Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ẹ̀kọ́ Nípa Ilé Iṣẹ́

    Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ìdílé ló wà tí wọ́n jẹ́ aláìní tí a kò lè ṣe iṣẹ́ ìhìnrere tí ó dára fún ju kí a ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tẹ̀dó lórí ilẹ̀ kí a sì kọ́ wọn bí wọn yóò ṣe lò ó tí wọn yóò fi máa rí oúnjẹ òòjọ́ ọ wọn jẹ. Ìwúlò fún irú ìrànlọ́wọ́ àti ẹ̀kọ́ ni a kò gbọdọ̀ fi mọ ní àwọn ìlú ń lá ń lá. Pàápàá ní ìlú pẹ̀lú, pẹ̀lú u gbogbo bí ó tí ṣe le ṣe é ṣe fún ìgbé ayé tí ó dára, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aláìní ni wọ́n wà nínú àìní tí ó pọ̀ púpọ̀. Gbogbo àwọn ará ìlú ni wọ́n ṣe aláìní ìmọ̀ nínú ilé iṣẹ́ àti ní ọ̀nà iṣẹ́ ìtọ́jú ìlera. Ìgbé ayé e tálákà pẹ̀lú àga àti aṣo péréte, láì sí àwọn ohun èlò, láì sí àwọn ìwé, tí wọ́n sì di aláìní pẹ̀lú sí àwọn ìtura àti àwọn ìrọ̀rùn, àti àwọn ọ̀nà ọ̀làjú. Àwọn ọkàn tí a pa lára tí wọ́n kò dápé, ṣàfihàn àwọn àyọrísí ohun búburú tí wọ́n ti jogún àti àwọn ìwà ìṣìnà. A gbọdọ̀ kọ́ irú àwọn ènìyàn yì í láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. Wọ́n ti gbé ìgbé ayé aláìníṣẹ́, ìgbé ayé tí ó ti díbàjẹ́, wọ́n sì nílò kí a kọ́ wọn láti ṣàtúnṣe sí àwọn ìwà yìí.- Ministry of Healing, p. 192.IIO 129.1

    A gbọdọ̀ ṣàkíyèsí sí dídá sílẹ̀ àwọn onírúurú ilé iṣẹ́ kí àwọn ìdílé tí wọ́n jẹ́ aláìní le è rí iṣẹ́ ṣe. Àwọn kanlé kanlé, àwọn alágbẹ̀dẹ àti àwọn mìíràn tí wọ́n ti ní ìmọ̀ lórí àwọn iṣẹ́ mìíràn tí ó wúlò, gbọdọ̀ ní ìmọ̀lára láti kọ́ àti láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn aláìlóye àti àwọn tí kò ní iṣẹ́ lọ́wọ́.- The Ministry of Healing, p.194.IIO 129.2

    Àwọn àgbẹ̀ onígbàgbọ́ lè ṣe iṣẹ́ ìhìnrere láti ran àwọn aláìní lọ́wọ́ láti rí ibùgbé lórí ilẹ̀, kí wọn sì kọ́ wọn láti roko kí ó sì mú ìbísí wá. Kọ́ wọn láti lo àwọn ohun èlò ti iṣẹ́ àgbẹ̀, kọ́ wọn bí wọ́n ṣe le roko sí onírúurú ohun ọ̀gbìn, bí wọ́n ṣe le è gbìn àti bí wọ́n ṣe lè tọ́jú àwọn ọgbà igi eléso.- The Ministry of Healing, p.193.IIO 129.3

    Nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn aláìní ààyè iṣẹ́ tí ó gbòòrò wà fún àwọn obìnrin àti fún àwọn ọkùnrin pẹ̀lú. Aláṣẹ tí ó lágbára, olùtọ́jú ilé, olùránṣọtà obìnrin, ọlọ́jọ̀jọ̀ ọmọ,- ìrànlọ́wọ́ gbogbo àwọn wọ̀nyí ni a nílò. Jẹ́ kí àwọn ará inú ilé tí wọ́n ṣe aláìní yìí kọ́ bí wọ́n ṣe lè ṣẹ oúnjẹ, bí wọ́n ṣe le ṣe àtúnṣe sí aṣọ ọ wọn tí ó bàjẹ́, láti ṣe ìtọ́jú aláìsàn, láti ṣe ìtọ́jú ilé dáadáa. Jẹ́ kí àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin kọ́ bí a ṣe ń ṣòwò tí ó dára tàbí kọ́ iṣẹ́ tí ó wúlò.- The Ministry of Healing, p.194.IIO 129.4

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents