Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  Ẹgbẹ́ tí ó Ń tẹ́ Ara a Rẹ̀ Lọ́rùn

  A fi ẹgbẹ́ kan hàn mí tí wọ́n mọ̀ nínú ara wọn pé àwọn ní agbára ìfisílẹ̀, ní ẹmi ifarajin àti ìfẹ́ láti máa ṣoore; síbẹ̀, wọn kò ṣe ohunkóhun.Wọ́n ní, wọ́n sì ń pọ́n ara wọn lé pé bí àwọn bá ní àǹfààní, tàbí wà ní ipò tí ó fi ààyè gbà wọ́n, kìbá ṣe é ṣe àti pé wọn kì bá ṣe iṣẹ́ ń lá àti iṣẹ́ rere, ṣùgbọ́n wọ́n ń dúró fún ààyè tí ó wọ̀, wọ́n kẹ́gàn àwọn táláká àhun tí wọ́n ń kùn fún owó oúnjẹ kékeré fún àwọn aláìní.Wọ́n rí i pé o ń gbé ìgbé ayé ìmọ̀-tara- ẹni- nìkan, àti pé kò ní ri ipe kúrò nínú ìmọ̀- tara- ẹni- nìkan láti ṣe rere fún àwọn ẹlòmíràn, láti bùkún wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn tàbí nípa lórí ohun ìní tí a fi sí ìkáwọ́ ọ rẹ láti lo lái si àṣìlò, tabi jẹ́ kó díbàjẹ́, tàbi bò ó mọ́lẹ̀. Gbogbo àwọn tí wọ́n háwọ́ ti wọn si mọ tara wọn nìkan, ni wọ́n yóò jíhìn fún ìwà ahun wọn, wọn yóò sì tún ṣe àlàyé fún àṣìlò ẹ̀bùn-un wọn. Ṣùgbọ́n àwọn tí wọ́n wúlò ni àwọn tí wọ́n ní agbára láti fi sílẹ̀,awọ́n ti n ǹkan ẹ̀mí kò ṣàjèjì sí láti mọ àwọn ohun ti ẹ̀mí, tí wọ́n si káwọ́ gbera, tí wọ́n ń dúró fún ànfààní tí wọ́n rò pé àwọn kò ní, síbẹ, wọ́n ń ṣe àfiwé e ìmúra sílẹ̀ ẹ wọn láti ṣe pẹ̀lú u ìfẹ́ inú ahun,tí wọ́n sì ronú jinlẹ̀ lórí ipó o wọn pé ó lọ́lá ju ti àwọn aládúgbò o wọn tí ó dàbí ènìyàn lásán, irúfẹ́ àwọn yìí ń tan ara wọn jẹ, kìkì àmúyẹ ohun ìní tí wọ́n ti kó lo, kàn ń ṣe afikún ẹrù tí a gbé lé wọn lọ́wọ́;tí wọ́n bá sì wá pa ẹ̀bùn tí Olúwa wọn fi lé wọn lọ́wọ́ mọ́ láí ṣe àtúnṣe, tàbí kó ìṣúra pamọ́, ìwà a wọn kò yàtọ̀ sí ti àwọn aládúgbóò o wọn fún àwọn ọkàn tí wọn kò kàsí.Sí àwọn yìí, wọn ó sọ pé,“Ẹ mọ ìfẹ́ Olúwa yín, síbẹ̀ ẹ kò ṣe é”.- Testimonies,vol.2, pp.250,251.IIO 36.3

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents