Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ọrọ Ìyànjú Sí Àwọn Alákọ́ọ́bẹ̀rẹ̀ Nínú Iṣẹ́ ìsìn Onígbàgbọ́

    Àwọn òṣìṣẹ́ tí ó ṣe oríire jùlọ ni àwọn tí wọ́n fi tìdùnnú tìdùnnú gba iṣẹ́ ẹ ti sínsin Ọlọ́run nínú àwọn ohun kékeré. Ẹnìkọ̀ọ̀kan ni ó ní láti ṣiṣẹ́ nípa lílo ìgbé ayé e rẹ bí òwú ìgbé ayé e rẹ̀ tí a fi ń hun aṣọ títí tí yóò fi yọrí.-Testimonies, vol.6, p.115.IIO 99.4

    A ní láti mú àwọn iṣẹ́ ẹ wa ojoojúmọ́ bí iṣẹ́ ìsìn, tí ó ń dàgbà ní gbogbo ìgbà nínú ìwúlò, nítorí pé a rí iṣẹ́ ẹ wa bí ohun tí ó ní ipa sí ìmọ́lẹ̀ ayérayé.- Testimonies, vol.9, p.150.IIO 99.5

    Oluwa wa ní ààyè fún ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú èrò ń lá a RẸ̀. Àwọn tálẹ́ńtì tí a kò nílò ni a kò fifún wa.-Testimonies, vol.9,p.37.IIO 99.6

    Ẹńìkọ̀ọ̀kan wa ni ó ní ààyè nínú èrò o ayérayé e ti ọ̀run. Ẹnìkọ̀ọ̀kan ní ó sì ní láti ṣiṣẹ́ ní ìfọwọsowọ́pọ̀ pẹ̀lú u Krístì fún ìgbàlà àwọn ọkàn.Bí a kò lè ṣàìní ìdánilójú pé a pèsè ààyè sílẹ̀ fún wa ní ibùgbé ọ̀run, bẹ́ẹ̀ ni a kò lè ṣàì ní ibi pàtàkì tí a ní láti ṣiṣẹ́ fún Ọlọ́run.- Christ’s Object Lessons, pp.326,327.IIO 99.7

    Ojú Olúwa wà lára ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ó jẹ́ ènìyàn an RẸ̀; Ó sì ní èrò o Rẹ̀ nípa ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn.- Testimonies, vol.6, p.12.IIO 99.8

    Gbogbo wa ni a ní ipa láti kó nínú iṣẹ́ náà. Kò sí ẹni tí áò rí bí aláìlẹ́bi níwájú Ọlọ́run àyàfi tí wọ́n bá fi tìtara tìtara àti àìmọ -tara-ẹni ṣiṣẹ́ fún ìgbàlà àwọn ọkàn.- Testimonies, vol.5,p.395.IIO 100.1

    A lè ṣí iṣẹ́ ẹ̀ rẹ sí orí ẹlòmíràn. Kò sí ẹnìkan ṣùgbọ́n ìwọ tìkalára à rẹ ni o le ṣe iṣẹ́ ẹ̀ rẹ. Tí o bá há ìmọ́lẹ̀ ẹ̀ rẹ mọ́wọ́, ẹnìkan gbọdọ̀ wà nínú òkùnkùn nípa àìkíyèsí ì rẹ.- Testimonies, vol.5, p.464.IIO 100.2

    Onírẹ̀lẹ̀ ọ̀ṣìṣẹ́ tí ó gbọ́ràn tí ó sì dáhùn sí ìpè Ọlọ́run lè ni idaniloju riri ìrànlọ́wọ́ Ọlọ̀run látòkè gbà láti gba iṣẹ́ tí ó tóbi tí ó sì jẹ́ mímọ́ Ó ń ṣe ìmúlò àwọn agbára ọgbọ́n àti ẹ̀mí tí ó ga jù, ó ń fi okun àti ìsọdimímọ́ fún iyè àti ọkàn. Nípa ìgbàgbọ́ nínú agbára Ọlọ́run, ó yanilẹ́nu bí ọkùnrin aláìlera ti jẹ́ alágbára lè jẹ́, bí ó ṣe le ṣe ìpinnu lórí àwọn ìgbìyànjú u rẹ̀, bí àwọn àṣeyorí i rẹ̀ ṣe ní ìbísí. Ẹni tí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú òye kékeré, ní ọ̀nà ìrẹra ẹni sílẹ̀, tí ó ń sọ ohun tí ó mọ̀, nígbàtí ó ń farabalẹ̀ wá òye síwájú, yóò rí gbogbo ìṣúra ti ọ̀run tí ó ń dúró de ohun tí ó ń bèèrè. Bí ó ṣe ń wá láti fi ìmọ́lẹ̀ hàn, bẹ́ẹ̀ ni ìmọ́lẹ̀ tí yóò gba yóò má a pọ̀ sí i. Bí ó ṣe ń gbìyànjú láti fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yé àwọn ènìyàn, pẹ̀lú ìfẹ́ fún àwọn ọkàn, òun náà yóò wà ní kedere. Bí a ṣe ń lo àwọn ìmọ̀ ọ wa tí a sì ń lo àwọn agbára a wà, bẹ́ẹ̀ ni ìmọ̀ àti agbára wa tí a ní yóò pọ̀ sí i.- Christ’s Object Lessons, p.354.IIO 100.3

    Ẹ jẹ́ kí ẹníkọ̀ọ̀kan wa ṣiṣẹ́ fún Ọlọ́run àti fún àwọn ọkàn; jẹ́ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan fi ọgbọ́n-an rẹ̀ hàn, kí a máṣe rí i nínú àìṣiṣé, kí ó má dúró de ẹlòmíràn láti fún ní iṣẹ́ ṣe. “Ẹnìkan” tí ó lè fún ọ ní iṣẹ́ ti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹrù iṣẹ́, àti pé ó jẹ́ àti fi àsìkò ṣòfò fún dídúró de ìtọ́sọ́nà a rẹ̀. Ọlọ́run yóò fi ọgbọ́n fún ọ láti ṣe àyípadà lẹ́ẹ̀kan náà; nítorí wọ́n sì ń pe ìpè náà, “Ọmọ, lọ ṣiṣẹ́ lónì í nínú ọgbà àjàrà à mi.”Lónì í, tí ìwọ yóò bá gbọ́ ohùn —un RẸ̀, máṣe sé ọkàn an rẹ le.” Heb.3:7,8. Síwájú Oun tí ó fẹ́ ó pè wọ́n ní “Ọmọ.” Ọ̀rọ̀ tí ó fi àsepapọ̀ tímọ́ tímọ́ hàn. Ó kún fún ìrọ́nú, àti àánú, tó bẹ́ẹ̀ ó gba kánjú kánjú! Ìpè e Rẹ̀ sì jẹ́ àṣẹ bákan náà.- Counsels to Teachers, p.419.IIO 100.4

    Agbára láti kọjú ìjà sí èsù ni a lè rí gbà nípa iṣẹ́ ìsìn tó múná dóko.- The Acts of The Apostles, p.105.Gbogbo ipá, gbogbo ise ti ìdájọ́ àti àánú àti inú rere ni ó ń gbé ohùn orin sókè l’ọ́run.- Review and Herald, Aug. 16, 1881.IIO 100.5

    Ẹ̀mí i ti Krístì i nì jẹ́ ẹ̀mí òjíṣẹ́ Ọlọ́run, òòfà ọkàn àkọ́kọ́ ni ti ọkàn tí a sọdọ̀tun ní láti mú àwọn ọkàn mìíràn bákan náà wá sí ọ̀dọ̀ Olùgbàlà. - The Great Controversy, p.70.IIO 101.1

    Ọ̀nà míìran tí a fi le dàgbà nínú oore-ọ̀fẹ́ ni kí a nífẹ̀ ẹ́ láti ṣiṣẹ́ tí Ọlọ́run fúnra a RẸ̀ ti pàṣẹ fún wa láti ṣe. - Review and Herald, June 7, 1887.IIO 101.2

    O kò nílò láti dúró de ààyè àkànṣe tàbí retí i àrágbá yamú yamù agbára kí o tò lè ṣiṣẹ́ fún Olúwa.-Steps to Christ, p.87.IIO 101.3

    Ẹni tí ó bá bùkun àwùjọ ọ rẹ̀, tí ó sì láṣeyọrí ní ayé, ni ẹni náà, bóyá ó lẹ́kọ̀ọ́ tàbí kò lẹ́kọ̀ọ́,ni tí ó lo gbogbo agbára a rẹp nìnu iṣẹ̀ ìsìn Ọlọ́run àti arákùnrinin rẹ̀.- Southern Watchman, April 2, 1903.IIO 101.4

    Ọ̀pọ̀ tí Ọlọ́run ti mu ´yẹ láti ṣe iṣẹ́ títayọ ni wọ́n ṣe àṣepé ohun díẹ̀, nítorí pé wọ́n dáwọ́lé ohun díẹ̀.-Christ’s Objẹct Lessons, p.331.IIO 101.5

    Tí o bá bàkù ní ìgbà mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún nínú ọgọ́ruǹ-ún, ṣùgbọ́n tí o ṣe àṣeyọrí nínú gbígba ọkàn ẹyọkan là kúrò nínú ìparun, o ti ṣe iṣẹ́ tí ó lọ́lá fún Olúwa nínú iṣẹ́ ẹ RẸ̀.-Testimonies, vol.4, p.132.IIO 101.6

    Ìbátan tí ó wà nínú Ọlọ́run àti ọkàn kan yàtọ̀ tí ó sì kún bí ìgbà tí kò sí ọkàn míìran mọ́ lórí ilẹ̀ ayé láti ṣe alábápín ìṣọ́ àánú u RẸ̀, kò sí ọkàn mìíràn fún èyí tí Ó fi ọmọ ọ RẸ̀ ọ̀wọ́n sílẹ̀ fún.- Steps to Christ, p.100.IIO 101.7

    Ọlọrun rí ó sì mọ̀, àti pé yóò lò ọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o jẹ́ aláì lágbára tí o bá fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ bí ẹ̀bùn tí o yà sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ẹ RẸ̀; nínú u ṣíṣẹ aápọn, nínú iṣẹ́ ìsìn àìwá ti ara ẹni, aláì lágbára di alágbára tí ó sì ń jẹ̀ gbádùn ìyìn-in RẸ̀ iyebíye. Ayọ̀ ọ ti Olúwa jẹ́ ìpilẹ̀sẹ̀ agbára. Tí o bá jẹ́ olóótọ́, àlàáfíà tí ó ju ìmọ̀ àti ohun gbogbo lọ ni yóò jẹ́ èrè è rẹ ní ayé yìí, àti ní ayé tí ń bọ̀ ìwọ yóò sì bọ́ sínú ayọ̀ Olúwa à rẹ.- Testimonies,8, p.34.IIO 101.8

    Awọn ènìyàn tí wọ́n ní tálẹ́ǹtì kékeré, tí wọ́n bá ṣe olóótọ́ nínú u pípa ọkàn-an wọn mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, lè jèrè ọkàn púpọ̀ fún Krístì. Harlan Page jẹ́ òtòṣì, onímọ̀ ẹ̀rọ tí agbára àtí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ọ rẹ̀ kéré jọjọ; ṣùgbọ́n ó mú iṣẹ́ yì í ní iṣẹ́ Pàtàkì láti mú kí iṣẹ́ Olúwa gbòòrò, gbogbo ìgbìyànjú u rẹ̀ ni a dé ládé pẹ̀lú àṣeyọrí. Ó ṣiṣẹ́ fún ìgbàlà àwọn arákùnrin-in rẹ̀ nínú ìbásọ̀rọ̀ níkọ̀kọ̀ àti nínú ìtara àdúrà.Ó dá àwọn ìpàdé àdúrà sílẹ̀, ó kó àwọn ilé ẹ̀kọ́ ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀ jọ, ó sì tún ń pín àwọn ìwé ìléwọ́ ké-kè-ké àti àwọn ìwé onígbàgbọ́ mìíràn tí a lè kà. Ní ojú ikú pẹ̀lú òjìji ayérayé tí ó wà níwájú u rẹ̀, ó lè sọ pé, “Mo mọ̀ pé oore-ọ̀fẹ́ ni gbogbo rẹ̀; kì í ṣe nípa ìtóyè ohun kan tí mo ṣe; ṣùgbọ́n Mo rò Mo sì rí ẹ̀rí pé ju ọgọ́rùn-ún àwọn ọkàn ni wọ́n yípadà sí Ọlọ́run nípa ohun èlò èmi fúnra à mi.”-Testimonies, vol.5, pp.307, 308. IIO 102.1

    Ilé ayé yìí kì í ṣe ọ̀run fún onígbàgbọ́,ṣùgbọ́n ó jẹ́ kìkì ilé iṣẹ́ ẹ ti Ọlọ́run, níbi tí a yóò ti mú wa yẹ láti dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn ańgẹ́lì tí kò lẹ́sẹ̀ ní ọ̀run mímọ́.- Testimonies, vol.2, p.187.IIO 102.2

    Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí wọ́n ní ìrẹ̀lẹ̀ tí wọ́n sì jẹ́ aláìní lè jẹ́ ìbùkún fún àwọn mìíràn. Ó lè má hàn sí wọn pé wọ́n ń ṣe ohun àkànṣe kan, ṣùgbọ́n nípa ipa tí o farasin wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ ẹ ìgbì ìbùkún tí yóò fẹ̀ tí yóò sì jìn, àyọrísí ìbùkún-un rẹ̀ ni wọ́n le má mọ̀ títí di ọjọ́ èrè ìkẹhìn. Wọn kò ní ìmọ̀lára tàbí kí wọn mọ̀ pé àwọn ń ṣe ohun tí ó tóbi kankan. Wọn kò fẹ́ kí wọn ṣàárẹ̀ pẹ̀lú àníyàn nípa àṣeyọrí. Ohun kan tí wọ́n nílò ni láti tẹ̀ ṣíwájú ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, kí wọn sì ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún wọn láti ṣe pẹ̀lú ọkàn, àyè e wọn kò sì ní já sí asán.Àwọn ọkàn-an wọn yóò má a dàgbà síwájú àti síwájú sí i nínú àwòrán-an ti Krístì; wọ́n jẹ́ alábàáṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run nínú ayé yìí, èyí tí yóò mú wọn yẹ fún iṣẹ́ tí ó ga jù àti ayọ̀ tí kò lábàwọ́n ní ayé tí ó ń bọ̀. - Steps to Christ, p.88.IIO 102.3

    Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló wà tí wọ́n ti fi ara a wọn fún Krístì, síbẹ̀ tí wọn kò rí ànfààní láti ṣiṣẹ́ tí ó tóbi tàbí rí ànfààní láti ṣe iṣẹ́ ń lá nínú iṣẹ́ ìsìn-in RẸ̀. Àwọn yìí le è rí ìtùnú nínú èrò pé kì í ṣe dandan ayé ìfara ẹni sílẹ̀ bí àwọn tí a pa nítorí ìgbàgbọ́ ọ wọn ni ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà sí Ọlọ́run. Ó lè má à jẹ́ òjíṣẹ́ Ọlọ́run tí ó fi ojoójúmọ́ ń dojúkọ ewu àti ikú, tí yóò dúró níbi tí ó ga jùlọ nínú àwọn ìwé ìṣirò ti ọ̀run. Onígbàgbọ́ náà tí ó nínú ìgbé ayé ìkọ̀kọ̀ ọ rẹ̀, nínú fífi ara a rẹ̀ sílẹ̀ ní ojoojúmọ́, nínú ìṣòótọ́ ti ohun tí ó ń lépa àti mímọ́ níti èrò, nínú ọkàn tútù lábẹ inúnibíni, nínú ìgbàgbọ́ àti ìfọkànsìn, nínú ṣíṣe òtítọ́ nínú ohun tí ó kéré jù, ẹni náà tí ó jẹ́ pé nínú ìgbé ayé e rẹ̀ nínú ilé ṣe ojú fún ìwà a ti Krístì, Irúfẹ́ ẹni yìí níwájú Ọlọrun lè jẹ́ iyebíye ju ẹni tí ó jẹ́ òjíṣẹ́ Ọlọrun tí ó lókìkí lágbáyé tàbí ẹni tí a pa nítorí ìgbàgbọ́ ọ rẹ̀ pàápàá.- Christ’s Object Lessons, p.403.IIO 102.4

    Kì í ṣe iye iṣẹ́ tí a ṣe tàbi àyọrísí i rẹ̀ ṣe hàn tó ṣùgbọ́n ẹ̀mí tí a fi ṣe iṣẹ́ náà, jẹ́ kí ó níye lórí níwájú Ọlọrun.- Christ’s Object Lessons, p.397.IIO 103.1

    Fífi ọwọ́ sí tí Olúwa fọwọ́ sí i kì í ṣe torí iṣẹ́ ń lá tí a ṣe, ṣùgbọ́n nítorí ọ̀pọ̀ n ǹkan tí a ti rí gbà, ṣùgbọ́n nítorí pé a ṣe olóòótọ́ nínú ohun díẹ̀. Kì í ṣe nítorí àwọn àṣeyọrí ń lá tí a fọwọ́ bà ṣùgbọ́n àwọn ìdí tí ó mú wa ṣe é, ni ó tẹ̀wọ̀n pẹ̀lú Ọlọ́run. Ìṣoore àti ìṣòtítọ́ ni Ọlọ́run kà sí ohun iyebíye ju títóbi iṣẹ́ tí a ṣe láṣeyọrí. - Testimonies, vol.2, pp.510, 511.IIO 103.2

    Máṣe kọjá lára àwọn ohun tí ó kéré, kí o sì má a wá iṣẹ́ tí ó tóbi. Ó lè ṣe àṣeyọrí nínú iṣẹ́ kékeré, kí o sì bàkù pátápátá nínú u gbígbì dánwò iṣẹ́ tí ó tóbi, kí ìrẹ̀wẹ̀sì sì bá ọ. Mú iṣẹ́ náà ní ọ̀kúnkúndùn níbikíbi tí ó ba ti rí i pé iṣẹ́ wà láti ṣe. Yálà o jẹ́ ọlọ́rọ̀ tàbí tálákà, o jẹ́ ẹni ń lá tàbí onírẹ̀lẹ̀, Ọlọrun ń pè ọ́ láti ṣaápọn nínú iṣẹ́ ìsìn-in RẸ̀. Yóò jẹ́ nípa ṣíṣẹ pẹ̀lú agbára a rẹ̀ ohun tí ọwọ́ ọ̀ rẹ bá bà láti ṣe ni ìwọ yóò mú tálẹ́ǹtì dàgbà àti mímúra fún iṣẹ́ náà. Nípa àwọn àìka àwọn ànfààní rẹ ojoojúmọ́ sí ni yóò mú kí o jẹ́ aláìléso tí o ò sì rẹ̀ dànù. Ìdí nìyí tí a fi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi aláìléso nínú ọgbà olúwa.- Testimonies,vol.9, p.129.IIO 103.3

    Ọlọ́run ń fẹ́ kí a lo ẹ̀bùn kọ̀ọ̀kan tí a ní; tí a bá ṣe èyí, a yóò ní àwọn ẹ̀bùn títóbi láti lò. Kò fún wa ní ohun tí ó ju ti ẹ̀dá lọ pẹ̀lú àwọn ohun àmúyẹ tí a kò ní ; ṣùgbọ́n nígbà tí a lo ohun tí a ní Yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú u wa láti mú kí a lágbára kí a sì pọ̀ sí i ní ọgbọ́n orí. Nípa gbogbo ọkàn-an wa, nínú ìtara, nínú ìfirúbọ fún iṣẹ́ ìsìn Olúwa, agbára wa yóò pọ̀ sí i.- Christ’s Objẹct Lessons, p.353,354.IIO 103.4

    Ọkàn Ọlọrun yọ̀ sí rírí àwọn onírúurú òtòṣì ; Ó yọ̀ nípa bíbojú wo àwọn tí kò wúlò tí wọ́n ní ìrẹ̀lẹ̀; Ó yọ̀ sí àwọn tí à ń ṣìlò;tí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tí ebi sì ń pa wọ́n sípa òdodo, nípa àì lágbára ọ̀pọ̀lọpọ̀ lati bẹ̀rẹ̀. Ó ń kí wọn káàbọ̀, bí wọ́n ṣe rí, ní ipò àwọn n ǹkan tí ó lè mú kí ọkàn ọ̀pọ̀ òjíṣẹ́ Ọlọ́run mìíràn rẹ̀wẹ̀sì.- Gospel Workers, p.37.IIO 103.5

    A nílò láti lọ sí ilẹ̀ àwọn kèfèrí , tàbí kí a fi ọ̀nà tóóró ilé sílẹ̀, tí ó bá jẹ́ pé ibẹ̀ ni iṣẹ́ ẹ wa dúró sí láti ṣiṣẹ́ fún Krístì. A lè ṣe eléyì í ní àyíká ilé, nínú ìjọ, láarin àwọn ẹlẹ́gbẹ ẹ wa, àti pẹ̀lú àwọn tí a jọ ń ṣòwò papọ̀.- Steps to Christ, p.81.IIO 103.6

    Tí a bá ńṣàṣàrò nínú ìgbé ayé àti àwọn ẹ̀kọ́ ọ ti Krístì, ìṣẹ̀lẹ̀ kọ̀ọ̀kan ni yóò fún wa ní kókó ọ̀rọ̀ fún ìjíròrò.- Testimonies, vol.9, p.63.IIO 104.1

    Ìgbé ayé e wa nínú ayé ni ìbẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé ní ọ̀run; ẹ̀kọ́ ọ ti ayé ni láti kọ́ni ní àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ ti ọ̀run; iṣẹ́- ìgbé ayé e wa níhìn-ín yìí jẹ́ ìkọ́ni iṣẹ́-ìgbé ayé lọ́hùn-ún. Ohun tí a jẹ́ nísinsinyìí nínú ìwà, àti iṣẹ̀ ìsìn mímọ́ dájúdájú jẹ́ àwòjíiji ohun tí a yóò jẹ́.- Education, p.307.IIO 104.2

    Gbogbo àwọn tí ó kọ̀ ànfààní ìdàpọ̀ pẹ̀lú Krístì nínú iṣẹ́ ìsìn, kọ ìkọ́ni kan tí ó ṣàfihàn ìmúyẹ fún ìbápín pẹ̀lú u RẸ̀ nínú ògo o RẸ̀. Wọn kọ ìkọ́ni pé nínú ayé yìí tí yóò fún wọn lágbára àti ìwà tí ó lọ́lá.-Education, p.264.IIO 104.3

    Kí ẹnikẹ́ni máṣe rò pé àwọn lè gbé ìgbé ayé ìmọ̀-tara-ẹni-nìkan, lẹ́yin tí wọ́n bá ti tẹ́ ìfẹ́ ọkàn-an wọn lọ́rùn, wọn yóò bọ́ sínú ayọ̀ Olúwa Ọlọ́run —un wọn. Nínú ayọ̀ ọ ti ìfẹ́ tí kò mọ tara rẹ̀ wọn kò ní lè kópa. Wọn kò ní lè yẹ fún àgbàlá ọ̀run. Wọn kò ní lè mọ rírì àyíká a ti ọ̀run tí ó kún fún ìfẹ́. Àwọn ohùn tí àwọn ángẹ́lì àti orin tí ohun èlò orin kò ní tẹ́ wọn lọ́rùn. Sí ọkàn-an wọn ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ẹ ti ọ̀run yóò jẹ́ èyí tí ó rú wọn lójú.- Christ’s Object Lessons, pp.364,365.IIO 104.4

    Ọlọrun ń pè wá láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú u sùúrù, àti ìfaradà nítorí pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún ló ń ṣègbé sínú ẹ̀ṣẹ̀ ẹ wọn, tí wọn fọ́n káàkiri ní ilẹ̀ gbogbo, bí ọkọ̀ tí ó fọ́ sí etí i bèbè òkun, Gbogbo àwọn tí ó ṣe alábápín nínú ògo ti Krístì gbọdọ̀ ṣe alábápín-in iṣẹ́ ẹ RẸ̀, ríran aláì lera lọ́wọ́, àwọn abòsì àti àwọn aláì nírètí.- Testimonies, vol.9, p.31.IIO 104.5

    Àwọn tí a kà kún ènìyàn lásán ní láti gba ipò o wọn bí àwọn òṣìṣẹ́. Kí wọn ṣe alábápín nínú ìbànújẹ́ àwọn arákùnrin-in wọn bí Olùgbàlà ṣe ṣe alábápín nínu àwọn ìṣòro ọmọnìyàn, wọn yóò le è Rí i nípa pé ó ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú u wọn.- Testimonies,vol.7, p.272.IIO 104.6

    Krístì ń retì fún àfijọ ọ RẸ̀ nínú àtẹ̀lé kọ̀ọ̀kan. Ọlọ́run ti yàn-án mọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan láti “dàrapọ̀ mọ́ àfijọ ti ọmọ ọ RẸ̀.” Nínú ẹnìkọ̀ọ̀kan ìfẹ́ ìpamọ́ra Kristi, ìwà mímọ́ ọ RẸ̀, ọkàn tútù, àánú àti òtítọ́ ọ RẸ̀ yẹ kí ó farahàn sí aráye.- The Desire of Ages, p.827.IIO 104.7

    Ìpè láti fi gbogbo wa sí orí i pẹpẹ fún iṣẹ́ ìsìn ni ó ti tọ̀ wá wá ní ẹnìkọ̀ọ̀kan. A kò bi wá léèrè láti sìn bí Èlíṣà ṣe sìn, tàbí kí a pè wá láti ta gbogbo ohun tí a ní; ṣùgbọ́n ohun tí Ọlọ́run ń bèèrè ni láti fi iṣẹ́ ìsìn RẸ̀ ṣe àkọ́kọ́ nínú ayé e wa, láti má ṣe gba ọjọ́ kan láàyè láti kọjá láti máṣe ohun kan láti mú iṣẹ́ ẹ RẸ̀ tẹ̀síwájú nínú ayé. Kò retí iṣẹ́ ìsìn kan náà láti ọ̀dọ̀ ọ gbogbo o wa. Ó lè pe ẹlòmíràn láti jẹ́ òṣìṣẹ́ ní ilẹ̀ àjèjì; Ó lè pe ẹlòmíràn láti fi ohun ìní i rẹ̀ ran iṣẹ́ ìhìnrère lọ́wọ́. Ọrẹ ẹnìkọ̀ọ̀kan ni Ọlọ́run gbà. Ìyàsímímọ́ ìgbé ayé àti gbogbo àwọn ìfẹ́ ẹ ìyàsímímọ́, ni wọn yóò gbọ́ tí wọn yóò sì gbọ́ràn sí ìpè e ti ọ̀run.- Phrophets and Kings, p.221.IIO 105.1

    Ọkùnrin ọlọ́gbọ́n ayé, tí ó ń ṣe àṣàrò tí ó sì ń ro èrò, tí iṣẹ́ ẹ rẹ̀ sì wà ní ọkàn-an rẹ̀ yóò wá láti jẹ́ ọlọgbọ́n, àti ní nífẹ̀ ẹ́ sí àwọn ohun tí ó jẹ́ ti ayérayé. Tí yóò bá fi ọ̀pọ̀ agbára a rẹ̀ láti fi ìṣúra ti ọ̀run pamọ́ àti ìgbé ayé tí ó jẹ́ ìbámu pẹ̀lú ìgbé ayé e ti Ọlọrun bí ó ṣe e ṣé láti pa èrè ayé mọ́, kí ni kò lè ṣe láṣepé?.- Testimonies, vol.6, p.297.IIO 105.2

    Ọlọrun yóò kọjá láarin àwọn tí ó wà ní ipò ìrẹ̀lẹ̀ láti sọ iṣẹ́ ìránṣẹ́ òtítọ́ ọ ti àsìkò yìí. Ọ̀pọ̀ irú u wọn ni a yóò rí tí yóò mú kí iṣẹ́ náà yára níhìn-ín àti lọ́hùn-ún, tí ẹ̀mí i Krístì ń rọ̀ láti fi ìmọ́lẹ̀ náà hàn fún àwọn tí ó wà l’óòkùn. Òtítọ́ náà dàbí iná nínú àwọn egungun, tí ó ń kún wọn pẹ̀lú ìfẹ́ láti jó láti la àwọn tí ó jòkó nínú òkùnkùn lóye. Ọ̀pọ̀ pàápàá láarin àwọn tí kò ní ìmọ̀ ẹ̀kọ́, ni yóò polongo ọ̀rọ̀ ọ ti Olúwa. Ẹ̀mí Olúwa yóò sì ti àwọn ọmọdé síwájú láti lọ láti sọ iṣẹ́ ìránṣẹ́ ẹ ti ọ̀run. Ẹ̀mí yíí ni a yóò dà sórí àwọn tí wọ́n fara wọn sílẹ̀ fún ìṣínílétí i RẸ̀. Tí wọn sọ àwọn òfin ènìyàn tí ó so wọ́n tí wọ́n sì rìn pẹ̀lú ìṣọ́ra, wọn yóò dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ogun ọ̀run ti Olúwa.- Testimonies, vol.7, pp. 26,27.IIO 105.3

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents