Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORÍ KẸRÌNLÁ ÒMÌNIRA Ẹ̀SÌN

    Àdúrà Tí ó Tọ́

    Dáfídì gbàdúrà, “Ó tó àkókò fún Ọ, Olúwa: nítorí tí wọn ti sọòfin Rẹ di asàn”. A ó ríi wípé rẹgí ni àdúrà yíì bá àkókò yíì mu. Ayé tí ṣáko jìnnà, kúrò lọdọ Ọlọrun ati ipò àìlófin ti ayé wà yíì yẹ ki ó mú ẹru ba ọkàn kí ó sì dari gbógbó ọkàn àwọn tí ó jẹ olótìtọọ sí ọdọ Ọba Àgbà fún àtúnṣe.IIO 155.1

    Agbára Ìjọ Àgùdà èyí tí ó ti rò láti yì òfin Ọlọrun padà nípa fífi ayédèru Ọjọ Isìnmi dípò Ọjọ Isìnmi ti Jèhófà, tóbẹẹ tó fi jẹ wípe ní káákìri àgbáyé ni gbogbo áwọn Onígbagbọ tí n bọwọ tí wọn sí ń bu ọlá fún ayédèru Ọjọ Ìsinmi yìí nígbàtí èyí tí ó jẹ Ọjọ Ìsinmi tòótọ di ohun àìlọwọ níwájú àwọn ènìyàn.IIO 155.2

    Lórí òfin Ọlọrun yìí ni ìjàkadì ńlá tí ó gbẹhin láàín Kristi ati Sátánì lórí ile aye yóò dá lé lórí èyí tí yóò mú kí gbogbo énìyàn aye o ṣe ipinnu tí wọn bá fẹ....kìí ṣe wípé àwọn ènìyàn pàtàkì yóò fi ojú tẹmbẹlú Ọjọ Ìsinmi fúnra wọn ṣùgbọn àwọn tí à ń wò gẹgẹbi ènìyàn Ọlọrun pàápàá, yóò fi agbára mú àwọn ènìyàn láti pa Ọjọ kìn-ín-ní ọsẹ mọ. Wọn ó máa tọka àwọn ènìyàn sí àwọn àjálù, ìjì, ìkún omi, ilẹ ríru àti ìṣẹlẹ iná gẹgẹbí ìdájọ ti o ń fihan wípé inú Ọlọrun kò dùn si pípa ọjọ kèéjè mọ gẹgẹbí Ọjọ Ìsinmi. Àwọn àjálù wọnyí yóò ma pọ síi nígbàgbo tí ìran yóò sì máa tẹle òmíràn tí àwọn tí ń tako òfin Ọlọrun yóò máa tọka sí àwọn diẹ tí ń pa òfin Ọjọ Ìsinmi tòótọ ti òfin kẹẹrin mọ gẹgẹbí àwọn tí ó ń mú rògbòdìyàn bá orílẹ èdè ayé. Àgbékalẹ èké yìí jẹ ètè Sátánì láti dẹ tàkúté fún àwọn tí kò wà ní ìmúrasílẹ.-Southern Wachman, June 28, 1904.IIO 155.3

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents