Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  Ìpè Sí Gbogbo Ìdílé Onígbàgbọ́

  Àwon ìdílé Onígbàgbó ló ye kí won ó lo sí àwon ìlú tàbí agbègbè tí àwon ènìyàn kò kà sí. Ẹ jé kí àwon àgbè, àwon onísòwò, àwon molémolé àti àwon onísé owó míràn gbogbo ó lọ sí àwon agbègbè tí àwon ènìyàn kò kà sí wònyí láti mú orò ayé won dàgbà nípa kíkó àwon ilé isé síbè, kí won ó kó ilé kèkeré síbè àti kí won ó sì máa ran àwon alàdùgbò won lówó.-The Ministry of Healing, p. 194.IIO 182.3

  Olúwa pe àwon ìdílé Onígbàgbó yìí láti lo sí àwon agbègbè tí òkùnkùn àti àsisé wà kí won ó sì fi ogbón se isé won pèlú ìfaradà fún Olúwa. A nílò ìfi-ara-ení-jìn kí a tó lè jé ìpè yìí. Nígbàtí òpòlopò ènìyàn ń retí kí á mú ohun ìdènà gbogbo kúrò ní ònà won béè ní àwọn okàn ń kú láìsí ìrètí àti láìní Olórun láyé. Òpò nítorí ìgbádùn ayé tàbí ìfé láti ní ìmò ìjìnlè ní won yóò gbìdánwò láti lo sí àwon agbègbè tó léwu tí won kò sì ní àǹfaàní sí àwon ohun tí ó dára. Níbo ní àwon tí ó ń fé láti fi ìgbàlà lọ àwon elòmíràn wà? Níbo ni àwon tí yóò lọ sí agbègbè àwon tí ó nílò ìhìnrere wà, kí won kí ó leè tóka Olùgbàlà sí àwon tí ó wà nínú òkùnkùn?.-Testimonies, Vol. 9, p. 33.IIO 183.1

  A ní àwon ìdílé tí ó le se ajíhìnrere sùgbón tí wọ́n ń sisé ara won sùgbón tí wọ́n tun ń sisé bákannáà fún Olùgbàlà pèlú owó tí kò dilè àti opolo pípé tí wón sì ń sisé ní àwon ònà orísirísi fún àseyorí isé Olúwa.-Testimonies, Vol. 9, p.40.IIO 183.2

  Tí àwon ìdílé bá se àwárí àwon ibi tí àwon ènìyàn bá wà nínú òkùnkùn tí èmí, tí wón sì jé ìmólè ó tàn láti ara won sí òdò àwon ènìyàn, dájúdájú àseyorí isé ńlá ni yóò jejo níbè. Jé kí wón fi pèlépèlé sisé won láì ná owó ìjo títí di ìgbà tí ìfé àwon ènìyàn yóò gbòòrò tó béè tí agbára won kò lé kaá mó tí won yóò sì fi nílò àwon àlúfà.-Testimonies, Vol. 6, p. 442.IIO 183.3

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents