Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents

ISE ISIN ONIGBAGBO

 - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    Mímú Ìpàdé Àdúrà Láàrínrín

    Ẹ jẹ́ kí ìpàdé àwọn ajíhìnrere ó wà gẹ́gẹ́ bí ibi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn ajíhìnrere.-Appeals to Our Churches, p. 11.IIO 211.3

    Gbogbo àwọn ìpàdé wa yálà tí àdúrà ni o tàbí àwọn mìíràn gbọ́dọ̀ wá fún ṣíṣe ìrànlọwọ àti ìgbani-níyànjú. Olúkúlukú ni ó gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ láti lè jẹ́ kí àwọn ìpàdé yìí ó lárinrin kí ó sì yọrí sí rere. Eléyìí lè wáyé nípa níní ìrírí ọ̀tun lójoójúmọ́ nínú ohun tí Ọlọ́run; àti láì dágunlá láti sọ ọ̀rọ̀ Rẹ̀ nínú ìpàdé àwọn ènìyàn. Tí a kò bá gba iyèméjì láàyè nínú ọkàn, kò lèè jẹyọ rara nínú àwọn ìpàdé wa.-Southern Watchman, Mar. 7, 1905.IIO 211.4

    Àwọn ìpàdé wa gbọ́dọ̀ jẹ èyí tí ó lárinrin. A gbọ́dọ̀ ní ìrírí ọ̀run ní gbogbo àyíká wa. Ẹ máà ṣe jẹ́ kí ìpàdé àdúrà wa ó wà fún ọ̀rọ̀ gígùn gẹ́gẹ́ bí ó ṣe máa ń rí èyí tí ó lè mú kí a fi àkokò ṣòfò. Gbogbo wa ni ó yẹ kí ó sa ipá wa láti ṣe ètò wa ní kíákíá, nígbà tí a bá sì parí, kí a mú ìpàdé wá sí ìparí. Nípa báyìí ni àwọn ènìyàn yóò fi ní ìfẹ́ sí ètò náà títí dópin. Èyí ni ọọrẹ wa sí Ọlọ́run tí ó sì jẹ́ ìsìn tí ó jẹ́ ìtẹwọ́gbà. Àwọn ìsìn Rẹ̀ kò gbọdọ̀ sú àwọn ènìyàn bíkòṣe èyí tí ó dùn mọ́ wọn. A gbọ́dọ̀ máa gbé nínú Kírísítì ní gbogbo ìgbà nígbà náà ni Kírísítì yóò máa gbé nínú wa nígbá tí a bá sì pàdé paapọ̀, ìfẹ́ Rẹ̀ yóò wà nínú ọkàn wa tí yóò sí máa ru bí omi nínú aṣálẹ̀ tí ó ń tu ènìyàn gbogbo lára, kí ó sì mú àwọn ọkàn tí ó fẹ ṣègbé ní ìtara láti mu nínú omi ìyè.-Testimonies, Vol. 5, p. 609.IIO 212.1

    Ẹ máà ṣe rò wí pé ẹ lè ta ọkàn àwọn ọ̀dọ́ jí nípa ṣíṣe ìwáásù gígùn ní àwọn ibi ìpàdé. Ẹ ṣe ìlànà lórí bí a ṣe lè ta ìfẹ́ ọkàn jí. Ẹ jẹ́ kí àwọn ọ̀dọ́ ó mú ìròhìn iṣẹ́ ìrìjú wọn wá lọ́sẹ̀ẹ̀sẹ̀ lórí ohun tí wọ́n ti ṣe fún Olùgbàlà àti àṣeyọrí wọn. Tí àwọn ìpàdé yìí bá jẹ́ irú èyí tí ó fún ni lánfààní láti jábọ̀ iṣẹ́ ìrìjú nígbà náà ni irú ìpàdé bẹ́ẹ̀ kò ní sú àwọn ènìyàn. Yóò dùn mọ́ àwọn ènìyàn láìsí ẹnikẹ́ni tí yóò pa ìpàdé jẹ.-Gospel Workers, pp. 210, 211. IIO 212.2

    Nígbà tí ìgbàgbọ́ wa bá rọ̀ mọ́ Kírísítì, òtítọ́ náà yóò mú ayọ̀ bá ọkàn bẹ́ẹ̀ni àwọn iṣẹ́ ìsìn wa kò ní sú àwọn ènìyàn. Àwọn ìpàdé wà tí kò ti fí ìgbà kan lókun, yóò gba agbára láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ a ó sì máa ní ìrírí tí ó dára bí a ti ń ṣe iṣẹ́ ìgbàgbọ́ wa.-Testimonies, Vol. 6, p. 437.IIO 212.3

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents