Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ÌMỌ̀ ÌYÀTỌ̀ OHUN Ẹ̀MÍ TI Ń DI BÀÌBÀÌ

    Kìí ṣe nínú ayé nìkan ni a ti rí àyọrísí àwọn ìjọ tí wọn kò kíyèsí àti ṣiṣẹ́ ní ọ̀nà Krístì. Nípa àì kàsí yìí, àwọn nǹkan ti wọ inú ìjọ tí o si ṣíjibo gíga àti ífẹ̀ mímọ́ ti iṣẹ́ Ọlọ́run.Ẹ̀mí ìsọ̀fintótó àti ìkorò ti wọ inú ìjọ, àti pé ìmọ ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti ń di bàìbàì. Nítorí ìdí èyí, ọ̀nà Ọlọ́run ti jìyà àdánù ń lá.-Testimonies, vol.6,p.297.IIO 38.3

    Mo kún fún ìbànújẹ́ nígbà tí mo ro ipò o wa gẹ́gẹ́ bí ènìyàn. Ọlọ́run ko ti i pa ilẹkun ọ̀run de mọ́ wa, ṣùgbọ́n ọ̀nà ìfàsẹ́hìn-in wa léra léra ti yà wá lọ́dọ̀ Ọlọ́run.Ìgbéraga, ojú kòkòrò, àti ìfẹ́ ayé tí ń gbé ọkàn an wa láì ní ìbẹ̀rù ìlékúrò tàbí ìdálẹ́bi. Ohun ìbani nínú jẹ́ àti abẹbẹ lúbẹ ẹ̀ṣẹ̀ ti ń gbé ní àarin wa, síbẹ̀ ìmọ̀ gbogbo ènìyàn ni pé ìjọ ń gbilẹ̀, àti pé ìṣerere ti ẹ̀mí ti wà ní gbogbo ẹ̀nù ọ̀nà a rẹ̀. Ìjọ ti kẹ̀yìn sí tí tẹ́lé Krístí adarí i wọn, ó sì ń fi pẹ̀lẹ́ pẹ̀lẹ́ pẹ̀hìndà lọ sí Égíbítì.Síbẹ̀ díẹ̀ ló ń ké fún wíwá agbára ti ẹ̀mí. Iyèméjì pàá pàá jùlọ àìní gbàgbọ́ àti àwọn ẹ̀ri ti ẹ̀mí Ọlọ́run ti mú ìwúra òdì bá ìjọ wà níbi gbogbo. Èyí ni ìfẹ́ Èsù.Testimonies, vol.5, p.217.IIO 39.1

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents