Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Iṣẹ́ ìsìn Àwọn Àlùfáà

    Ìrànlọ́wọ́ tí ó dára tí àwọn àlùfáà lè fún àwọn ọmọ ìjọ kì í ṣe íwàásù, ṣùgbọ́n ṣíṣe àgbékalẹ̀ iṣẹ́ fún wọn. Fun ọ̀kọ̀ọkan wọn ni n ǹkan láti ṣé fun áwọn míiran. Ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí i pé bí olùgba oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọ́run wọ́n wà ní abẹ́ àṣe láti ṣiṣẹ́ fún Un. Ati pẹ̀lú ki gbogbo wọn kọ́ bí wọ́n ṣe lè ṣiṣẹ́. Pàápàá bí àwọn tí wọ́n bá jẹ́ ọmọ ijọ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbàgbọ́ gbọdọ̀ kọ́ láti jẹ́ alábá —a-ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú Olọrun.- Testimonies,vol.9, p.82.IIO 69.4

    Awọn alufaa ,waasu ti otitọ tí yóò darì eniyan sí iṣẹ́ àdáṣe fún àwọn tí kò sí ní ọ̀dọ̀ ọ Krístì. Gbìyànjú kí ọ̀kọ̀ọkan wọn jà fitafita ní gbogbo ọ̀nà.- Testimonies, vol.9,.p.124.IIO 69.5

    Jẹ ki awọn alufaa kọ́ àwọn ọmọ ìjọ pé láti dàgbà nínú ẹmi, wọn gbọdọ gbé ẹrù ti Ọlọrun gbé lé wọn lórí-ẹrù u dídarí àwọn ọkàn sí òtítọ́. Gbogbo awọn tí kò ṣe ojúṣe e wọn ni a gbọdọ̀ bẹ̀wò, a gbọdọ̀ gbàdúrà pẹ̀lú u wọn, kí a ṣiṣẹ́ fún wọn. Máṣe darí àwọn eniyan láti dúró lórí àwọn òjíṣẹ Ọlọ́run; kọ́ wọn láti lo ẹ̀bùn un wọn nínú fífi òtítọ́ fún àwọn tí ó yí wọn ká.Nínú ṣíṣe iṣẹ́ yìí, wọn yóò ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ti àwọn ángẹ́lì ọ̀run, wọn yóò sì ní ìrírí tí yóò mú ìgbàgbọ́ ọ wọn dàgbà, tí yóò fún wọn ní àbáṣepọ̀ tí ó múná dóko pẹ̀lú Ọlọ́run.- Gospel Workers, p.200.IIO 69.6

    Nínú sí ṣiṣẹ́ níbi tí a ti ní àwọn díẹ̀ nínú ìgbàgbọ́, àwọn àlùfáà gbọdọ̀ lákọ́kọ́ láti má a wá ọ̀pọ̀ aláìgbàgbọ́ láti jèrè, bí i láti kọ́ àwọn ìjọ fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà. Jẹ́ kí ó ṣiṣẹ́ fún wọn ẹnìkọ̀ọkan, kí ó ṣapá láti sọ wọ́n jí láti wá ìrírí tó jinlẹ̀ fúnra a wọn, àti láti ṣiṣẹ́ fún ẹlòmíràn. Nígbà tí wọ́n bá ti gbáradì láti mú alùfáà dúró nípa àdúra a wọn àti iṣẹ́ ẹ wọn, àṣeyọrí ń lá ni yóò bá ìgbìyànjú u wọn.- Gospel Workers, p.196.IIO 70.1

    Ní àwọn abala kan ipo àwọn àlùfáà fara pẹ ti aṣáájú àwọn ikọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ tàbí ọ̀gágun atukọ̀ ojú omi. Ó yẹ kí wọ́n bojútó àwọn tí ó wà lábẹ́ ẹ wọn láti ríi pé wọ́n ṣe iṣẹ́ tí a yàn fún wọn bí ó ṣe tọ́ àti lásìkò tí ó yẹ, àfi ìgbà pàjáwìrì nìkan ni wọ́n tó lè ṣe ọ̀fintótó. Ẹni tí ó ní ẹ̀rọ ń lá kan rí igbákejì i rẹ̀ nínú kẹ̀ẹ̀kẹ́, tí ó ń ṣe atunṣe ǹkan pẹ́-pẹ̀-pẹ́, nígbà tí ìdá mẹ́fà nínú méjìlá òṣìṣẹ́ ní abala náà dúró, tí wọn ń wò láì ṣe ohunkóhun. Olùdásílẹ̀, lẹ́hìn tí ó kọ́ n ǹkan tí ó dájú láti lè rí i dájú pé kò sí àì sòótọ́ kan tí a ṣe, pe aṣojú u rẹ̀ sí ibi iṣẹ́ ẹ rẹ̀ ó sì yọọ́ kúrò lẹ́nu iṣẹ́ nípa sísan owó iṣẹ́ ẹ rẹ̀ fun lẹ́kúnrẹ́rẹ́. Ni ìyàlẹ́nu aṣáájú yìí béèrè fún àlàyé. A sì fi fún pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ yìí; “Mo gbà ọ́ láti pa àwọn mẹ́fà mọ́ sí ẹnu iṣẹ́. Mo rí i pé àwọn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà ni wọn kò ṣe ohunkóhun, o sì ń ṣe iṣẹ́ ti ẹnìkan. N kò lè san owó àwọn méje nítorí pé o kọ́ àwọn mẹ́fà láti má ṣiṣẹ́.”IIO 70.2

    Ní ọ̀nà kan, ìṣẹ̀lẹ̀ yì í lè bá ara wọn mu, ní ọ̀nà mìíràn ó sì lè yàtọ̀. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn alufaa ló bàkù nínú àì mọ báwo tàbí àì le gbìyànjú, láti ni ọmọ ìjọ lẹ́kúnrẹ́rẹ́ láti kópa ní onírúurú ẹ̀ka ti iṣẹ́ ìjọ. Ti alufaa yóò bá farabalẹ̀ láti ní àti làti mú kí agbo wọn kópa takun takun níbi iṣẹ́, wọn yóò le ṣe àṣeyọrí rere, wọn yóò lè ní ààyè láti kọ́kọ́ àti láti sàbẹ̀wò ìgbàgbọ́ àti láti yàgò fún ohun tí ó lè mú èdè àìyedè wá.- Gospel workers, pp.197,198.IIO 70.3

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents