Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Àwọn Aṣojú Ní Ọ̀nà Ìrìn-Àjò

    Gbogbo àwọn tí wọ́n ti gbọ́ ìpè e ti wákàtí náà ti wọ iṣẹ́ ìsìn ti òṣìṣẹ́ Olúwa a wọn, wọ́n le è ṣàṣàrò lórí nípa àwọn ìlànà iṣẹ́ ẹ RẸ̀. Ní àsìkò iṣẹ́ ìránṣẹ́ ẹ RẸ̀ ní ayé, Olùgbàlà lo ànfààní àwọn ààyè tí Ó rí láarin àwọn ọ̀nà ìrìn-àjò. Ní Kápánámù ni Jesu ń jòkó ní ìdákúrekú ní ọ̀nà àjò o RẸ̀ lálọ àti lábọ̀ tí ó sì wá di mímọ̀ bí “ìlú u RẸ̀.” Ìlú yìí ni a ṣe àmúyẹ ẹ rẹ̀ bí àarin gbùngbùn iṣẹ́ Olùgbàlà. Bí ó tilẹ̀ wà ní òpópónà Dámáskúù lọ sí Jérúsálẹ́mù àti Égíbítì, títí lọ dé òkun Mẹditaráníà, ó jẹ́ ọ̀nà ìrìn-àjò tó lágbára láti rìn. Àwọn ènìyàn láti ìlú mìíràn ni wọ́n ń gba ìlú tí ó tóbi yì í kọjá,tàbi tí wọ́n ń sinmi níbẹ̀ lọ́nà ìrìn- àjò o wọn lálọ àti lábọ̀.Jesu le è pàdé àwọn orílẹ̀-èdè àti gbogbo ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ níbẹ̀, ọlọ́rọ̀ àti ènìyàn pàtàkì, àti bí i àwọn aláìní àti onírẹ̀lẹ̀, tí wọn yóò sì gbé àwọn ẹ̀kọ́ yìí lọ sí àwọn ìlú mìíràn àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilé.Wọn yóò sì rú àwọn ìwádìí àsọtẹ́lẹ̀ sókè, wọn yóò sì darí ìfarabalẹ̀ ẹ wọn lọ sí ọ̀dọ̀ Olugbala àti iṣẹ́ ẹ RẸ̀ ni wọn yóò sì gbé lọ sí iwájú aráyé.- Testimonies, vol.9, p. 121.IIO 127.1

    Nínú àwọn àgbáyé tí ó lókìkí nínú ètò ìlera tí wọ́n péjọ àti láarin àwọn oníṣòwò tí wọn ń rin ìrìn- àjò, tí ó há gádígádí pẹ̀lú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn tí wọ́n ń wá ìwòsàn àti ìgbádùn, Òjíṣẹ́ Olọ́run ti o wa lori ijọ àti àwọn òǹtàwé tí ó dángájíá láti mú kí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn wà ní ìfarabalẹ̀. Jẹ́ kí àwọn òṣìṣẹ́ yìí wá ọ̀nà láti fi ìhìnrere lọ̀ ní àsìkò yìí, kí wọn ṣe àwọn ìpàdé tí wọ́n bá ní ànfààní. Jẹ́ kí wọn yára lo àwọn ànfààní yìí láti sọ̀rọ̀ fún àwọn ènìyàn. Jẹ́ kí wọn bá àwọn eniyan pàdé pẹ̀lú u iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti Jòhánù Onítẹ̀bọmi gbé rù pẹ̀lú ìfẹ̀gbẹ́ kẹ̀gbẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́, “Ẹ ronú pìwàdà: nítorí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.” Matt. 3:2. A ní láti sọ̀rọ̀ Ọlọrun láìlábùlà àti agbára, pé àwọn tí wọ́n bá létí láti fi gbọ́ le è gbọ́ òtítọ́. Báyìí ìhìnrere ti òtítọ́ ọ ti àsìkò yìí ni a yóò gbé lọ sí ẹnu ọ̀nà àwọn tí kò tí ì mọ̀ ọ́ rárá, kì í sì í ṣe àwọn díẹ̀ ni yóò gbà á tí wọn yóò sì gbé e lọ sí àwọn ilé e wọn ní káàkiri àgbáyé.-Testimonies, vol.9, p.122IIO 127.2

    “Iṣẹ́ ìránṣẹ́ ẹ ti ìwòsàn” àti “àwọn ìkọ́ni tí Kristi” jẹ́ àwọn ìwé tí ó ṣe é lò lọ́nà àkànṣe níbi ìgbafẹ́ àwọn arìnrìn àjò àti pé ohun tí ó bá ṣe é ṣe ni kí a ṣe láti fi ẹ̀dà awọn iṣẹ́ yì í sí ọwọ́ àwọn tí ọwọ́ ọ wọn dilẹ̀ àti àwọn tí ọkàn-an wọn fà sí ìwé kíkà.- Testimonies, vol.9, p.85.IIO 127.3

    A gbọdọ̀ dá Ilé ìtajà oúnjẹ fún ìlera àti yàrá tí a ti ń tọ́jú aláìsàn sílẹ̀. A gbọdọ̀ fi ibi ìgbafẹ́ létí òkun kún àwọn ìgbìyànjú u wa ní ọ̀nà yìí. Bí a ṣe gbọ́ ohùn Jòánù Onítẹ̀bọmi ní aginjù, “Ẹ tún ọ̀nà Oluwa ṣe”, bákan náà ni a gbọdọ̀ gbọ́ ohùn àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run níbi ìgbafẹ́ fú- àwọ- arì-rì-àjò àti ìpéjọ ní etí òkun.- Testimonies, vol.7, pp.55, 56.IIO 127.4

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents