Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Èka Ilé Ìtẹ̀wé

    Ìwọ tí o gba òtítọ́ ọ ti àsìkò yì í gbọ́, jí dìde. Iṣẹ́ ẹ̀ rẹ ní báyìí láti mú gbogbo ọ̀nà tí ó le è ṣe é ṣe láti rán àwọn tí ó lóye òtítọ́ láti polongo o rẹ̀. Ará owó tí ó ń wá láti inú àwọn ìwé àtẹ̀jáde e wa tí a tà ni a gbọdọ̀ lò láti mú kí ohun èlò o wa pọ̀ sí i nínú ṣíṣe ọ̀pọ̀ ìwé tí yóò sí àwọn ojú tí ó ti fọ́ tí yóò sí ilẹ̀ tí a kò ro nínú ṣọ́kàn.- Testimonies, vol.9, p.62.IIO 148.5

    Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn, Ọlọrun fún mi ní àwọn ìtọ́sọ́nà pàtàkì pé a gbọdọ̀ gbé àwọn ilé dìde ní ibi gbogbo ní Amẹ́ríkà, úróòpù, àti àwọn ilé mìíràn fún àtẹ̀jáde ìwé tí ó kún fún ìmọ́lẹ̀ òtítọ̀ ọ ti ìsinsinyìí. Ó pàṣẹ pé gbogbo ìgbìyànjú ní a ní láti gbà láti rán jáde lọ sí ayé láti ọ̀dọ̀ àwọn tí ń tẹ̀wé iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìwé ìpè àti ìkìlọ̀. Àwọn díẹ̀ ni a yóò dé ọ̀dọ̀ ọ wọn nípa àwọn ìwé e wa tí a kò sì lè dé ọ̀dọ̀ ọ wọn ní ọ̀nà mìíràn. Nínú àwọn ìwé àti tàkààdá ni ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ tí ó mọ́lẹ̀ yóò sì tàn lọ láti la aráyé lóye nípa òtítọ́ ọ ti àsìkò yì í.- Testimonies, vol.8, p.87.IIO 148.6

    A ti fi hàn mí pé àwọn ìwé àtẹ̀jáde e wa ni a gbọdọ̀ tẹ̀ ní onírúurú àwọn èdè kí a sì fi sọwọ́ sí gbogbo ìlú tí ó lajú ní gbogbo ọ̀nà. Kín ni ìwúlò owó ní àsìkò yì í, nínú fífiwé pẹ̀lú ìdíyelé àwọn ọkàn? A gbọdọ̀ ṣe àṣàrò pé gbogbo fàdákà nínú ohun ìní i wa jẹ́ ti Ọlọ́run kì í ṣe tiwa; gẹ́gẹ́ bí ìgbẹ́kẹ̀lé iyebíye láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run sí wa; a kò gbọdọ̀ fi ṣòfò fún ohun tí kò wúlò, ṣùgbọ́n kí a lò ó pẹ̀lú ìṣọ́ra nínú iṣẹ́ Ọlọrun, nínú iṣẹ́ ẹ gbígba ọkàn àwọn ọkùnrin àti obìnrin là kúrò nínú ègbé.- Life Sketches, p.214.IIO 149.1

    Òtítọ́ ọ̀rọ̀ tí a tẹ̀ ní a ní láti túmọ̀ sí onírúurú àwọn èdè, kí a sì gbé e lọ sí òpin ayé.- Testimonies, vol.9, p.26.IIO 149.2

    Àwọn ìwé àtẹ̀jáde ni ó ní láti túmọ́ sí onírúurú èdè;fún gbogbo ayé kí a ba à a le è wàásù ìhìnrere náà. Sí olúkúlùkù òṣìṣẹ́ Kristi ṣèlérí agbára ọ̀run tí yóò mú àwọn iṣẹ́ ẹ RẸ̀ láṣeyọrí.- Testimonies, vol.9, p.34.IIO 149.3

    Àwọn ìwé àtẹ̀jáde e wa gbọdọ̀ lọ sí ibi gbogbo. Jẹ́ kí wọn tẹ̀ ẹ́ jáde ní onírúurú èdè tí ó yàtọ̀. Iṣẹ́ ìránṣẹ́ ẹ ti angẹli kẹta ni a ní láti fún ni nípasẹ̀ ohun èlò yìí àti nípasẹ̀ Olùkọ́ ààye è nì.Ìwọ tí o gba òtítọ́ ọ ti àsìkò yì í gbọ́, jí dìde.- The Colporteur Evangelist, p.101.IIO 149.4

    Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn eniyan Ọlọrun ni ó ní láti jáde lọ pẹ̀lú àwọn ìwé àtẹ̀jáde e wa síbi gbogbo tí a kò tí ì polongo iṣẹ́ ìránṣẹ́ angẹli keta dé. Àwọn ìwé e wa ni a ní láti tẹ̀ jáde ní onírúurú èdè tí ó yàtọ̀. Pẹ̀lú àwọn ìwé yìí, onírẹ̀lẹ̀, olóótọ́ ènìyàn ni ó ní láti jáde bí i òjíṣẹ́ Ọlọ́run òǹtàwé, tí ó sì ń gbé òtítọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn tí ó jẹ́ pé wọn kò lè ní òye láíláí.- Testimonies, vol.9, p.33,34.IIO 149.5

    Láti ìlú ń lá dé ìlú ń lá, láti ilẹ̀ ìbí ẹni dé ilẹ̀ ìbí ẹni, wọ́n ní láti gbé àwọn ìwé àtẹ̀jáde tí ó kún fún àwọn ìlérí i ti ìpadàbọ̀ wá Olùgbàlà láìpẹ́.- Testimonies, vol.9. p.34.IIO 149.6

    A ti fi hàn mí pé àwọn ìwé àtẹ̀jáde nísisinyìí tí ń ṣiṣẹ́ lórí àwọn ọkàn díẹ̀ ní àwọn ìlú mìíràn tí ó sì ń fọ́ ògiri èrò búburú àti ìsìn èké. Wọ́n fi hàn mí àwọn ọkunrin ati awọn obinrin tí wọ́n ń ṣe àṣàrò pẹ̀lú ìfẹ́ kíkan kíkan sí àwọn tákààdá àti àwọn ewé díẹ̀ ní ti ìwé ìléwọ́ lórí òtítọ́ ọ ti ìsinsìnyìí. Wọn yóò ka àwọn ẹ̀rí tó yanilẹ́nu tí ó, sì jẹ́ tuntun sí wọn, wọn yóò sì ṣí Bibeli pẹ̀lú ìfẹ́ tuntun tó jinlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àkòrí òtítọ́ tí ó ti ṣókùnkùn sí wọn tí ó sì tẹ́jú, ní pàtàkì jùlọ ìmọ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ìsinmi ti òfin kẹrin. Bí wọ́n ṣe ń wá inú Ìwé Mímọ́ láti rí i bóyá àwọn n ǹkan wọ̀nyí rí bẹ́ ẹ̀, ìmọ́lẹ́ tuntun tàn sí òye e wọn, nítorí àwọn ańgẹ́lì ń rá bàbà yíkà a wọn, tí ó sì ń tẹ̀ ẹ́ mọ́ wọn lí ọkàn pẹ̀lú àwọn òtítọ́ tí ó wà nínú àwọn ìwé àtẹ̀jáde tí wọ́n ti ǹ kà.IIO 150.1

    Mo rí wọn tí wọ́n ń ka àwọn tákààdá lọ́wọ́ àti ìwé ìléwọ́ ní ọwọ́ kan àti Bíbélì ní ọwọ́ kejì, nígbà tí wọ́n ń wá a, wọ́n kún fún omijé; wọ́n tẹríba níwájú Ọlọ́run nínú ìtara, àdúrà ìrẹ̀lẹ̀, láti tọ́ wọn sọ́nà nínú u gbogbo òtítọ́,- ohun tí ó ń ṣe pàtó fún wọn kì wọn tó ké pè É. Nígbà tí wọ́n sì gba òtítọ́ náà sínú ọkàn-an wọn, tí wọn sì rí okùn ìbárẹ́ òtítọ́, Bíbélì náà sí wọn jẹ́ ìwé titun; wọ́n fàámọ́ra mọ́ ọkàn-an wọn pẹ̀lú ọkàn ọpẹ́, nígbà tí ojú u wọn ń tàn pẹ̀lú ìdùnnú ati ayọ̀ mímọ́. Eléyìí kò tẹ́ wọn lọ́run pẹ̀lú ìgbádùn ìmọ́lẹ̀ fúnra a wọn lásán, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ fún àwọn mìíran.IIO 150.2

    Díẹ̀ ṣe ìfisílẹ̀ ń lá nítorí òtítọ́ àti láti ṣè rànwọ́ fún àwọn ara a wọn tí wọ́n wà lókùnkùn. Ní báyìí à ń pèsè ọ̀nà sílẹ̀ láti ṣiṣẹ́ tí ó tóbi nínú u pínpín àwọn ìwé ìléwọ́ àti tákààdá ní àwọn èdè mìíràn.- Life Sketches, pp.214, 215.IIO 150.3

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents