Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Ojúṣe Àti Iṣẹ́ Àwọn Ènìyàn Ọlọ́run

    Àsíá òtítọ àti òmìnira ẹsin èyí tí àwọn aṣáájú iṣẹ ìhinrere ti ìjọ àti ìjẹrìísí Ọlọrun ti gbe ga láti ọpọlọpọ ọdún sẹhìn ni àkókò ìjàkadì ìkẹhìn yìí ni a ti fi le wa lọwọ. Ojúṣe fún ti ẹbùn ńlá yìí wà lórí gbogbo àwọn ti Ọlọrun ti bùkún làti ni òye ọrọ Rẹ. A gbọdọ gba ọrọ yìí gẹgẹ bi àṣẹ ti ò ga jùlọ. A gbọdọ mọ wípé gbogbo àwọn ti ò wà ni ìjọba ni a gbọdọ bú ọla fún nitoripe Ọlọrun ni ó mú wọn débẹ ṣùgbọn nígbà ti òfin wọn bá tako ti Ọlọrun, a gbọdọ gbọ ti Ọlọrun ju ti ènìyàn lọ. Ọrọ Ọlọrun ni a gbọdọ mọ wípé O ga ju gbogbo òfin ènìyàn lọ. “Bàyìí ní Olúwa wí” ni a kò gbọdọ gbé ti si ẹgbẹ kan kí á sì wá gba “Báyìí ni ìjọba wi” gbọ. ÀAdé Jésù ni a gbọdọ gbé ga ju adé Ọba ayé lọ.-The Acts of the Apostles, pp. 68, 69.IIO 161.4

    Àwa gẹgẹ bi ènìyàn kò tíì ṣe àṣeyọri nínú iṣẹ ti Olúwa gbé lé wa lọwọ. Bẹẹni a kò tíì múra sílẹ fún wàhálà òfin Ọjọ ìsinmi ti ọjọ kìn-ín-ní ọsẹ yóò mú wá. Iṣẹ wa ni bí àwọn àmìn ewu wọnyìí ti ń farahàn làti bẹrẹ iṣẹ. Kí ẹnikẹni ma ṣe jókòó tẹtẹrẹ nígbà tí àwọn ibi wọnyí bá ń yọjú kí ó sì máa sọ wípé iṣẹ náà gbọdọ tẹsiwajú nítorípé àsọtẹlẹ ti sọọ tẹlẹ àti wípé Ọlọrun yóò dáàbò bo àwọn ènìyàn Rẹ. A kò ṣe ifẹ Ọlọrun tí a bá wà ní ìdákẹjẹ láìṣe ohunkóhun láti dáàbò bo òmìnira ti ọkàn. IIO 162.1

    Àdúrà kíkan-kíkan ni a gbọdọ máa gbà sí Ọlọrun wípé kí ìyọnu náà ó máa tíì dé títí di ìgbà tí a ó fi ṣe iṣẹ èyí tí a ti fi ìgbà pípẹ patì sẹgbẹ kan. Ẹ jẹ kí a máa fi ítara gbàdúrà kí a sì ṣiṣẹ papọ pẹlú ìṣọkan àti àdúrà.-Testimonies, Vol. 5, pp. 713, 714.IIO 162.2

    Ojúṣe wa ni làti ríì wípé a sa ipá wa láti ré ibi tí ó ń bọwa dojúkọwá sọnù.IIO 162.3

    Ó yẹ kí á mú ẹtanú kúrò nípa jíjẹ kí ìmọlẹ wa tàn níwájú àwọn ènìyàn. Òtítọ ọrọ tó ń lọ lọwọ ni ó yẹ kí á gbé kò wọn lójú nípa dídúró ní agbedeméji láti lè dojúkọ àwọn àtakò tó ń dẹkun òmìnira ti ọkàn.-Testimonies, Vol. 5, p. 452.IIO 162.4

    Nígbà tí Ọlọrun ti fún wa ni ìmọlẹ láti fi àwọn ewu tí ó wà níwájú wa hàn wá, báwo ni a ṣe lè wá dúró ní mímọ níwájú Rẹ tí a kò bá sa ipa wa láti fihàn fún àwọn ẹlòmíràn? Ṣé yóò wá tẹ wá lọrun láti dojúkọ àwọn rògbòdìyàn ákókò yìí láti kìlọ fún wọn bí?.-Testimonies, Vol. 5, p. 712.IIO 162.5

    Nígbà tí àwọn alátùn-ùntò àgbáyé bá ń gbé ìgbésẹ láti dẹkun òmìnira ẹsìn, ó yẹ kí àwọn olórí wa ti gbé ìgbésẹ láti takò akitiyan yan. Kìí ṣe ìlànà Ọlọrun láti má jẹẹ kí ìmọlẹ òtítọ àkókò yìí tí wọn nilò ó má ṣe tàn dé ọdọ wọn. Kìí ṣe gbogbo àwọn àlúfà wa tí wọn ń kéde iṣẹ ìránṣẹ áńgẹlì kẹẹta ni wọn ní òye iṣẹ ìránṣẹ yìí ní kíkún. Àwọn ẹgbẹ alátùn-ùntò àgbáyé yìí ni àwọn kan rò wípé wọn kò ṣe pàtàkì tó bẹẹ gẹ tí wọn rò wípé kò yẹ kí wọn kọbiara sí wọn àti wípé wọn rò wípé tí wọn bá kà wọn sí, wọn le máa bèèrè àwọn ìbéèrè tí ó yàtọ sí iṣẹ ìránṣẹ áńgẹlì kẹẹta. Kí Ọlọrun kí ó dáríjì àwọn arákùnrin wa wọnyí bí wọn ṣe ń túmọ iṣẹ ìránṣẹ pàtàkí yìí fún àkokò yìí.- Testimonies, Vol. 5, p.715.IIO 162.6

    Ní ọpọlọpọ ọdún sẹhìn ni a ti ń fojú sọnà fún òfin ọjọ kìn-ín-ní ọsẹ, ṣùgbọn nísisìnyí tí àwọn ẹgbẹ yìí bẹrẹ iṣẹ wọn lórí wa, a wá ń béèrè wípé, ńjẹ àwọn ènìyàn wa yóò sa ipa ti wọn lórí ọrọ yìí bí? Ńjẹ a kò lè ṣe ìrànlọwọ nípa gbígbé gbèdéke sókè nípa pipe àwọn ti ń bọla fun ẹtọ ati àńfààní ìsìn wọn síwájú? Àkókò náà ń súnmọ nígbàtí wọn óò máa fìyà jẹ àwọn tí ó yàn láti pa òfin Ọlọrun mọ ju ti ènìyàn lọ. Ṣé ó wá yẹ kí á panu mọ nígbàtí àwọn ènìyàn yóò máa tẹ òfin Ọlọrun mímọ mọlẹ bí? Nígbà tí àwọn alátakò bá ń fi ara mọ Róòmù. Ẹ jẹ kí á dìde nípa níní òye kí á sí wo ìjà tí ó wà ní ọnà tí ó tọ. Ẹ jẹ kí àwọn alóòre gbé ohùn wọn sókè kí wọn sì wàásù iṣẹ ìránṣẹ èyì tíí ṣe òtítọ àkokò yìí fún ìgbà yìí. Ẹ jẹ kí a fi hàn fún àwọn ènìyàn ibi tí a wà nínú ìtàn àsọtẹlẹ, kí á sì ta ẹmí àtakò tòótọ sí ẹkọ òdì jí, bákannáà kí a si ta aráye jí sí ìmọ òtítọ ti òmìnira sí ìsìn tì wọn ti mọ tẹlẹ rí jí.-Testimonies, Vol. 5, p. 716.IIO 163.1

    Ó yẹ kí a ta àwọn ènìyàn jí kí wọn lè dènà àwọn ọtá tí ó ń gbógún ti ànfáàni òmìnira ti ẹsìn àti tí ètò jíjẹ ọmọ ìlú.-Spirit of Prophesy, Vol. 4, p. 382.IIO 163.2

    Ṣé ó wá yẹ kí á jókò fọwọ lẹrán nínú rògbòdìyàn yìí? ... kí Ọlọrun kí ó ràn wá lọwọ kúrò nínú ìwà àìlèrónù jinlẹ tí ó ti bá wa láti ọdún pípẹ.-Review and Herald, Dec. 18, 188.IIO 163.3

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents