun aigbagbọ, fun ibẹmilo, ati fun gigan ofin mimọ Ọlọrun, awọn olori wọnyii ni wọn ṣe okunfa fun iwa ẹṣẹ to wa ninu ẹsin Kristẹni.ANN 260.6

  Sibẹ, awọn wọnyi n sọ wipe iwa ibajẹ to n yara kankan tan kalẹ yii waye nitori bi a ti n ba eyi ti a n pe ni “Ọjọ Isinmi Kristẹni” jẹ, ati pe fifi ofin muni pa ọjọ Sọnde mọ yoo da iwa rere pada sinu awujọ. A n ṣe ikede yii, ni pataki julọ ni ilẹ Amẹrika, nibi ti a ti waasu igbagbọ nipa ọjọ Isinmi tootọ julọ. Nibi, iṣẹ iwọntuwọnsi, ọkan ninu iṣẹ atunṣe ìwà ti o lokiki to tun ṣe pataki julọ, ni a saba maa n sopọ mọ ẹgbẹ ti n ja fun ọjọ Sọnde, ti awọn ti n polongo rẹ si n fi ara wọn han gẹgẹ bi ẹnipe wọn n ṣe iṣẹ ti o dara fun awujọ, awọn ti wọn si kọ lati darapọ mọ wọn ni a pe ni ọta iwọntuwọnsi ati iṣẹ atunṣe. Ṣugbọn nitori pe ẹgbẹ ti o fi idi aṣiṣe mulẹ darapọ mọ iṣẹ ti o dara funra rẹ, ko ni ki a fi oju rere wo aṣiṣe naa. A le fi majele pamọ nipa riro o pọ mọ ounjẹ ti o dara, ṣugbọn a ko yi iṣẹda rẹ pada. Dipo eyi, o tubọ lewu si ni, nitori pe a le jẹ ẹ laimọ. O jẹ ọkan lara awọn ete Satani lati da eke pọ mọ ọpọlọpọ otitọ lati le fun ni iyin. Awọn adari ẹgbẹ fun ọjọ Sọnde le kede iṣẹ atunṣe ti awọn eniyan nilo, awọn ẹkọ ti wọn wa ni ibamu pẹlu Bibeli, sibẹ niwọn igba ti wọn ba ṣi ni ohun kan ti o tako ofin Ọlọrun, awọn iranṣẹ Rẹ ko le darapọ mọ wọn. Ko si ohun ti o le dawọn lare lati kọ aṣẹ Ọlọrun silẹ fun ilana eniyan.ANN 261.1

  Nipasẹ aṣiṣe nla meji yii, aiku ọkan ati wipe ọjọ Sọnde jẹ mimọ, Satani yoo ko awọn eniyan si abẹ ẹtan rẹ. Nigba ti eyi akọkọ se ipilẹ fun ibẹmilo, eyi ti o kẹyin mu ibaṣepọ pẹlu Romu wa. Awọn Protestant United States yoo jẹ ẹni akọkọ lati na ọwọ wọn kọja ọgbun lati di ibẹmilo mu, wọn a na ọwọ wọn kọja koto nla lati so ọwọ pọ pẹlu agbara Romu; labẹ agbara irẹpọ mẹtẹẹta yii, orilẹ ede yii yoo tẹle isisẹ Romu lati tẹ ẹtọ si ẹri ọkan loju.ANN 261.2

  Bi ibẹmilo ti n farawe ẹsin Kristẹni afẹnujẹ ti ode oni, o ni agbara ti o pọ si lati tannijẹ ati lati dẹkun muni. Satani funra rẹ ti yipada, o n tẹle ilana ọlaju asiko yii. Yoo fi ara han gẹgẹ bi angẹli imọlẹ. Nipasẹ ohun elo ibẹmilo, a o ṣe iṣẹ iyanu, awọn alaisan a ri iwosan, ọpọlọpọ awọn iṣẹ iyanu ti a ko le sẹ ni yoo ṣẹlẹ. A ti bi awọn ẹmi naa ba ti n sọ wipe wọn gbagbọ ninu Bibeli, ti wọn si n bọwọ fun awọn agbekalẹ ijọ, a o gba iṣẹ wọn gẹgẹ bi ifarahan agbara Ọlọrun.ANN 261.3

  Ami idanimọ laarin awọn ti wọn pe ara wọn ni Kristẹni ati awọn alaiwabiọlọrun ti fẹrẹ parẹ tan. Awọn ọmọ ijọ fẹran awọn ohun ti aye fẹran, wọn si ṣetan lati darapọ mọ wọn, Satani si pinu lati so wọn pọ sinu ara kan ki o si fun iṣẹ rẹ lokun nipa gbígbá gbogbo wọn sinu ẹgbẹ ibẹmilo. Awọn atẹle popu ti wọn n fọnnu wipe iṣẹ iyanu jẹ ami pato lati mọ ijọ tootọ, yoo ṣe e tanjẹ ni kiakia nipasẹ agbara ti n ṣiṣẹ iyanu yii; ati awọn Protestant, nigba ti wọn ti kọ apata otitọ silẹ, a o tan wọn jẹ pẹlu. Awọn atẹle popu ati awọn araye bakan naa yoo gba afarawe iwabiọlọrun laisi agbara rẹ, wọn a si ri ninu ẹgbẹ nla yii iyipada araye ati gbigbe ẹgbẹrun ọdun ti a ti n reti fun igba pipẹ wọle.ANN 261.4

  Nipasẹ ibẹmilo, Satani fi ara han gẹgẹ bi ẹni ti o n ṣe araye loore, o n wo aisan awọn eniyan san, o si n sọ wipe oun n mu ilana ẹsin igbagbọ tuntun ti o dara wa; ṣugbọn bakan naa o n ṣiṣẹ lati pa wọn run. Awọn idanwo rẹ n dari ọpọlọpọ sinu iparun. Ainiwọntuwọnsi ki i muni ronu, titẹ ifẹ ara ẹni lọrun, ija ati itajẹsilẹ a tẹle. Satani ni inudidun si ogun, nitori ti o n ru itara ti o buru julọ ninu ọkan soke, a wa gba awọn ẹni igbekun rẹ ti wọn ti kun fun iwa ibajẹ ati ẹjẹ sinu ayeraye. Erongba rẹ ni lati ru awọn orilẹ ede soke lati ba ara wọn jagun, nitori nipa eyi a yi awọn ọkan kuro ninu iṣẹ imura silẹ lati le duro ni ọjọ Ọlọrun.ANN 261.5

  Satani n ṣiṣẹ nipasẹ awọn ohun inu aye lati le kore awọn ti ko mura silẹ. O ti kọ nipa aṣiri iṣẹda, o si n lo gbogbo agbara rẹ lati dari awọn nnkan wọnyi niwọn bi Ọlọrun ba ti gba a laaye to. Nigba ti a gba a laaye lati jẹ Jobu niya, ẹ wo bi ẹran ọsin, ati agbo ẹran, iranṣẹ, ile ati awọn ọmọ ṣe padanu, ti ajalu kan n tẹle ekeji lẹyẹ ò sọka. Ọlọrun ni o n daabo bo awọn ẹda Rẹ ti O si mọ odi yi wọn ka kuro lọwọ agbara apanirun. Ṣugbọn awọn Kristẹni ti fi ẹgan wọn han si ofin Jehofa, Oluwa a si ṣe ohun ti O kede wipe Oun yoo ṣe—yoo fa ọwọ ibukun Rẹ kuro ninu aye, yoo si mu aabo Rẹ kuro lori awọn ti wọn ṣọtẹ si ofin Rẹ, ti wọn n kọ awọn miran, ti wọn si n fi ipa mu mu wọn lati ṣe bẹẹ. Satani ní akoso lori gbogbo awọn ti Ọlọrun ko daabo bo. Yoo ṣe rere fun awọn kan, yoo bukun wọn lati tẹ iṣẹ rẹ siwaju, yoo si ko wahala ba awọn miran, a si mu ki awọn eniyan o gbagbọ wipe Ọlọrun ni o n jẹ wọn niya.ANN 262.1

  Nigba ti o n fi ara han fun awọn ọmọ eniyan gẹgẹ bi oluwosan nla ti o le wo gbogbo aisan wọn, yoo mu aisan ati ajalu wa, titi ti ilu nla a fi parun tan ti a si di ahoro. Ani bayii, o wa lẹnu iṣẹ. Ninu ijamba ati ajalu lori okun ati ilẹ, ninu ina nla, ẹfuufu lile ati yinyin alagbara, ninu iji, ikun omi, afẹfẹ, igbi omi, ilẹ riri, ni ibi gbogbo, ni oriṣiriṣi ọna, Satani n lo agbara rẹ. O n gba ikore ti o ti pọn danu, iyan ati inira a si tẹle. O n mu òórùn buburu wa sinu afẹfẹ, ti ọpọ eniyan si n ku nipasẹ ajakalẹ arun. Awọn abẹwo wọnyi a maa wa lemọlemọ a si maa lewu si. Iparun yoo wa lori eniyan ati ẹranko. “Ile aye n kẹdun o si n ṣa,” “awọn agberaga . . . ru. Aye pẹlu ti dibajẹ, nitori awọn olugbe inu rẹ; nitori ti wọn ti tàpá si ofin, wọn ti yi ilana pada, wọn si ti da majẹmu ayeraye.” Aisaya 24:4, 5.ANN 262.2

  Nigba naa ni atannijẹ nla naa a rọ awọn eniyan rẹ wipe awọn ti n sin Ọlọrun ni wọn n fa awọn iṣẹlẹ ibi wọnyi. Awọn ti wọn fa ibinu Ọlọrun yoo fi ẹsun gbogbo wahala wọn kan awọn ti igbọran wọn si ofin Ọlọrun jẹ ibawi atigbadegba fun awọn ẹlẹṣẹ. A o sọ wipe awọn eniyan n bi Ọlọrun ninu nipa riru isinmi ọjọ Sọnde; wipe ẹṣẹ ti mu àjálù wá, eyi ti ko ni ṣiwọ ayafi bi a ba fipa muni pa ọjọ Sọnde mọ; ati pe awọn ti n waasu nipa ofin kẹrin, ti wọn n tipasẹ eyi n ba ọjọ Sọnde jẹ, ni awọn ti n da eniyan laamu, ti wọn di idapada ojurere Ọlọrun ati ọrọ aye yii lọwọ. Bayi iru ẹsun ti a fi kan iranṣẹ Ọlọrun ni igba atijọ ni a o tunsọ, ati lori ohun kan naa ti a fi idi rẹ mulẹ daradara: “O si ṣe, nigba ti Ahabu ri Elija, Ahabu wi fun pe, Ṣe iwọ ni, ẹni ti n yọ ile Isreali lẹnu? Oun si da a lohun wipe, emi kọ ni o n yọ Isreali lẹnu; bikoṣe iwọ ati ile baba rẹ, ni ti wipe ẹyin ti kọ ofin Oluwa silẹ, ẹ si ti tẹle Baalimu.” 1 Awọn Ọba 18:17, 18. Bi ibinu awọn eniyan ba ṣe n ru soke nitori ẹsun eke yii, wọn a wuwa si awọn aṣoju Ọlọrun eyi ti yoo dabi eyi ti Isreali apẹyinda wu si Elija.ANN 262.3

  Agbara ti n ṣe iṣẹ iyanu ti o farahan nipasẹ ibẹmilo a ṣa ipa rẹ lati tako awọn ti wọn yàn lati gbọ ti Ọlọrun ju ti eniyan lọ. Ohùn lati ọdọ awọn ẹmi wa yoo sọ wipe Ọlọrun ti ran wọn lati fi aṣiṣe awọn ti wọn kọ ọjọ Sọnde silẹ han wọn, wọn a sọ pe a nilati ṣe igbọran si ofin orilẹ ede gẹgẹ bi ofin Ọlọrun. Wọn a kẹdun fun iwa ibajẹ nla ti o wa ninu aye, wọn a si kín ẹri awọn olukọ ẹlẹsin lẹyin wipe iwa ibajẹ ti o wa ninu ilu waye nitori pe a n ba ọjọ Sọnde jẹ ni. Ibinu nla ni a o fihan si awọn ti wọn kọ lati gba ẹri wọn.ANN 262.4

  Iṣọwọṣiṣẹ Satani ninu ijakadi ti o kẹyin yii pẹlu awọn eniyan Ọlọrun jẹ eyi kan naa ti o lo ni ibẹrẹ ijakadi nla naa ni ọrun. O sọ wipe oun fẹ lati jẹ ki ijọba Ọlọrun o fi ẹsẹ mulẹ, nigba ti o n ṣiṣẹ ni idakọnkọ lati bi i lulẹ. Iṣẹ gan an ti o n ṣe ni o fi ẹsun rẹ kan awọn angẹli ti wọn jẹ olootọ. Ilana itanjẹ kan naa ni o farahan ninu itan ijọ Romu. O sọ pe oun n ṣiṣẹ gẹgẹ bi aṣoju Ọrun, nigba ti o n wọna lati gbe ara rẹ ga ju Ọlọrun lọ ti o si n yi ofin Rẹ pada. Labẹ iṣakoso Romu, a pe awọn ti wọn jiya iku nitori iṣotitọ wọn si iyinrere ni aṣebi, a sọ wipe wọn wa ni iṣọkan pẹlu Satani; gbogbo ọna ti o ṣe e ṣe ni a lo lati ko itiju ba wọn, lati mu ki awọn eniyan o ri wọn, ani ki awọn funra wọn o ri ara wọn gẹgẹ bi ọdaran ti o buru julọ. Bẹẹ gẹgẹ ni yoo ti ri ni akoko yii. Nigba ti Satani n wọna lati pa awọn ti wọn bọwọ fun ofin Ọlọrun run, yoo jẹ ki a fi ẹsun kan wọn gẹgẹ bi awọn ti ko bu ọla fun Ọlọrun ti wọn si n fa idajọ Rẹ wa si ori aye.ANN 262.5

  Ọlọrun ki i fi ipa mu ifẹ tabi ẹri ọkan ẹni, ṣugbọn ohun ti Satani saba maa n lo—lati ni akoso lori awọn ti ko le tanjẹ—ni ifipamuni pẹlu iwa ika. Nipasẹ ẹru tabi agbara, o ṣe akitiyan lati ṣe akoso ẹri ọkan ki o si gba ijọsin fun ara rẹ. Lati ṣe eyi, o n ṣiṣẹ nipasẹ awọn alaṣẹ ẹsin ati oṣelu, o n mi si wọn lati fi ipa muni ṣe igbọran si ofin eniyan ni atako si ofin Ọlọrun.ANN 263.1

  Awọn ti wọn bọwọ fun ọjọ Isinmi Bibeli ni a o bawi gẹgẹ bi ọta ofin ati eto, wipe wọn n wo ohun ti n muni wuwa rere lawujọ lulẹ, wọn ṣe okunfa iwa rudurudu ati iwa ibajẹ, ati pe wọn n pe idajọ Ọlọrun wa si ori aye. Iwoye pẹlu otitọ inu wọn ni a o pe ni aigbọran, orikunkun ati ikẹgan ofin. A o fi ẹsun kan wọn wipe wọn ko fẹran ijọba. Awọn oniwaasu ti wọn sọ wipe a ko nilo lati ṣe igbọran si ofin Ọlọrun a waasu lori pẹpẹ wipe a ni ojuṣe lati ṣe igbọran si aṣẹ ilu gẹgẹ bi eyi ti Ọlọrun fi ọwọ si. Ni awọn ile aṣofin, gbọngan idajọ, a o fi awọn ti n pa ofin mọ han ni ọna ti ko tọ, a o si da wọn lẹbi. A o ṣi ọrọ wọn tumọ, a o tumọ erongba wọn ni ọna to buru julọ.ANN 263.2

  Bi awọn ijọ Protestant ti n kọ ọrọ Iwe Mimọ ti o han kedere ti o tun fi ofin Ọlọrun han silẹ, wọn a fẹ lati pa awọn ti wọn ko le fi Bibeli bi igbagbọ wọn wó lẹnu mọ. Bi o tilẹ jẹ wipe wọn fọ oju ara wọn si otitọ naa, wọn n ṣe nisinsinyii ohun ti yoo yọri si inunibini si awọn ti wọn fi tọkantọkan kọ lati ṣe ohun ti awọn Kristẹni yooku n ṣe, ni ṣiṣe igbọran si ọjọ isinmi popu.ANN 263.3

  Awọn alaṣẹ ijọ ati ilu a parapọ lati funni ni abẹtẹlẹ, lati parọwa si ni tabi lati fi ipa mu gbogbo eniyan lati bọwọ fun ọjọ Sọnde. Wọn a fi ofin aninilara rọpo aṣẹ Ọlọrun ti kò si nibẹ. Iwa ibajẹ inu oṣelu n ba ifẹ fun ododo ati ọwọ fun otitọ jẹ; ani ni ilẹ Amẹrika ti ominira wa, awọn alaṣẹ ati aṣofin, lati le ri oju rere awọn eniyan, a tẹ si ohun ti gbogbo aye n fẹ lati fi ofin de pipa ọjọ Sọnde mọ. A ko wa ni bọwọ fun ominira ọkan mọ, eyi ti o náni ni irubọ nla lati ni. Ninu ikọlu ti n bọwa laipẹ, a o ri imuṣẹ ọrọ woli naa: “Dragoni naa si binu gidigidi si obinrin naa, o si lọ ba eyi ti o ṣeku ninu iru ọmọ rẹ jagun, awọn ti n pa ofin Ọlọrun mọ, ti wọn si ni ẹri Jesu Kristi.” Ifihan 12:17.ANN 263.4

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents