Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ààbò Láti Òkè Wá

    Bí ìjakàdì yìí kò tilẹ lópin, síbẹ kò sí ẹnití Ọlọrun fi sílẹ nìkanṣoṣo. Àwọn angẹli Ọlọrun n dáàbò bo àwọn tí ó fi ìrẹlẹ rìn níwájú Rẹ bẹẹni Ọlọrun kì yóò sì dalẹ àwọn tó gbẹkẹlè E. Bí àwọn ọmọ Rẹ ṣe ń tọ Ọ wá fún ààbò bẹẹni Ó ń gbé ọpágun sókè fún wọn tí Ó sì ń sọ wípé, “Máṣe fọwọkàn wọn nítorí pé ti Èmi ni wọn. Mo ti kọ wọn sí ọwọ Mí.-“Prophets and Kings, p. 571. Ọrun súnmọ àwọn tó ń jìyà nítorí òdodo bẹẹnì Kristi fi ìfẹ hàn sí olótìtọọ ènìyàn. Ó jìyà pẹlú àwọn olódodo àti wípé ẹnikẹni tí ó bá fọwọkàn wọn fọwọkàn Òun náà pẹlú. Agbára tí ó wà láti gbà wọn kúrò nínú ewu ti ara náà ni yóò sì gbà wọn kúrò nínú ibi èyí tí ó sì fi ṣeéṣe fún àwọn ìránṣẹ Ọlọrun láti dúró nínú ìwà òtítọ nínú ipòkípò.-Prophets and Kings, p. 545.IIO 166.2

    Nígbà míràn ó máa ń dàbí ẹní wípé Ọlọrun ti gbàgbé wàhálà tí ó ń dojúkọ ìjọ àti ìyà tí àwọn ọtá fi ń jẹ wọn. Ṣùgbọn èyí kò rí bẹẹ nítorí pé kò si ohun tí ó ṣọwọn sí Ọlọrun ju ìjọ Rẹ lọ nítorí náà k’O jẹ fi ìjọ Rẹ sílẹ fún ìyà jẹ. Yóò sì fi ìyà jẹ àwọn tí kò ṣojú Rẹ dáadáa nígbà tí y’O sì ṣàánú fún àwọn tó ṣojú Rẹ nítòótọ.-Prophets and Kings, p. 590.IIO 166.3

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents