Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Èrè e Ti Ìsinsinyìí

    Inúdídùn.- Àwọn tí ó fi ayé e wọn sílẹ́ fún iṣẹ́ ìsìn in Kristi mọ ìtumọ̀ inú dídùn. Àdúrà àti èròǹgbà a wọn lọ jìnà réré. Àwọn fúnra a wọn ń dàgbà bí wọ́n ti ń gbìyànjú láti ran ẹlòmíràn lọ́wọ́. Wọ́n ní èkọ́ nínú ètò ń lá, iṣẹ́ tí ó le jù, báwo ni wọn yóò ṣe dàgbà nígbà tí wọ́n fi ara wọn sínú orísun ìmọ́lẹ̀ àti ìbùkún? Irú àwọn wọ̀nyìí gba ọgbọ́n láti ọ̀run. Wọ́n ń bá Jésù rìn lójoojúmọ́ ńinú ipa a Rẹ̀. Kò sì sí ààyè fún àjórẹ̀yìn nínú ẹ̀mí.- Testimonies, vol.9, p.42.IIO 269.1

    Ìjọ tí ó ṣe iṣẹ́ yìí láṣeyọrí jẹ́ ìjọ tí ó láyọ̀. Ọkùnrin tàbí obìnrin náà tí ọkàn an rẹ̀ kún fún àánú àti ìfẹ́ fún àwọn tí ó ti ṣìnà tí ó sì ṣiṣẹ́ láti mú wọn padà sínú agbo Olùsọ́ Àgùtàn ń lá ni ẹni tí ó ń ṣiṣẹ́ ìbùkún. Haà! Irú èrò tó ó fi ayọ̀ kún ọkàn wo lèyí, wípé nígbà tí a bá gba ẹlẹ́ṣẹ̀ kan là, ayọ̀ púpọ̀ ni ó ń bẹ ní ọ̀run jù lórí olódodo márùndínlọ́gọ́rùn-ún lọ.- Testimonies, vol.2,p.22.IIO 269.2

    Kò sì iṣẹ́ tí ó nira fún ẹni tí ó jọ̀wọ́ ara a rẹ̀ fún Ọlọ́run.”Ṣísiṣẹ́ fún Ọlọ́run” ni oògùn ìmúláradá láti ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ tí Ọlọ́run bá yàn fún- un láti ṣe.- Testimonies, vol.9.p.150.IIO 269.3

    Iṣẹ́ Kankan tí ó nira fún àwọn òṣìṣẹ́ Krìsténì nínú iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún wọn. Ayọ̀ Olúwa a máa kún ọkàn -an wọn láti rí i pé a dá àwọn ọkàn kúrò lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀; ayọ̀ yìí ni ó sì dúró gẹ́gẹ́ bí owó tí a san padà fún-un fún iṣẹ́ ìṣẹ́ra ẹni.- Souther Watchman, April2, 1903.IIO 269.4

    Láti jẹ́ òṣìṣẹ́ tí ó ń fi sùúrù tèsíwájú nínú rere ṣíṣe èyí tí ó mú iṣẹ́ ìṣẹ́ra ẹni dání jẹ́ iṣẹ́ ológo èyí tí ó ń mú inú ọ̀run dùn.- Testimonies, vol.2, p.24.IIO 269.5

    Inú Krístì a máa dùn láti ṣe àmúlò àwọn ohun èlò tí kò nírètí, àwọn tí Sàtánì ti rẹ̀sílẹ̀ tí ó sì ti lò gẹ́gẹ́ bí ohun èlò fún oore ọ̀fẹ́ ẹ rẹ̀....Ó fi àwọn ọmọ ọ rẹ̀ ṣe ohun èlò láti ṣe àṣeparí iṣẹ́ yìí àti láti ṣe àṣeyọrí nínú ayé yìí tí wọn yóò sì padà gba èrè rere fún iṣẹ́ ẹ wọn.- Testimonies, vol.6, pp.308,309.IIO 270.1

    Ìbùkún.-Gbogbo akitiyan tí a bá ṣe fún Kristi ni yóò padà yọrí sí ìbùkún lórí i wa.- Christ’s Object lessons, p.354.IIO 270.2

    Gbogbo iṣẹ́ rere tí a ṣe, gbogbo ìfira-ẹni-rúbọ tí a ṣe lórúkọ Jésù ni ó má a yọrí sí èrè ń lá. Nínú ṣíṣe iṣẹ́ , Ọlọ́run a máa sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni Ó sì máa ń pín ìbùkún.- Testimonies, vol.4,p.145.IIO 270.3

    A gbọdọ̀ gbé nínú ayé yìí pẹ̀lú èròǹgbà àti jèrè ọkàn fún Olùgbàlà. Tí a bá pa ènìyàn lára, a jẹ́ wípé a ń pa ara wa lára. Tí a bá bùkún ẹlòmíràn, bákan náà ni a ń bùkún ara a wa; ipa gbogbo iṣẹ́ rere tí a ṣe ni ó ń farahàn nínú ọkàn a wa. - Testimonies, vol.4, p.72.IIO 270.4

    Gbogbo ìtànsán ìmọ́lẹ̀ tí a tàn sí àwọn ẹlòmíràn ni yóò farahàn nínú ọkàn —an wa. Gbogbo ọ̀rọ̀ rere àti ọ̀rọ̀ ìtùnú tí a sọ sí àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn, gbogbo bí a ṣe mú ìtura bá àwọn tí a pọ́n lójú àti àwọn ẹ̀bùn tí a pèsè fún ìlò àwọn ènìyàn, àwọn ohun tí a ti pèsè tàbí ṣe láti fi ògo fún Ọlọ́run ni yóò mú èrè wá fún àwọn tí ó pèsè e rẹ̀. Gbogbo àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ yìí ni wọn yóò pa òfin ọ̀run mọ́ tí wọn yóò sì jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run. - Testimonies, vol.4, p.56.IIO 270.5

    Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èrè ń lá a ti ìkẹyìn yóò wáyé nígbà bíbọ̀ Kristi, síbẹ̀ iṣẹ́ ìsìn òtítọ́ fún Ọlọ́run má a ń mú èrè wá láyé yìí. Ìdènà, àtakò àti ìkorò ọkàn èyí tí ó mú ìpòruurù ọkàn wá èyí tí òṣìṣẹ́ ní láti dojúkọ. Ó lè má rì í èrè làálà a rẹ̀. Ṣùgbọ́n nínú àwọn n ǹkan wònyí, yóò rí èrè ìbùkún n ǹkan wọ̀nyí èyí tí a san padà fún un. Gbogbo àwọn tí ó jọ̀wọ́ ara a wọn fún Ọlọ́run nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ láìsí ìmọ̀ ti ara ẹni nìkan fún ìran ènìyàn ni ó fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Olúwa Ológo. Èrò ọkaǹ yìn dùnmọ́ àwọn òṣìṣẹ́, ó di ìfẹ́ ọkàn mú bẹ́ẹ̀ ni ó pèsè ọkàn sílẹ̀ fún ohunkóhun tí ó wù kí ó lè ṣẹlẹ̀. - Testimonies, vol.6, pp.305,306.IIO 270.6

    Ìlera. - Rere ṣíṣe jẹ́ ọ̀nà àbáyọ tí ó múná dóko fún àìsàn. Àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ yìí ni a pè láti pe Ọlọ́run, Ó sì ti ṣèlérí láti dá wọn lóhùn. A yóò tẹ́ ọkàn —an wọn lọ́rùn nígbà òùngbẹ bẹ́ẹ̀ni wọn yóò sì dàbí ọgbà tí a bomi rin nígbà gbogbo. - Testimonies, vol.2, p.29.IIO 270.7

    Nínú ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọrun, pẹ̀lú u Jésù, àti pẹ̀lú àwọn angẹli mímọ́, bẹ́ẹ̀ ni a yí wọn ká pẹ̀lú àyíká ọ̀run, àyíká tí ó mú ìlera bá ọkàn, tí ó ń fún ọgbọ́n ní agbára àti ayọ̀ fún ọkàn. - Testimonies, vol.6, p.306.IIO 271.1

    Níní inú dídùn láti ṣe rere sí àwọn ẹlòmíràn má ń mú ayọ̀ tó kún ọkàn wá èyí tí ó sì ń mú kí ẹ̀jẹ̀ ara ṣàn kíákíá èyí tí ó sì ń mú kí àlàáfíà wà nínú ọpọlọ àti àwọn èyà ara.- Testimonies, ẹol.4, p.56.IIO 271.2

    Okun.- Tí alágbára ènìyàn bá kọ̀ láti ṣiṣẹ́, láìpẹ́ ni àárẹ̀ yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní sẹlẹ̀ sí i. Ijọ́kíjọ́ tàbi ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá kọ̀ jálẹ̀ láti ru àjàgà àwọn ẹlòmíràn ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ wípé ti ara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀ yóò bèrè sí ní àìlera nípa ti ẹ̀mí. Iṣẹ́ ni ó máa ń túbọ̀ mú kí agbára ènìyàn ó lágbára síi. Iṣẹ́ ẹ ti ẹ̀mí àti ríru àjàgà àwọn ará ni ó máa ń fún ìjọ Kristi ní agbára sí i. Testiminies, vol.2,p.22.IIO 271.3

    Àlàáfíà. - Nígbà tí a bá ń ṣiṣẹ́ fuń ẹlòmíràn nígbà náà ni èrè e wa yóò jẹ́ ìtẹ́lọ́rùn dídùn pẹ̀lú àlàáfíà òun ìfọ̀kàn balẹ̀. Nígbà tí a bá mú iṣẹ́ ìṣerere wa sí àwọn ẹlòmíràn ní ọ̀kúnkúndùn, a yóò ní ayọ̀ tòótọ́ láti ṣiṣẹ́ ẹ wa tọkàn tọkàn. Èyí yóò sì mú èrè ń lá tí ó ju ti ayé e wa èyí tí àwọn angẹli ń ṣe àkíyèsí tí wọ́n sì ń ṣe àkọsílẹ̀ ẹ rẹ̀ nínú ìwé ayérayé. - Testimonies, vol.2 p.132.IIO 271.4

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents