Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ìlànà Tí ó Yege

    Ònà tuntun kàn tí a le fi dé òdò àwon kèfèrí ní ìpolongo ìkóre. Ìlànà yí ti mú àseyorí wá ní òpòlopò àgbègbè nípa mímú ìbùkún wá pèlú ìkówójọ sínú àpò ìjo, èyí tí ó sì ti mú kí àwon tí kìí sẹ omo ìjo beèrè sí ní ní òye isé ìránse angeli kèta ní pàtàkì jùlo ní ilé àwon kèfèrí. Àwọn ènìyàn ti fi ìfé hàn láti mò síi nípa irú agbára yìí, èyí tí ó ń so ìgbé ayé àti okàn ènìyàn dì ọ̀tun. Òpòlopó àwon ènìyàn nì ó ti gbó nípa òrò Olórun tí orúko Olórun si ti di ìyìn logo.-MS, “Consecrated Efforts to Reach Unbelievers”, June 5, 1914.IIO 167.2

    Àwon kàn sọ wípé kò tọ̀nà láti gba ẹ̀bun lówó àwon aláìgbàgbọ́. Ẹ jẹ́ kí irú ení bẹ́ẹ̀ ó béère wípé: “Taló ní ayé àti èkun rẹ̀ àti ohun gbogbo tó wà níbè, taló ní àwon ohun ìsura bíi wúrà àti fàdákà?” Òpòlopò ìsura ní Olórun ní ní gbogbo ayé. Ó sì ti fi sí ìkáwó gbogbo ènìyàn àti àwon tó gbóràn àti àwon aláìgboràn. Ó sì setán láti fọwọ́ tọ́ okàn ènìyàn gbogbo àti àwon kèfèrí pàápàá láti fi owó sílè láti ran isé Rè lówó, yó Ò si se èyí nígbàtí àwon ènìyàn Rè bá fí ogbón tò wọ́n lọ tí wọ́n sì pe àkíyèsí wọ́n sí àǹfaàní èyí tí wọ́n ní. Tí a bá fí pélèpélè se àgbékalè àwọn ohun tí a nílò fún isé olórun níwájú àwon wònyí, wọn óọ̀ fí sílè tokàntokàn láti mú kí òtító àkokò yìí tèsíwájú. Òpòlopò àǹfaàní ní àwon ènìyàn Olórun tí pàdánù lódò àwon wònyí nítorí wón yàn láti ta kété sí ayé.-Southern Watchman, Mar. 15, 1904.IIO 167.3

    Olórun sí ń fowó tó okàn àwon oba àti olórí nítorí àwon ènìyàn Rè. Ó ye kí àwon òsìsé Olórun ó lo àǹfaàní yìí tí Ó tí fí sí okàn àwon ènìyàn láti mú isé Rè tèsíwájú. Àwon tí èbun yìí tí owó rè wá lè jé ohun èlọ̀ láti tàn ìmólè sí àwon orílè-èdè tí òkùnkùn bò mọ́lọ̀. Bí ó tilè jé wípé àwon ènìyàn kò mo Olórun tàbí òrò Rè ní ònàkọnà, síbè a kò gbódò kọ èbun wọn sílè.-Southern Watchman, Mar. 15, 1904.IIO 168.1

    Ńi owó ènìyàn gbogbo ní Olórun tí fi isé Rè sí kí olúkúlùkù baà lè mú wá sí òdò Rè ohun tí ó tó láti mú kí isé Rè tèsíwájú. Ní ìwòn ìgbàtí a sì wà láyé tí Èmí Olórun sìí ń rọ àwon ènìyàn béèni ó ye kí á má gba àánú kí á sì má se àánú fún elòmíràn. Ó yẹ kí á fún ayé ní ìmólè òtító gégébí a se gbàá láti inú Bíbélì, béèná ní ó sì ye kí á gbà lówó aráyé oun tí Olórun fi sí won lókàn láti fi sílè fún isé Rè.-Souther Watchman, Mar. 15, 1904.IIO 168.2

    Nísisìnyí, òpòlopò orò àgbáyé wà lówó àwon kèfèrí súgbón ti Olúwa ní ilè àti èkun rẹ̀ “Tèmi ní Wúrà àti Fàdákà ni Olúwa wí”. Gbogbo eranko ìgbé ní Tèmi, Mo mọ gbogb eye tó wà lóke, àti àwọn eranko búburú sì jẹ́ tèmi pèlú. Tí ebi bá ń pa Mí, Èmi kò ní so fún yín nítorípé tèmi ni gbogbo àgbáyé àti èkun rè”. Ó ye kí àwon Onígbagbó ó ní lópòlopò kí wón sì mò wípé ẹ̀tó àti isé won ni, bí wọ́n se ń mọ rírì àgbékalè tòótó láti lo gbogbo ohun tí ó tí òkè wá fún ìtèsíwájú ìjoba Olórun ní ayé.-Southern Watchman, Mar. 15, 1904.IIO 168.3

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents