Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORÍ — KẸTÀLÁ IṢẸ́ ÌRÁNṢẸ́ Ẹ TI OJU ÌWÉ TI A TI TE

    Iṣẹ́ Àkọ́kọ́ Pàtàkì

    Tí iṣẹ́ kan bá wà tí ó ṣe pàtàkì ju èkejì lọ, ohun ni wíwá àwọn ìwé àtẹ̀jáde e wa síwájú u gbogbo ènìyàn, èyí tí yóò darí i wọn láti wá inu Iwe Mimọ. Iṣẹ́ ajíhìnrere- fífi àwọn ìwé àtẹ̀jáde e wa han àwọn ìdílé, bá wọn sọ̀rọ̀, kí o sì gbàdúrà pẹ̀lú u wọn àti fún wọn —jẹ́ iṣẹ́ rere.- The Colporteur Evangelist, p.80.IIO 145.1

    Jẹ kí ọmọ Onírètí Bíbọ̀ ọ Jesu bi ara a rẹ̀ léèrè, “kín ni mo lè ṣe láti polongo iṣẹ́ ìránṣẹ ẹ ti angẹ̀lì kẹta”? Krístì wá sí ayé láti fi iṣẹ́ iranṣẹ yìí fún ìránṣẹ́ ẹ RẸ̀ láti fún àwọn ìjọ. A ní láti polongo o rẹ̀ fún olúkúlùkù orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà, èdè àti ènìyàn. Báwo ni a ṣe le è fún wọn? Pínpín àwọn ìwé e wa jẹ́ ọ̀nà kan tí iṣẹ́ ìránṣẹ́ fi lè jẹ́ pípolono. Jẹ́ kí olúkúlùkù onígbàgbọ́ fọ́n àwọn ìwé ìléwọ́ àti ewé kékeré àti àwọn ìwé tí ó kún fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ ẹ ti àsìkò yìí káàkiri. Àwọn òǹtàwé ni a nílò tí yóò jáde lọ láti fọ́n àwọn ìwé àtẹ̀jáde e wa sí ibi gbogbo. —Southern Watchman, Jan 5, 1904.IIO 145.2

    Àwọn tákàdá àti àwọn ìwé jẹ́ ọ̀nà tí Ọlọrun láti pa iṣẹ́ iranṣẹ mọ́ fún àsìkò yìí títí lọ síwájú àwọn ènìyàn. Nínú ìlanilóye àti ìjẹ́wọ́ àwọn ọkàn, àwọn ìwé àtẹ̀jáde yóò ṣe iṣẹ́ ń lá tí ó rìn jìnnà ju èyí tí a le ṣe láṣeyọrí nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ ọ̀rọ̀ ọ RẸ̀ nìkan. Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun tí ó dákẹ́ tí a fi sílẹ̀ sínú àwọn ilé àwọn ènìyàn nípa iṣẹ́ àwọn òǹtàwé, yóò fi agbára fún iṣẹ́ iranṣẹ ìhìnrere ní ọ̀nàkọnà; nítorí pé Ẹ̀mí Mímọ́ yóò jẹ́ kó wọ̀ wọ́n lọ́kàn bí wọ́n bá ṣe ń ka àwọn ìwé yìí, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe fi wọ àwọn ọkàn tí wọ́n fetísílẹ̀ fún ìwàásù ọ̀rọ̀ ọ RẸ̀. Iṣẹ iranṣẹ àwọn ángẹ́lì kan náà fiyèsí àwọn ìwé tí ó ní òtítọ́ nínú bí wọ́n ṣe fiyèsí iṣẹ́ àwọn òjíṣẹ́ Ọlọrun.- Testimonies, vol.6, pp. 315, 316.IIO 145.3

    Máṣe fi iṣẹ́ òǹtàwé yìí sílẹ̀ kí ó wà ní àìlera. Jẹ́ kí àwọn ìwé tí ó kún fún ìmọ́lẹ̀ lórí òtítọ́ wá síwájú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn bí ó bá ṣe le ṣe é ṣe. Àwọn olóòtú olú ilé iṣẹ́ ẹ wa àti àwọn mìíràn tí wọ́n wà ní àwọn ipò tí ó ṣe pàtàkì ni iṣẹ lati ṣe ninu ọrọ yii.- Southern Watchman, April 25, 1905.IIO 145.4

    Aráyé ní láti gba ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ náà nípasẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ ajíhìnrere ọ̀rọ̀ náà nínú àwọn ìwé àsìkò. Àwọn ìwé àtẹ̀jáde e wa yẹ kí ó fihàn pé òpin ohun gbogbo ti dé tán.- The Colporteur Evangelist, p.100.IIO 146.1

    Àwọn ìwé àtẹ̀jáde e wa ní báyìí tí ń so èso ìhìnrere, wọ́n sì jẹ́ ohun èlò nínú mímú ọ̀pọ̀ ọkàn wá fún Kristi bí i wíwàásù ọ̀rọ̀ náà. Gbogbo àwọn ìjọ ni a ti gbé sókè gẹ́gẹ́ bí àyọrísí fífọ́n káàkiri i wọn. Nínú iṣẹ́ yìí olúkúlùkù ọmọ ẹ̀yìn-in Kristi ni ó lè kópa kan.- Review and Herald, June 10, 1880.IIO 146.2

    Ìránṣẹ́ Ọlọ́run láti ọ̀run dúró ní àarin wa, ó sì ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ àti àṣẹ. Ó jẹ́ kí a mọ̀ dájú pé ìhìnrere ti ìjọba ọ̀run jẹ́ iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún ayé tí ó ń ṣègbé, àti pé iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí, bí ó ṣe wà nínú àwọn ìwé àtẹ̀jáde tí a ti tẹ̀, àti àwọn tí a kò tí ì gbé jáde, ni a gbọdọ̀ fọ́n káàkiri láarin àwọn ènìyàn tí ó wà nítòsí tàbí ní ọ̀nà jínjìn.- testimonies, vol.9, p.69.IIO 146.3

    Èṣù ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́lọ́wọ́ ní ẹ̀ka iṣẹ́ ẹ rẹ̀ yìí, fífọ́n káàkiri ìwé tí ó jẹ́ ayédèrú tí ń ṣe àkóbá fún ìwà ó sì ń fún ọkàn àwọn ọ̀dọ́ ní májèlé. Ìwé àwọn aláìgbàgbọ́ ti fọ́n káàkiri jákè jádò ayé. Kín ni ìdí tí gbogbo àwọn ọmọ ìjọ kò fi ní ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ nínú rírán àwọn ìwé àtẹ̀jáde yì í lọ tí yóò mú kí àwọn ọkàn gbé sókè, tí yóò sì mú òtítọ́ náà lọ tààrà síwájú u wọn? Àwọn ìwé yìí àti àwọn ìwé ìléwọ́ jẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ ayé, ó sì ti ń fi ọ̀pọ̀ ìgbà jẹ́ ohun èlò nínú u yíyí àwọn ọkàn padà.-Review and Herald, June 10, 1880.IIO 146.4

    A ti sùn lọ, bí ó ṣe wà, nípaṣẹ̀ iṣẹ́ tí a lè ṣẹ láṣeyọrí nípa pínpín àwọn ìwé tí a ti ṣètò sílẹ̀. Nísinsinyìí, kí a lo àwọn ìwé àsìkò àti àwọn ìwé pẹ̀lú ọgbọ́n, kí a wàásù ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ìfọwọ́sọ̀yà, kí aráyé ba à le è lóye iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí Kristi fún Jòánù ní erékùsù u Pátímò.- The Colporteur Evangelist, p.101.IIO 146.5

    Ẹ̀yin ọmọ ìjọ, ẹ jí gírí sí pàtàkì ìfọ́n káàkiri ìwé e wa, kí ẹ sì ya ọ̀pọ̀ àsìkò sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ yìí. Fi àwọn ìwé sí ilé àwọn ènìyàn, ìwé ìléwọ́ àti àwọn ìwé tí yóò wàásù ìhìnrere ní oríṣiríṣi ọ̀nà. Kò sí àsìkò tí a lè sọnù. Jẹ́ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ fi ara wọn sílẹ̀ tinú tinú àti láì- ní-ìmọ-tara-ẹni-nìkan fún iṣẹ́ òǹtàwé, nípa báyìí wọn yóò lè ṣè rànlọ́wọ́ láti ṣe ìkìlọ̀ tí a nílò lọ́pọ̀lọpọ̀. Nígbà tí ìjọ bá gba iṣẹ́ tí a yàn-án, yóò jáde lọ “tọ́ bí òṣùpá, mọ́lẹ̀ bí oòrùn, ó sì bani lẹ́rù bí ẹgbẹ́ ọmọ ogun pẹ̀lú àwọn àsìá.- Southern Watchman, Noẹ.20, 1902.IIO 147.1

    Ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ ń tàn àwọn ìtàṣán-àn ìmọ́lẹ̀ dídán-an rẹ̀ sí orí ayé nípa ìgbìyànjú àwọn ajíhìnrere. Àwọn òǹtẹ̀wé ni ohun èlò nípa èyí tí a fi ń dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó lè má ṣe é ṣe láti dé ọ̀dọ̀ ọ wọn nípasẹ̀ ìgbìyànjú òjíṣẹ́ Ọlọrun.- Testimonies, vol.5, p.388.IIO 147.2

    Òru ìṣòro ni a fẹ́rè lò tán, Sátánì ń gbé agbára àkóso o rẹ̀ bọ̀ nítorí pé ó mọ̀ pé àsìkò òun kúrú. Iná Ọlọrun sì wà ní orí ayé, láti pe gbogbo àwọn tí ó mọ òtítọ́ láti sápamọ́ sínú ihò àpáta, kí wọn sì wo ògo Ọlọ́run. A kò gbọdọ̀ fi n ǹkan bo òtítọ́ mọ́lẹ̀ báyìí. Ọ̀rọ̀ ìgboyà ni a gbọdọ̀ sọ. Òtítọ́ tí kò ní àbùlà ni a gbọdọ̀ sọ, nínú ewé ìwé kékeré, eléyìí ni a gbọdọ̀ fọ́nká gẹ́gẹ́ bí ewé àkókò ìkórè. - Testimonies, vol.9, p.231.IIO 147.3

    Àwọn òǹtàwé ni a nílò láti gba iṣẹ́ ẹ gbígbé àwọn ìránṣẹ́ olùdákẹ́jẹ́ òtítọ́ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn,- òǹtàwé tí ó ní ìmọ̀lára ẹrù wúwo fún àwọn ọkàn, tí ó sì lè sọ àwọn ọ̀rọ̀ ní àsìkò o rẹ̀ fuń àwọn tí wọ́n ń wá ìmọ́lẹ̀. Àwọn díẹ̀ lè sọ pé, “Ẹ̀mi kì í ṣe òjíṣẹ́ Ọlọ́run; Èmi kò lè wàásù fún àwọn ènìyàn.” O lè má le wàásù, ṣùgbọ́n o lè jẹ́ òjíṣẹ́ Ọlọrun, ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ nípa bíbá àìní àwọn tí ó ń bá pàdé; ó le è jẹ́ ọwọ́ ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun, ṣíṣẹ bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣe ṣiṣẹ́; o le è bi àwọn tí ò ń bá pàdé tí wọ́n bá fẹ́ràn Jesu Olúwa.- Southern Watchman, Nov.20, 1902.IIO 147.4

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents