Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ogbon Àti Ìròtélè

    Bí Nehemiah tilè ti ń wá ìrànlówó Olórun, sùgbón síbè kò káwó gbera kí a wá máa rò wípé òun kò ní ojúse kankan mó láti se nínú isé tàbí èròǹgbà láti tún Jérúsálémù kó. Pèlú ogbón àti ìròtélè tó wuni jojo, ó tèsíwájú láti se gbogbo àwon ètò tó lè mú kí isé náà jé àseyorí. Ó sì ń gbé gbogbo ìgbésè kánkán pèlú èmí ìṣọra.-Souhern Wachman, Mar. 1, 1904.IIO 239.2

    Àpeere okùnrin mímó yìí (Nehemiah) gbodò jé èkó rere fún gbogbo ènìyàn Olórun, wípé àdúrà gbígbà pèlú ìgbàgbó nìkan kò tó, bíkòse isé takuntakun pèlú òdodo. Mélòó mélòó ìgbà ni a ti bá ìsòro pàdé pẹ̀lú ohun ìdíwó nínú isé pàtàkì yìí nítorí tí a kò ka ogbón, ìròtélè àti ìfaradà sí nínú isé ìsìn. Eléyìí jé àsìse ń lá. Ó jé ìse wa láti sa gbogbo ipá àti agbára wa èyí tí yóò mú wa jé òsìsé pàtàkì tí ó kún ojú òsùwòn fún Olórun. Síse àbojútó fíní fíní àti gbígbé ètò tí ó múná dóko kalè se pàtàkì fún àseyorí isé Olórun gégé bí ó ti rí ní ìgbà Nehemiah.- Southern Watchman, Mar. 15, 1904.IIO 239.3

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents