Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  Ọwọ́ Ìjà Ipa Ìdílé A Máa Rìn Jìnà

  Ìdílé Onígbàgbọ́ tí ó dúró dáadáa gbọ́dọ̀ jẹ́ alátìlẹ́hìn fún ẹ̀sìn ìgbàgbọ́, irú àtìlẹ́hìn èyí tí àwọn aláìgbàgbọ́ kò gbọdọ̀ rí àléébù rẹ̀. Gbogbo ènìyàn ni ó mọ̀ wí pé ilé máa ń kó ipa lórí ẹbí èyí tí ó máa n mú-lọ́kàn àwọn ọmọ, àti wí pé Ọlọ́run Abráhámù wà pẹ̀lú wọn. Tí ìdílé Onígbàgbọ́ bá kọ ìha tó dára sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sin, wọn yóò lo agbára ipa wọn sí rere. Wọn yóò sì jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ ayé.-” Patriarchs and Prophets, p. 144.IIO 208.1

  Iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti ilé tayọ ti àwọn mọ̀lẹ́bí wọn. Ìdílé Onígbàgbọ́ gbọ́dọ̀ jẹ́ ibi àwòkọ́ṣe rere, níbi tí àti ń kọ́ wa ní àgbékalẹ̀ ìwà rere ti ayé. Ilé ní agbára lórí ọkàn àti ayé ènìyàn ju ìwáàsù tó lágbára èyí tí ẹnikẹ́ni lèè wà lọ. Bí àwọn ọmọ ṣee ń jáde láti irú ilé bẹ́ẹ̀ ni wọn ó máa fi ìwà tí wọ́n ti kọ́ nílé wọn kọ́ àwọn elòmíràn. Àwọn àgbékalẹ̀ ìwà rere, àlááfíà, ìyé, ẹwà àti àṣeyọrí yóò ti ṣàn lọ sí ibi tí aṣálẹ̀ àti iyàn wá.-The Minisstry of Healing, p. 355.IIO 209.1

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents