Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Jẹ́ Ẹni tí ó Fani Mọ́ra

    Èmi yóò sọ níti gbogbo àwọn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ fún Krístì pé, níbikíbi tí wọ́n bá ti ní ànfààní láti rí àwọn ènìyàn ní ẹ̀bá iná, lo ànfààní ì rẹ. Gbé Bíbélì ì rẹ, kí o sì ṣí àwọn òtítọ́ ń lá yìí níwájú u wọn. Àṣeyọrí ì rẹ kò ní dúró lórí i ìmọ̀ àti àṣeparí gẹ́gẹ́ bí agbára à rẹ láti wá ọ̀nà dé ọkàn.Nípa kíkóni mọ́ra àti sísún mọ́ ènìyàn,ó lè rọrùn fún ọ láti darí èrò ọkàn-an wọn ju ohun tí ìjíròrò lè ṣe lọ.Fífi Krístì lọ̀ nínú ìdílé, ní ẹ̀bá iná, àti nínú àwọn àkójọpọ̀ kékèré lábẹ́lẹ̀, má ń mú àṣeyọrí púpọ̀ wá nínú u jíjèrè àwọn ọkàn fún Jésù ju àwọn ìwàásù tí a wà ní ìta gbangba, sí àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn, tàbí nínú u gbọ̀gàn tàbí àwọn ìjọ.- Gospel workers, p.193.IIO 122.3

    Àpẹẹrẹ Kristi nínú síso ara a Rẹ̀ pọ̀ mọ́ ìfẹ́ àwọn ènìyàn pẹ̀lú u gbogbo àwọn tí wọ́n ń wàásù ọ̀rọ̀ ọ RẸ̀. A kò ní láti kọ ìpéjọpọ̀ sílẹ̀, a kò gbọdọ̀ ya ara wa sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Láti lè dé ọ̀dọ̀ àwọn ẹgbẹẹgbẹ́, a gbọdọ̀ pàdé e wọn níbi tí wọ́n wà. Wọn yóò má a wá wa lẹ́ẹ̀kẹ̀ẹ̀kan láti bá wọn rẹ́. Kì í ṣe orí i pẹpẹ nìkan ni a ti lè fọwọ́ ba àwọn ọkàn nípa òtítọ́ ọ̀run. Pàá pàá ibi tí a ti lè ṣiṣẹ́ mìíràn wà, ó lè jẹ́ ibi tí a ti ní ìrètí kíkún. A le è ri nínú ilé e ti onírẹ̀lẹ̀, àti nínú ilé àwọn ẹni ń lá; níbi ìgbàlejò, àti nínú àwùjọ fún ìgbádùn ara ẹni. - The Desire of Ages, p.152.IIO 122.4

    Kò yọ Kristi sílẹ̀, Ó ti fi ẹ̀ṣẹ̀ Pàtàkì fún àwọn Farisí nípa kíkúrò nínú àwọn òfin tí ó le láti tẹ̀. Ó rí ìjọba ti ẹ̀sìn tí a ṣọgbà yíká nípa ògiri ń lá tí a yà sọ́tọ̀, tí ó lọ́wọ̀ jù fún n ǹkan ojoojúmọ́ ìgbé ayé. Àwọn ògiri ìyapa ni ó bì ṣubú. Nínú ìfarakanra a RẸ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn, kò béèrè pé, kín ni ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ ọ̀ rẹ? inú ìjọ wo ni o wà? Ó nawọ́ agbára ìrànlọ́wọ́ ọ RẸ̀ fún àwọn tí ó nílò ìrànlọ́wọ́. Dípò kí ó fi ara a RẸ̀ sínú yàrá ìdágbé láti fi ìwà a RẸ̀ ọ̀run hàn, Ó ṣiṣẹ́ taratara fún àwọn ènìyàn. Ó tẹnumọ́ ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ pé ìsìn inú u Bibeli kò ní ìparun ti ara nínú. Ó kọ́ ni pé ìsìn mímọ́ àti àìléèérí kò wà fún àkókò kan àti ààyè àkànṣe. Ni gbogbo ìgbà àti ní ibi gbogbo Ó fi ìfẹ́ ẹ RẸ̀ hàn sí àwọn ènìyàn, Ó sì tàn ìmọ́lẹ̀ nípa ara a RẸ̀ níti ìbọ̀wọ̀ fún tí ó ṣe inú dídùn. - The desire of Ages, p.86.IIO 123.1

    Nínú ẹ̀tanú u wọn, Ó gba ìwà inú rere àwọn ènìyàn tí wọ́n ń kẹ́gàn yìí, Ó sùn ní abẹ́ òrùlé e wọn, Ó ń jẹun pẹ̀lú u wọn ní orí i tábìlì i wọn, - Ó ń ṣe alábápín nínú oúnjẹ tí wọ́n pèsè tí wọ́n sì ń pín pẹ̀lú ọwọ́ ọ wọn, - Ó ń kọ́ni ní àwọn ọ̀pọ́pọ́nà a wọn, Ó lò pẹ̀lú u wọn pẹ̀lú ìhìnrere àti àánú tí kò lópin. - The Desire of Ages, p.193.IIO 123.2

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents