Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Àpèjọ Ọkàn Kan

    Iṣẹ́ Kristi kún fún àwọn ìfọ̀rọ̀wérọ̀ ọ ti ọlọ́danni. Ó ní ọ̀wọ̀ tòótọ́ fún àpéjọ ọkàn-kan tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀. Ìmọ̀ tí ọkàn kan yìí gbà ni ó gbé lọ sí ọ̀dọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún.-Testimonies, vol.6, p.115.IIO 116.4

    Ó dákú Ó sì ṣàárẹ̀; síbẹ̀ kò dágunlá sí ànfààní sísọ̀rọ̀ sí obìnrin kan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àlejò ni, àjèjì láti ilẹ̀ Ísírẹ́lì, tí ó sì ń gbé nínú ẹ̀sẹ̀ tí ó hàn sí gbangba.- The Desire of Ages, p.194.IIO 116.5

    Olùgbàlà kò dúró de àwọn ìjọ láti péjọ. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni Ó má a ń bèrè àwọn ẹ̀kọ́ ọ RẸ̀ pẹ̀lú àwọn díẹ̀ tí wọ́n péjọ nípa a RẸ̀, ṣùgbọ́n ní ẹnì kọ̀ọ̀kan ni àwọn tí ó ń kọjá lọ yóò dúró láti tẹ́tí sílẹ̀, títí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò fi gbọ́ ọ̀rọ̀ ọ RẸ̀ pẹ̀lú ìyanu àti ìbẹ̀rù nípasẹ̀ olùkọ́ tí a rán láti ọ̀run. Kí òṣìṣẹ́ ẹ Kristi máṣe rò pé kò le è sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìtara kan náà sí àwọn olùgbọ́ díẹ̀ sí ẹgbẹ́ tí ó tóbi. Ó lè jẹ́ ẹnìkan péré ni ó ní láti gbọ́ iṣẹ́ iranṣẹ náà; ṣùgbọ́n tani ó lè sọ bí ipa a rẹ̀ yóò ṣe rìn jìnnà tó? Ó dàbí ohun kékeré, pàápàá sí àwọn àpóstélì i RẸ̀, fún Olùgbàlà láti lo àkókò o RẸ̀ lórí obìnrin ará Samáríà. ṣùgbọ́n Ó rí ìdí láti ní ìtara àti ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ pẹ̀lú u rẹ̀ ju pẹ̀lú àwọn ọba, àwọn ìgbìmọ̀, àwọn olórí àlùfáà. À ti ṣe àtúnsọ àwọn ẹ̀kọ́ tí ó fún obìnrin náà ní àwọn ibí tí ó jìnnà réré.- The Desire of Ages, p.194.IIO 116.6

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents