Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Àǹfààní Àtọ̀run Wá

    Ẹ̀gbẹ̀lẹ́gbẹ̀ ni àwọn ènìyàn, ẹ̀yà àti orílẹ̀ èdè ni ó wà ní orílẹ̀ èdè wa tí wọ́n jẹ aláìmọ̀kan àti a gba ohun asán gbọ́, tí wọn kò ní ìmọ̀ Bíbélì àti ìkọ́ni rẹ̀. Ọwọ́ Ọlọ́run ni ó mú wọn wá sí ìlú Amẹ́ríkà kí wọ́n baa lè ní ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ èyí ti a fi hàn láti inú ọ̀rọ̀ Rẹ̀ àti kí wọn lè jẹ́ ajogún ìgbàgbọ́ tí ń gba ni làà.-Review and Herald, Mar. 1, 1887.IIO 200.1

    Ọlọ́run nínú àánú Rẹ̀ tí mú wọn wá sí ẹnu ọ̀nà wa, ó sì ti fi wọ́n lé wa lọ́wọ́, kí wọn baà lè kọ́ òtítọ́ kí wọn sì yẹ láti ṣe iṣẹ́ èyí tí a kò lè ṣe nípa mímú ìmọ́lẹ̀ náà tàn sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ní gbogbo èdè.-Review and Herald, Oct. 29, 1914.IIO 200.2

    Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àlejò wọ̀nyìí ni wọ́n wà níbí nípaṣẹ̀ àánú Ọlọ́run kí wọ́n baa lè ní àǹfààní làti gbọ́ òtítọ́ fún àkokò yìí kí wọ́n sì gba ìmúrasílẹ̀ tí yóò mú wọn yẹ láti padà lọ sí ìlú wọn gẹ́gẹ́ bí àwọn tí yóò máa tan ìmọ́lẹ̀ iyebíye yìí, èyí tí ń tàn tààrà láti ìtẹ́ Ọlọ́run wa.-Pacific Union Recorder, Apr. 21, 1910.IIO 200.3

    Àwọn àǹfààní ńlá máa wáyé ní gbogbo àwọn àgbègbè tí ó wà lókèèrè fún iṣẹ́ Ọlọ́run tí a bá sa ipa tòótọ́ lórí àwọn àlejò wọ̀nyìí tí wọ́n wà ní àwọn ìlú ńlá ńlá tí ó wà ní ìlú wa. Láàárín àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin yìí ni a ti rí àwọn tó jẹ́ wí pé lẹ́hìn tí wọ́n bá ti gba òtítọ́ yìí gbọ́ ni wọ́n yóò ye láti sọ òtítọ́ náà fún àwọn ènìyàn wa tí ó wà lórílẹ̀ èdè wa àti ni àwọn orílẹ̀ èdè tóókù. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn pàápàá yóò tilẹ̀ padà lọ sí ìlú abínibí wọn pẹ̀lú èrò àti jèrè ọkàn àwọn ọ̀rẹ́ wọn. Wọ́n le wàásù iṣẹ́ ìránṣẹ́ ańgẹ́lì kẹta fún àwọn ẹbí àti aládùúgbò wọn.-Review and Herald, Oct. 29, 1914. IIO 200.4

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents