Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Pàtàkì Pẹpẹ Ìdílé

    Fún gbogbo ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ wí pé òun fẹ́ràn Ọlọ́run, ẹ mú Jésù dání lọ sí ibi gbogbo tí ẹ bá ń lọ àti gẹ́gẹ bí àwọn bàbá ìgbàgbọ́ ti ìgbaanì, ẹ máa tẹ pẹpẹ fún Ọlọ́run níbikíbi tí ẹ bá lọ. A nílò láti ṣe àtúnṣe lórí eléyìí, irú àtúnṣe tí ó jìn tí ó sì gbòòrò (Testimonies, Vol. 5, pp. 320, 321).IIO 209.3

    Sátánì ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti mú kí àwọn ènìyàn jínà sí Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ni o sì ń ṣe àṣeyọrí nínú èròǹgbà rẹ̀ nígbà tí iṣẹ́ tàbí okòòwò àwọn ènìyàn ti jẹ wọ́n lọ́kàn ju ohun tí Ọlọ́run lò tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí wọn kò ní àyè fún kíkà Bíbélì, gbígbàdúrà níkọ̀kọ̀ àti kíkọ orin ìyìn àti ọpẹ́ ní ibi pẹpẹ àdúrà wọn ní òwúrọ̀ àti àṣálẹ́.-Testimonies, Vol. 5, p. 426.IIO 209.4

    Ẹ jẹ́ kí ìsìn ìdílé dùn kí ó sì lárinrin.-Testimonies, Vol. 5, 335.IIO 209.5

    Ẹ jẹ́ kí a kọ́ àwọn ọmọ wa bí a ti máa n bọ̀wọ̀ fún àkókò àdúrà, ẹ jẹ́ kí á kọ́ wọn láti máa darapọ̀ mọ́ ìdílé ní ibi àdúrà tàbí ìsìn òwúrọ̀.-Testimonies, Vol. 5, p. 424.IIO 209.6

    Ó yẹ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ó máa dùn mọ́ àwọn ọmọ nínú, kìí ṣe ki o máa lé wọn sá. Wákàtí ìsìn ìdílé gbọ́dọ̀ jẹ́ wákàtí tí ó láyọ̀ jùlọ lójoojúmọ́. Ẹ yan ẹsẹ̀ Bíbélì tí ó dára tí ó sì rọrùn; ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ darapọ̀ nínú orin kíkọ, ẹ jẹ́ kí àdúrà jẹ́ kúkúrú kí ó sì lọ tààrà.-Southern Watchman, June 13, 1905.IIO 210.1

    Ẹ jẹ́ kí a kí àwọn àlejò wa ní ibi pẹpẹ ìdílé, kí àkókò àdúrà fi àmì sí ọkàn àwọn tí ó fẹ́ran ohun ígbádùn ayé tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ tí àwọn tí ó wá bẹ̀ wá wò yóò fi di ẹni ìgbàlà kúrò lọ́wọ́ ikú. Nítorí Ọlọ́run ka irú iṣẹ́ yìí sí tí Ó fi sọ pé, “Èmi yóò bùkún.-“Testimonies, Vol. 6, p. 347.IIO 210.2

    Ẹ jẹ́ kí a kọ́ àwọn ọmọ bí wọ́n ṣe ń bọ̀wọ̀ àti ọlá fún àkókò àdúrà. Kí a tó jáde lọ sí ẹnu iṣẹ́ òòjọ́ wa, ẹ jẹ́ kí gbogbo ìdílé ó péjọ pọ̀ kí bàbá, tàbí màmá èyí ni tí bàbá kò bá sí nílé, gbàdúrá sí Ọlọ́run fún ààbò Rẹ̀ lórí wọ́n ní ọjọ́ náà. Ẹ wá pẹ̀lú ọkàn ìrẹ̀lẹ̀ àti ọkàn jẹ́jẹ́, ní mímú irú ewu tí ó wà níwájú wa ní ọjọ́ náà kí a sì fí ìgbàgbọ́ gbàdúrà níbi pẹpẹ yìí kí a sì fi wọ́n sí abẹ́ ìtọ́jú Ọlọ́run. Àwọn ańgẹ́lì Ọlọ́run yóò pa àwọn ọmọ tí a fi lé Ọlọ́run lọ́wọ́ yìí mọ́. Ó jẹ ojúṣé àwọn obì Onígbàgbọ́ yálà ní òwúrọ̀ ni tàbí lálẹ́ nípasẹ̀ àdúrà pẹ̀lú ìtara ìgbàgbọ́ láti mọ odi yí àwọn ọmọ wọn ká. Kí wọ́n fi sùúrù kọ́ wọn bí a ṣe ń gbé ìgbé ayé tí ó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn.-Testimonies, Vol. 1, pp. 397-398.IIO 210.3

    Ábráhámù ọ̀rẹ́ Olọ́run fún wa ní àpẹẹrẹ rere, fún wa ní àpẹẹrẹ tí ó yẹ. ìgbé ayé rẹ̀ jẹ́ kìki àdúrà. Níbikíbi tí ó bá pagọ̀ sí, ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni ó máa ń tẹ́ pẹpẹ àdúrà rẹ̀ si, tí yóò sì pe gbogbo àwọn tí ó wà ní àgọ́ rẹ̀ sí ibi pẹpẹ rẹ̀ láàárọ̀ àti lááálẹ́. Nígbà tí a bá ká àgọ́ rẹ̀ kúrò, pẹpẹ rẹ̀ ṣì dúró síbẹ̀. Ní ọjọ́ iwájú nígbà tí ó bá rán ẹnikẹ́ni nínú aráa Kénánì níṣẹ́, tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá dé ibi pẹpẹ Ábráhámù yìí, wọ́n a máa mọ ẹni tí ó ti gba ibẹ̀ kọjá ṣáájú wọn, nígbà tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá pàgọ́ rẹ̀, yóò tún pẹpẹ náà ṣe, yóò sì sin Ọlọ́run alààyè.-Patriarchs and Prophets, p. 128.IIO 210.4

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents