Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Àkọsílẹ̀ Ańgẹ́lì Naa

    Tí àwọn ọkọ bá jáde lọ sí ẹnu iṣẹ́ wọn, tí wọ́n sì fi àwọn ọmọ sí ọwọ́ ìtọ́jú àti ìtọ́ni àwọn ìyàwó àti màmá nílé, a ó ò rí i wí pé iṣẹ́ kan náà ni àwọn màmá tàbí ìyáwó yìí ń ṣe pẹ̀lú bàbá tí ó jáde lọ sẹ́nu iṣẹ́. Lótìtọ́ ọ̀kan jáde lọ ṣiṣẹ́ ní ìgboro fún iṣẹ́ ìjèrè ọkàn nígbà tí èkejì ń ṣe iṣẹ́ àbójútó ọmọ nígbà gbogbo pàápàá tayọ iṣẹ́ ti bàbá tàbí ọkọ. Iṣẹ́ ìyàwó yìí jẹ́ iṣẹ́ ọlọ́wọ̀ èyí tí ó ṣe Pàtàkì púpọ̀ — láti gbin ìwà rere sínú ayé àwọn ọmọ, láti kọ́ wọn ní bí wọ́n yóò ṣe wúlò níbi àti bí wọn yóò ṣe yẹ fún ọjọ́ ọ̀la àti ayé tí kò nípẹ̀kun. Bàbá tí ó ń ṣiṣẹ́ ìhìnrere ní ìta lèè gba ọlá láti ọ̀dọ ènìyàn nígbà tí ẹni tí ó ń ṣiṣé ilé lèè máà rí èrè rere kan gbà fún làálàá rẹ̀. Ṣùgbọ́n tí ó bá ṣiṣẹ́ fún ìdàgbàsókè ìdílé rẹ̀, tí ó fi ìwà bí Ọlọ́run kọ́ wọn nígbà náà ni ańgẹli olùṣe àkọsílẹ̀ yóò kọ orúkọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere tí ó ga jùlọ ní gbogbo àgbáyé nítorí Ọlọ́run kìí wò bí ènìyàn ti máa ń wò nítorí ènìyàn ń wo ojú ṣùgbọ́n Ọlọ́run a máa wo ọkàn.-Testimonies, Vol. , p. 594.IIO 207.2

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents