Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Kò Sí Ààyè Fún Ìjáfara

    “Ọjọ́ ń lá Olúwa súnmọ́ tòsí, ó súnmọ́ tòsí, ó sì ń bọ̀ kánkán.” Zeph.1:14. Ẹ jẹ́ kí a bọ bàtà ìhìnrere,pẹ̀lú ìgbáradì láti tẹ̀síwájú ní kété tí a bá gba àṣẹ .- Testimonies, vol.9, p.48.IIO 78.1

    Àwọn ọmọ ìjọ... gbọdọ̀ múra sílẹ̀ nígbà gbogbo láti hù jáde sínú iṣẹ́ ní ìgbọràn sí àṣẹ Olúwa a wọn. Níbikíbi tí a bá rí iṣẹ́ tí ó ń dúro dè wá láti ṣe, a níláti ṣe é, kí a wo Jésù ní gbogbo ìgbà.... Tí ọ̀kọ̀ọ̀kan ọmọ ìjọ bá jẹ́ ajíhìnrere alaàyè, iṣẹ́ ìránṣẹ́ yóò tètè tàn ká ní gbogbo ìlú, sí gbogbo ènìyàn, orílẹ̀-èdè, àti gbogbo èdè.- Testimonies, vol.9, p.32.IIO 78.2

    À ń súnmọ́ òpin ìtàn ilé ayé. A ní iṣẹ́ ń lá níwájú u wa, - Iṣẹ́ ìparí tí ń fi ìkìlọ̀ ìkẹhìn fún ayé tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀. Àwọn ènìyàn wà tí aó mú kúrò níbi ìtulẹ̀ ẹ wọn, láti inú ọgbà àjàrà, láti onírúurú ẹ̀ka iṣẹ́, tí Ọlọ́run yóò rán jáde láti fi iṣẹ́ ìhìnrere fún aráyé. - Testimonies, vol.7, p.270.IIO 78.3

    Kéde rẹ̀ jákèjádo ìbú àti òòró ti ayé. Sọ fún àwọn ènìyàn pé ọjọ́ Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀, ó sì ń bọ̀ kánkán. Máṣe yọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀ láì gba ìkìlọ̀. A le è wà níbi àwọn ọkàn tí wọ́n ṣe àìní tí wọ́n wà nínú ìṣìnà, a ti lè kà wá mọ́ àwọn aláìmọ̀kan. Gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ tí a ti gbà ju àwọn tó kù, a jẹ́ ajigbèsè láti fi irúfẹ́ èyí kọ́ wọn. - Testimonies, vol.6, p.22.IIO 78.4

    Ẹ̀yin ará l'ọ́kùnrin àti l'óbìnrin, ó ti pẹ́ jù láti ya àkókò àti ara wa sọ́tọ̀ fún ìfira ẹni jì. Máṣe jẹ́ kí ìgbà ìkẹhìn bá ọ láìní ìṣúra ti ọ̀run. Wọ́nà láti mú ìtẹ̀síwájú bá ìṣẹ́gun ti àgbélèbù ú, wá láti la ọkàn lóye, ṣiṣẹ́ fún ìgbàlà àwọn ẹnìkejì ì rẹ, iṣẹ́ ẹ̀ rẹ yóò sì wà lábẹ́ ìdánwò ti iná.-Testimonies, vol.9, p.56. IIO 78.5

    A níláti sọ iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí ní kánkán, ìlà sí ìlà, àṣẹ lé àṣẹ. Láìpẹ́ àwọn ènìyàn ni wọ́n yóò fagbára mú láti ṣe ìpinnu ń lá, iṣẹ́ ẹ wa sì ni láti rí i pé a fún wọn ni ààyè láti ní òye ti òtítọ́, kí wọn ba à le dúró pẹ̀lú ìmọ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún. Olúwa ń pe àwọn ènìyàn an RẸ̀ láti ṣiṣẹ́-ṣiṣẹ́ tìtara tìtara àti pẹ̀lú ọgbọ́n nígbà tí ilẹ̀kùn àánú kò tí ì di títì. - Testimonies, vol.9, pp.126, 127.IIO 79.1

    Ákókò kò sí láti fi ṣòfò, òpin ti súnmọ́ tòsí. Ọna anfaani lati waasu otitọ naa lati ibi kan de ibi keji yoo kun fun ewu laipẹ. Gbogbo ohun ìdíwọ́ ni yoo jẹ lilò láti dènà àwọn ìránṣẹ́ Olúwa, kí wọn má ba à le ṣe èyí tí wọn le ṣe báyìí nígbà náà. A gbọ́dọ̀ kọju mọ wo iṣẹ́ ẹ wa kí a sì tẹ̀síwájú kíákíá nínú ogun jíjà tọkàn tọkàn. Nínú ìmọ́lẹ̀ tí a fihàn mí níti Ọlọ́run, mo mọ̀ pé agbára òkùnkùn ń ṣiṣẹ́ rẹ̀ kíkankíkan lábẹ́nú, àti pẹ̀lú rínrìn ní ìwà olè Sátánì ń gbilẹ̀ sìi láti mú àwọn tí ó ń sùn báyìí, gẹ́gẹ́ bí ìkookò ṣe ń mú ìparun rẹ̀ wá. A ní àwọn ìkìlọ̀ nísinsinyí tí a lè fún ni, a ní iṣẹ́ láti ṣe nísinsinyí; ṣùgbọ́n láìpẹ́, ó má a le ju bí a ti lérò lọ. Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ láti pa ọ̀nà ti ìmọ́lẹ̀ mọ́, láti ṣiṣẹ́ ní títẹjú mọ́ Jésù adarí i wa,àti sùúrù, ìfaradà tẹ̀síwájú láti ṣégun.- Testimonies, vol.6. p.22.IIO 79.2

    Ìjáfara léwu, pé ọ̀kan tí ó le rí, pé ọkàn tí ó yẹ kí o ṣí ìwé mímọ́ fún, kọjá ibi tí o le è dé, Sátánì ti pèsè àwọn àwọ̀n fún ẹsẹ̀ ẹ rẹ̀, àti pé lọ́la o lè ṣiṣẹ́ fún un pẹ̀lú ètò láti jẹ́ olórí ọ̀tá ti Ọlọ́run. Kín ló dé tó ń jáfara ọjọ́ kan? Kín ló dé tí o kò lọ síbi iṣẹ́ náà lẹ́ẹ̀kan?- Testimonies, vol.6, p.443.IIO 79.3

    Ìṣọ́ra àti òótọ́ ni Ọlọ́run ń bèrè lọ́wọ́ àwọn àtẹ̀lé e RẸ̀ ní ìran yìí; ṣùgbọ́n nísinsinyí à ń dúró létí i bèbè ti ilé ayérayé,dídi òtítọ́ mú, pẹ̀lú u níní ìmọ́lẹ̀ ń lá,iṣẹ́ tí ó ṣe pàtàkì, àìṣèmẹ́lẹ́ ẹ wa gbodọ̀ jẹ́ ìlọ́po. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ni ó níláti ṣe àṣeparí agbára a rẹ̀, Arákunrin mi, ò ń fi ìgbàlà rẹ wéwu tí o bá fà sẹ́hìn báyìí. Ọlọ́run yóò pè ọ́ láti jíhìn tí o bá bàkù nínú iṣẹ́ tí Ó yàn ọ́ láti ṣe.- Testimonies,vol.5,pp.460,461.IIO 79.4

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents