Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Àwọn Obìnrin Òjíṣẹ́ Ọlọ́run

    Àti Obìnrin àti ọkùrin náà le kopa nínú iṣẹ́ fífi òtítọ́ pamọ́ sí ibi tí ó ti lè jẹ jáde tí yóò sì fihàn.Wọ́n lè gba ipò wọn nínú iṣẹ́ yìí níbi ìpèníjà yìí, Ọlọ́run yóò sì ṣiṣẹ́ nípasẹ̀ ẹ wọn. Bí òye iṣẹ́ tí a gbé lé wọn lọ́wọ́ bá yé wọn, kí wọn ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìṣàkóso ẹ̀mí Ọlọ́run, wọn kì bá ní ìfira ẹni jì tí ó yẹ fún àsìkò yìì.Olùgbàlà yóò wá tan ìmọ́lẹ̀ sí àwọn obìnrin oní -ṣẹ́ra-ẹni, ìmọ́lẹ̀ ti ojú u rẹ̀, èyí yóò sì fún wọn ní agbára tí ó kọjá a ti àwọn ọkunrin. Wọ́n le è ṣe é nínú ìdílé e wọn, iṣẹ́ tí àwọn ọkùrin kò le è ṣe, iṣẹ́ tí ó wọ inú ọkàn enìyàn, wọ́n lè súnmọ́ àwọn ọkàn tí àwọn ọkùrin kò lè dé ọ̀dọ̀ ọ wọn. Iṣẹ́ ẹ wọn wúlò. Àwọn obìnrin tí wọ́n lóye tí wọ́n sì farabalẹ̀ lè ṣe iṣẹ́ rere nípa sí ṣàlàyé òtítọ́ fún àwọn ènìyàn nínú ilé e wọn. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bí a ṣe ṣàlàyé e rẹ̀, yóò ní ipa èyí tí yóò mú gbogbo ìdílé yípadà.-Testimonies, vol.9, pp.128, 129.IIO 27.2

    Gbogbo àwọn tí wọ́n bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́ gbọdọ̀ ní àwọn àmúyẹ tí ó fara pẹ́ ti Màríà àti Màtá,-fífẹ́ tọkàn tọkàn láti jíhìn àti ìfẹ àìṣẹ̀tàn ti òtítọ́.A gbọdọ̀ gbé ìfẹ́ tara ẹni àti ìmọ̀-tara-ẹni- nìkan tì sápá kan. Ọlọ́run ń pe àwọn obìnrin tí ó ní ìtara, òṣìṣẹ́ tí ó m’òye, , onítara ènìyàn, onírọ́nú àti olóótọ́ sí àgbékalẹ̀. Ó ń pè fún àwọn obìnrin onífaradà, tí wọn yóò mú ọkàn wọn kúrò nínú ti ara wọn àti ohun tí ó lé rọ̀ wọ́n lọ́rùn, tí wọn yóò sì gbé ọkàn wọn sí Krístì,tí wọn yóò sọ̀rọ̀ òtítọ́, gbígbàdúrà pẹ́lú àwọn tí wọ́n l’ánfààní láti rí, ṣíṣiṣẹ́ fún ìjèrè àwọn ọkàn.-Testimonies, vol.6, p118.IIO 27.3

    Àwọn obìnrin lè ṣiṣẹ́ láti gba olùforúkọ sílẹ̀ fún ìwe àtìgbàdégbà a wa ní ọ̀nà yóò tan ìmọ́lẹ̀ sí ọkàn púpọ.-Review and Herald, June 10, 1880.IIO 28.1

    Àwọn obìnrin tí ó lọ́lá wà tí wọn ti hùwà ìgboyà láti ṣe ìpinnu fún òtítọ́ nínú òṣùwọ̀n ti ẹ̀rí. Wọ́n fi òtítọ́ inú gba òtítọ́ náà. Wọ́n ní ọgbọ́n, ìkíyèsí àti agbára, wọn yóò sì jẹ́ aláṣeyọrí òṣìṣẹ́ fún Olúwa a wọn.Àwọn obìnrin onígbàgbọ́ ni a pè.-Review and Herald, Dec.19, 1878.IIO 28.2

    Àwọn obìnrin wa lè ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ra òṣìṣẹ́ nínú kíkọ́ àti mímú jáde, nínú ìfọwọ́bà òtítọ́ ti àwọn ọ̀rẹ́ tí ó ti gba àwọn ìwe ìléwọ́ ọ wa….Àwọn obìnrin tí wọ́n ní ìpìlẹ̀ tàbi àgbékalẹ̀ tó dúró àti ìwà tí ó ń ṣe ìpinnu ni a nílò, àwọn obìnrin tí wọ́n gbàgbọ́ pé ó ń gbé l’ótítọ́ nínú ìgbà ìkehìn tí ìkìlọ̀ tí a ò fún aráyé….Àwọn wọ̀nyí gan an ni Ọlọ́run lè lò nínú iṣẹ́ ìhìnrere…Eléyìí ní gbogbo ọ̀nà ṣe iyebíye fún Ọlọ́run nípa títú palẹ̀ àwọn ìwé ìléwọ́ kí wọn sì pín ìwé ìléwọ́ àtìgbàdégbà tí ó ń sọ nípa àwọn (àmì àkókò.)-Review and Herald, Dec 19, 1878.IIO 28.3

    N kò sọ pé obìnrin gbọdọ̀ wá ọ̀nà láti jẹ́ olùdìbò tàbí ẹni tí ó ń di ipò mú ṣùgbọ́n ajíhìnrere, kíkọ́ òtítọ́ nípa kíkọ àwọn ìwé ránṣẹ́, pínpín ìwé ìléwọ́ àti rírọ̀ wọ́n láti dáwó sí àwọn ìwé àtìgbàdégbà tí ó kún fún òtítọ́ ti àsìkò yìí.O lè ṣe ohun púpọ̀.-Review and Herald, Dec 19, 1878.IIO 28.4

    Tí obìnrin ogún bá wà tí ọ̀kan, fẹ́ mú iṣẹ́ mímọ́ yìí ní ọ̀kúnkúndùn, a máa wá rí àwọn ọkàn tí yóò yí padà sí òtítọ́.-Review and Herald, Jan.2, 1879.IIO 28.5

    Àwọn obìnrin tí ó lè ṣiṣẹ́ ni a nílò ní àsìkò yìí, àwọn obìnrin tí kó ka ara wọn sí pàtàkì, ṣùgbọn tí wọ́n ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, tí wọn yóò sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ti Krístì níbi tí wọ́n bá ti rí iṣẹ́ láti ṣe fún ìgbàlà àwọn ọkàn.-Review and Herald, Jan.2,1879. Àwọn Ọgọrun obìnrin lè wà níbi iṣẹ́ lónìí tí wọ́n bá fẹ́. Wọ́n gbọdọ̀ wọ ara wọn láṣọ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú ìwọ̀n —tú- wọ̀n- sì, láì léérí àti aṣọ títọ́, tí wọ́n yọ ara wọn kúrò nínú ọ̀ṣọ́ ṣíṣe, kí wọn sì wá lo àkokò wọn tí wọn ì bá lò fún nǹkan tí kò wúlo fún iṣẹ́ ìhìnrere. A lè fi ìwé ránṣẹ́ sí àwọn ọ̀rẹ́ ẹ wa tí ó wà lọ́nà jínjìn, àwọn obìnrin wa lè pàdé pọ̀ láti jíròrò lórí bí wọ́n ó ṣè ṣe iṣẹ́ náà dáadáa. A lè fi owó pamọ́ láti fifún Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọrẹ, a lé lo owó o wa sórí àwọn ìwé àti ìwé ìléwọ́ pélébé pélébé láti fi ránṣẹ́ sí àwọn ọ̀rẹ́ ẹ wa. Àwọn tí wọ́n jòkó láì ṣe ohunkóhun gbọdọ̀ lọ láti ṣiṣẹ́. Kí obìnrin kọ̀ọ̀kan tí ó pe ara rẹ̀ ni ọmọ Ọlọ́run ní ìmọ̀lára nípa iṣẹ́ tí a gbé lé e lọ́wọ́ láti ran àwọn tí ó wà ní àyíká a rẹ̀ lọ́wọ́.-Review and Herald, Dec.12, 1878.IIO 29.1

    Àwọn obìnrin tí ń wọ̀nà láti yọ ara wọn kúro nípa gbígba ojúṣe tí ó nílò èrò àti ìmúlò ti ọkàn; síbẹ̀ èyí ni ìjánu tí wọ́n nílò láti mú ìrìn ìgbàgbọ́ ọ wọn pé, wọ́n lè jẹ́ ajíhìnrere ní ilẹ̀ àjèjì, wọ́n lè nífẹ̀ ẹ́ sí pínpín ìwé ìléwọ́ àti ìwé tí ó bá ìgbàgbọ̀ ọ́ wa mu.-Review and Herald, Dec.12, 1878.IIO 29.2

    Obìnrin, ẹ máṣe káárẹ̀ níti iṣẹ́ ìhìnrere. Iṣẹ́ tí gbogbo wa lè ṣe ni àṣèyorí ni tí a bá wà pẹ̀lú Ọlọ́run.Kí ó tó di pé a kọ ìwé láti ṣe ìwádìí, lójoojúmọ́,kí a gbé ọkàn wa sókè sí Ọlọ́run nínú àdúrà, pé kí a lè ṣàṣeyorí nípa kíkọ́ àwọn ẹ̀ka tí a lè sopọ̀ sínú àjàrà tòótọ́, kí wọn sì so èso fún ògo Ọlọ́run. Gbogbo àwọn tí ó bá ní ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn nípa nínú iṣẹ́ yìí, wọn o máa kọ́ ara wọn láti ìgbà dé ìgbà gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà Olúwa,-Review and Herald, June 19,1880IIO 29.3

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents