Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  Ìwé e Ti Ètò Ìlera

  Àwọn òǹtàwé gbọdọ̀ pe àkíyèsí àwọn tí wọ́n bẹ̀wò sí àwọn ìwé àtẹ̀jáde lórí ètò ìlera, kí wọn sọ fún wọn nípa ẹ̀kọ́ tí ó níye lórí tí ó wà nínú àwọn ìwé àsìkò o wa èyí tí ó kún fún títọ́jú aláìsàn àti ìtọ́jú àwọn àrùn. Sọ fún wọn nípa ìkọ́ni yìí kí wọn sì ṣe ìmúlò o rẹ̀ yóò sì mú ìlera bá ìdílé. Ṣe àlàyé fún wọn bí ó ṣe ṣe pàtàkì tó fún ìdílé kọ̀ọ̀kan láti ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ẹ ti ayé. Darí àwọn ọkàn-an wọn sí Ẹni tí ó dá tí ó sì mú kí ẹ̀rọ ìyanu ti ara a wà ní ipò o rẹ̀. Sọ fún wọn pé ipa a tiwa ni láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, kí a sì ṣe ìtọ́jú pẹ̀lú ògbọ́n fún gbogbo ọpọlọ àti àwọn ẹ̀yà ara a wa.IIO 152.4

  Ìtọ́jú ara a wa dáadáa jẹ́ ojúṣe ń lá, tí ó sì gba ìmọ̀ ti o jinlẹ̀ nípa àwọn ẹ̀yà ara a rẹ. Sọ fún wọn pé a kò bu ọlá fún Ọlọ́run nígbà tí a bá ń ṣògo nípa adùn oúnjẹ àti ìfẹ́kúfẹ̀ ẹ́, nígbà tí ènìyàn bá ṣi ẹ̀rọ ti ara lò, kí ó sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àìlera àti ìṣòro. Sọ fún wọn pé àwọn ìwé tí o ní fún títa fún wọn ní ọ̀pọ̀ ẹ̀kó tí ó níye lórí nípa ìlera, àti nípa ṣíṣe àmúlò ẹ̀kọ́ yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòro àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó pẹ̀lú tí à ń ná nínú u sísan owó fún ìwé oníṣègùn, ni a yóò pamọ́. Sọ fún wọn pé ìmọ̀ràn tí kò ṣe é ṣe fún wọn láti rí gbà lọ́dọ̀ oníṣègùn-un wọn nígbà tí wọ́n bá ṣe àbẹ̀wò kékeré sí ọ̀dọ̀ ọ wọn ni ó wà nínú àwọn ìwé yìí. - Southern Watchman, Nov.20, 1902.IIO 153.1

  Nígbà tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin bá gba iṣẹ́ ìwé títà tí ó kún pẹ̀lú ìfojúsọ́nà kíkankíkan láti gba àwọn arákùnrin-in wọn là, wọn yóò rí àwọn ọkàn tí ó yípadà. Láti ara iṣẹ́ ẹ wọn yóò sa àwọn ìkórè jọ fún Ọlọrun. Lẹ́yìn náà, jẹ́ kí wọn lọ bí ajíhìnrere láti fọ́n káàkiri òtítọ́ ọ ti àsìkò yìí, gbàdúrà léraléra fún ìdàgbàsókè ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ̀, pé kí wọn le è mọ̀ bí wọn yóò ṣe sọ àwọn ọ̀rọ̀ náà ní àsìkò fún àwọn tí ọkàn-an wọn ń ṣàárẹ̀. Wọ́n gbọdọ̀ ṣàtúnṣe àǹfààní kọ̀ọ̀kan fún ṣíṣe iṣẹ́ inú rere, kí wọn rántí pé ní báyìí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún Oluwa….Nínú iṣẹ́ ẹ wọn, wọ́n gbọdọ̀ mú díẹ̀ lára àwọn ìwé ìlera ní gbogbo ìgbà pẹ̀lú u wọn; nítorí pé àtúnṣe ètò ìlera ni ó jẹ́ ọwọ́ ọ̀tún fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ náà. - Southern Watchman, Jan 15, 1903.IIO 153.2

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents