Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Àwọn Ajẹ́rìí.

    A jẹ́ ajẹ́rìí fún krístì, a kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ǹnkan ayé yìí gba ọkàn àti àkókò o wa.-Testimonies,vol.9,pp 53-54.IIO 15.4

    “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rì í mì ni Olúwa wí...., mo ti sọ, mo sì ti gbàlà, mo ti fi hàn nígbà tí kò sí Ọlọ́run àjèjì láarin yín:fún ìdí èyi, ẹ̀yin ni ẹlẹ́rì í Mi “Èmi Olúwa ti pè yín nínú òdodo, èmi ó di ọwọ́ rẹ mú, màá sì pa yín mọ́, màá si fi ọ́ ṣẹ̀rí májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn, fún ìmọ́lẹ̀ àwọn kèfèrí, láti la ojú àwọn tí kò ríran, láti tú òǹdè sílẹ̀ àti àwọn tí wọ́n jòkó kúrò nínú òkùnkùn ní ilé túbú”.-The Acts of the Apostles. P.10.IIO 15.5

    Àwọn ènìyàn ti ayé ń sin àwọn Ọlọ́run èké wọ́n sì gbọdọ̀ yí wọn padà kúrò nínú ìsìn èké e wọn, kìí ṣe nípa ṣíṣe àtakò àwọn òrìṣà wọn, ṣùgbọ́n nípa gbígbọ́ ohun tí ó dára jùlọ.Oore-Olúwa ní láti di mímọ̀.”Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rì í mi ni Olúwa wí,pé èmi ni Olúwa” .-Christ Objects Lessons,p.299.IIO 16.1

    Gbogbo àwọn tí yóò bá wọ ìlu ọ̀run nínú ìgbé ayé wọn gbọdọ̀ fi Krístì ṣe àwòkọ́ṣe e wọn.Eyí ni yóò mú wọn jẹ́ ìránṣẹ́ fún Krístì,ẹlẹ́rì í rẹ̀. Wọ́n ní láti jẹ́ ẹnití ó mọ́ gaara,láì fi lúúlú bojú ní títako iṣẹ́ ibi wọn, ní títọ́ka ẹlẹ́ṣẹ̀ sí ọ̀dọ́ àgùtàn Ọlọ́run,ẹni tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ.-Testimonies, ,p.23.IIO 16.2

    Àwọn àtẹ̀lé e rẹ̀ fẹ́ lọ gẹ́gẹ́ bí ajẹ́rì í Krístì láti sọ f’áráyé ohun tí wọ́n ti rí,tí wọ́n sì ti gbọ́ nípa Rẹ̀,.Ibi tí a fi wọń sí ṣe pàtàkì jùlọ nínú èyí tí a ti pe ọmọ ènìyàn sí rí, ó wà ní ipò kejì lẹ́hìn Krístì fúnra a rẹ̀. Wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ alábàá ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run láti gba ènìyàn là.-The Acts of the Apostles,p.19.IIO 16.3

    Olùkọ́ni látọ̀run sọ pé:Ẹ̀mí ì mi nìkan tó láti kọ́ àti láti fi ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ hàn. Ohun tí a fi ojú rí lè ní ipa lórí ọkàn ènìyàn fún ìgbà díẹ̀.Èmi yóò pàṣẹ ti òdodo lórí ẹ̀rí ọkàn, àwọn ènìyàn yóò sì ṣe ẹlẹ́rì í mi ní jákè jádò ayé Ní ìdánilójú ẹ̀tọ́ tí mo ní lórí àkókò ènìyàn,owó o rẹ̀ àti òye è rẹ̀.-Testimonies,vol.7, p159.IIO 16.4

    Ìjẹ́wọ́ wa nípa ìṣòtítọ́ o rẹ̀, ní aṣojú ọ̀run ti yan bí ọ̀nà fún ṣíṣe àfihaǹ Krístì fún aráyé. A gbọdọ̀ gba oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí ó fihàn nípasẹ̀ ẹni mímọ́ ìgbà a nì. Ṣùgbọ́n èyí tí ó sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ jù ni ìjẹ́rìí ìrírí ti ara wa. A jẹ́ ajẹ́rí fún Ọlọ́run bí a ṣe ń ṣe ìfihaǹ nínú ara ti agbára tí íṣe ti ọ̀run.Olúkúlùkù ni ó ń gbé ayé tí ó yàtọ̀ sí ti ẹlòmíràn àti ìrírí tí kò jọra sí ti ẹnikẹ́ni. Èròǹgbà Ọlọ́run ni kí ìyìn wa gòkè tọ̀ ọ́ ní ìbámu sí ìrírí oníkálùkù. Ìmọ̀ tí ó níye lórí fún ìyìn ògo ti oore-òfẹ́ ẹ rẹ̀, nígbà tí ó bá wà ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú ìwà bíi Krístì, yóò ní agbára tí kò ṣe é ta ṣọnù, tí ń ṣiṣẹ́ fún ìgbàlà àwọn ọkàn.-The Desire of Ages, p.347.IIO 16.5

    Ọlọ́run kò le ṣe ìpàtẹ ìmọ̀ ọ rẹ̀ àti ìyanu oore-ọ̀fẹ́ láarin ayé tí ó kún fún aláìgbàgbọ́ àyà àfi tí ó bá ní ẹlẹ́rìí tí ó káàkiri gbogbo ayé. Ètò Ọlọ́run ni pé àwọn tí ó bá jẹ́ alábápín ìgbàlà ń lá rẹ̀ nípasẹ̀ Jésù Krístí gbọdọ̀ jẹ́ ajíhìnrere ní ilẹ̀ àjèjì, atànmọ́lẹ̀ jákè jádò ayé, láti jẹ́ àmì fún àwọn ènìyàn, ìwé alààyè tí a kọ, tí gbogbo ènìyàn ti mọ̀ tí wọ́n sì ti kà, Ìgbàgbọ́ ọ wọn àti iṣẹ́ ẹ wọn jẹ́rìí sí sísún mọ́lé Olùgbàlà, kí ó sì fihàn pé wọ́n kò tíì gba oore-òfẹ́ Olúwa lásán. A gbọdọ̀ ki àwọn ènìyàn nílọ̀ láti gbáradì fún ìdájọ́ tí ń bọ̀wá.-Testimonies, vol.2, pp.631, 632.IIO 16.6

    Bí àwọn “ọmọ ẹ̀yìn” ṣe ń ṣàṣàrò lórí ìjẹ́ mímọ́ Rẹ̀, ìgbé ayé mímọ́ ọ Rẹ̀, wọ́n rò pé kò sí iṣẹ́ tí yóò lè le fún àwọn, kò sí ìfira ẹni jì tó tóbi tó kí wọn jẹ́rìí nínú ayé wọn sí ìfẹ́ ìwà Krístì, O, kì bá ti dùn tó tí ó bá ṣe é ṣe láti tún ọdún mẹ́ta náà gbé lẹ́ẹ̀kan síi, wọ́n rò pé ìṣesí i wọn kì bá ti yàtọ̀! tí wọ́n bá lè rí ọ̀gá a wọn lẹ́ẹ̀kan sii, báwo ni wọn ìbá ṣe fihàn pẹ̀lú ìtara bí ìfẹ́ ẹ wọn síI ṣe jinlẹ̀ tó,àti bí wọ́n ṣe fi tọkàntọkàn banújẹ́ fún mímú ìbànújẹ́ Báa nípa ọ̀rọ̀ àti iṣé àìgbàgbọ́! ṣùgbọ́n a tù wọ́n nínú nípa èrò pé a dáríjì wọ́n. Wọ́n sì ṣe ìpinnu pé, bí ó bá ṣe é ṣe,wọn ó ò ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún àìgbàgbọ́ nípa fífi ìgboyà jọ̀wọ́ o rẹ̀ níwájú àgbáyé.-The Acts of the Apostles,p.36.IIO 17.1

    Àwọn ẹlẹ́mìí àìmọ́ méjì tí a mú bọ̀ sípò ni wọ́n jẹ́ ajíhìnrere àkọ́kọ́ tí Krístì rán láti wàásù ní ẹkùn Dẹ́kápólì. Fún ìṣẹ́jú díẹ̀ péré, àwọn ọkùnrin yìí ti ní ànfààní láti gbọ́ àwọn ìkọ́ni ti Krístì. Kò sì sí ìwàásù kán láti ẹnu Rẹ̀ tí ó bọ́ sí etí wọn.Wọn kò lè kọ́ ènìyàn bí àwọn àtẹ̀lé tí wọ́n ti wà ní ojoojúmọ́ pẹ̀lú Jésù ti ń ṣe.Ṣùgbọ́n wọ́n mọ̀ nínú ara wọn pé Jésù ni Mèsáyà náà. Wọ́n lè sọ ohun tí wọ́n mọ̀, ohun tí wọ́n ti rí àti tí wọ́n ti gbọ́, wọ́n sì ní ìmọ̀lára agbára Ọlọ́run.Eléyìí ni ẹnì kọ̀ọ̀kan lè se, ọkàn bẹ́ẹ̀ tí ó ti fọwọ́kàn nípa oore-òfẹ́ Ọlọ́run.Jòhánù, olùfẹ, àtẹ̀lé Krístì kọ: pé “ohun tí ó ti wà ní àtètèkọ́ṣe, ohun tí àwa ti gbọ́, ohun tí àwa ti rí pẹ̀lú ojú u wa, ohun tí àwa ti wò tí a sì ti fi ọwọ́ ọ wa gbá mú, ti ọ̀rọ̀ ìyè;… Pé ohun tí àwa ti rí tí a sì tì si ti gbọ́ ni a fihàn fún un yín,”IIO 17.2

    Bí àwọn ajẹ́rì í fún Krístì, a ní láti sọ ohun tí a mọ̀, ohun tí àwa fúnra wa ti rí, àti ohun tí a ti gbọ́ tí a sì tì ní ìmọ̀lára. Tí a bá ti ń tẹ̀lé Jésù ní ṣíṣẹ̀ n tẹ̀lé, a ó ri ohun tí ó tọ́ láti tọ́ka sí láti sọ nípa bí a ṣe dán ìlérí i rẹ̀ wò tí a sì rí pé òtítọ́ ni ìlérí rẹ̀. A lè jẹ́ ajérìí sí ohun tí a ti mọ̀ nípa oore-ọ̀fẹ́ Krístì. Eléyìí sì ni ẹ̀rí ti Olúwa wa pè wá si, àti fún ìlò ayé tí ó ńṣègbé. - The Desire of Ages, p.340.IIO 17.3

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents