Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Òkùnkùn-un Ti Ẹ̀mi

    Àsìkò ti ìṣókùnkùn ti ẹ̀mí nìyí nínú ìjọ ti àgbáyé. Àìlóye ohun ti ọ̀run ti fi Ọlọ́run pamọ́ àti òtítọ́ láti fojú wò. Àwọn ikọ̀ ogun ti ẹni búburú i ń kójọ ní agbára. Èṣù ń tan àwọn alábá ṣiṣẹ́ ẹ rẹ̀ pé òun yóò ṣiṣẹ́ tí yóò di aráyé nígbèkùn. Nígbà tí ìjọ kawọ gbera pẹlu ilọwọọwọ,Sátánì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ń jà fita fita.Àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ kò yí ayé padà; nítorí pé àwọn fúnra a wọn bàjẹ́ pẹ̀lú ìmọ-tara-ẹni- nìkan àti ìgbéraga àti nínílò láti mọ̀ lára ti agbára tí í yíni padà ti Ọlọ́run láarin wọn kí wọn tó lè darí àwọn mìíràn sí jíjẹ́ mímọ́ tàbí òṣùwọ̀n gíga.- Testimonies,vol.9, p.65.IIO 55.2

    Ní ayé e wa, bí i ti àtijọ́, àwọn òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni a yà sọ́tọ̀ fún àwọn ìmọ̀ àti àwọn àkíyèsí ènìyàn. Àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní òjíṣẹ́ ìhìnrere kò gba gbogbo Bíbélì gbọ́ bí ọ̀rọ̀ tí ó ní ìmísí. Ọkùnrin olóye kan kọ abala kan; ẹlòmíràn ń ṣe ìbéèrè nípa abala mìíràn. Wọ́n gbé ìdájọ́ ọ wọn kalẹ̀ ga jù sí ọ̀rọ̀ náà; àti pé Ìwé mímọ èyi tí wọn ń kọ dúró lórí àṣẹ ẹ wọn. Àṣẹ àtòkèwá a rẹ̀ ni a sọ dasán. Báyì í àwọn èso àìgbàgbọ́ ni wọ́n gbìn káàkiri; nítorí pé wọ́n ti dabarú àwọn ènìyàn, wọn kò sì mọ ohun tí ó yẹ kí wọn gbàgbọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbàgbọ́ ló wà tí kò yẹ kí ọkàn gbà láàyè.- Christ’s Object Lessons,p.39.IIO 55.3

    Ìwà búburú ti ń dé ibi gíga tí kò dé rí tẹ́lẹ̀, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni wọ́n ń kígbe “àlàáfíà àti ìgbàlà.” Ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ Ọlọ́run òtítọ́ ní láti lọ pẹ̀lẹ́ pẹ̀lẹ́ láti tẹ̀ iṣẹ̀ ẹ wọn sìwàjù, kì a wọ̀ wọ́n pẹ̀lú ìhámọ́ra ogun ti ọ̀run, wọ́n gbọdọ̀ tẹ̀síwájú láì bẹ̀rù pẹ̀lú ìṣẹ́gun, láì lè dúró ìjagun wọn t´ití tí gbogbo ọkàn tí ó wà ní ṣàkání i wọn yóò fi gba iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti òtítọ́ ti àsìkò yìí.- The Acts of the Apostles, p.220.IIO 56.1

    Ó yẹ kí ipò tí ẹ̀sìn wà láyé lónìí bani lẹ́rù. Àánu Ọlọ́run ti di ti ṣiré ṣiré. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni ó sì ti sọ òfin Jèófà di asán, “fífi òfin ènìyàn kọ́ni ní ẹ̀kọ́”. Iwa èérí gbilẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ ìjọ ní ilẹ̀ ẹ wa; Kì í ṣe irú ìwà èérí tí à ń rò,- ṣíṣẹ́ ọ̀rọ̀ ọ Bíbélì ní gbangba,- ṣùgbọ́n,iwa eeri tí a wọ̀ tàbi wé ní aṣọ ti onígbàgbọ́; nígbà tí wọ́n ń jin ìgbàgbọ́ inú Bíbélì lẹ́sẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìfihàn ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Àdúrà tí kò lé è tàsé àti ìfaraji tó loorin ati ifọkansin to rinlẹ ti yẹra fun iwa asan. Nítorí èyí, ìyípadà kúro nínú ẹ̀kọ́ tí a ti gbà pẹ̀lú ìfẹ́kúfẹ̀ ẹ́ ti ara ń borí. Ọlọ́run sọ pé “Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nígbà ayé e Lọ́ọ̀tì,... bẹ́ẹ̀ náà ni yóò wà nígbà tí ọmọ ènìyàn yóò farahàn.” Àkọsílẹ̀ ojoojúmọ́ ti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti kọjá ń jẹ́rì í sí ìmúṣẹ ti ọ̀rọ̀ ọ Rẹ̀. Ilé ayé ti dé ibi pípọ́n fún ìparun. Láìpẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run ni áò dà jáde àti pé ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹlẹ́ṣẹ̀ ni áò jẹrun.- Patriachs and Prophets, p.166.IIO 56.2

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents