Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Èròǹgbà

    Kí ni ìdí pàtàkì fún ìpéjọpọ̀? Ṣé ó jẹ́ ọ̀nà láti sọ fún Ọlọ́run ohun gbogbo tí a mọ̀ nípa àdúrà? À ń pé jọpọ̀ láti lè gbé ara wa ró nípa ṣíṣe pàṣípàrọ̀ àwọn èrò ọkàn àti ìmọ̀lára, láti di alágbará, àti ìmọ́lẹ̀, àti ìgboyà nípa mímọ ìrètí àti ìfẹ́ ọkàn, nípasẹ̀ gbígbà àdúrà àtọkànwá, èyí tí ó mú kí á gba òkun àti agbára láti ọ̀dọ̀ Ẹni tí Ó jẹ́ Orísun Agbára wa.- Testimonies, Vol. 2, p. 578.IIO 194.3

    Èrò mìíràn wà fún ìdí tí a fi ń ní ìpàdé ìpàgọ́. Ó jẹ́ ọ̀nà láti gbé ìgbé àyé ìgbàgbọ́ wa sókè. Iṣẹ́ ọlọ́wọ̀ pàtàkì ni Ọlọ́run ti gbé lé wa lọ́wọ́, a sì gbọ́dọ̀ máa pàdé láti gba ìtọ́ni kí a ba lè yẹ láti ṣe iṣẹ́ náà. A gbọ́dọ̀ mọ ipa tí olúkulúkú yóò sà láti ṣe iṣẹ́ tí Olúwa fún wa láyé, láti leè jẹ́ kí wọ́n dá òfin Ọlọ́run láré, kí a sì gbé Olùgbàlà sókè gẹ́gẹ́ bí “Ọ̀dọ́ Àgùtàn Ọlọ́run”, èyí tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ aráyé lọ” (Johanu 1:29). A nílò láti péjọ pọ̀ kí a lè gba ìfọwọ́tọ́ àtòkèwá, kí a baa lè ní òye iṣẹ́ wa nínú ilé.-Testimonies, Vol. 6, pp. 32, 33.IIO 194.4

    Tí a bá ṣe ètò ìpàdé àgọ́ dáadáa, ó jẹ́ ilé-ìwé tí àwọn àlùfáà, àwọn alàgbà, àwọn díákónì leè kọ́ bí a ti ṣe lè ṣe iṣẹ́ tí ó dára jùlọ fún Olúwa. Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ilé-ìwé àti fún gbogbo ọmọ ìjọ ni àǹfààní láti kọ́ ọ̀nà Olúwa lọ́nà tí ó dára jùlọ, tí àwọn Onígbàgbọ́ ti lè kọ́ ẹ̀kọ́ tí yóò lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ran àwon mìíràn lọ́wọ́.-Testimonies, Vol. 6, p. 49.IIO 195.1

    Nínú àwọn ìpàdé ìpàgọ́ wa ti ó ti kọjá, níbẹ̀ ni àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti tún àwọn àǹfààní iyebíye ṣe èyí tí wọ́n lè ti kó àwọn ènìyàn ní àwọn ọ̀nà tó ṣeé fojúrí nínú bí a ṣe lè gbé òtítọ́ tí ń gbanilà tí iṣẹ́ ìránṣẹ́ áńgẹ́lì kẹta lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ wọn gbogbo. Ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ wọn ni a ti kọ́ ní àwọn ọ̀nà láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere tí kò gbowó oṣù lọ́wọ́ ẹnìkankan láti ilé wọn. Ọ̀pọ̀ sì ti darí padà sílé láti àwọn ìpàgọ́ wọn láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lu ìtára ńlá àti ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ ju bí wọ́n ṣe wà tẹ́lẹ̀ rí. Yóò ti dùn mọ́ Ọlọ́run tó tí a bá túbọ̀ ń fún àwọn ọmọ ìjọ tí ó ń lọ sí ìpàgọ́ ní àwọn ìlànà yìí ju bí a ti ṣe ń fún wọn tẹ́lẹ̀ rí. Gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ wa àti àwọn arákùnrin àti arábìnrin ni àwọn ilé iṣẹ́ wa gbogbo gbọ́dọ̀ rántí wí pé nǹkan gbòógì nínú àwọn ìdí tí a fi ń péjọ pọ̀ lọ́dọọdún ni kí gbogbo wa léè ní ọgbọ́n èyí tí a fi ṣe iṣẹ́ ìjèrè ọkàn lẹ́nìkọ̀ọ̀kan.-Testimonies, Vol. 9, p. 81.IIO 195.2

    Ní àwọn ilé-iṣẹ́ wa kọ̀ọ̀kan, àwọn olórí máa ń lọ́ra láti fi àwọn ọ̀nà ìlànà yìí hàn. Ìwáásù ni àwọn elòmíràn máa ń ṣe kàkà kí wọ́n dánilẹ́kọ̀ọ́. Ṣùgbọ́n ní ibi iru ìpàgọ́ ọlọ́dọọ́dún yìí, a kò gbọdọ̀ dẹ́kun láti lo àǹfààní tí a ní yìí láti kọ́ àwọn Onígbàgbọ́ ní ọ̀nà tí wọ́n lè gbà ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere ní ibi tí wọ́n ń gbé.-Testimonies, Vol. 9, p. 82.IIO 195.3

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents