Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ìgbésí Ayé Tí ó ń jèrè Ọkàn

    Kìí ṣe kí a wàásù òtítọ́ nìkan, kí a pínpin ìwé ìwáásù pélébé, ni a fi lè jẹ́rìí fún Ọlọ́run.Ẹ jẹ́ kí á rántí pé ìgbé ayé ìwà bì Ọlọ́run jẹ́ bíi àríyànjiyàn alágbára tí a fi lè gbè ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ lẹ́sẹ̀,àti pé ìwà onígbàgbọ́ tí ó láléébù le è ṣe jàǹbá nínú ayé ju ìwà àwọn ẹni tí ó wà nínú ayé lọ. Kìí ṣe gbogbo ìwé tí a kọ ni ó lè wúlò fún ìgbé ayé mímọ́. Àwọn ẹnìyàn yóò gba ìgbésí ayé àwọn ìjọ gbọ́ ju ìwáásù àlùfáà lọ.Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ipa tí ìwàásù tí a wà lórí i pẹpẹ ń tako ìwàásù tí a wà nínú ìgbé ayé àwọn tí wọ́n pe ara wọn ni agbẹnusọ fún òtítọ́. - Testimonies,vol.9,p.21.IIO 26.1

    Ìgbé ayé ti Krístì ni ipa tí ó ń tẹ̀síwájú àti síwájú sí I, Ipa tí ó so Ó pọ̀ mọ́ Ọlọ́run àti ìran ènìyàn. Nípasẹ̀ Krístì, Ọlọ́run ti wọ̀ wá ní aṣọ pẹ̀lú ipa láti mú kí ó ṣe é ṣe fún un láti gbé ìgbé ayé ara a rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ẹnìkọ̀ọ̀kan a so wá pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn bíi ti wa, ẹ̀ka nínú Ọlọ́run tí ó tóbi, a sì dúró lábẹ́ ẹ àjọṣepọ̀ tí ó jẹ́ ọ̀ràn-an-yàn.Ko si ẹni tí ó lè dá dúró nípa ti ara rẹ̀ láìsí arákùnrin- in rẹ̀; nítorí ìdúró dáa dáa wa ń ran ẹnìkejì, ètò Ọlọ́run ni kí ìmọ̀lára tí ó yẹ fún ìtọ́jú àwọn ẹlòmíràn, kí a sì l’épa láti gbé ìdùnnú un wọn sókè. - Christ Object Lessons, p.339.IIO 26.2

    Ẹ̀sìn ti inú Bíbélì kìí ṣe kí ó pààlà láarin ẹ̀yìn ìwé, tàbí láarin igun ilé Ọlọ́run. Kì í ṣe ohun tí a le gbé síta ní ẹnì kọ̀ọ̀kan fún ànfààní ara wa, kí a sì tún ṣọ́ra láti fi sẹ́gbẹ̀ ẹ́ kan. Ó wá láti ya ìgbé ayé e wa sí mímọ́, kí ó fi ara rẹ̀ hàn nínú òwòkówò tí ó bá ń ṣe àti nínú ìbáṣepọ̀ ara wa.-The desire of Ages, pp.306, 307.IIO 26.3

    Èròǹgbà Ọlọ́run ni láti ṣ’ògo nínú ara a rẹ̀ nínú àwọn ènìyàn níwájú aráyé. Ó ń retí àwọn tí wọ́n jẹ́ orúkọ mọ́ ọ lára láti ṣ’ojú rẹ̀ nínú ọ̀rọ̀, àti ìṣe e wọn.Èrò o wọn gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́, ọ̀rọ̀ ẹnu wọn gbọdọ̀ lọ́lá, kí ó sì múni dàgbà, kí ó fa àwọn tí ó wà nítòsí i wọn súnmọ́ Olùgbàlà. Ẹ̀sìn Krístì yẹ kó wọ inú ara wọn nípa ohun tí à ń ṣe tí a sì ń sọ. Gbogbo òwò tí wọ́n bá ń ṣe gbọdọ̀ jẹ́ bí òórùn dídùn níwájú Olúwa. Testimonies, vol.9, p.21.IIO 26.4

    Jẹ́ kí oníṣòwò ṣe òwò o rẹ̀ ní ọ̀nà tí yóò fi ògo fún Ọlọ́run nítorí òtítọ́ rẹ̀. Jẹ́ kí ó gbé ìgbàgbọ́ ọ rẹ̀ wọ inú ohunkohun tí ó bá ń ṣe, kí ó ṣàfihàn ẹ̀mí Ọlọ́run fún àwọn ènìyàn. Jẹ́ kí onímọ̀ ẹ̀rọ jẹ́ aláìṣèmẹ́lẹ́ àti aṣojú tòótọ́, ẹni tí ó rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ ní ìlú Jùdéà. Jẹ́ kí ẹni tí ó ń jẹ́ orúkọ mọ Krístì l’ára ṣiṣẹ́ gidigidi tí àwọn ènìyàn nípa rírí iṣẹ́ rere rẹ̀ yóò lè yin Ẹlẹ́dàá àti Olùrapàdà lógo.-Bible Echo, June 10, 1901.IIO 27.1

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents