Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  ORÍ OGÚN WÍWÀÁSÙ FÚN ÀWỌN ỌLỌ́RỌ̀ ÀTI ÀWON ÈNÌYÀN PÀTÀKÌ

  Kí A Máà Ṣe Fi Ojú Pa Wọ́n Rẹ́

  Iṣẹ́ tí a gbọ́dọ̀ ṣe fún àwọn ọlọ́rọ̀ ni eléyìí. Ó yẹ kí a ta wọn jí sí ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bíi àwọn tí Ọlọ́run ti fi ẹ̀bùn Rẹ̀ pamọ́ sí lọ́wọ́. Ó yẹ kí a rán wọn létí wí pé wọn ó jínhìn iṣẹ́ wọn fún Ẹni tí yóò ṣe ìdájọ́ àwọn alààyè àti òkú. Àwọn ọlọ́rọ̀ náà nílò iṣẹ́ ìfẹ́ wa nínú ìbẹ̀rù Olúwa. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ wọn tí ẹ̀rù ohunkóhun kò sì bà wọ́n. Ó yẹ kí a ṣí wọn lójú inú sí ohun tí yóò maa wà láíláí.-Christ’s Object Lessons, p. 230.IIO 202.1

  Àwọn ènìyàn kìí sáàbà fi ohun ti ẹ̀ẹ̀mí lọ àwọn tí ó tayọ nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tàbí ọrọ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn Onígbàgbọ́ ni wọn kìí sáàbà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn wọ̀nyìí, èyí kò sì yẹ kó rí bẹ́ẹ̀. Kò yẹ kí a fọwọ́ lẹ́rán máa wòran àwọn tí ń ṣègbé nítorí pé wọn jẹ́ adájọ́, oníṣòwò tàbí agbẹjọ́rò. Tí a bá rí ẹni tí ó fẹ́ ṣubú, ẹ̀tọ́ wa yẹ kí a rán ẹni náà lọ́wọ́ láì wo ti ipò rẹ̀ láwùjọ. Bákan náà ni kò yẹ kí a máà ṣe aláìkílọ̀ fún ọkàn tí ń ṣègbé. Kò yẹ kí a fi ojú pa ẹnikẹ́ni rẹ́ nítorí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ sí ohun tí í ṣe tí ayé.- Christ’s Object Lessons, p. 230, 231.IIO 202.2

  Ó yẹ kí a ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìrora ọkàn fún àwọn tí wọ́n wà ní ipò gígà, ó yẹ kí a pè wọ́n wá sí ibi àsè ìgbéyàwó.-Southern Watchman, Mar. 1, 1904.IIO 202.3

  Ìfẹ́ Ọlọ́run ni kí a yí àwọn ọlọ́rọ̀ lọkàn padà kí wọ́n sì jẹ olùgbọ̀wọ̀ Rẹ̀ láti dé ọ̀dọ̀ àwọn elòmíràn. Ìfẹ́ Ọlọ́run fún àwọn tí ó lè ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ àti ìmúbọ̀sípò ní wí pé wọn yóò rí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ iyebiye ni, bẹ́ẹ̀ni ìwà wọn yóò sì yípadà, wọn yóò sì lo ọrọ̀ tí Ó fi sí ìkáwọ́ wọn fún iṣẹ́ Rẹ̀. Yóò fẹ́ kí wọ́n lo ọrọ̀ wọn tí Ó fi fún wọn fún iṣẹ́ rere, èyí tí yóò mú kí ọ̀nà iṣẹ́ ìhìnrere ó là tí a o sì kéde rẹ̀ fún gbogbo ènìyàn níbikíbi.-Testimonies, Vol. 9, p.114.IIO 202.4

  Ó yẹ kí a ṣe àwárí àwọn ènìyàn tí ó wà nípò gíga pẹ̀lú ìtara àti ìfẹ́. Àwọn oníṣòwò ní ipò gíga, àwọn onímọ̀ sáyẹ̀nsì tí wọn ní ojú ìwòye, àwọn ọlọ́pọlọ pípe, àwọn olùkọ́ iṣẹ́ ìhìnrere èyí tí wọ́n kò tíì mọ òtítọ pàtàkì yìí, àwọn wọ̀nyìí ni ó yẹ kí wọ́n ó kọ́kọ́ gbọ́ ìpè yìí. Àwọn ni ó yẹ kí a fún ní ìwé ìpè náà.-Christ’s Object Lessons, p. 230.IIO 203.1

  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ aṣìṣe ni a ti ṣe sẹ́hìn nípa ṣíṣe aláìwàásù òtítọ́ yìí fún àwọn àlùfáà àti àwọn ènìyàn ńlá wọ̀nyìí. A ti pa àwọn tí kìí ṣe ọmọ ìjọ wa tì jù bí ó ṣe yẹ lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé kò yẹ kí a dàbí wọn nígbà tí a bá ń bá wọn dọ́ọ̀rẹ́ síbẹ̀ àwọn kan wà tí ó yẹ kí a fi tọkàntara ṣiṣẹ́ fún láti gba ẹ̀èmí wọn là. Ó yẹ kí a ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ bí a ṣe lè jéré irú àwọn ọkàn báyìí fún àwon ènìyàn wa.- Testimonies, Vol. 5, pp. 580, 581.IIO 203.2

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents