Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORI — KẸ́JO KÍKÓ ÀWỌN ỌMỌ OGUN ONÍGBÀGBỌ́ JỌ

    Dandan Ni Ètò Jẹ́

    Àkókò náà kúrú, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ni a sì gbọdọ̀ kójọ láti ṣe iṣẹ́ ń lá.-Testimonies, vol.9, p.27.IIO 72.1

    Dídá sílẹ̀ ẹgbẹ́ ké-kè-ké gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ ìgbìyànjú onígbàgbọ́ ni a fifún mi láti ọwọ́ ẹnìkan tí kò fẹ́ ṣìnà.- Testimonies,vol.7, pp.21,22.IIO 72.2

    Jẹ́ kí ó wà nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan, àwọn ẹgbẹ́ tí a kójọ dáadáa láti ṣiṣẹ́ ní agbègbè ìjọ náà. - Review and Herald, Sept.29, 1891.IIO 72.3

    Ní ìlú ń la kọ̀ọ̀kan ẹgbẹ́ ológun gbọdọ̀ wà tí a kójọ, àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n gbọ́ ìbáwí; kì í ṣe ẹyọ kan ṣáá tàbí méjì, ṣùgbọ́n bí ogún ni a gbọdọ̀ pèsè sílẹ̀ láti ṣiṣẹ́.- General Conference Bulletin, 1893, p.37.IIO 72.4

    Nínú àwọn ìjọ ọ wa jẹ́ kí a dá àwọn ẹgbẹ́ sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn. Kí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn wà ní ìṣọ̀kan nínú sí siṣẹ́ bí apẹja ènìyàn. Jẹ́ kí wọn wá láti kó àwọn ọkàn jọ kúrò nínú ìwà ìbàjẹ́ ti ayé sínú ìfẹ́ ẹ Krístì tó ń gbani tí kò sì lábàwọ́n. - Testimonies, vol.7, p.21.IIO 72.5

    Ìjọ Krístì nínú ayé ni a kójọ fún ìdí iṣẹ́ ìhìnrere, Ọlọ́run sì fẹ́ rí gbogbo ìjọ láti gbèrò ọ̀nà tí ó jẹ́ wípé òkè àti ìsàlẹ̀, olówó àti tálákà, yóò fi gbọ́ iṣẹ́ ìránṣẹ́ ẹ ti òtítọ́.- Testimonies, vol.6, p.29.IIO 72.6

    Tí ọ̀pọ̀ ènìyàn nínú ìjọ bá wà, jẹ́ kí àwọn ọmọ ijọ pín ara wọn sí ẹgbẹ́ ké-kè-ké, láti máa ṣiṣẹ́ fún àwọn ìjọ nìkan ṣùgbọ́n fún àwọn aláìgbàgbọ́. Níbi kan tí ó bá jẹ́ ẹnìkan tàbi ẹni méjì ni ó mọ òtítọ́, jẹ́ kí wọn kó ara wọn jọ bí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ológun.- Testimonies, vol.7, p.22.IIO 72.7

    Tí ìbáwí àti àṣẹ bá ṣe Pàtàkì fún àṣeyọrí iṣẹ́ ní ojú ogun, irú èyí ni áò nílò jú nínú ìjagun nínú èyí tí a jẹ́ akópa bí ohun tí a rí láti jèrè tí ó sì níye lórí tí ó sì gbé sókè jùlọ ní ìwà, ju àwọn ọmọ ogun tí ń jìjàdù lórí i pápá ogun. Nínú u rògbòdìyàn èyí tí a kópa nínú u rẹ̀, ànfààní ayérayé wà nínu ewu. - Testimonies, vol.1, p.649.IIO 72.8

    Ọlọ́run jẹ́ Ọlọ́run ètò, gbogbo ohun tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀run ni ó wà létò létò; Ìtẹríba àti ìkóra-ẹni-níjánu jẹ́ àmì àmúyẹ àwọn ogun ọ̀run.Ibi tí ètò àti ìfọwọ́-so-wọ́-pọ̀ bá wà ni àṣeyọrí lè wà. Ọlọrun ń fẹ́ ètò àti ìmọ̀ nínú iṣẹ́ ẹ Rẹ̀ nísinsiǹyí tí kò kéré sí ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ. Gbogbo àwọn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ fún- Un ní láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọgbọ́n, kì í ṣe nínú àìbìkítà, tàbí yọ́bọ yọ̀bọ. Yóò fẹ́ kí iṣẹ́ ẹ Rẹ̀ jẹ́ ṣíṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìṣe déédé, kí Ó ba à le fi èdìdì àti ìfohùn sì í Rẹ̀ lórí i rẹ̀.- Patriachs and Prophets, p.376. IIO 73.1

    Iṣẹ́ tí a kójọ dáadáa ni a gbọdọ̀ ṣe nínú ìjọ, kí àwọn ọmọ ijọ ba à lè ní ìmọ̀ bí a ṣe le fi ìmọ́lẹ̀ fún ẹlòmíràn, kí ó sì lè fi okun kún ìgbàgbọ́ ọ wọn àti dídàgbà sókè nínú òye e wọn. Bí wọ́n ṣe ń fifún ẹlòmíràn èyí tí wọ́n ti rí gbà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, wọn yóò lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́. Ìjọ tí ó ń ṣiṣẹ́ ni ìjọ tí ó wà láàyè. Òkúta ni ó ní láti tú ìmọ́lẹ̀ jáde. Onígbàgbọ́ kọ̀ọ̀kan ni a fiwé òkúta iyebíye tí ó ń di ògo Ọlọ́run mú tí ó sì ń tàn ìmọ́lẹ̀.- Testimonies, vol.6 p.435.IIO 73.2

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents