Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  Ṣíṣe Àfihàn Àwọn Ìlànà Iṣẹ́ Ìhìnrere.

  Ní kíkópa nínú iṣẹ́ ìpàgọ́, gbogbo wa ni ó yẹ kí a kọ́ bí a ti ṣe lè ṣe àṣèyọrí nínú ilé ìjọsìn wa nílé.-Testimonies, Vol. 6, p.49.IIO 195.4

  Díẹ̀ nínú àwọn ìpàgọ́ wa, àwọn ẹgbẹẹgbẹ́ tó lágbára ni a ti ṣe àgbékalẹ̀ láti lọ sí àwọn ìlú-ńlá àti ìgbèríko láti pín àwọn ìwé ìléwọ́ fún àwọn ènìyàn nígbà tí wọ́n á sì tún pè wọn wá síbi ìp àgọ́ náà. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ àwọn ọgọọgọ̀rún ènìyàn ni a ti ri tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ní wá síbi ìpàdé náà déédé.-Testimonies, Vol 6, p.36.IIO 195.5

  A le è lọ síbi ìpàgọ́, kìí ṣe láti gbàá nìkan bíkòṣe láti sa ipá tiwa. Gbogbo ènìyàn ni ó jẹ́ akópa nínú ìfẹ́ Kírísítì tí ń dáríjì ni, gbogbo awọn tí Ẹ̀mí Ọlọ́run ti ṣí lójú tí wọ́n sì ti ní ìyípadà ọkàn sí òtítọ́ náà, ni yóò mọ̀ wí pé pẹ̀lú ìbùkún iyebíye tí òun ti rí gbà yìí ni òun náà ti gba iṣẹ́ láti fi òtítọ́ náà kọ́ gbogbo ẹni tí òun bá ti ṣe alábàpádé rẹ̀. Gbogbo àwọn tí ó bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ni Olúwa yóò lò láti dé ọ̀dọ̀ àwọn tí àlùfáà kò lè dé ọ̀dọ̀ wọn. Ẹ̀mí Ọlọ́run yóò lò wọ́n láti sọ ọ̀rọ̀ èyí tí ó fi ore-ọ̀fẹ́ Kírísítì tí ń gba ni là hàn.-Testimonies, Vol. 6, p. 43.IIO 196.1

  Nígbà tí a bá tẹ̀lé àgbékalẹ̀ ọ̀nà Ọlọ́run “a jẹ́ alábàṣiṣé paapọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run”. Irúfẹ́ ipò yòówù tí a lè wà, ìbáà jẹ́ ààrẹ kọ́ńfúrẹ́ẹ́sì, àwọn àlùfáà ni, àwọn olùkọ̀ní, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ni tàbí àwọn ọmọ ìjọ ni — gbogbo wa ni a ó jíhìn lọ́dọ̀ Olúwa bí a ti ṣe lo àwọn àǹfààní wa láti tan ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ ìsìsìnyí fún àwọn tí wọn kò ní òtítọ́ náà. Ọ̀nà kan gbòógì tí Ọlọ́run sì fẹ́ lò ni àwọn ìwèé wa. Ní àwọn ilé-ìwé wa àti ilé-ìwòsàn wa, ní àwọn ìjọ tí a tí ń jọ́sìn pàápàá jùlọ ní àwọn ìpàgọ́ ọlọ́dọọ́dún wa, a gbọ́dọ̀ ṣe àmúlò ọ̀nà pàtàkì yìí. Pẹ̀lú sùúrù, àwọn òṣìṣé tó fara jìn tí a ti yàn wọ̀nyìí gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn ènìyàn wa bí a ṣe lè bá àwọn aláìgbàgbọ̀ sọ̀rọ̀ ní ọ̀nà tí ó dára tí a lè fi jèrè ọkàn wọn àti bí a ṣe lè fi ọgbọ́n fún wọn ni àwọn ìwé wa, èyí tí ó kún fún òtítọ́ ti ìsìsìnyí.- Testimonies, Vol. 9, pp. 86, 87.IIO 196.2

  Iṣẹ́ ṣíṣe nínú àwọn ìpàgọ́ wa gbọ́dọ̀ wà létòletò, kìí ṣe gẹ́gẹ́ bí i ìmọ̀ ìṣe ènìyàn, bíkòṣe ní ìlànà iṣẹ́ kírísítì. A gbọ́dọ̀ fa àwọn ọmọ ìjọ láti ṣiṣẹ́.-Testimonies, Vol. 9, p. 120.IIO 197.1

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents