Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Tí ó Bọ́ Sí Àsìkò

    N kò le è fi tagbára tagbára rọ gbogbo àwọn ọmọ ìjọ, gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ òjíṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́, gbogbo àwọn tí wọ́n gba iṣẹ́ ìránṣẹ́ ẹ ti ańgẹ́li kẹta gbọ́, gbogbo àwọn tí wọ́n yí ẹsẹ̀ ẹ wọn kúrò ní ọjọ́ ọ Sátidé, láti ṣe àṣàrò lórí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ẹ ti ìwé ìsáyà orí kejìdínlọ́gọ́ta.IIO 140.1

    Iṣẹ́ ìwà ọrẹ tí a ṣe ìkìlọ̀ ọ rẹ̀ nínú orí ìwé yìí ni iṣẹ́ tí Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn ènìyàn-an RẸ̀ ṣe ní àsìkò yìí. Ó jẹ́ iṣẹ́ tí ó yàn fúnra a RẸ̀. A kò fi wá sínú iyèméjì bí i níbo ni iṣẹ́ ìránṣẹ́ náà ti bá wa, àti, àsìkò ìmúṣẹ tí a sàmì sí, nítorí a kà á “Àwọn tí wọn yóò jẹ́ tirẹ̀ yóò tún ibi àtijọ́ kọ́, wọn yóò gbé àwọn ìpìlẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ sókè; wọn yóò sì má a pè wọ́n ní alátúnṣe ibi ahoro, olùmúbọ́sípò àwọn ọ̀nà tí a lè gbé.”. Ìsinmi ọjọ́ kèje jẹ́ ohun ìrántí fún Ọlọ́run, àmì iṣẹ́ ẹ RẸ̀ nínú dídá ayé, ni a ti yí ní ipò padà nípa ọkùnrin ẹ̀ṣẹ̀. Àwọn ènìyàn Ọlọrun ní iṣẹ́ pàtàkì láti ṣe nínú títún ihò tí a dálu sí òfin —in RẸ̀ ṣe; bí a ṣe ń súnmọ́ òpin, bẹ́ẹ̀ náà ni iṣẹ́ yìí gba ìkánjú. Gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ Ọlọrun yóò fihàn pé awọn gba àmì i RẸ̀ nípa pípa àwọn òfin-in RẸ̀ mọ́. Wọ́n jẹ́ àwọn alátúnṣe àwọn ọ̀nà tí a le è gbé….Iṣẹ́ oníṣègùn ajíhìnrere tòótọ́ ni a so pọ̀ tí a kò sì le è yà wọ́n pẹ̀lú u pípa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ nínú èyí tí a dárúkọ ọjọ́ ìsinmi ní pàtàkì, níwọ̀n ìgbà tí ó sì ti jẹ́ ọjọ́ ìrántí Oluwa nínú isẹ́ ìṣẹ̀dá. Awọn tí ó ń pa á mọ́ ni a so pọ̀ mọ́ iṣẹ́ olùmúbọ́sípò tí àwòrán ìwà a ti Ọlọrun nínú ènìyàn. Èyí ni iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí àwọn ènìyàn Ọlọrun ní láti mú tẹ̀síwájú ní àsìkò yìí. Iṣẹ iranṣẹ yìí, tí a bá ṣe é bí ó ti tọ́, yóò mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbùkún tó pọ̀ bá ìjọ. Testimonies, vol.6, pp.265, 266.IIO 140.2

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents