Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  Ànfààní Fún Ìpínfúnni Lọ́fẹ̀ ẹ́

  Jẹ́ kí àwọn ìwé di pínpín pẹ̀lú òye nínú àwọn ọkọ̀ ojú irin, ní àwọn òpópónà, nínú àwọn ọkọ̀ ojú omi àti nípasẹ̀ àpò ìwé (Lẹta).- Gospel Workers, p.353.IIO 150.4

  Ní àsìkò yìí nínú ìrìn-àjò, àwọn ànfààní wà láti pàdé pẹ̀lú àwọn ọkunrin àti àwọn obinrin ti gbogbo lẹ́gbẹ́lẹ́gbẹ́, àti ọ̀pọ̀ láti àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn, jẹ́ èyí tí ó tóbi ju ti ìgbà ayé e ísírẹ́lì lọ. Àwọn òpópónà ìrìn-àjò ti wà ní ìlọ́po lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún. Pẹ̀lú ìyanu ni Ọlọ́run fi fi ṣètò o ọ̀nà. Àwọn aṣojú ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé, pẹ̀lú oníruurú àwọn ohun èlò, ni wọ́n ti wà ní ìkáwọ́ o wa,.Bibeli àti àwọn ìwé àtẹ̀jáde ní onírúurú èdè ni a ti fi lélẹ̀ fún ọ̀títọ́ ọ ti àsìkò yìí, wà ní ọwọ́ ọ wa, ni a le è yára gbé kíákíá lọ sí gbogbo ayé.- Gospel Workers, p.352.IIO 150.5

  Jẹ́ kí àwọn ìwé kékeré àti àwọn ìwé ìléwọ́, àwọn tákààdá àti àwọn ìwé lọ sí gbogbo ọ̀nà, gbé pẹ̀lu u rẹ̀, níbikíbi tí o bá ń lọ, ẹrù àwọn àṣàyàn ìwé ìléwọ́, tí ó le fi lé ènìyàn lọ́wọ́ tí o bá ti ní ànfààní. Ta èyí tí o bá lè tà, kí o sì yá tàbí kí o fún wọn láti mú lọ bí ó bá ṣe gbà. Àyọrísí pàtàkì yóò sì tẹ̀lé e.- Review and Herald, June 10, 1880.IIO 151.1

  A ti fi hàn mí pé a kò ṣe iṣẹ́ ẹ wa pẹ̀lú fífọ́n ká lọ́fẹ̀ ẹ́ àwọn ìwé àtẹ̀jáde e wa ké-kè-ké. Àwọn ọkàn tí wọ́n jẹ́ olóótọ́ wà tí wọn ì bá mú láti gba òtítọ́ yìí mọ́ra nípa ọ̀nà yìí nìkan…. Àwọn ìwé ìléwọ́ bíi ojú ewé mẹ́rin, mẹ́jọ, tàbí tí ó ní ojú ewé mẹ́rìndínlógún, ni a le è pèsè pẹ̀lú owó tí kò tó n ǹkan, láti ara owó tí a pa nípa ọrẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n ní iṣẹ́ yì í lọ́kàn. Nígbà tí o bá kọ lẹ́tà sí ọ̀rẹ́, o le è fi ọ̀kan tàbí méjì sínú u rẹ̀ láì fi kún owó ìfìwé ránṣẹ́. Nígbà tí ó bá ṣe alábàápàdé ènìyàn nínú àwọn ọkọ̀, nínú ọkọ̀ ojú omi, ní orí ìtàgé, ẹni tí ó rò pé òun léti kí ó gbọ́, ó le è fi ìwé ìléwọ́ fún wọn.- Testimonies, vol.1, pp.551, 552.IIO 151.2

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents