Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
 • Results
 • Related
 • Featured
No results found for: "".
 • Weighted Relevancy
 • Content Sequence
 • Relevancy
 • Earliest First
 • Latest First
  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents

  Ewu tí ó Ń bẹ nínú Iṣẹ́ Ajíhìnrere

  Ẹ máṣe jẹ́ kí a gbàgbé pé bí iṣẹ́ ṣe ń pọ̀ síi, tí a sì ń ṣe àṣeyọrí nínú iṣẹ́ tí a gbọdọ̀ ṣe parí, ewu wà nínú u gbígbáralé àwọn èrò àti ìlànà eniyan,ó lè ṣe é ṣe kí a má gbàdúrà tó bí ó ṣe yẹ, kí ìgbàgbọ́ ọ wa má sì tó n ǹkan. A má a wà nínú ewu ìpàdánù rírí ìdí tí a fi ní láti gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run wa nù, ẹni tí ó lè mú kí iṣẹ́ ẹ wa láṣeyọrí; ṣùgbọ́n bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè ṣe é ṣe kí ó rí báyìí,kí ẹnikẹ́ni máṣe rò pé ènìyàn bí ohun èlò lè ṣe aláì ṣe tó bó ṣe yẹ. Rárá kì í ṣe pe yoo ṣe alaiṣe to bo ṣe yẹ, ṣùgbọ́n láti ṣe púpọ̀ nípa gbígba ẹ̀bùn ti ọ̀run, Ẹ̀mí Mímọ́ náà.- Review and Herald, July 4, 1893.IIO 98.3

  Àwọn ìgbà mìíràn wà tí ìjọ yóò dìde nípa agbára, àti iṣẹ́ ìtara yóò sì jẹ́ àyọrísí; nítorí pé agbára tí i fúnni níyè ti ẹ̀mí mímọ́ yóò fún àwọn ọmọ ìjọ lókun láti lọ láti mú àwọn ọkàn fún Krístì. Ṣùgbọ́n nígbà tí iṣẹ́ yì í bá farahàn, awọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ní ìtara jùlọ ni yóò rí ìgbàlà tí wọ́n bá gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun nìkan nípa ìdúró ṣinṣin, àdúrà ìtara. Wọ́n yóò nílò láti gbàdúrà pé nípa oore-ọ̀fẹ́ ẹ ti Krístì wọn yóò lè rí ìgbàlà nípa fífi iṣẹ́ ẹ wọn yangàn tàbí láti sọ iṣẹ́ di olùgbàlà a wọn.IIO 99.1

  Wọ́n gbọdọ̀ má a wo Jésù ní gbogbo ìgbà, kí wọn lè mọ̀ pé agbára a RẸ̀ tí ó ṣiṣẹ́, kí wọn sì le fi ògo fún Ọlọ́run. Wọ́n má a pè wá láti ṣe ìpinnu àwọn ìgbìyànjú u wá láti tẹ iṣẹ́ Ọlọ́run síwájú, àti gbígbàdúrà sí baba wa ọ̀run yóò ṣe pàtàkì.Ó máa ṣe pàtàkì fún wa láti kópa nínú àdúrà nínú u kọ́lọ́fín-in wa, nínú ìdílé, àti nínú ìjọ.-Review and Herald, July 4, 1893.IIO 99.2

  Lòjú àwọn olùkọ́ni, ìgbòkè gbodò asán ni wọ́n kàkún ẹ̀sìn. Wọ́n dúró lórí iṣẹ́ òde ara láti ṣàfihàn bí ìfọkànsìn in wọn ṣe pọ̀ tó. Báyìí wọ́n ya àwọn ọkàn an wọn kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun, wọ́n sì dúró lórí i pé àwọn ti tó tán. Irú àwọn ewu báyìí sì wà; bí iṣẹ́ ṣe ń pọ̀ sí i, tí àwọn ènìyàn sì ń ṣe àṣeyọrí nínú ṣíṣe iṣẹ́ kíṣẹ́ fún Ọlọ́run, ewu wá nínú gbígbẹ́kẹ̀lé èrò àti àwọn ìlànà ènìyàn.Ó lè ṣe é ṣe làti ma gbàdúrà kúnjú òṣùwọ̀n, kí a sì ní ìgbàgbọ́ tí kò tó n ǹkan. Bí àwọn àpóstélì, a wà nínú ewu ìfọ́jú ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run, tí a sì ń wá láti sọ iṣẹ́ ara wọn di olùgbàla. A ní láti ma a wo Jesu lemọ́ lemọ́, kí a mọ̀ pé agbára a RẸ̀ ni ó ṣiṣẹ́ náà. Nígbà tí a lè ṣiṣẹ́ tìtara tìtara fún ìgbàlà àwọn tí wọ́n ti sọnù, ní láti wá ààyè láti ṣàṣàrò, fún àdúrà, àti láti kọ́ nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Iṣẹ́ tí a ṣe láṣeyọrí nìkan pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àdúrà, tí krístì sì yà sí mímọ́ nípa ìtóyè e RẸ̀ ni yóò farahàn níkẹhìn láti jẹ́ bí iṣẹ́ rere.- The Desire of Ages, p.362.IIO 99.3

  Larger font
  Smaller font
  Copy
  Print
  Contents