Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ìgbáradì Fún IṢẹ́ Náà

    Àwọn àtẹ̀lé e Krístì kò bá ọkàn àti ìfẹ́ Ọlọ́run pàdé,tí ó bá tẹ́ wọn lọ́rùn láti dúró nínú àìlóye ọ̀rọ̀ ọ RẸ̀. Gbogbo o wa ni a gbọdọ̀ jẹ́ akẹ́kọ̀ ọ́ Bíbélì. Ọlọ́run pa á láṣẹ fún àwọn àtẹ̀lé e RẸ̀, “Ẹ má a wá inú ìwé Mímọ́; nítorí nínú u rẹ́ ni ẹ ró pé ẹ ti le rí ìyè àìnípẹ̀kun: wọ̀nyí ni àwọn tí ń jẹ́rì í mi”. Pétérù gbà wá níyànjú, “Ṣùgbọ́n ẹ sọ Ọlọ́run di mímọ́ nínú ọkàn-an yín; kí ẹ sì múra sílẹ̀ ní ojoojúmọ́ láti fi ìdáhùn fún ènìyàn tí ó ń bèère ìdí ìrètí tí ó wà nínú u yín pẹ̀lú ọkàn tútù àti ìbẹ̀rù”. - Testimonies, vol.2, pp.633, 634.IIO 143.2

    Awọn tí wọ́n bá ní ìyípadà ọkàn ní tòótọ́ gbọdọ̀ ní ìmọ̀ síwájú àti síwájú síi nínú òye e wọn nípa Ìwé Mímọ́, kí wọn ba à le è sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìmọ́lẹ̀ àti ti ìgbàlà fún àwọn tí wọ́n wà nínú òkùnkùn tí wọ́n sì ń ṣègbé sínú ẹ̀ṣẹ̀ ẹ wọn. - Testimonies, vol.9, p.121.IIO 143.3

    A ní láti fi ìkìlọ̀ ìkẹhìn Ọlọrun fún àwọn ènìyàn, kín ni ó gbọdọ̀ jẹ́ ìtara a wa nínú ṣíṣe àṣàrò nínú u Bibeli, àti ìtara a wa nínú u títan ìmọ́lẹ̀! Jẹ́ kí ọkàn kọ̀ọ̀kan tí ó ti gba ìtàṣán ọ̀run wá láti fi kọ́ni. Jẹ́ kí àwọn òṣìṣẹ́ lọ láti ojúlé dé ojúlé, kí wọn sì ṣí Bíbélì fún àwọn ènìyàn, kí wọn pín àwọn ìwé àtẹ̀jáde e wa, kí wọn sọ fún àwọn mìíràn ní ti ìmọ́lẹ̀ tí ó ti bùkún ọkàn-an wọn.- Gospel Worker, p.353.IIO 143.4

    Iṣẹ́ tí a ṣe tí ó sì pé ni a le è gbé lọ sí ilé ìkọ́ni fún àwọn òṣìṣẹ́ ẹ Bíbélì tí ń tẹ̀ síwájú. Nígbà tí à ń ṣe ìwàásù ìta gbangba, tí a so pọ̀ pẹ̀lú ilé-ìwé ìkọ́ni yì í tàbí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ìlú gbọdọ̀ jẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ní ìrírí nínú jínjinlẹ̀ nínú òye ti Ẹ̀mí, tí ó lè fún àwọn òṣìṣẹ́ ẹ Bíbélì ní ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́, tí ó lè ní ìdàpọ̀ tọkàntọkàn nínú ìgbìyànjú ènìyàn gbogbo tí ó jáde lọ.- Testimonies, vol.9, p.111.IIO 143.5

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents