Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ṣíṣe Àtúnṣe Ìwà

    Gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà wí pé wọ́n ní ìwọ̀n-tún-wọ̀n-sí, ó yẹ kí Ìjọ Onírètí Bíbọ̀ Jésù ó wà níwájú.-Gospel Workers, p. 384.IIO 218.4

    Lórí ọ̀rọ̀ ìwọ̀n-tún-wọ̀n-sí, ẹ dúró lórí ipò yín láì ṣiyèméjì. Kí ẹ sì dàbí àpata tí a kò leè ṣí nídìí.-Gospel Workers, p. 394.IIO 219.1

    Yàtọ̀ sí ti sísọ̀rọ̀ ní ìta gbangba, a ní iṣẹ́ láti ṣe lórí ìwọ̀n-tun-wọ̀n-sí. Ẹ jẹ́ kí a kọ àwọn ìpinlẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́ wa sínú ìwé kékeré alaidilù kí a sì lò ó láti ta àwọn ènìyàn wa jí láti darapọ̀ mọ́ àwọn tí kò tíì mọ òtítọ́. Ìwọ̀nba àṣeyọrí tí a ní ninu iṣe iranṣẹ dá lórí ṣiṣé iṣẹ́ takuntakun pẹ̀lú sísé ara ẹni àti láti fi ara ẹni jìn. Olúwa nìkan mọ̀ wí pé a ò bá ti ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ ìbá ṣe wí pé gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́, a rẹ ara wa sílẹ̀ níwájú Rẹ̀ tí a sì polongo òtítọ́ ti ìwọ̀n-tún-wọ́n-sí ní ọ̀nà tààrà.-Gospel Workers, p. 385. IIO 219.2

    Ọ̀rọ̀ ìwọ̀n-tún-wọ̀n-sí yìí ni ó yẹ kí gbogbo wa ó tìlẹ́hìn. Ìwà àìní ìwọ̀n-tún-wọ̀n-sí ń dàgbà, ìwà ìbàjẹ́ náà kò gbẹ́hìn, bẹ́ẹ̀ sì ni a nílò àwọn ìwé tí ó sọ̀rọ̀ nípa ètò ìlera. Ṣíṣe àmúlò àwọn ìwé wa wọ̀nyìí jẹ́ onígbọ̀wọ́ fún iṣẹ́ ìhìnrere èyí tí ó ń tọ́ àwọn ènìyàn láti lèè máa ka Bíbélì láti ní òye òtítọ́ náà. Ó yẹ kí a ṣe ìkìlọ̀ ewu ńlá tí ó wà nínú ìwà àìní ìwọ̀n-tún-wọ̀n-sí, gbogbo àwọn tí ń pa ọjọ́ ìsinmi keje mọ́ ni ó gbọ́dọ̀ kọ́ ẹ̀kọ́ kí wọ́n sì máa fi àwọn ìlànà ètò ìlera tí ó wà nínú àwọn ìwé wa wọ̀nyìí ṣe ìwà hù. Ju eléyìí lọ, ó yẹ kí wọ́n ó pín àwọn ìwé wọ̀nyìí ni gbogbo àdúgbò wọn.-Southern Watchman, Nov. 20, 1902.IIO 219.3

    Ẹ jẹ́ kí wọ́n ó jẹ́jẹ̀ẹ́ láti máa lo àwọn owó tí wọ́n fi ń mutí , mu sìgá, fún ìtura àwọn aláìsàn, àwọn aláìní àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn ọmọdé àti àwọn ọ̀dọ́ kí wọn baà lè wúlò lẹ́hìn wá ọ̀la nínú ayé.-The Ministry of Healing, p. 211.IIO 219.4

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents