Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ìtẹ́wọ́gbà Náà.

    Àwọn ọmolẹ́yìn Kírísítì gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́, gẹ́gẹ́ bí Òun náà ti ṣe é. A gbọ́dọ̀ fún àwọn tí ebi ń pa lóúnjẹ, daṣọ bo àwọn tí wọ́n wà níhòhò, kí a sì tu àwọn tí ń ṣíṣẹ̀ẹ́ tí a sì ń pọ́n lójú nínú. Ó yẹ kí á wàásù fún àwọn tí wọ́n ti sọ ìrètí nù kí á sì fi dá wọn lójú wípé wọ́n ṣì ní ìrètí, àti wí pé a o mú ìlerí tí Ọlọ́run ti ṣe fún wa ṣe, “Òdodo rẹ̀ yóò máa wà níwájú wa àti ògo Ọlọ́run yóò sì máa tọ̀ wá lẹ́hìn.-The Desire of Ages, p. 350.IIO 186.2

    Àwọn tí wọ́n ti ń ṣe ìrànlọ́wọ́ nínú iṣẹ́ Onígbàgbọ́ yìí ti ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ láti ṣe, Ó sì ti tẹ́wọ́gba iṣẹ́ wọn. Èyí tí wọ́n ti ṣe ní ìlànà yìí ni iṣẹ́ tí gbogbo ọmọ Ìjọ Onírètí gbọ́dọ̀ fi tọkàn-tọkàn tẹ́wọ́gbà kí wọ́n sì dìímú ṣinṣin. Ní kíkọ ojúṣe wa, èyí tí ó wà ní ìkáwọ́ wa yìí, ní kíkọ̀ láti ní àjàgà yìí, ń ṣe ni ìjọ ń pàdánù lọ́pọ̀lọpọ̀. Ìbá ṣe pé ìjọ mu iṣẹ́ yìí lọ́kùn-ún-kún-dùn ni, wọn ì bá jẹ́ ọ̀nà láti gba ọ̀pọ̀ ẹ̀mí là.-Testimonies, Vol. 6, p. 295.IIO 187.1

    Gbogbo ẹ̀bùn Ọlọ́run ni a gbọ́dọ̀ lò láti fi bùkún àwọn ìran ènìyàn gbogbo láti mú ìtura bá àwọn tí ó ṣe aláìní. A gbọ́dọ̀ bọ́ àwọn tí ebi ń pa, da aṣọ bo àwọn tí ó wà níhòòhò, tọ́jú àwọn opó àti àwon ọmọ òrukàn, láti wàásù fún àwọn oníròbínújẹ́ àti àwọn tí a pọ́n lójú. Ọlọ́run kò fẹ́ kí òṣì kí ó gbinlẹ̀ nínú ayé. Ọlọ́run kò fẹ́ ìwà bámúbámú ni mo yó èmi ò mọ̀ bóyá ebí ń pa ẹnìkankan. Nígbà ti awon elòmíran kò sì rí nǹkan jẹ. Àwọn ohun amáyé gbádùn ni Ó ti fi sí ìkáwọ́ àwọn ènìyàn gbogbo láti lè máa ṣe rere nípa bíbùkún ọmọ ènìyàn. Olúwa sọ wí pé, “Ta ohun ìní rẹ kí o sì fi ṣe ìtọrẹ fún àwọn ẹlòmíràn”. Ẹ ṣetán láti ṣe alábàápín kí ẹ sì nífẹ̀ẹ́ láti polongo ìhìnrere. “Nígbà tí ẹ bá pe àsè, ẹ pe àwọn aláiìní, àwọn arọ, àwọn afọ́jú”. “Ẹ tú àwọn ẹni ibi ká”, “Ẹ gbé àjàgà kúrò lọ́rùn àwọ́n ènìyàn”, “Ẹ tú àwọn oǹdè sílẹ̀”, “Ẹ já gbogbo àwọn àjàgà”, Ẹ fi oúnjẹ yín fún àwọn tí ebi ń pa”, “Ẹ mú àwọn ọkàn tí a tanù wá sílé yín”, “Nígbà tí ẹ bá rí àwọn tí ó wà níhòòhò, ẹ daṣo bò wọ́n”, “Ẹ tu àwọn tí a ń pọn lójú nínú”, “Ẹ lọ sí gbogbo ayé, kí ẹ sì wàásù ìhìnrere fún gbogbo ẹ̀dá”. Àwọn wọ̀nyìí ni àṣẹ Olúwa. Ǹ jẹ́ àwọn tí a ń pè ní Onígbàgbọ́ ń ṣe àwọn iṣẹ́ wọ̀nyìí bí?.-Christ Object Lessons, pp. 370, 371.IIO 187.2

    Iṣé rere ni èso tí Kírísítì ń fẹ́ kí á so, ọ̀rọ̀ rere, iṣẹ́ àánú, ṣiṣẹ́ àwọn aláìní, àwọn ọtọ̀ṣì, àti àwọn tí à ń pọ́n lójú jẹ̀jẹ́. Nígbà tí a bá káànú àwọn ọkàn tí ó wúwo tàbi ṣòfò, nígbà tí a bá ń fi fún àwọn aláìní, tí a fi aṣọ bo àwọn tí ó wà níhòòhò, tí a ń ṣe ìtọ́jú àwọn àlejò nígbà náà ni àwọn ańgẹ́lì yóò súnmọ́ ọ̀dọ̀ wa tí Olúwa yóò sì mú ìrora wa kúrò. Gbogbo àwọn ìwà rere tí à ń hù ni ó ń mú kí ayọ̀ ó wà lọ́rùn- un. Láti ọ̀run wá ni Ọlọ́run ti bojúwò àwọn tí ń ṣe iṣẹ́ àánú wọ̀nyìí tí Ó sì kà wọ́n mọ́ ìṣura iyebíye Rẹ̀, “Wọ́n ó sì jẹ́ t’Emi ní ọjọ́ tí Mo bá ka àwọn ìṣura Mi”. Gbogbo iṣẹ àánú sí àwọn aláìní àti àwọn tí ìyà ń je ni ó dàbí ẹni wí pé Jésù ni à ń ṣee fún. Nígbà tí a bá ran àwọn tálákà lọ́wọ́, tí a bá àwọn tí à ń pọ́n lójú kẹ́dùn, tí a sì bá àwọn ọmọ òrukàn ṣeré nígbà náà ni à ń ní ìbáṣepọ̀ tímọ́tímọ pẹ̀lú Jésù.-Tesimonies, Vol. 2, p, 25.IIO 187.3

    Ṣíṣe àkójọ àwọn aláìní, àwọn tí a pọ́n lójú, àwọn ti ń jẹ̀yà, àwọn ni iṣẹ́ tí gbogbo ìjọ tí ó bá gba òtítọ́ ti àkókò yìí gbọ́ yẹ kí ó ti máa ṣe. Ó yẹ kí á fi àáánú hàn bí i ti ará Samáríà ni nípa pípèsè àwọn ohun èlò ti ara, bíbọ́ àwọn tí ebi ń pa, mímú àwọn òtòṣì tí ebi ń pa wá sínú ilé wá nípa gbígbà ore-ọ̀fẹ́ àti okun lójoójúmọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí inú wọn kò dùn. Kí a sì ran àwọn tí kò lè ran ara wọn lọ́wọ́. Nípa ṣíṣe iṣẹ́ yìí, a ní aǹfààní tí ó dára láti fi Kírísítì tí a kàn mọ́ àgbélèbú hàn.-Testimonies, Vol. 6, p. 276.IIO 188.1

    Ọ̀pọ̀ ni ó ń yà lẹ́nu ìdí tí àdúrà wọn kò fi ní ìtumọ̀, tí ìgbàgbọ́ wọn fúyẹ́ tí kò lẹ́sẹ̀ ń lẹ̀, ìrìnàjò ìgbàgbọ́ wọn ṣ’ókùnkùn kò sì ṣe ń gbẹ́kẹ̀lé. Wọn a wí pé àwọn ṣáà ti gba àwẹ̀, “tí a sì ti rìn pẹ̀lú ìbànújẹ́ ọkàn níwájú Olúwa àwọn ọmọ ogun?” Nínú Isaiah orí kejìdínlọ́gọ́ta Jésù fihàn wá níbẹ̀ bí ìṣípòpadà yóò ṣe bá àwọn ìwà wọ̀nyìí. . . .ẹsẹ̀ kẹfà àti ìkeje. Èyí ní ọ̀nà tí Kírísítì ti là sílẹ̀ fún àwọn tí ọkàn wọn ń ṣàárẹ̀, àwọn oníyèméjì ọkàn, àwọn ti ọkan wọn n pòrùúru. Ẹ jẹ́ kí eni tí ó ti fi ìgbà kan rìn níwájú Olúwa pẹ̀lú ìbánújẹ́ ọkàn, dìde kí ó sì ran ẹni tí ó nílò ìrànlọ́wọ́ lọ́wọ́.-Testimonies, Vol. 6, p. 266.IIO 188.2

    Ògo Olúwa máa ń wà nínú gbígbé ẹni tó ti ṣubú dúró, títu oníròbínújẹ́ nínú. Nígbà tí kírísìtí bá ti ń jọba nínú ọkàn ènìyàn, Yóò ṣàfihàn rẹ̀ lọ́nà kan. Ibikíbi tí ó bá ti ṣe iṣẹ́, ìsìn Rẹ̀ yóò máa bùkún àwọn ènìyàn, níbikíbi tí ó bá ti ṣiṣẹ́, ìmọ́lẹ̀ a máa wà.-Christ’s Object Lessons, p. 386.IIO 188.3

    Opó Sáréfátì fi oúnjẹ rẹ̀ ṣe ìtọ̀rẹ àánú fún Èlíjàh, lẹ́hìn-ò-rẹhìn, a dá ẹ̀mí rẹ̀ àti ti ọmọ rẹ̀ sí. Bẹ́ẹ̀ náà ni yóò sì rí fún gbogbo ẹni tí ó bá ṣàánú àwọn aláìní. Ọlọ́run ti ṣèlérí ìbúkún ńlá. Bẹ́ẹ̀ni kò tíì yípadà. Agbára Rẹ̀ sì wà síbẹ̀ àní bí ó ti rí ní ìgbà Èlíjàh.-Prophets and Kings, pp. 131, 132.IIO 188.4

    Ìfẹ́ Kírísítì tí ó bá fi ara hàn nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí kò mọ tìwọ̀n ara rẹ̀ nìkan máa ń yí ọkàn àwọn ènìyàn búburú padà ju ìdájọ́ ti inú ilé ìdájọ́ lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ilé ìdájọ́ máa ń fi ìyà jẹ àwọn arúfin, ṣùgbọ́n ìfẹ́ ọkàn àwọn ajíhìnrere léè ṣe jù báyìí lọ. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn ọkàn tó yigbi lábẹ́ òfin máa ń yòrò lábẹ́ ìfẹ́ Kírísítì.-The Ministry of Healing, p. 106.IIO 189.1

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents