Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Àrọwà Sí Ìjọ Tí ó Ń ṣe Ìmẹ́lẹ́

    Ó jẹ́ ohun ìjìnlẹ̀ pé kò sí tó àwọn ọgọ́rùn- ún ní ibi iṣẹ́ nísinsinyìí níbo síbẹ̀ ẹnìkan wà. Gbogbo ẹ̀dá ti ọ̀run ní ìyàlẹ́nu sí àìbìkítà, ìtutù, ìjáfara ti àwọn tí wọ́n jẹ́wọ́ láti jẹ́ ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Ọlọ́run. Nínú òtítọ́ agbára ààyè wà níbẹ̀.- Testimonies, vol.9, p.42.IIO 89.1

    A ko le ri igbala ninu imẹlẹ ati ainiṣẹ, ko si iru n nkan wọnyi bi ẹni ti o ti ni iyipada ti o n gbe igbe aye alaini ranlọwọ, igbe aye alai wulo. Ko ṣe e ṣe fun wa lati ni ero ijọba ọrun. Onilọra tabi onimẹlẹ eniyan ko le wọ ibẹ....Awọn ti wọn kọ lati fọwọ sowọ pọ pẹlu Ọlọrun ni aye, ko le ni ifọwọ sowọ pọ pẹlu u RẸ ni ọrun. Yoo lewu lati mu wọn lọ sọrun.- Christ’s Object Lessons, p.280.IIO 89.2

    Àwọn ọ̀run sì ń wò kíkan kíkan pẹ̀lú ìfẹ́ lórí ìjọ, láti rí ohun tí olúkúlùkù ọmọ ìjọ ń ṣe láti fòye han àwọn tí ó wà l'ókúnkún.- Review and Herald, Feb.27, 1894.IIO 89.3

    O gbọdọ̀ ronú pé ò ń bá Ọlọ́run ṣòwò, o sì gbọdọ̀ máa rántí pé kì í ṣe ọmọdé tí o le è fi ṣeré. O kò lè kópa nínú iṣẹ́ ẹ RẸ̀ kí o sì fi sílẹ̀ nígbà tí ó bá wù ọ́. - Testimonies, vol.2, p.221.IIO 89.4

    Awọn oloye ti ọrun ti n duro lati fọwọ sowọ pọ pẹlu awọn aṣoju eniyan, ṣugbọn a ko ti i ṣe akiyesi ifarahan an wọn. — Testimonies, vol.6, p.297.IIO 89.5

    Àwọn ángẹ́lì ọ̀run ti ń dúró pẹ́ fún àwọn aṣojú ènìyàn- àwọn ọmọ ìjọ- láti- fọwọ́ -sowọ́- pọ̀ pẹ̀lú u wọn nínú iṣẹ́ ń lá tí a ní láti ṣe. Wọ́n ń dúró dè ọ́. - Testimonies, vol.9, pp.46, 47.IIO 89.6

    Ọ̀pọ̀, ọ̀pọ̀ ló ti ń súnmọ́ ọjọ́ Olúwa láì ṣé ohun kan, tí wọ́n ń yẹra fún ẹrù rírù, fún ìdí èyí wọ́n di aràrá olùfọkànsìn. Bí ṣí ṣiṣẹ́ fún Ọlọ́run ṣe rí, àwọn abala ìwé ìtàn ìgbé ayé e wọn tí òfò ìṣófo hàn. Àwọn jẹ́ igi nínú ọgbà a ti Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kìkì gbígbilẹ̀ ni, wọ́n ṣ'ókùnkùn pẹ̀lú ẹ̀ka igi aláì léso tí ó wà ní ilẹ̀ èyí tí àwọn tí ń so èso ì bá ti gbà. - Review and herald, May 22, 1888.IIO 89.7

    Ewu wà fún àwọn tí wọ́n ṣe díẹ̀ tàbí tí wọn kò ṣe rárá fún Ọlọ́run. Oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run kò ní fi bẹ́ ẹ̀ bá ọkàn ẹni tí ó ní ànfààní àti ààyè tí ó dákẹ́ gbé.-Review and Herald, Aug. 22, 1899.IIO 89.8

    Kò sí àsìkò fún wa báyìí láti sùn, - kò sí àkókò láti ké nínú àbámọ̀ tí kò wúlò. Ẹni tí ó bá dáwọ́lé àti tòògbé nísinsinyìí yóò pàdánù ànfààní iyebíye ti iṣẹ́ rere. A ti fún wa ní ànfààní tí ó ní ìbùkún láti kó àwọn ìtí jọ nínú ìkórè ń lá; àti ọkàn kọ̀ọ̀kan tí a gbàlà yóò jẹ́ àfikún ìràwọ̀ nínú adé e Jésù Olùràpadà a wa tí à ń júbà.IIO 90.1

    Tani ó nítara láti fi ìhámọ́ra lélẹ̀ nígbà tí ó bá jagun síwájú díẹ̀ yóò ní ìṣẹ́gun titun yóò gba àwọn àmì ẹ̀yẹ ìṣẹ́gun titun fún ayérayé?- Reẹiew and Herald, Oct.25, 1881.IIO 90.2

    Àwọn ìránṣẹ́ ọ̀run ń ṣiṣẹ́ ẹ wọn; ṣùgbọ́n kín ni àwa ń ṣe? Ará l'ọ́kùnrin àti lóbìnrin, Ọlọ́run ń pè yín láti ra ìgbà padà. Súnmọ́ Ọlọ́run. Sọ ẹ̀bùn lílò ò rẹ jí pẹ́pẹ́. Jẹ́ kí àwọn tí wọ́n ti ní ànfààní láti faramọ́ pẹ̀lú àwọn ìdí ti ìgbàgbọ́ ọ wa, lo ìmọ̀ yìí nísinsìnyìí.- Historical Sketches, p. 288.IIO 90.3

    Báwo ní a ṣe le ṣe àtúnwí àdúrà Olúwa, “Kí ìjọba à rẹ dé, , Ìfẹ́ ẹ tìrẹ ni kí á ṣe láyé bí wọ́n ti ń ṣe ní ọ̀run,” Jòkó jẹ́ ẹ́ nínú ilé è rẹ láì ṣè rànwọ́ láti tan ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ sí àwọn ẹlòmíran? Báwo ni o ṣe lè gbé ọwọ́ ọ̀ rẹ sókè sí Ọlọ́run kí o sì bèèrè fún ìbùkún un RẸ̀ lórí ara à rẹ àti àwọn ìdílé è rẹ, nígbà tí o ṣe ohun kín-kin-ní láti ran ẹlòmíràn lọ́wọ́? — Historical Sketches,p.288IIO 90.4

    Àwọn kan wà láarin wa tó jẹ́ pé tí wọń bá lè rò ó, wọn yóò kíyèsí ipò àìṣedédé e wọn bí ẹ̀ṣẹ̀ àìfiyèsí ní ti àwọn ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fifún wọn. Ará l’ọ́kùnrin àti l’óbìnrin, Olùrapàdà à rẹ àti gbogbo àwọn ańgẹ́lì mímọ́ ń banújẹ́ sí ọkàn àn rẹ tí o ṣé le. Krístì fi ẹ̀mí i RẸ̀ lélẹ̀ láti gba àwọn ọkàn là, síbẹ̀ ìwọ tí o ti mọ ìfẹ́ ẹ RẸ̀ ṣe ìgbìyànjú kékeré láti fi ìbùkún oore-ọ̀fẹ́ ẹ RẸ̀ fún àwọn tí Ó kú fún. Irú ìdágunlá àti àìfiyèsí tí iṣẹ́ ìsìn jẹ́ ìyàlẹ́nu sí àwọn àǹgẹ́lì. Ní ìdájọ́ o má a bá àwọn ọkàn tí o kò kíyèsí pàdé. Ní ọjọ́ ń lá náà, o má a dá ara à rẹ lẹ́bi àti pé o tún má a bá ara à rẹ wí. Kí Ọlọ́run darí ì rẹ sí ìrònúpìwàdà báyìí. Kí ó dáríji àwọn ènìyàn an RẸ̀ fún àìfiyèsí iṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà a RẸ̀ èyí tí Ó ti fifún wọn láti ṣe.- Testimonies, vol.6, pp.425, 426.IIO 90.5

    Kíni kí á sọ sí ọmọ ìjọ tí ó ń ṣè ‘mẹ́lẹ́ láti jẹ́ kí ó mọ pàtàkì àì bo tálẹ́ǹti i rẹ̀ mọ́lẹ̀ àti f´ifi ṣe pàṣípààrọ̀? Kò ní sí aláì níṣẹ́, onímẹ́lẹ́ ní ìjọba Ọlọ́run.Báwo ni ì bá ti dára tó kí Ọlọ́run jẹ́ kí pàtàkì n ǹkan wọ̀nyí síwájú àwọn ìjọ tí ó ń sùn! Báwo ni Síónì ì bá ṣe dìde kí ó sì wọ aṣọ ẹwà a rẹ̀! Báwo ni yóò ṣe tàn!-Testimonies, vol.6, p.434.IIO 91.1

    Iṣẹ́ wà fún àwọn tí kò mọ òtítọ́ láti ṣe, gẹ́gẹ́ bí irú iṣẹ́ tí wọ́n ṣe fún ọ nígbà tí o wà nínú òkùnkùn. Ó ti pẹ́ jù fún ọ láti sùn, ó ti pẹ́ jù fún ọ láti jẹ́ onímẹ́lẹ́. Sí ẹnìkọ̀ọ̀kan ni baálé ilé ti fún ní iṣẹ́. Ẹ jẹ́ kí á tẹ̀síwájú kí a máṣe fà sẹ́hìn. À ń fẹ́ ìyípadà ọ̀tun lójoojúmọ́. À ń fẹ́ kí ìfẹ́ Jésù má a sọ kúlúkúlú nínú ọkàn an wa, kí a ba à le è jẹ́ ohun èlo nínú gbígba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkàn là.-Review and Herald, June 10, 1880.IIO 91.2

    Ọlọ́run ń fẹ́ pé ọkàn kọ̀ọ̀kan tí ó gbà láti jẹ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin,kò gbọdọ̀ kúrò nínú gbogbo àìṣedédé nìkan, ṣùgbọ́n kí ó pọ̀ ní àánú ṣíṣe, ìṣẹ́ra- ẹni àti ìrẹ̀lẹ̀. Olúwa ti ṣ’àfihàn iṣẹ́ tí ó dájú níti òfin àti iṣẹ́, tí ó gbọdọ̀ kìlọ̀ fún wa nípa kíkíyèsí iṣẹ́ ẹ wa. Ó wípé “Ẹnikẹ́ni tí kò ní, ní ọwọ́ ọ rẹ̀ ni áò ti gba ohun tí ó rò pé òun ní.” Àwọn tí kò bá ṣ’àtúnṣe lórí ànfààní, tí kò sì lo oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọ́run fún wọn, ní ìfọkànsìn díẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀, àti ní òpin gbogbo o rẹ̀ nínú oorun ti ẹ̀mí, pàdánù ohun tí ó ti fìgbà kan ní. Wọn kò pèsè sílẹ̀ fún ohun tí wọ́n nílò ní ọjọ́ iwájú nínú jíjèrè ìrírí ń lá nínú níní ìmọ̀ púpọ̀ nípa àwọn ohun ti ọ̀run, tó bẹ́ẹ̀ tí ìṣòro àti ìdánwò bá dé sórí i wọn, wọn yóò lè dúró. Nígbà tí inúnibíni tàbi ìdánwò bá wà , ẹ̀ka yìí sọ ìgboyà àti ìgbàgbọ́ ọ wọn nù, ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ wọn ni áò sì gbà lọ, nítorí pé wọn kò rí ìdí láti mú kí ìpìlẹ̀ ẹ wọn dúró. Ọkàn an wọn kò ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àpáta ayérayé.- Review and Herald, March 27, 1894.IIO 91.3

    Báwo ni ọjọ́ ń lá náà yóò ṣe ní ìbẹ̀rù tó láti rí àwọn tí a jọ ní ìbáṣepọ̀ tímọ́ tímọ́ ti a yà sọ́tọ̀ kúrò lára a wa títí láí; láti rí àwọn ará nínú ìdílé e wa, yálà àwọn ọmọ ọ wa, àínígbàlà; láti rí àwọn tí ó ti ṣàbẹ̀wò sí ilé e wa, tí wọ́n sì jẹun lórí àwọn tábìlì i wa, láarin àwọn tí ó sọnù. Nígbà náà ni áò bèèrè ìbéèrè lọ́wọ́ ara a wa, ṣé nítorí àìní sùúrù mi, àìní ìwà bí i Krístì; ṣé nítorí pé ara à mi kò sí ní abẹ́ ìṣàkóso, pé ẹ̀sìn ìn ti Krístì ti di àìládùn sí wọn?IIO 91.4

    A ní láti kìlọ̀ fún aráyé nípa bíbọ̀ wá Olúwa láìpẹ́. A ní ṣùgbọ́n àkókò kékeké láti fi ṣiṣẹ́. Ọ̀pọ̀ ọdún ló ti kọjá sí ayérayé tí ó yẹ kí a ti ṣ’àtúnṣe nínú wíwá ìjọba Ọlọ́run àti òdodo o RẸ̀, àti nínú u títan ìmọ́lẹ̀ sí àwọn mìíràn. Báyìí, Ọlọ́run ń pe àwọn ènìyàn an RẸ̀ tí wọ́n ní ìmọ́lẹ̀ ń lá tí wọ́n sì ti fi ìdí òtítọ́ múlẹ̀, tí wọ́n sì ti fún ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́, láti ṣiṣẹ́ fún ara a wọn àti fún ẹlòmíràn bí èyí tí wọn kò tí ì ṣe tẹ́lẹ̀ rí. Ṣe ìmúlò agbára; ṣe ìmúlò gbogbo agbára, gbogbo ẹ̀bùn tí ó wà ní ìkáwọ́ ọ yín; ẹ lo gbogbo ìmọ́lẹ̀ tí Ọlọ́run ti fifún - un yín láti ṣe rere fún ẹlòmíràn. Máṣe gbìyànjú láti jẹ́ oníwàásù, ṣùgbọ́n kí ẹ jẹ́ ajíhìnrere fún Ọlọ́run. Southern Watchman, June 20, 1905.IIO 92.1

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents